Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Sún Mọ́ Àwọn Àgbàlagbà Tí Wọ́n Jẹ́ Ọlọgbọ́n

Mo Sún Mọ́ Àwọn Àgbàlagbà Tí Wọ́n Jẹ́ Ọlọgbọ́n

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Sún Mọ́ Àwọn Àgbàlagbà Tí Wọ́n Jẹ́ Ọlọgbọ́n

Gẹ́gẹ́ bí Elva Gjerde ṣe sọ ọ́

Ní nǹkan bí àádọ́rin [70] ọdún sẹ́yìn, àlejò kan wá sí ilé wa, ó dá àbá kan fún Bàbá mi, àbá náà ló sì yí ìgbésí ayé mi pa dà pátápátá. Láti ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, àwọn èèyàn mélòó kan tún ti ní ipa lórí ìgbésí ayé mi. Nípasẹ̀ èyí, mo ti ní ọ̀rẹ́ àtàtà kan tí mo mọyì àjọṣe mi pẹ̀lú rẹ̀ ju ohunkóhun mìíràn lọ. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.

ỌDÚN 1932 ni wọ́n bí mi ní ìlú Sydney lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Àwọn òbí mi gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ wọn kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Màmá mi kọ́ mi pé gbogbo ohun téèyàn ń ṣe ni Ọlọ́run ń rí, ó sì ṣe tán láti fìyà jẹ mí bí mo bá ṣàìgbọràn. Èyí mú kí n máa bẹ̀rù Ọlọ́run. Síbẹ̀, ohun tó wà nínú Bíbélì fà mí mọ́ra. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n màmá mi obìnrin bá wá sọ́dọ̀ wa láwọn òpin ọ̀sẹ̀, wọ́n máa ń sọ àwọn ìtàn alárinrin tó wà nínú Bíbélì fún mi. Ńṣe ni mo máa ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí wọ́n tún máa wá.

Nígbà tí mi ò tíì pé ọmọ ogún ọdún, bàbá mi máa ń ka ọ̀wọ́ àwọn ìwé kan tí màmá mi gbà lọ́wọ́ ìyá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí bàbá mi kà nínú àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni náà wú wọn lórí gan-an débi pé wọ́n gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n ń kọ́ bàbá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, wọ́n rí mi tí mò ń kẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n tiẹ̀ fẹ́ lé mi pa dà lọ sùn, àmọ́ àlejò náà sọ pé, “Ẹ ò ṣe jẹ́ kí Elva jókòó tì wá?” Àbá tí àlejò yẹn dá ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tuntun, ó sì tún mú kí n di ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí èmi àti bàbá mi fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Ẹ̀kọ́ tí bàbá mi ń kọ́ mú kí wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn. Wọ́n tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í káwọ́ ìbínú wọn. Èyí ló sún ìyá mi àti Frank ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé. * Àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tẹ̀ síwájú, nígbà tó yá, a ṣe ìrìbọmi, a sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Látìgbà yẹn wá, ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ti ní ipa tó dára lórí ìgbésí ayé mi bí mo ṣe ń dàgbà.

NÍGBÀ TÍ MO FẸ́ PINNU OHUN TÍ MO MÁA FI AYÉ MI ṢE

Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, mo sún mọ́ àwọn àgbàlagbà tí wọ́n wà nínú ìjọ wa. Ọ̀kan lára wọn ni Alice Place, arábìnrin àgbàlagbà kan tó kọ́kọ́ wá wàásù fún ìdílé wa. Ńṣe ni wọ́n dà bí ìyá àgbà fún mi. Àwọn ni wọ́n kọ́ mi bí mo ṣe lè máa wàásù, wọ́n sì tún gbà mí níyànjú láti tẹ̀ síwájú kí n lè ṣe ìrìbọmi. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], mo ṣe ìrìbọmi.

