Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Ọlọ́run “Ìgbà Àti Àsìkò”

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Ọlọ́run “Ìgbà Àti Àsìkò”

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Ọlọ́run “Ìgbà Àti Àsìkò”

“Ó . . . ń yí ìgbà àti àsìkò padà, ó ń mú àwọn ọba kúrò, ó sì ń fi àwọn ọba jẹ.”—DÁN. 2:21.

BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?

Báwo ni àwọn ohun tí Jèhófà dá àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ní ìmúṣẹ ṣe fi hàn pé Jèhófà ni Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà?

Ní báyìí tó ti dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run “ìgbà àti àsìkò,” kí ló yẹ kí èyí sún wa láti ṣe?

Kí nìdí tí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé àti ìwéwèé àwọn èèyàn kò fi lè yí àkókò tí Jèhófà ti ṣètò láti mú ète rẹ̀ ṣẹ pa dà?

1, 2. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ní òye kíkún nípa ohun tí àkókò jẹ́?

 TIPẸ́TIPẸ́ kí Jèhófà Ọlọ́run tó ṣẹ̀dá èèyàn ló ti ṣètò ọ̀nà tí a ó máa fi díwọ̀n àkókò. Ní ọjọ́ kẹrin ìṣẹ̀dá, Ọlọ́run sọ pé: “Kí orísun ìmọ́lẹ̀ wà ní òfuurufú ọ̀run láti mú ìpínyà wà láàárín ọ̀sán àti òru; wọn yóò sì wà fún àmì àti fún àwọn àsìkò àti fún àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún.” (Jẹ́n. 1:14, 19, 26) Kò sí àní-àní pé ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn, ó sì bá ìfẹ́ Jèhófà mu.

2 Àmọ́ títí di báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ń jiyàn lórí ohun tí àkókò jẹ́ gan-an. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé: “Àkókò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣòro jù lọ láti lóye láyé yìí. Kò sí ẹni tó lè sọ ohun tó jẹ́ gan-an.” Síbẹ̀, Jèhófà ní òye kíkún nípa ohun tí àkókò jẹ́. Ó ṣe tán, òun ni “Ẹlẹ́dàá ọ̀run, . . . Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀.” Jèhófà sì tún ni “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.” (Aísá. 45:18; 46:10) Kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè túbọ̀ lágbára, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ní ìmúṣẹ ṣe fi hàn pé Jèhófà ni Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà.

ÀWỌN OHUN TÍ ỌLỌ́RUN DÁ MÚ KÁ NÍ ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ OLÙPÀKÓKÒMỌ́ ŃLÁ NÁÀ

3. Báwo ni àkókò tí Ọlọ́run dá mọ́ àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí?

3 Àkókò tí Ọlọ́run dá mọ́ àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé máa ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí. Bí àpẹẹrẹ, àkókò tí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sọ lọ́jọ̀ sí ojú sánmà àti àwọn ìràwọ̀ fi ń lọ yí po lójú òfuurufú kò tíì yí pa dà rí. A lè mọ ibi tí wọ́n wà ní àkókò èyíkéyìí, ìyẹn sì ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìgbà tó wà nínú ọdún, ó tún máa ń jẹ́ kí àwọn atukọ̀ tàbí àwọn awakọ̀ òfuurufú mọ ibi tó yẹ kí wọ́n forí lé bí wọ́n bá ń rìnrìn-àjò. Ká sòótọ́, Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá àwọn ohun tá a fi ń díwọ̀n àkókò lọ́nà tó ṣe rẹ́gí yìí ní “okun inú nínú agbára,” ó sì yẹ ká máa yìn ín.—Ka Aísáyà 40:26.

4. Báwo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe hàn nínú bí ewéko, ẹyẹ àtàwọn ẹranko ṣe ń mọ àkókò?

4 A tún lè ṣàkíyèsí ìṣètò àkókò tó ṣe rẹ́gí nínú àwọn nǹkan bí ewéko, ẹyẹ àtàwọn ẹranko. Ohun kan wà tí Ọlọ́run dá mọ́ àwọn ewéko, ẹyẹ àtàwọn ẹranko, èyí tó dà bí aago tó sì máa ń darí wọn. Ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ ọ̀pọ̀ ẹyẹ máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ìgbà tó yẹ kí wọ́n ṣí kúrò ní ibi tí wọ́n wà lọ sí ibòmíì. (Jer. 8:7) Àwa èèyàn náà ní aago àdámọ́ni tiwa, wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] tó wà nínú ọjọ́ kan ló sì ń darí rẹ̀. Bí arìnrìn-àjò kan bá wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sí ibi tí aago wọn ti yàtọ̀ sí ti ibi tó ti ń bọ̀, ó lè tó ọjọ́ mélòó kan kí ara rẹ̀ tó bá àkókò ibẹ̀ mu. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan tí Ọlọ́run dá ni à ń rí àpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àkókò lára wọn, èyí sì ń jẹ́ ká rí agbára àti ọgbọ́n Ọlọ́run “ìgbà àti àsìkò.” (Ka Sáàmù 104:24.) Bẹ́ẹ̀ ni o, Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà ní ọgbọ́n àti agbára tó ju ti ẹ̀dá èyíkéyìí lọ fíìfíì. Ó dá wa lójú pé ó máa ṣe gbogbo ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe.

ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ TÓ NÍ ÌMÚṢẸ LÁSÌKÒ Ń FÚN ÌGBÀGBỌ́ LÓKUN

5. (a) Ọ̀nà kan ṣoṣo wo la lè gbà mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú àwa èèyàn? (b) Kí ló mú kí Jèhófà lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé?

5 Àwọn ohun tí Jèhófà dá jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa “àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí,” àmọ́ wọn kò dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì irú bíi, Kí ló ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn lọ́jọ́ iwájú? (Róòmù 1:20) Inú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti lè rí ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Tá a bá ṣàyẹ̀wò Bíbélì, a máa rí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ní ìmúṣẹ ní àkókò pàtó tó yẹ kí wọ́n ní ìmúṣẹ! Jèhófà lè sọ àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀ torí pé ó mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́nà pípé. Láfikún sí i, ohun tí Ìwé Mímọ́ bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ máa ń ní ìmúṣẹ lásìkò tó yẹ torí pé Jèhófà Ọlọ́run lè mú kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ àti ní ìbámu pẹ̀lú àkókò tí ó là sílẹ̀.

6. Kí ló fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká lóye ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì?

6 Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó ń jọ́sìn òun lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́, kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣe wọ́n láǹfààní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú tí àwa èèyàn fi ń wo àkókò kọ́ ni Ọlọ́run fi ń wò ó, síbẹ̀ tó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun kan máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò pàtó kan, ọ̀nà tá a máa gbà lóyè rẹ̀ ló máa ń gbà sọ ọ́. (Ka Sáàmù 90:4.) Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa “àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin” tí “a ti múra sílẹ̀ fún wákàtí àti ọjọ́ àti oṣù àti ọdún.” Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà díwọ̀n àkókò yìí rọrùn fún àwa èèyàn láti lóye. (Ìṣí. 9:14, 15) Bí a sì ṣe ń rí i tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ń ní ìmúṣẹ ní àkókò pàtó tó yẹ kí wọ́n ní ìmúṣẹ yìí yẹ kó fún ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run “ìgbà àti àsìkò” àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lókun. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

7. Báwo ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà nípa Jerúsálẹ́mù àti Júdà ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà?

7 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọ̀rọ̀ Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà tọ “Jeremáyà wá nípa gbogbo àwọn ènìyàn Júdà ní ọdún kẹrin Jèhóákímù ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà.” (Jer. 25:1) Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun Jerúsálẹ́mù àti bí wọ́n ṣe máa kó àwọn Júù nígbèkùn láti ilẹ̀ Júdà lọ sí ìlú Bábílónì. Bí wọ́n bá débẹ̀, wọ́n máa “sin ọba Bábílónì fún àádọ́rin ọdún.” Àwọn ọmọ ogun Bábílónì pa ìlú Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n sì kó àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ Júdà lọ sí ìlú Bábílónì. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí àádọ́rin [70] ọdún náà bá pé? Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní ìbámu pẹ̀lú lílo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí yín, dájúdájú, èmi yóò fìdí ọ̀rọ̀ rere mi múlẹ̀ fún yín, láti mú yín padà wá sí ibí yìí.’” (Jer. 25:11, 12; 29:10) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ lásìkò náà gẹ́lẹ́, ìyẹn lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn tí àwọn ará Mídíà àti Páṣíà dá àwọn Júù sílẹ̀ kúrò ní ìlú Bábílónì.

8, 9. Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa bíbọ̀ Mèsáyà àti ìgbékalẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run “ìgbà àti àsìkò”?

8 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ míì tó kan àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́. Nígbà tó ku nǹkan bí ọdún méjì kí àwọn Júù kúrò ní ìlú Bábílónì, Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa fara hàn ní ọ̀rìnlénírínwó ọdún ó lé mẹ́ta [483] lẹ́yìn tí wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n tún Jerúsálẹ́mù kọ́. Ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ọba Mídíà òun Páṣíà pa àṣẹ náà. Nígbà tí ọ̀rìnlénírínwó ọdún ó lé mẹ́ta náà sì pé gẹ́lẹ́, ìyẹn ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù ará Násárétì nígbà tó ṣe ìrìbọmi, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di Mèsáyà. *Neh. 2:1, 5-8; Dán. 9:24, 25; Lúùkù 3:1, 2, 21, 22.

