Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀

Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí Max Lloyd ṣe sọ ọ́

Ní alẹ́ ọjọ́ kan lọ́dún 1955, èmi àti ẹnì kan tá a jọ jẹ́ míṣọ́nnárì wà lẹ́nu iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Paraguay, ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù nígbà tí àwọn jàǹdùkú kan tínú ń bí yí ilé tá a wà ká tí wọ́n sì ń kígbe pé: “Òrìṣà tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ ni òrìṣà wa, ẹ̀jẹ̀ àwọn gringos ló sì ń fẹ́.” Báwo ni àwa gringos (àjèjì) ṣe dé ibẹ̀?

Ẹ JẸ́ kí n sọ bọ́rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni mo dàgbà sí, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Lọ́dún 1938, bàbá mi gba ìwé Enemies [Àwọn Ọ̀tá] lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan. Bàbá àti màmá mi kò gba tàwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní àgbègbè wa torí pé ìtàn àròsọ ni wọ́n ka àwọn apá kan nínú Bíbélì sí. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, àwọn òbí mi ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà. Láti ìgbà yẹn ni ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà ti di apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìdílé wa. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Lesley, tó fi ọdún márùn-ún jù mí lọ, ló ṣe ìrìbọmi tẹ̀ lé e, èmi náà sì ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1940 nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án.

Kété lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, wọ́n fòfin de títẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pípín in kiri lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ni mí, mo kọ́ bí màá ṣe máa fi Bíbélì nìkan ṣàlàyé ìgbàgbọ́ mi. Mo sọ ọ́ di àṣà láti máa mú Bíbélì lọ síléèwé, kí n lè máa fi han àwọn èèyàn ìdí tí mi ò fi ń kí àsíá orílẹ̀-èdè tàbí tí mi ò fi ń ṣagbátẹrù ogun tí wọ́n ń jà.—Ẹ́kís. 20:4, 5; Mát. 4:10; Jòh. 17:16; 1 Jòh. 5:21.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọléèwé wa kì í bá mi da nǹkan pọ̀ torí ẹni tó ń ṣe amí fún àwọn ará Jámánì ni wọ́n kà mí sí. Nígbà yẹn, wọ́n máa ń fi sinimá hàn wá níléèwé. Kó tó bẹ̀rẹ̀, ó yẹ kí olúkúlùkù dìde láti kọ orin orílẹ̀-èdè. Tí mi ò bá dìde, àwọn ọmọkùnrin méjì tàbí mẹ́ta yóò gbìyànjú láti fi irun orí mi fà mí dìde. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n lé mi kúrò ní iléèwé torí pé mi ò fi ìgbàgbọ́ mi tó dá lórí Bíbélì sílẹ̀. Àmọ́, ó ṣeé ṣe fún mi láti kàwé láti ilé nípasẹ̀ ìkọ̀wé-ránṣẹ́.

ÀFOJÚSÙN TÍ ỌWỌ́ MI TẸ̀ LẸ́YÌN-Ọ̀-RẸYÌN

Àfojúsùn mi ni pé màá di aṣáájú-ọ̀nà tí mo bá pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Torí náà, ó dùn mi gan-an nígbà tí àwọn òbí mi sọ fún mi pé mo ní láti kọ́kọ́ wá iṣẹ́ ṣe. Wọ́n tún fi dandan lé e pé kí n máa san owó yàrá tí mò ń gbé àti oúnjẹ tí mò ń jẹ, àmọ́ wọ́n ṣèlérí pé mo lè di aṣáájú-ọ̀nà tí mo bá ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún. Èyí ló mú kó jẹ́ pé gbogbo ìgbà la máa ń sọ̀rọ̀ nípa owó tó ń wọlé fún mi. Mo sọ pé ńṣe ni mo fẹ́ máa tọ́jú rẹ̀ nítorí ìgbà tí mo bá di aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ńṣe ni wọ́n máa ń gbà á lọ́wọ́ mi.