Mo tún sún mọ́ tọkọtaya àgbàlagbà kan tí wọ́n ń jẹ́ Percy àti Madge [Margaret] Dunham. Àjọṣe mi pẹ̀lú wọn ní ipa tó pọ̀ lórí ọjọ́ ọ̀la mi. Mo fẹ́ràn ìṣirò, mo sì ti pinnu pé mo máa di ẹni tó ń kọ́ni ní ìṣirò. Arákùnrin àti arábìnrin Dunham ti sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Latvia láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1939. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n pè wọ́n pé kí wọ́n wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Ọsirélíà tó wà ní ìgbèríko kan tó jìnnà sí ìlú Sydney. Ọ̀rọ̀ mi jẹ tọkọtaya yìí lógún gan-an. Wọ́n sọ ọ̀pọ̀ ìrírí alárinrin tí wọ́n ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Èyí sì mú kí n rí i pé kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń tẹ́ni lọ́rùn ju kíkọ́ni ní ìṣirò lọ. Nítorí náà, mo pinnu pé èmi náà máa di míṣọ́nnárì.

Kí n lè máa múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì, Arákùnrin àti Arábìnrin Dunham gbà mí níyànjú pé kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà. Torí náà, ní ọdún 1948, nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́ mẹ́wàá tó ń fi tayọ̀tayọ̀ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà nínú ìjọ wa ní ìgbèríko Hurstville, ní ìlú Sydney.

Láwọn ọdún mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, mo ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní àwọn ìlú mẹ́rin kan tó wà ní ìpínlẹ̀ New South Wales àti Queensland. Ọ̀kan lára àwọn tí mo kọ́kọ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Betty Law (ó ti di Betty Remnant báyìí). Ọmọbìnrin náà láájò, ó sì fi ọdún méjì jù mí lọ. Nígbà tó yá, èmi pẹ̀lú rẹ̀ la jọ wá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Cowra tó wà ní nǹkan bí òjìlérúgba ó dín mẹ́wàá [230] kìlómítà sí apá ìwọ̀ oòrùn ìlú Sydney. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà díẹ̀ ni èmi àti Betty fi jọ ṣiṣẹ́ pọ̀, ọ̀rẹ́ ṣì ni wá títí dòní.

Nígbà tí wọ́n ní kí n lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, mo kó lọ sí ìlú Narrandera tó wà ní nǹkan bí okòólérúgba [220] kìlómítà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Cowra. Arábìnrin Joy Lennox (ó ti di Joy Hunter báyìí), ni alábàáṣiṣẹ́ mi tuntun. Òun náà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà onítara, ó sì tún fi ọdún méjì jù mí lọ. Àwa méjèèjì nìkan la jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní ìlú yẹn. Ilé àwọn tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Ray àti Esther Irons ni èmi àti Joy ń gbé, wọ́n sì lawọ́ gan-an. Tọkọtaya náà, ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́. Inú oko tí wọ́n ti ń sin àgùntàn tí wọ́n sì ti ń ṣọ̀gbìn àlìkámà ni Ray àti ọmọkùnrin wọn ti máa ń ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀, Esther àti àwọn ọmọbìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì ní ilé kan tí wọ́n ń fi àwọn èèyàn wọ̀ sí ládùúgbò. Ní àwọn ọjọ́ Sunday, èmi àti Joy máa ń se oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ìdílé Irons àti àwọn lébìrà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó méjìlá tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ rélùwéè, tí wọ́n sì máa ń wọ̀ sọ́dọ̀ wọn, ebi á sì ti máa pa àwọn òṣìṣẹ́ yìí gan-an. Iṣẹ́ tí à ń ṣe yìí la fi ń dí díẹ̀ lára owó ilé wa. Lẹ́yìn tá a bá sì ti palẹ̀ mọ́, a máa ń fún ìdílé Irons ní oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀, ìyẹn ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń ṣe pẹ̀lú wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Ray, ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wá sínú òtítọ́, wọ́n sì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ wà nínú Ìjọ Narrandera.

Ní ọdún 1951, mo lọ sí àpéjọ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe ní ìlú Sydney. Níbẹ̀ ni mo ti lọ sí ìpàdé àkànṣe kan tí wọ́n ṣe pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Abẹ́ àtíbàbà ńlá kan la ti ṣe ìpàdé náà, àwa tá a sì wá síbẹ̀ lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300]. Arákùnrin Nathan Knorr tó wá láti Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ló bá wa sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà, ó sì ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó láti mú ìhìn rere dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ la tẹ́tí sí kínníkínní. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ní gúúsù Òkun Pàsífíìkì àtàwọn àgbègbè míì. Inú mi dùn púpọ̀ pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́tàdínlógún tí wọ́n pè láti ilẹ̀ Ọsirélíà sí kíláàsì kọkàndínlógún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1952. Ọmọ ogún [20] ọdún ni mí nígbà tí ọwọ́ mi tẹ iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì tó jẹ́ àfojúsùn mi!