9 Ní báyìí wá kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Ìjọba náà. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run máa gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “àmì” wíwàníhìn-ín Jésù, ó sì tọ́ka sí ìgbà tí wọ́n máa lé Sátánì kúrò ní ọ̀run, èyí tó máa yọrí sí ègbé fún ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:3-14; Ìṣí. 12:9, 12) Síwájú sí i, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tọ́ka sí àkókò náà gan-an tí èyí máa ṣẹlẹ̀, ìyẹn ní ọdún 1914, nígbà tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi pé” tí Ìjọba Ọlọ́run yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọ̀run.—Lúùkù 21:24; Dán. 4:10-17. *

10. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú wo ló dájú pé ó máa wáyé ní àkókò tó yẹ kó wáyé gẹ́lẹ́?

10 Ohun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ayé báyìí ni “ìpọ́njú ńlá” tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Ohun tó máa tẹ̀ lé e ni Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Kò sí àní-àní pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa wáyé ní àkókò tí Ọlọ́run ti pinnu. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, Jèhófà ti pinnu “ọjọ́ àti wákàtí” tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yóò wáyé.—Mát. 24:21, 36; Ìṣí. 20:6.

‘Ẹ MÁA RA ÀKÓKÒ TÍ Ó RỌGBỌ PA DÀ’

11. Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé, ipa wo ló yẹ kó ní lórí wa?

11 Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àti pé a ti ń gbé ní “àkókò òpin,” ipa wo ló yẹ kí ìyẹn ní lórí wa? (Dán. 12:4) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kíyè sí i pé ńṣe ni ayé yìí ń bà jẹ́ sí i, síbẹ̀ kò yé wọn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ló ń ní ìmúṣẹ. Wọ́n lè máa retí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo nǹkan á dojú rú pátápátá tàbí kí wọ́n gbà pé lọ́nà kan ṣá ìsapá àwọn èèyàn yóò mú “àlàáfíà àti ààbò” wá. (1 Tẹs. 5:3) Àmọ́, kí ni èrò tiwa nípa ayé yìí? Tá a bá gbà pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé Sátánì là ń gbé yìí àti pé òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìyẹn mú ká máa lo àkókò tó ṣẹ́ kù láti fi ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run “ìgbà àti àsìkò” ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́n? (2 Tím. 3:1) Ó yẹ ká ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nípa bí a ṣe ń lo àkókò wa.—Ka Éfésù 5:15-17.

12. Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ọjọ́ Nóà?

12 Kò rọrùn láti ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’ nínú ayé tó kún fún àwọn ohun tó ń fa ìpínyà ọkàn yìí. Jésù kìlọ̀ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” Báwo ni àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí? Ọlọ́run ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ayé ìgbà yẹn máa pa run. Ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn burúkú máa kú sínú àkúnya omi tó kárí ayé. Níwọ̀n bí Nóà ti jẹ́ “oníwàásù òdodo,” ó fi ìṣòtítọ́ polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀. (Mát. 24:37; 2 Pét. 2:5) Àmọ́ ńṣe ni “wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, . . . wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” Torí náà, Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mát. 24:38, 39, 44) Ẹ jẹ́ ká dà bíi Nóà, ṣùgbọ́n ká má ṣe fìwà jọ àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀. Kí ló máa jẹ́ ká lè wà ní ìmúratán?

13, 14. Kí ló yẹ ká máa rántí nípa Jèhófà, èyí tó máa jẹ́ ká lè máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín bá a ti ń dúró de bíbọ̀ Ọmọ ènìyàn?

13 Lóòótọ́ wákàtí tí a kò ronú pé yóò jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa rántí pé Jèhófà ni Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà. Kì í ṣe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé tàbí ìwéwèé àwọn èèyàn ló ń pinnu ìgbà tí Jèhófà máa ṣe nǹkan. Jèhófà lágbára láti darí àkókò àti ibi tí àwọn ọ̀ràn máa yọrí sí kí àwọn ohun tó ní lọ́kàn lè ní ìmúṣẹ. (Ka Dáníẹ́lì 2:21.) Kódà Òwe 21:1 sọ fún wa pé: “Ọkàn-àyà ọba dà bí ìṣàn omi ní ọwọ́ Jèhófà. Ibi gbogbo tí ó bá ní inú dídùn sí, ni ó ń darí rẹ̀ sí.”

