Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ò Ń gbé Ògo Jèhófà Yọ?

Ǹjẹ́ Ò Ń gbé Ògo Jèhófà Yọ?

Ǹjẹ́ Ò Ń gbé Ògo Jèhófà Yọ?

“A ń . . . ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà bí i dígí.”​—2 KỌ́R. 3:18.

BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, báwo la ṣe lè máa fi ògo fún Jèhófà?

Báwo ni àwọn àdúrà wa àti lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ ṣe ń jẹ́ ká gbé ògo Ọlọ́run yọ?

Kí ni kò ní jẹ́ ká dẹ́kun láti máa fi ògo fún Jèhófà?

1, 2. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwa èèyàn lè máa fi àwọn ànímọ́ Jèhófà ṣèwà hù?

 GBOGBO wa la jọ àwọn òbí wa lọ́nà kan tàbí òmíràn. Torí náà, kì í yani lẹ́nu bí ẹnì kan bá sọ fún ọmọdékùnrin kan pé, ‘Bàbá rẹ lo jọ.’ Wọ́n lè sọ fún ọmọdébìnrin kan pé, ‘O mú mi rántí màmá rẹ.’ Ohun tí àwọn òbí bá ń ṣe sì làwọn ọmọ náà máa ń fẹ́ láti ṣe. Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ a lè fi ìwà jọ Baba wa ọ̀run, Jèhófà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò rí Jèhófà rí, a lè fi òye mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣíṣeyebíye tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tá à ń kíyè sí àwọn ohun tó dá, tá a sì ń ṣe àṣàrò lórí Ìwé Mímọ́, pàápàá jù lọ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run sọ àtàwọn ohun tó ṣe. (Jòh. 1:18; Róòmù 1:20) Ó ṣeé ṣe fún wa láti gbé ògo Jèhófà yọ.

2 Kí Ọlọ́run tó dá Ádámù àti Éfà, ó dá a lójú pé àwọn èèyàn á lè ṣàgbéyọ ohun tí òun ní lọ́kàn fún wọn, pé wọ́n á máa fi irú àwọn ànímọ́ tí òun ní ṣèwà hù àti pé wọn yóò máa fi ògo fún òun. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27.) Bá a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run, ó yẹ ká máa fi àwọn ànímọ́ Ẹni tó dá wa ṣèwà hù. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò ní àǹfààní láti máa gbé ògo Ọlọ́run yọ láìka àṣà ìbílẹ̀ wa, bá a ṣe kàwé tó, tàbí ẹ̀yà wa sí. Kí nìdí? Ìdí ni pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

3. Báwo ni iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe ń rí lára àwọn Kristẹni?

3 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń gbé ògo Jèhófà yọ. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tá a ti fi ẹ̀mí bí fi sọ pé: “Nígbà tí a ń fi ojú tí a kò fi ìbòjú bò ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà bí i dígí, gbogbo wa ni a sì ń pa lára dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo.” (2 Kọ́r. 3:18) Nígbà tí wòlíì Mósè ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti orí Òkè Sínáì tí àwọn wàláà tí wọ́n kọ Òfin Mẹ́wàá sí sì wà ní ọwọ́ rẹ̀, awọ ojú rẹ̀ ń mú ìtànṣán jáde torí pé Jèhófà ti bá a sọ̀rọ̀. (Ẹ́kís. 34:29, 30) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tíì ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni, tí awọ ojú wọn kì í sì í mú ìtànṣán jáde, síbẹ̀ ayọ̀ ń hàn lójú wọn bí wọ́n ṣe ń sọ fún àwọn èèyàn nípa Jèhófà, àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàwọn ohun àgbàyanu tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé. Bíi dígí ayé ìgbàanì tí wọ́n fi irin ṣe èyí tó máa ń kọ mọ̀nà, àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń gbé ògo Jèhófà yọ nínú ìgbésí ayé wọn àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. (2 Kọ́r. 4:1) Ǹjẹ́ ìwọ náà ń gbé ògo Jèhófà yọ nípa híhu ìwà tí inú Ọlọ́run dùn sí àti nínú ìgbòkègbodò rẹ gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń ṣe déédéé?