Nígbà tí àkókò tó fún mi láti di aṣáájú-ọ̀nà, àwọn òbí mi pè mí jókòó wọ́n sì ṣàlàyé fún mi pé ńṣe ni àwọn ń tọ́jú owó ti mò ń kó fún wọn sí báńkì. Wọ́n wá kó gbogbo rẹ̀ fún mi kí n lè fi ra aṣọ àtàwọn nǹkan míì tí mo nílò fún iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Wọ́n kọ́ mi láti máa bójú tó ara mi láìgbára lé ẹnikẹ́ni. Nígbà tí mo ronú pa dà sẹ́yìn, mo rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ yẹn ṣeyebíye gan-an ni.

Nígbà tí èmi àti Lesley ń dàgbà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà sábà máa ń dé sí ilé wa, a sì gbádùn lílọ sí òde ẹ̀rí pẹ̀lú wọn. Iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ìjẹ́rìí òpópónà àti dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la máa ń fi òpin ọ̀sẹ̀ wa ṣe. Ọgọ́ta [60] wákàtí làwọn akéde nínú ìjọ máa ń sapá láti lé bá lóṣooṣù ní àkókò yẹn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni màmá mi máa ń lé wákàtí yẹn bá, èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún èmi àti Lesley ẹ̀gbọ́n mi.

MO ṢE AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ NÍ ERÉKÙṢÙ TASMANIA

Erékùṣù Tasmania lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni mo ti kọ́kọ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ibẹ̀ ni ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Young ti ń sìn. Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi kúrò níbẹ̀ lọ sí kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dógún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ojú máa ń tì mí gan-an, mi ò sì tíì lọ gbé ibòmíì tó jìnnà sí ilé rí. Àwọn kan tiẹ̀ ń sọ pé mi ò lè lò ju oṣù mẹ́ta lọ níbẹ̀. Síbẹ̀, láàárín ọdún kan, ìyẹn lọ́dún 1950, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ, tí à ń pè ní olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà báyìí. Lẹ́yìn náà wọ́n yàn mí láti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, arákùnrin ọ̀dọ́ míì sì di alábàáṣiṣẹ́ mi.

Ìlú kan tó wà ní àdádó tí wọ́n ti ń wa bàbà ni wọ́n yàn wá sí, kò sì sí Ẹlẹ́rìí kankan níbẹ̀. Ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ni ọkọ̀ bọ́ọ̀sì gbé wa débẹ̀. Inú òtẹ́ẹ̀lì àtijọ́ kan báyìí la sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Lọ́jọ́ kejì, bá a ṣe ń lọ wàásù láti ilé dé ilé, à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tá a wàásù fún bóyá a lè rí yàrá kan tó ṣí sílẹ̀ gbà. Bí ilẹ̀ ọjọ́ yẹn ṣe ń ṣú lọ, ọkùnrin kan sọ fún wa pé kò séèyàn nínú ilé òjíṣẹ́ ìsìn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian, ó sì ní ká lọ bá díákónì tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀. Ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ọ̀yàn, ó sì gbà ká máa gbénú ilé náà. Àmọ́, ó máa ń rí bákan tá a bá ń jáde látinú ilé àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì láti lọ wàásù lójoojúmọ́.

Àwọn èèyàn máa ń tẹ́tí sọ́rọ̀ wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù náà. A máa ń ní ìjíròrò tó lárinrin pẹ̀lú àwọn èèyàn, a sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní olú ìlú mọ̀ nípa èyí, tí wọ́n sì tún gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé inú ilé òjíṣẹ́ ìsìn, wọ́n sọ fún díákónì pé kó lé wa jáde ní kíá mọ́sá. Bí ilé yẹn ṣe bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́ nìyẹn!