14 Jèhófà lè mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé kó bàa lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, kí wọ́n sì ṣẹlẹ̀ lásìkò tó fẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ìyípadà pípabanbarì tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ, ní pàtàkì jù lọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kan iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tó para pọ̀ di Soviet Union tẹ́lẹ̀rí pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ìwọ̀nba èèyàn ló lè gbà gbọ́ pé irú ìyípadà pípabanbarì yìí lè wáyé kíákíá bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àbájáde àwọn ìyípadà yẹn ni pé, a ti wá ń wàásù ìhìn rere jákèjádò ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ti fi òfin de iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà kan. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ra àkókò pa dà ká lè máa fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run “ìgbà àti àsìkò.”

NÍ ÌGBÀGBỌ́ PÉ JÈHÓFÀ MÁA MÚ ÈTE RẸ̀ ṢẸ NÍ ÀKÓKÒ TÓ TI PINNU

15. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run?

15 Ká lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nìṣó ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà máa mú ète rẹ̀ ṣẹ ní àkókò tó ti pinnu. Bí ipò àwọn nǹkan ṣe ń yí pa dà nínú ayé lè mú ká ṣe àwọn àyípadà kan nínú ọ̀nà tí à ń gbà ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ètò Ọlọ́run lè ṣe àwọn àtúnṣe táá mú ká lè máa bá iṣẹ́ kíkéde Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe nìṣó. Tá a bá ń fara mọ́ irú àwọn àtúnṣe bẹ́ẹ̀ ní kíkún tá a sì ń fi ìdúróṣinṣin ṣe iṣẹ́ ìsìn wa bí Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ “orí ìjọ” ṣe ń darí wa, ńṣe là ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run “ìgbà àti àsìkò.”—Éfé. 5:23.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́?

16 Jèhófà fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun nígbà gbogbo, ká sì fọkàn tán òun pátápátá pé òun máa pèsè “ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” (Héb. 4:16) Ǹjẹ́ ìyẹn kò fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ Jèhófà lógún? (Mát. 6:8; 10:29-31) À ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run tá a bá ń gbàdúrà déédéé pé kó ràn wá lọ́wọ́, tá à ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àdúrà wa, tá a sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Láfikún sí i, ẹ jẹ́ ká máa rántí láti gbàdúrà fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.

17, 18. (a) Kí ni Jèhófà máa ṣe fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ láìpẹ́ láìjìnnà? (b) Ìdẹkùn wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún?

17 Àkókò yìí kọ́ ló yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí í “mikàn nínú àìnígbàgbọ́,” kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ ká di alágbára nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. (Róòmù 4:20) Ọ̀tá Ọlọ́run ni Sátánì àtàwọn tó wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀, wọ́n sì ń gbìyànjú láti ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ tí Jésù gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ lọ́wọ́. (Mát. 28:19, 20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èṣù ń gbéjà kò wá, síbẹ̀ a mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn, ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.” Ó mọ bó ṣe máa “dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.”—1 Tím. 4:10; 2 Pét. 2:9.

18 Jèhófà máa pa ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí run láìpẹ́ láìjìnnà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò tíì fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tí kò sì tíì sọ àkókò pàtó tí èyí máa wáyé, ó dá wa lójú pé Kristi máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá Jèhófà run ní àkókò tí ó tọ́, Jèhófà yóò sì dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run láre. Torí náà, àṣìṣe ńlá ló máa jẹ́ fún wa bí a kò bá fi òye mọ “àwọn ìgbà àti àwọn àsìkò” tá a wà báyìí! Ǹjẹ́ ká má ṣe kó sínú ìdẹkùn ríronú pé “ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.”—1 Tẹs. 5:1; 2 Pét. 3:3, 4.

“FI Ẹ̀MÍ ÌDÚRÓDENI HÀN”

19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn fún Jèhófà?

19 Ara ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ìran èèyàn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ òun tó lẹ́wà títí gbére. Oníwàásù 3:11 sọ pé: “Ohun gbogbo ni [Jèhófà] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀. Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”

20 Inú wá mà dùn gan-an ni o pé Jèhófà kò tíì yí ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún àwa èèyàn pa dà! (Mál. 3:6) ‘Kò sí àyídà ìyípo òjìji’ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Ják. 1:17) Kì í ṣe ohun tí àwa èèyàn fi ń díwọ̀n àkókò, irú bí ayé ṣe ń yí po, ni Ọlọ́run fi ń díwọ̀n àkókò tó máa ṣe àwọn nǹkan. “Ọba ayérayé” ni Jèhófà. (1 Tím. 1:17) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa “fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà [wa].” (Míkà 7:7) Àní, kí ẹ “jẹ́ onígboyà, kí ọkàn-àyà yín sì jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin tí ń dúró de Jèhófà.”—Sm. 31:24.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Dáníẹ́lì ní ìgbàgbọ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run máa ní ìmúṣẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ǹjẹ́ ò ń lo àkókò rẹ lọ́nà tí ó tọ́ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà?