Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Bí Mo Ṣe Fẹ́ Kó Rí Bẹ́ẹ̀ Náà Ló Rí”

“Bí Mo Ṣe Fẹ́ Kó Rí Bẹ́ẹ̀ Náà Ló Rí”

“Bí Mo Ṣe Fẹ́ Kó Rí Bẹ́ẹ̀ Náà Ló Rí”

Ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, Emilia, ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àmọ́, ó ní láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa bó ṣe máa ń láyọ̀ tó nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sì wù ú kó pa dà sẹ́nu iṣẹ́ náà.

Síbẹ̀, àkókò tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ Emilia ń gbà lọ́wọ́ rẹ̀ ti pọ̀ jù, ìyẹn kò sì fún un láyọ̀. Ìgbà kan wà tó kérora níṣojú àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ó sọ pé: “Ká ní àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ lè dín kù ni!” Ọ̀rọ̀ náà dé etígbọ̀ọ́ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá òótọ́ ló sọ bẹ́ẹ̀. Emilia sọ fún un pé òótọ́ lòun sọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe olùdarí ilé iṣẹ́ gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí i torí pé ìlànà ilé iṣẹ́ náà gba pé kí gbogbo òṣìṣẹ́ máa fi gbogbo ẹ̀mí wọn ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbà wọ́n fún. Arábìnrin wa gbára dì láti bá olùdarí ilé iṣẹ́ ṣèpàdé lórí ọ̀ràn náà, ó sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìgboyà.

Nígbà tí ìpàdé náà ń lọ lọ́wọ́, Emilia lo ìgboyà, ó sì fi ọgbọ́n sọ fún olùdarí ilé iṣẹ́ náà pé òun máa fẹ́ kí wọ́n bá òun dín àkókò tí òun fi ń ṣiṣẹ́ kù. Ó ṣàlàyé pé òun máa ń lo àkókò ìsinmi òun láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ó fi kún un pé: “Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò hùwà tó dára mọ́. Wọ́n nílò ẹni tó máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa hùwà ọmọlúwàbí tí wọ́n á sì máa tẹ̀ lé ìlànà, torí náà ọgbọ́n Ọlọ́run tí mo fi ń kọ́ wọn látinú Bíbélì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ gidigidi. Mi ò ní fẹ́ kí àwọn nǹkan tí mò ń ṣe lẹ́yìn iṣẹ́ mú kí n má lè ṣe iṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n níbí, àmọ́ mo máa nílò àkókò púpọ̀ sí i láti máa fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tí mo fi fẹ́ kẹ́ ẹ bá mi dín àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ kù.”

Olùdarí ilé iṣẹ́ náà tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa ó sì sọ pé òun náà ti ronú nígbà kan rí pé bóyá kí òun máa ran àwọn aláìlera àtàwọn òtòṣì lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: “Nítorí àwọn ìdí tó o kà sílẹ̀ yìí, mo lérò pé mo ní láti fara mọ́ ohun tó o béèrè fún. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ pé owó oṣù rẹ máa dín kù?” Emilia sọ pé òun mọ̀ bẹ́ẹ̀ àti pé bó bá pọn dandan, ńṣe lòun á jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn. Ó tún sọ pé: “Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ lára àfojúsùn mi ni pé kí n máa ṣe ohun tó ní láárí fún àwọn èèyàn.” Olùdarí ilé iṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Mo máa ń gba tàwọn tí kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan, tí wọ́n ń fi àkókò wọn ran àwọn míì lọ́wọ́.”

Kò tíì sí ẹnikẹ́ni tí wọ́n gbà síṣẹ́ nílé iṣẹ́ náà tí wọ́n tíì fún ní irú àǹfààní yẹn rí. Ní báyìí, wọ́n ti gbà pé kí Emilia máa fi ọjọ́ mẹ́rin péré ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀. Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà ló tún wá jẹ́ fún un pé wọ́n tún fi kún owó oṣù rẹ̀ tó fi jẹ́ pé owó tó ń gbà kò dín kú sí iye tí wọ́n ń san fún un tẹ́lẹ̀! Ó sọ pé: “Bí mo ṣe fẹ́ kó rí, bẹ́ẹ̀ náà ló rí, ó máa ṣeé ṣe fún mi láti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé!”

Ṣé ìwọ náà ti ronú nípa àtúnṣe tó o lè ṣe kó o bàa lè wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí kó o lè pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 32]

Olùdarí ilé iṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Mo máa ń gba tàwọn tí kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan, tí wọ́n ń fi àkókò wọn ran àwọn míì lọ́wọ́”