Lẹ́yìn tá a ti wàásù di ọ̀sán gan-gan ní ọjọ́ kejì, a bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi tá a máa sùn sí lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ibi táwọn òǹwòran máa ń jókòó sí ní pápá ìṣeré ni ibi tó dára jù lọ tá a rí. A wá ibì kan tọ́jú àwọn àpò aṣọ wa sí níbẹ̀, a sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ilẹ̀ ti fẹ́ máa ṣú, àmọ́ a pinnu láti dé àwọn ilé mélòó kan tó ṣẹ́ kù ní òpópónà yẹn. Ní ibì kan, ọkùnrin kan sọ pé ká wá máa gbénú ilé kékeré oníyàrá méjì tó wà ní ẹ̀yìnkùlé òun!

MO DI ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ MO SÌ LỌ SÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ

Lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí oṣù mẹ́jọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yìí, mo gba ìsọfúnni láti ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Ọsirélíà pé kí n di alábòójútó àyíká. Èyí yà mí lẹ́nu gan-an torí pé ọmọ ogún ọdún péré ni mí. Lẹ́yìn tí mo ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèbẹ̀wò déédéé sí àwọn ìjọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà ní àyíká tí mò ń bẹ̀ wò ló dàgbà jù mí lọ, àmọ́ wọn kò fojú tẹ́ńbẹ́lú mi torí pé mo jẹ́ ọ̀dọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n fojú pàtàkì wo iṣẹ́ tí mò ń ṣe.

Onírúurú nǹkan ni mo máa ń bá pàdé bí mo ṣe ń lọ láti ìjọ kan sí òmíràn. Lọ́sẹ̀ kan mo lè wọ bọ́ọ̀sì, ọ̀sẹ̀ míì sì wà tí màá wọ bọ́ọ̀sì ojú irin, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí kí n gun alùpùpù, màá ru báàgì aṣọ mi, màá sì fa báàgì òde ẹ̀rí mi lọ́wọ́. Mo máa ń láyọ̀ gan-an tí mo bá dé sílé àwọn ará. Arákùnrin kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ ìjọ fẹ́ kí n dé sí ọ̀dọ̀ òun bó tílẹ̀ jẹ́ pé kò tíì parí ilé rẹ̀. Lọ́sẹ̀ yẹn, inú ilé ìwẹ̀ ni wọ́n gbé bẹ́ẹ̀dì tí mo fi sùn sí, àmọ́ a láyọ̀ gan-an torí pé a gbé ara wa ró nípa tẹ̀mí!

Ìyàlẹ́nu míì tí mo tún rí wáyé lọ́dún 1953 nígbà tí wọ́n fi fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ fún kíláàsì kejìlélógún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ránṣẹ́ sí mi. Àmọ́ bí inú mi ṣe ń dùn lápá kan, ẹ̀rù tún ń bà mí. Ohun tó sì fà á ni pé, lẹ́yìn tí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti ọkọ rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní July 30, 1950, orílẹ̀-èdè Pakistan ni wọ́n rán wọn lọ. Kò pé ọdún kan lẹ́yìn náà ti Lesley fi ṣàìsàn tó sì kú síbẹ̀. Mo wá ronú pé báwo ló ṣe máa rí lára àwọn òbí mi, tí èmi náà bá tún gbéra lọ sí apá ibòmíì lórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn? Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Lọ sin Jèhófà ní ibikíbi tó bá rán ẹ lọ́.” Mi ò tún fojú kan bàbá mi mọ́ lẹ́yìn náà. Wọ́n kú lọ́dún 1957.