Ó WÙ WÁ PÉ KÁ MÁA GBÉ ÒGO JÈHÓFÀ YỌ

4, 5. (a) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ìṣòro wo ni gbogbo wa ń bá yí? (b) Ipa wo ni ẹ̀ṣẹ̀ ti ní lórí wa?

4 Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, kò sí àní-àní pé ó wù wá pé ká máa bọlá fún Ẹlẹ́dàá wa, ká sì máa fi ògo fún un nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà òdì kejì ohun tá a ní lọ́kàn la máa ń ṣe. Pọ́ọ̀lù náà dojú kọ irú ìṣòro yìí. (Ka Róòmù 7:21-25.) Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìdí tá a fi ní láti sapá lọ́nà yìí, ó ní: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Bẹ́ẹ̀ ni o, torí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù, gbogbo èèyàn ti di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tó dà bí ọba búburú tó ń jẹ gàba léni lórí.—Róòmù 5:12; 6:12.

5 Kí ni ẹ̀ṣẹ̀? Ẹ̀ṣẹ̀ ni ohunkóhun tó bá ti lòdì sí ànímọ́ Jèhófà, àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwọn ìlànà rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Ńṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ba àjọṣe tí èèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Bí ọfà ṣe máa ń tàsé ibi tí wọ́n bá ta á sí nígbà míì, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe é jẹ́ ká dójú ìlà ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ọ̀nà méjì la sì lè gbà dẹ́ṣẹ̀, yálà lọ́nà èèṣì tàbí ká mọ̀ọ́mọ̀. (Núm. 15:27-31) Ẹ̀ṣẹ̀ ti ní ipa tó lágbára gan-an lórí àwọn èèyàn ó sì ti mú kí wọ́n jìnnà sí Ẹlẹ́dàá wọn. (Sm. 51:5; Aísá. 59:2; Kól. 1:21) Nípa bẹ́ẹ̀, ìran èèyàn lápapọ̀ kò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Jèhófà, wọn kò sì ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti gbígbé ògo Ọlọ́run yọ. Dájúdájú, ẹ̀ṣẹ̀ ni àìlera tó burú jù lọ tó ń pọ́n aráyé lójú.

6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, báwo la ṣe lè máa fi ògo fún Ọlọ́run?

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, Jèhófà ti fi hàn pé òun jẹ́ “Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí.” (Róòmù 15:13) Ó ti ṣètò ọ̀nà tó máa gbà mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ìyẹn ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Tá a bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ náà, a kò ní jẹ́ “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀” mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni a óò máa gbé ògo Jèhófà yọ. (Róòmù 5:19; 6:6; Jòh. 3:16) Tí a kò bá jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó dájú pé a ó máa rí ìbùkún Jèhófà ní báyìí. Bákan náà a máa gbádùn àwọn ìbùkún míì lọ́jọ́ iwájú, a máa di ẹni pípé a ó sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Lóòótọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣì ni wá, àmọ́ ìbùkún àgbàyanu ló jẹ́ fún wa pé Ọlọ́run ń wò wá bí ẹni tó lè máa gbé ògo rẹ̀ yọ!

BÁ A ṢE LÈ MÁA GBÉ ÒGO ỌLỌ́RUN YỌ

7. Kí la gbọ́dọ̀ gbà nípa ara wa ká bàa lè máa gbé ògo Ọlọ́run yọ?

7 Ká bàa lè wà ní ipò tó tọ́ láti máa gbé ògo Ọlọ́run yọ, a gbọ́dọ̀ gbà ní tòótọ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. (2 Kíró. 6:36) Torí náà, a gbọ́dọ̀ gbà pé a ní ibi tá a kù sí, ká sì máa sapá láti ṣàtúnṣe, ká bàa lè tẹ̀ síwájú débi tí a ó fi lè máa fògo fún Ọlọ́run ní tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó ń tàbùkù síni nípa wíwo àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, a gbọ́dọ̀ pe orí ara wa wálé, ká wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ká sì ṣe ohun tó máa jẹ́ ká rí ìrànlọ́wọ́ náà gbà. (Ják. 5:14, 15) Èyí ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó yẹ ká gbé tá a bá fẹ́ máa bọlá fún Ọlọ́run lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò ara wa látìgbàdégbà ká lè mọ̀ bóyá à ń ṣe ohun tó bá àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run mu. (Òwe 28:18; 1 Kọ́r. 10:12) Ohun yòówù kó máa mú ká fẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀, gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa sapá láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ká bàa lè máa gbé ògo Ọlọ́run yọ.

8. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, kí ló yẹ ká ṣe?

8 Jésù ni ẹnì kan ṣoṣo tí kò jáwọ́ nínú ṣíṣe ohun tó dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, tó sì gbé ògo Ọlọ́run yọ títí tó fi kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í ṣe ẹni pípé bíi ti Jésù, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, a sì gbọ́dọ̀ sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Pét. 2:21) Jèhófà máa ń kíyè sí bá a ṣe ń sapá tó àti bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó sì máa ń bù kún ìsapá àtọkànwá wa ká lè máa fi ògo fún un.

9. Ipa wo ni Bíbélì ń kó nínú ìgbésí ayé àwọn Kristẹni tó ń sapá kí wọ́n lè dójú ìlà àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́?

9 Bíbélì tíì ṣe Ọ̀rọ̀ Jèhófà lè tànmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wa ká lè sunwọ̀n sí i. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́ ká sì tún máa ṣe àṣàrò nígbà tá a bá ka Bíbélì. (Sm. 1:1-3) Tá a bá ń ka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, ó máa jẹ́ ká lè sunwọ̀n sí i. (Ka Jákọ́bù 1:22-25.) Ìmọ̀ Bíbélì tá a ní ló jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́, òun ló sì ń fún ìpinnu wa láti máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lágbára àti láti máa ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí.—Sm. 119:11, 47, 48.

10. Báwo ni àdúrà ṣe lè mú ká túbọ̀ máa sin Jèhófà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?

10 Ká bàa lè máa gbé ògo Ọlọ́run yọ, a tún gbọ́dọ̀ máa “ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Ó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ ká máa sin òun lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Torí náà, ó tọ́ ká máa bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, kó fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i, kó fún wa lókun ká má bàa ṣubú sínú ìdẹwò àti pé kó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tím. 2:15; Mát. 6:13; Lúùkù 11:13; 17:5) Bí ọmọ kan ṣe ń gbára lé bàbá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí àwa náà máa gbára lé Jèhófà, Baba wa ọ̀run. Tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ máa sìn ín ní kíkún, a máa ní ìdánilójú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ronú pé ńṣe là ń yọ Jèhófà lẹ́nu! Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa yìn ín nínú àdúrà wa, ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ká máa wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ní pàtàkì nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò, ká sì máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín lọ́nà tó máa fi ògo fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.—Sm. 86:12; Ják. 1:5-7.

11. Báwo ni àwọn ìpàdé ìjọ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa gbé ògo Ọlọ́run yọ?

11 Ọlọ́run ti fi àbójútó àwọn àgùntàn rẹ̀ ṣíṣeyebíye sí ìkáwọ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45-47; Sm. 100:3) Ẹgbẹ́ ẹrú náà fẹ́ kí gbogbo wá máa gbé ògo Jèhófà yọ. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni òjíṣẹ́, àwọn ìpàdé wa máa ń tún ipò tẹ̀mí wa ṣe, bí aránṣọ kan ṣe máa ń bá wa tún aṣọ wa ṣe kó lè dùn ún wò lára wa. (Héb. 10:24, 25) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa tètè dé sí ìpàdé, torí pé bó bá ti mọ́ wa lára láti máa pẹ́ ká tó dé ìpàdé, a ó máa pàdánù díẹ̀, ó kéré tán, lára àtúnṣe tẹ̀mí tó pọn dandan pé ká rí gbà kí ìrísí wa lè sunwọ̀n sí i gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà.

