Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Àwọn Farisí”

“Ẹ Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Àwọn Farisí”

“Ẹ Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Àwọn Farisí”

Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí, èyí tí í ṣe àgàbàgebè.” (Lúùkù 12:1) Nínú orí Bíbélì míì tí Jésù ti sọ ọ̀rọ̀ tó jọ èyí, ó ṣe kedere pé “ẹ̀kọ́” àwọn Farisí ló ń dẹ́bi fún.—Mát. 16:12.

Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo “ìwúkàrà,” tàbí ohun tó ń mú kí ìyẹ̀fun wú, láti ṣàpẹẹrẹ ìdíbàjẹ́. Láìsí àní-àní, ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti ìwà wọn ní ipa tí kò dára lórí àwọn tó ń gbọ́rọ̀ wọn. Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisí fi léwu?

1 Àwọn Farisí máa ń gbéra ga torí pé wọ́n ka ara wọn sí olódodo, wọ́n sì máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn èèyàn tó jẹ́ gbáàtúù.

Ti pé àwọn Farisí jẹ́ olódodo lójú ara wọn yìí fara hàn nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jésù. Ó sọ pé: “Farisí náà dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gba nǹkan wọ̀nyí ní àdúrà sí ara rẹ̀, ‘Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé èmi kò rí bí àwọn ènìyàn yòókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòdodo, panṣágà, tàbí bí agbowó orí yìí pàápàá. Mo ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́sẹ̀, mo ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní.’ Ṣùgbọ́n agbowó orí tí ó dúró ní òkèèrè kò fẹ́ láti gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run pàápàá, ṣùgbọ́n ó sáà ń lu igẹ̀ rẹ̀ ṣáá, ó ń wí pé, ‘Ọlọ́run, fi oore ọ̀fẹ́ hàn sí èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’”—Lúùkù 18:11-13.

Jésù gbóríyìn fún agbowó orí yẹn nítorí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó hù. Ó ní: “Mo sọ fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ẹni tí a fi hàn ní olódodo ju [Farisí] yẹn; nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óò tẹ́ lógo, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.” (Lúùkù 18:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìṣòótọ́ ni àwọn èèyàn mọ àwọn agbowó orí sí, Jésù wá bó ṣe lè ran àwọn tó bá tẹ́tí sí i nínú wọn lọ́wọ́. Ó kéré tán, àwọn agbowó orí méjì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àwọn ni Mátíù àti Sákéù.

Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé à ń ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ torí àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa tàbí àwọn àǹfààní kan tá a ní tàbí nítorí àwọn àṣìṣe àti àìlera wọn ńkọ́? A gbọ́dọ̀ yára mú irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn, torí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ìfẹ́ a máa mú suuru, a máa ṣe oore. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kì í fọ́nnu. Ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í hu ìwà ìmọ-ti-ara-ẹni-nìkan. Kì í tètè bínú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn. Ìfẹ́ kì í fi ohun buburu ṣe ayọ̀, ṣugbọn a máa yọ̀ ninu òtítọ́.”—1 Kọ́r. 13:4-6, Ìròhìn Ayọ̀.

Ńṣe ló yẹ ká fi ìwà jọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Lẹ́yìn tó ti sọ pé “Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là,” ó fi kún un pé: “Nínú àwọn wọ̀nyí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.”—1 Tím. 1:15.

Àwọn ìbéèrè tó yẹ ká ronú lé lórí:

Ǹjẹ́ mo mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí àti pé nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ni mo fi lè rí ìgbàlà? Àbí ńṣe ni mo máa ń ronú pé mo sàn ju àwọn míì lọ torí pé ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀, torí àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí mo ní nínú ètò Ọlọ́run tàbí nítorí àwọn ẹ̀bùn àbímọ́ni kan?

2 Àwọn Farisí máa ń pe àfiyèsí síra wọn nípa fífi ara wọn hàn bí olódodo ní gbangba. Wọ́n máa ń wá ipò ọlá àti àwọn orúkọ oyè táá mú kí àwọn èèyàn kà wọ́n sí ẹni pàtàkì.