Kò pẹ́ tí èmi àti àwọn Ẹlẹ́rìí márùn-ún míì láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà fi gbéra ìrìn àjò orí omi lọ sí New York City. Ọ̀sẹ̀ mẹ́fà la fi rin ìrìn àjò náà. Bá a ṣe ń lọ, à ń ka Bíbélì, à ń kẹ́kọ̀ọ́, a sì ń jẹ́rìí fún àwọn èrò tá a jọ wà nínú ọkọ̀. Ká tó lọ sí ibi tá a ti máa ṣe ilé ẹ̀kọ́ náà ní ìlú South Lansing, ní ìpínlẹ̀ New York, a lọ ṣe àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe ní pápá ìṣeré Yankee ní oṣù July ọdún 1953. Gbogbo àwa tá a wá sí àpéjọ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti okòó lé lẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́sàn-án [165,829]!

Apá ibi gbogbo lágbàáyé ni àwa ọgọ́fà [120] tá a jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì náà ti wá. Ọjọ́ tá a ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege la tó mọ ibi tí wọ́n rán wa lọ. Ńṣe la sáré lọ sí yàrá ìkàwé ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ká lè mọ̀ nípa orílẹ̀-èdè tí wọ́n rán wa lọ. Mo rí i pé orílẹ̀-èdè Paraguay ni wọ́n yàn mí sí, ìtàn sì fi hàn pé rògbòdìyàn ìṣèlú máa ń wáyé níbẹ̀ lemọ́lemọ́. Láìpẹ́ lẹ́yìn tí mo débẹ̀, mo béèrè lọ́wọ́ àwọn míṣọ́nnárì tá a jọ wà níbẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ kan pé “àríyá” wo ni wọ́n ń ṣe láàárín òru? Wọ́n rẹ́rìn-ín músẹ́ wọ́n sì sọ pé: “Rògbòdìyàn ìṣèlú ti ṣojú ìwọ náà fún ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn. Yọjú wòta.” Bí mo ṣe wo ìta báyìí, ńṣe láwọn sójà dúró sí àwọn igun ọ̀nà!

ÌṢẸ̀LẸ̀ KAN TÓ PABANBARÌ

Nígbà kan báyìí, mo tẹ̀ lé alábòójútó àyíká lọ bẹ ìjọ kan tó wà ní àdádó wò, ká lè fi fíìmù The New World Society in Action hàn wọ́n. Nǹkan bíi wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́sàn-án la fi rìnrìn-àjò, a kọ́kọ́ wọ ọkọ̀ ojú irin, a tún gun ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ kan tí wọ́n so mọ́ ẹṣin, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yìn a wá gun kẹ̀kẹ́ tí màlúù ń fà. A gbé ẹ̀rọ amúnáwá àti ẹ̀rọ tó ń gbé àwòrán jáde sára ògiri dání. Ọjọ́ kejì lẹ́yìn tá a dé ibi tá à ń lọ la ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn àrọko, a sì ń pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá wo fíìmù náà lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Nǹkan bí èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló wá.

Lẹ́yìn nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú tá a ti ń fi fíìmù náà hàn wọ́n, wọ́n sọ fún wa pé ká wọnú ilé lọ kíákíá. A sáré gbé ẹ̀rọ tó ń gbé àwòrán jáde sára ògiri náà, a sì wọlé lọ. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn làwọn ọkùnrin kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, tí wọ́n ń yìnbọn, tí wọ́n sì ń kígbe pé: “Òrìṣà tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ ni òrìṣà wa, ẹ̀jẹ̀ àwọn gringos ló sì ń fẹ́.” Àwọn gringos méjì péré ló wà níbẹ̀, mo sì jẹ́ ọ̀kan lára wọn! Àwọn tó wá wo fíìmù náà kò jẹ́ kí àwọn jàǹdùkú náà ráyè jálẹ̀kùn wọlé. Àmọ́ àwọn alátakò náà pa dà wá ní nǹkan bí aago mẹ́ta òru, wọ́n ń yìnbọn wọ́n sì ń sọ pé ọwọ́ àwọn á tẹ̀ wá tá a bá ń lọ.