Ẹ JẸ́ KÁ DI ALÁFARAWÉ ỌLỌ́RUN

12. Báwo la ṣe lè di aláfarawé Ọlọ́run?

12 Tá a bá fẹ́ máa gbé ògo Jèhófà yọ, a gbọ́dọ̀ “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfé. 5:1) Ọ̀nà kan tá a lè gbà di aláfarawé Ọlọ́run ni pé ká máa fi ojú tó fi ń wo nǹkan wò ó. Tá a bá ń gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ńṣe là ń tàbùkù sí i, a sì tún ń ṣe ìpalára fún ara wa. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Sátánì Èṣù ló ń darí ayé yìí, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè máa kórìíra àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra ká sì nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn ohun tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí. (Sm. 97:10; 1 Jòh. 5:19) Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú látọkànwá pé ọ̀nà títọ́ kan ṣoṣo tá a lè máa gbà sin Ọlọ́run ni pé ká máa ṣe ohun gbogbo fún ògo rẹ̀.—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:31.

13. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, kí ni èyí sì máa sún wa láti ṣe?

13 Jèhófà kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, àwa náà sì gbọ́dọ̀ kórìíra rẹ̀. Torí náà, ńṣe ló yẹ ká sá jìnnà pátápátá sí ohunkóhun tó lè máa mú ká hùwà àìtọ́. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ ta kété sí ìpẹ̀yìndà, torí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tí kò ní jẹ́ ká lè máa fi ògo fún Ọlọ́run. (Diu. 13:6-9) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká máa da ohunkóhun pọ̀ pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà tàbí ẹnikẹ́ni tó pe ara rẹ̀ ní arákùnrin àmọ́ tí kì í bọlá fún Ọlọ́run. Ohun tó yẹ ká ṣe náà nìyẹn bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé inú ìdílé wa ni onítọ̀hún wà. (1 Kọ́r. 5:11) Bí a bá ń gbìyànjú láti bá àwọn apẹ̀yìndà tàbí àwọn míì tí wọ́n ń ṣàríwísí ètò Jèhófà jiyàn, kò sí àǹfààní kankan tí ìyẹn máa ṣe fún wa. Ká sòótọ́, ó léwu fún wa nípa tẹ̀mí kò sì tún bójú mu pé ká máa tú ìsọfúnni wọn yẹ̀ wò, yálà a rí i nínú ìwé tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Ka Aísáyà 5:20; Mátíù 7:6.

14. Bá a ti ń sapá láti máa gbé ògo Ọlọ́run yọ, ànímọ́ pàtàkì wo ló yẹ ká ní, kí sì nìdí?

14 Ọ̀nà kan tó ta yọ tá a lè gbà fi ìwà jọ Baba wa ọ̀run ni pé ká máa fi ìfẹ́ hàn. Àwa náà gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ní ìfẹ́. (1 Jòh. 4:16-19) Ní ti gidi, ìfẹ́ tá a ní láàárín ara wa ń fi wá hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wá àti pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Jòh. 13:34, 35) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún lè fẹ́ nípa lórí wa, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ sapá láti borí rẹ̀, ká sì rí i pé à ń fi ìfẹ́ hàn nígbà gbogbo. Tá a bá ní ìfẹ́ àtàwọn ànímọ́ míì tí Ọlọ́run ní, kò ní jẹ́ ká máa ṣe ohun tí kò dáa kò sì ní jẹ́ ká máa dẹ́ṣẹ̀.—2 Pét. 1:5-7.

15. Báwo ni ìfẹ́ ṣe máa ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?

15 Ìfẹ́ máa ń mú kó wù wá láti ṣe ohun rere fún àwọn èèyàn. (Róòmù 13:8-10) Bí àpẹẹrẹ, ìfẹ́ tá a ní fún ọkọ tàbí aya wa kò ní jẹ́ ká sọ ibùsùn ìgbéyàwó wa di ẹlẹ́gbin. Ìfẹ́ tá a ní fún àwọn alàgbà, pa pọ̀ pẹ̀lú ojú pàtàkì tá a fi ń wo iṣẹ́ wọn, máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ onígbọràn, á sì jẹ́ ká máa tẹrí ba fún wọn. Àwọn ọmọ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn máa ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, wọ́n máa ń bọlá fún wọn, wọn kò sì ní máa sọ̀rọ̀ wọn láìdáa. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a kò ní máa wò wọ́n bíi pé wọn kò já mọ́ nǹkan kan tàbí ká máa sọ̀rọ̀ àrífín sí wọn. (Ják. 3:9) Àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn Ọlọ́run sì máa ń bá wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.—Ìṣe 20:28, 29.