Àmọ́, Jésù kìlọ̀ pé: “Gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni wọ́n ń ṣe kí àwọn ènìyàn lè rí wọn; nítorí wọ́n mú àwọn akóló ìkó-ìwé-mímọ́-sí fẹ̀, èyí tí wọ́n ń dè mọ́ ara láti fi ṣe ìṣọ́rí, wọ́n sì sọ ìṣẹ́tí ẹ̀wù wọn di títóbi. Wọ́n fẹ́ ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù, àti ìkíni ní àwọn ibi ọjà àti kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní Rábì.” (Mát. 23:5-7) Ìwà wọn yàtọ̀ pátápátá sí ti Jésù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni tó sì jẹ́ ẹni pípé, ó níwà ìrẹ̀lẹ̀. Nígbà tí ọkùnrin kan báyìí pe Jésù ní “ẹni rere,” Jésù sọ pé: “Èé ṣe tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.” (Máàkù 10:18) Ìgbà kan tún wà tí Jésù wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.—Jòh. 13:1-15.

Ó yẹ kí Kristẹni tòótọ́ kan máa sin àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Gál. 5:13) Èyí wá túbọ̀ ṣe pàtàkì fún àwọn tó bá fẹ́ kúnjú ìwọ̀n láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ. Ó dára kéèyàn máa “nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó,” àmọ́ ìfẹ́ tí ẹnì kan ní láti ran àwọn míì lọ́wọ́ ló yẹ kó sún un láti ní irú àfojúsùn bẹ́ẹ̀. “Ipò iṣẹ́” yìí kì í ṣe ipò ọlá tàbí ti agbára. Àwọn tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ “ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” bíi ti Jésù.—1 Tím. 3:1, 6; Mát. 11:29.

Àwọn ìbéèrè tó yẹ ká ronú lé lórí:

Ṣé kì í ṣe àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ nìkan ni mo máa ń ṣoore fún, bóyá torí kí n lè wà ní ipò àṣẹ tàbí kí n lè ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i? Ṣé kì í ṣe kìkì apá tó máa mú káwọn èèyàn mọ̀ mí kí wọ́n sì máa yìn mí ni mo máa ń gbájú mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Àbí, ṣe ni mo máa ń fẹ́ láti gbayì lójú àwọn èèyàn?

3 Òfin àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Farisí mú kí pípa Òfin Mósè mọ́ di ẹrù ìnira fún àwọn èèyàn tó jẹ́ gbáàtúù.

Inú Òfin Mósè ni gbogbo ìlànà nípa bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ṣe máa jọ́sìn Jèhófà wà. Àmọ́, Òfin náà kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Òfin náà sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì, àmọ́ kò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ohun tí wọ́n lè kà sí iṣẹ́ àti ohun tí wọn kò lè kà sí iṣẹ́. (Ẹ́kís. 20:10) Torí náà, àwọn Farisí wá ọ̀nà láti fi àwọn òfin wọn, àlàyé wọn àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn rọ́pò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí Òfin kò pèsè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò fara mọ́ àwọn òfin àdábọwọ́ tí àwọn Farisí gbé kalẹ̀, ó pa Òfin Mósè mọ́. (Mát. 5:17, 18; 23:23) Jésù kò rin kinkin mọ́ ohun tí Òfin sọ. Ó fi òye mọ ohun tí Òfin wà fún àti ìdí tó fi yẹ kéèyàn máa fi àánú hàn kó sì bá àwọn míì kẹ́dùn. Ó fi òye bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò, kódà nígbà tí wọ́n já a kulẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọ mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n wà lójúfò kí wọ́n sì máa ṣọ́nà ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un, síbẹ̀ wọ́n sùn lọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó fọ̀rọ̀ náà ro ara rẹ̀ wò, ó sì sọ pé: “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”—Máàkù 14:34-42.

Àwọn ìbéèrè tó yẹ ká ronú lé lórí:

Ṣé kì í ṣe pé mo máa ń wá bí mo ṣe máa gbé òfin àdábọwọ́ tàbí ìlànà ti ara mi kalẹ̀ tàbí kí n tiẹ̀ sọ èrò ti ara mi di òfin? Ǹjẹ́ ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ àwọn èèyàn fi hàn pé mo jẹ́ ẹni tó ń fi òye báni lò?

Ronú lórí bí ẹ̀kọ́ Jésù àti ti àwọn Farisí ṣe yàtọ̀ síra. Ǹjẹ́ o rí àwọn ọ̀nà tó o lè gbà sunwọ̀n sí i? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò ṣe pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn Farisí de àwọn akóló ìkó-ìwé-mímọ́-sí mọ́ ara.—Mát. 23:2, 5

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwọn Kristẹni tó jẹ́ alàgbà kì í ṣe bíi ti àwọn Farisí agbéraga, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wọn máa ń mú kí wọ́n sin àwọn ẹlòmíì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ṣé ìwọ náà máa ń fi òye bá àwọn èèyàn lò bí Jésù ti ṣe tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí ò ń retí látọ̀dọ̀ wọn?