NÍGBÀ TÍ MO NÍ LÁTI YÍ OJÚ TÍ MO FI Ń WO NǸKAN PA DÀ

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìbákẹ́gbẹ́ tí mo ní nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì mú kí ìmọ̀ tí mo ní nípa Bíbélì jinlẹ̀ sí i, ó fún ìgbàgbọ́ mi lókun, ó sì tún ní ipa tó lágbára lórí ìwà mi. Ọ̀dọ́ ni mí, tèmi ló sì máa ń yé mi, mi ò kì í fẹ́ ṣe àṣìṣe, ohun tí mo sì máa ń retí látọ̀dọ̀ àwọn míì náà nìyẹn. Nígbà míì, ọwọ́ tí mo fi ń mú nǹkan ti máa ń le koko jù. Bí àpẹẹrẹ, ẹnú yà mí nígbà kan tí mo rí Arákùnrin Knorr níbi tó ti ń gbá bọ́ọ̀lù ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì!

Àwọn olùkọ́ wa ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì tí wọ́n ní ìfòyemọ̀, tí wọ́n sì ti ń sìn látọjọ́ pípẹ́ ti ní láti rí i pé ńṣe ni mò ń tiraka kí n lè máa ṣe ohun tó tọ́. Wọ́n sún mọ́ mi, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè tún ìrònú mi ṣe. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó mọyì ohun tí à ń ṣe, tí kò sì le koko mọ́ wa tàbí kó máa béèrè ohun tó ju agbára wa lọ lọ́wọ́ wa. Lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi náà tún ràn mí lọ́wọ́. Mo rántí ọ̀kan nínú wọn tó sọ pé: “Elva, Jèhófà kò kó ẹgba dání láti máa fi nà wá. Nítorí náà, má máa le koko mọ́ ara rẹ jù!” Ọ̀rọ̀ tó rọra sọ wẹ́rẹ́ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni.

Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n rán èmi àtàwọn mẹ́rin míì lára àwọn tá a jọ wà ní kíláàsì lọ sí orílẹ̀-èdè Nàmíbíà nílẹ̀ Áfíríkà. Kò pẹ́ tí gbogbo wa fi bẹ̀rẹ̀ sí í darí ọgọ́rin [80] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo fẹ́ràn orílẹ̀-èdè Nàmíbíà àti iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì, àmọ́ èmi àti ọ̀kan lára àwọn tá a jọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ń fẹ́ra, orílẹ̀-èdè Switzerland ni wọ́n rán an lọ. Lẹ́yìn tí mo lo ọdún kan ní orílẹ̀-èdè Nàmíbíà, mo lọ bá àfẹ́sọ́nà mi ní orílẹ̀-èdè Switzerland. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, èmi àti ọkọ mi jọ máa ń lọ sí àwọn ìjọ tó ń bẹ̀ wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká.

NÍGBÀ TÍ ÌṢÒRO DÉ

Lẹ́yìn tí mo ti gbádùn wíwà pẹ̀lú ọkọ mi fún ọdún márùn-ún bó ṣe ń bẹ ìjọ wo gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, wọ́n pè wá sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Switzerland. Inú mi dùn gan-an pé mo wà láàárín ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ohun kan tó ń bani nínú jẹ́ gan-an fi ṣẹlẹ̀ sí mi. Mo rí i pé ọkọ mi ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi àti sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó já mi jù sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dùn mí wọra gan-an! Ì bá ṣòro fún mi gan-an láti fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bí kò bá sí ti àwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n ràn mí lọ́wọ́. Wọ́n máa ń fetí sí mi nígbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀, wọ́n á sì fún mi láyè kí n lè sinmi nígbà tó bá yẹ kí n fún ara nísinmi. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wọn àti bí wọ́n ṣe fi inú rere hàn sí mi ràn mí lọ́wọ́ nígbà ìṣòro tó kọjá àfẹnusọ yìí, ó sì tún mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