16. Tá a bá ń fi ìfẹ́ hàn, báwo ló ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń wàásù?

16 Ó tún yẹ ká máa fi ìfẹ́ hàn lọ́nà tó ta yọ tá a bá ń wàásù. Nítorí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tá a ní sí Jèhófà, a kò ní rẹ̀wẹ̀sì bí àwọn èèyàn bá ń dágunlá tàbí tí wọ́n kọ̀ láti tẹ́tí sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni a ó máa bá a nìṣó láti máa wàásù ìhìn rere. Ìfẹ́ á mú ká máa múra sílẹ̀ dáadáa ká sì máa gbìyànjú láti jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa, a kò ní máa wo iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run bí iṣẹ́ tí kò gbádùn mọ́ni tàbí ojúṣe kan lásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá la ó máa kà á sí, a ó sì máa ṣe é tayọ̀tayọ̀.—Mát. 10:7.

MÁ ṢE DẸ́KUN LÁTI MÁA FI ÒGO FÚN JÈHÓFÀ

17. Kí nìdí tí gbígbà pé a ti kùnà ògo Ọlọ́run fi ń ṣe wá láǹfààní?

17 Àwọn èèyàn inú ayé lápapọ̀ kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí nǹkan kan, àmọ́ a kà á sí ní tiwa. Ìdí nìyẹn tá a fi mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ máa sa gbogbo ipá wa ká lè borí àwọn ohun tó máa ń mú ká fẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀. Tá a bá gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ó máa jẹ́ ká lè dá ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ kó bàa lè mú ká ṣe ohun tó tọ́ nígbà tó bá ń ṣe wá bíi pé ká dẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 7:22, 23) Lóòótọ́ o, a lè ní ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí, àmọ́ Ọlọ́run lè fún wa lókun láti ṣe ohun tó tọ́ nígbàkigbà tá a bá dojú kọ àdánwò.—2 Kọ́r. 12:10.

18, 19. (a) Kí ló máa jẹ́ ká lè borí ìjà tí à ń bá àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú jà? (b) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

18 Tá a bá fẹ́ máa fi ògo fún Jèhófà, a tún gbọ́dọ̀ máa bá àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú jà. Ohun ìjà tẹ̀mí tí Ọlọ́run ti fún wa máa jẹ́ ká lè borí nínú ìjà náà. (Éfé. 6:11-13) Sátánì ń jà fitafita kó lè gba ògo tó tọ́ sí Jèhófà nìkan. Èṣù tún ń sa gbogbo ipá rẹ̀ kó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ẹ ò rí i pé ojútì gbáà ló máa jẹ́ fún Sátánì bí àwa àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn aláìpé míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin àtàwọn ọmọdé bá pa ìwà títọ́ wa mọ́ sí Ọlọ́run tá a sì ń fi ògo fún un! Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa yin Jèhófà, bíi ti àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run, tí wọ́n fi ìtara sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”—Ìṣí. 4:11.

19 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí, a kò ní dẹ́kun láti máa fi ògo fún Jèhófà. Ó dájú pé inú rẹ̀ máa ń dùn pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn adúróṣinṣin ló ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun tí wọ́n sì ń gbé ògo òun yọ. (Òwe 27:11) Kí ìrònú tiwa náà sì jọ ti Dáfídì tó kọ ọ́ lórin pé: “Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, ṣe ni èmi yóò sì máa yin orúkọ rẹ lógo fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sm. 86:12) À ń fojú sọ́nà fún àkókò náà tí a óò máa gbé ògo Jèhófà yọ lọ́nà pípé tí a óò sì lè máa yìn ín títí láé! Ohun tí àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn máa gbádùn rẹ̀ nìyẹn, èyí sì máa fún wọn láyọ̀. Ṣé ìwọ náà ń gbé ògo Jèhófà Ọlọ́run yọ báyìí, tó o sì ní ìrètí láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí láé fáàbàdà?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ǹjẹ́ ò ń gbé ògo Jèhófà yọ láwọn ọ̀nà yìí?