Mo tún rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo gbọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn látẹnu àwọn àgbàlagbà tí ọ̀pọ̀ àdánwò tí wọ́n dojú kọ ti sọ di ọlọgbọ́n. Lára irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni èyí tí Arábìnrin Madge Dunham sọ fún mi nígbà kan, ó ní: “Elva, bí o ṣe ń fi ìgbésí ayé rẹ sin Jèhófà, o máa kojú ọ̀pọ̀ àdánwò, àmọ́ ó lè jẹ́ ọ̀dọ̀ àwọn tó sún mọ́ ẹ jù lọ ni àdánwò tó le koko jù lọ ti máa wá. Nígbà tí àwọn àdánwò náà bá ń yọjú, rí i pé o sún mọ́ Jèhófà. Máa rántí pé Jèhófà lò ń sìn, kì í ṣe èèyàn aláìpé!” Ìmọ̀ràn arábìnrin yìí ló ń tọ́ mi sọ́nà láwọn ìgbà tí mo bá ní ìṣòro. Mo pinnu pé mi ò ní jẹ́ kí àṣìṣe ọkọ mi mú kí n fi Jèhófà sílẹ̀.

Nígbà tó yá, mo pinnu láti lọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà nítòsí àwọn ẹbí mi. Nígbà tí mo wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí mo wọ̀ pa dà sílé, mò ń gbádùn ìjíròrò Bíbélì tó lárinrin pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn èrò inú ọkọ̀ náà. Ọkùnrin jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Norway wà lára àwọn èrò inú ọkọ̀ náà, Arne Gjerde ni orúkọ rẹ̀. Ohun tó gbọ́ dùn mọ́ ọn nínú. Nígbà tó yá, Arne wá kí èmi àtàwọn èèyàn mi ní ìlú Sydney. Ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí yára gan-an, ó sì wá sínú òtítọ́. Èmi àti Arne ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 1963, a sì bí ọmọkùnrin wa Gary ní ọdún méjì lẹ́yìn náà.

NÍGBÀ TÍ MO TÚN FOJÚ WINÁ ÌṢÒRO MÍÌ

Èmi, ọkọ mi, àti Gary ọmọ wa láyọ̀, a sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ìdílé wa. Kò pẹ́ tí ọkọ mi fi mú kí ilé wa túbọ̀ ní àyè kí àwọn òbí mi tó ti dàgbà lè wá máa gbé pẹ̀lú wa. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tá a ṣègbéyàwó, a tún fojú winá ìṣòro míì. Àyẹ̀wò fi hàn pé ọkọ mi ní àrùn jẹjẹrẹ inú ọpọlọ. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń lọ wò ó ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń fi ẹ̀rọ kan tó ń lo ìtànṣán tọ́jú rẹ̀, ìtọ́jú náà sì gba àkókò gígùn. Ara rẹ̀ kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í yá, àmọ́ ipò rẹ̀ tún wá bẹ̀rẹ̀ sí í burú débi pé ó ní àrùn rọpárọsẹ̀. Wọ́n sọ fún mi pé ó máa kú ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan sí ìgbà yẹn. Àmọ́, ọkọ mi kò kú. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó padà sílé, mo sì rọra ń tọ́jú rẹ̀ títí tára rẹ̀ fi yá. Nígbà tó ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ó sì tún ń pa dà bójú tó ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Bó ṣe jẹ́ ọlọ́yàyà èèyàn tó sì mọ bá a ti í pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín, mú kí ara rẹ̀ tètè yá, ó sì tún mú kó rọrùn fún mi láti máa tọ́jú rẹ̀ nìṣó.

Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1986, àìsàn ọkọ mi tún wá burú sí i. Àwọn òbí mi ti kú nígbà yẹn, torí náà a kó lọ sí àgbègbè kan tó lẹ́wà tí wọ́n ń pè ní Blue Mountains èyí tó wà lẹ́yìn òde ìlú Sydney, èyí sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ wa. Nígbà tó yá, Gary ọmọ wa gbé ọmọbìnrin kan tó ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Karin níyàwó, wọ́n sì sọ pé ká wá máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Láàárín oṣù díẹ̀, gbogbo wa ṣí lọ sí ilé kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí àdúgbò tí èmi àti ọkọ mi ń gbé tẹ́lẹ̀.

Ní nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀ sígbà tí ọkọ mi kú, kò lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì mọ́, torí náà ó nílò ìtọ́jú lójú méjèèjì. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ilé ni mo máa ń wà ní gbogbo àsìkò yẹn, mo máa ń lo wákàtí méjì lójoojúmọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá sì ń lọ lọ́wọ́, mo máa ń rí ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nípa bí mo ṣe lè kojú ìṣòro mi. Àwọn tí wọ́n ti dàgbà nínú ìjọ wa tún máa ń wá kí mi, àwọn kan lára wọn sì ti ní irú ìṣòro yìí nígbà kan rí. Ìbẹ̀wò wọn máa ń mú kí ara mi yá gágá! Ọkọ mi kú ní oṣù April, ọdún 2003, ó sì ní ìrètí tó dájú pé òun máa jí dìde.

ÌTÌLẸ́YÌN TÓ GA JÙ LỌ TÍ MO RÍ GBÀ

Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, tèmi nìkan ló máa ń yé mi. Àmọ́ mo ti wá rí i pé nǹkan kì í fìgbà gbogbo rí bí èèyàn ṣe rò. Mo ti gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún, mo sì ti fara da ìṣòro méjì tó lágbára. Mo pàdánù ọkọ méjì, èyí àkọ́kọ́ ṣe panṣágà, ó já mi jù sílẹ̀, èkejì sì kú. Àmọ́ mo rí ìtọ́sọ́nà àti ìtùnú gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà. Síbẹ̀, ìtìlẹ́yìn tó ga jù lọ tí mo rí gbà jẹ́ láti ọ̀dọ̀ “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” náà, Jèhófà Ọlọ́run. (Dán. 7:9) Ìmọ̀ràn rẹ̀ ti mú kí n ṣe àtúnṣe ìwà mi, ó sì ti mú kí n ní àwọn ìrírí alárinrin nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Nígbà tí ìṣòro dé ‘Jèhófà fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ gbé mi ró, ìtùnú rẹ̀ sì ṣìkẹ́ ọkàn mi.’ (Sm. 94:18, 19) Mo tún ti gbádùn ìtìlẹ́yìn àti ìfẹ́ látọ̀dọ̀ ìdílé mi àti àwọn ‘alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.’ (Òwe 17:17) Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ ọlọgbọ́n ló sì pọ̀ jù nínú wọn.

Baba ńlá náà Jóòbù béèrè pé: “Ọgbọ́n kò ha wà láàárín àwọn àgbàlagbà àti òye nínú gígùn àwọn ọjọ́?” (Jóòbù 12:12) Ohun tí ojú mi ti rí sẹ́yìn jẹ́ kí n gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ìmọ̀ràn àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n ti ràn mí lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ ìtùnú wọn ti gbé mi ró, ìbákẹ́gbẹ́ tí mo ní pẹ̀lú wọn sì ti mú kí ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i. Inú mi dùn pé mo sún mọ́ wọn.

Ní báyìí tí mo ti pé ọgọ́rin [80] ọdún, èmi fúnra mi ti di àgbàlagbà. Ohun tí ojú mi ti rí máa ń jẹ́ kí n tètè lóye ohun tí àwọn àgbàlagbà ń fẹ́. Ó ṣì máa ń wù mí pé kí n lọ bẹ̀ wọ́n wò, kí n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, mo tún máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́. Bí wọ́n ṣe máa ń ta pọ́n-ún pọ́n-un máa ń dá mi lára yá, ìtara wọn sì máa ń ranni. Nígbà tí mo bá kíyè sí i pé àwọn ọ̀dọ́ ń gbìyànjú láti sún mọ́ mi fún ìtọ́sọ́nà tàbí ìtìlẹ́yìn, inú mi máa ń dùn láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Nígbà tó yá Frank Lambert, ẹ̀gbọ́n Elva di aṣáájú-ọ̀nà onítara ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn 1983 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 110 sí 112 sọ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ìrírí amóríyá tó ní nípa bó ṣe máa ń rìnrìn-àjò láti lọ ṣiṣẹ́ ìwàásù nígbà yẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ìgbà tí èmi àti Joy Lennox ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Narrandera

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Elva àtàwọn kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní orílẹ̀-èdè Switzerland lọ́dún 1960

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Mò ń tọ́jú Arne ọkọ mi nígbà tí ara rẹ̀ kò yá