Àwọn arákùnrin náà kàn sí agbófinró ìlú yẹn, ó sì kó ẹṣin méjì wá lọ́sàn-án ọjọ́ náà láti fi gbé wa lọ sí ìgboro. Bá a ṣe ń lọ, tá a bá ti dé ibi tí igbó pọ̀ sí, yóò fa ìbọn rẹ̀ yọ á sì sáré lọ síwájú láti wo bí ibẹ̀ ṣe rí. Mo rí i pé ẹṣin jẹ́ ohun ìrìnnà tó wọ́pọ̀ lágbègbè náà, fún ìdí yìí èmi náà ra ẹṣin kan nígbà tó yá.

WỌ́N RÁN ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ MÍÌ WÁ

Iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ ń kẹ́sẹ járí bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń ṣàtakò sí wa. Lọ́dún 1955, àwọn míṣọ́nnárì tuntun márùn-ún tún dé sí orílẹ̀-èdè náà, arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Kánádà wà lára wọn, Elsie Swanson lorúkọ rẹ̀, kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ló sì ti ṣe tán. A jọ wà pa pọ̀ fún àkókò díẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì kí wọ́n tó wá rán-an lọ sí ìlú míì. Ó ti ya gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ ló rí gbà lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, torí pé wọn kò kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Èmi àti Elsie ṣe ìgbéyàwó ní December 31, 1957, a sì jọ ń gbé ilé míṣọ́nnárì tó wà ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Paraguay.

Kò sí omi ẹ̀rọ ní ilé wa, àmọ́ a ní kànga kan ní ẹ̀yìnkùlé. Torí náà, kò sí ilé ìwẹ̀ àti ilé ìgbọ̀nsẹ̀ nínú ilé, kò sí ẹ̀rọ ìfọṣọ, kódà kò sí fìríìjì. A kì í ra oúnjẹ tó lè bà jẹ́ pa mọ́ sílé, ojoojúmọ́ la máa ń ra èyí tá a bá nílò. Àmọ́ bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ yìí pẹ̀lú àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ mú kí àkókò yìí jẹ́ àkókò aláyọ̀ nínú ìgbéyàwó wa.

Lọ́dún 1963 tá a lọ wo màmá mi ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, kò pẹ́ tá a dé ọ̀dọ̀ wọn tí wọ́n fi ní àrùn ọkàn, ó jọ pé inú wọn tó dùn nígbà tí wọ́n fojú kàn mí lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá ló fà á. Nígbà tí àkókò ń sún mọ́ láti pa dà sẹ́nu iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Paraguay, a wá dójú kọ ọ̀kan lára ìpinnu tó ṣòro jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Ṣé ká fi màmá mi sílẹ̀ ní ilé ìwòsàn, ká máa retí pé ẹnì kan á bójú tó wọn, ká sì pa dà ṣẹ́nu iṣẹ́ wa tá a fẹ́ràn gan-an, lórílẹ̀-èdè Paraguay? Lẹ́yìn tí èmi àti Elsie ìyàwó mi ti gbàdúrà gan-an nípa rẹ̀, a pinnu láti dúró ká lè bójú tó Màmá. Síbẹ̀ títí tí wọ́n fi kú lọ́dún 1966, a ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

Àǹfààní ló jẹ́ fún mi pé wọ́n lò mí lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti àgbègbè lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà fún ọ̀pọ̀ ọdún, mo sì tún ní àǹfààní láti jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ọlọ́run fún àwọn alàgbà. Àmọ́ ìyípadà míì tún wáyé nínú ìgbésí ayé wa. Wọ́n yàn mí láti sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Nígbà tá a wá fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tuntun, wọ́n yàn mí láti jẹ́ alága ìgbìmọ̀ ìkọ́lé. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ tó fọwọ́ sowọ́ pọ̀, a parí kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì rèǹtè-rente kan.

Wọ́n wá ní kí n lọ ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, ìyẹn ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè kan. Mo tún láǹfààní láti máa lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì jákèjádò ayé wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó láti ilẹ̀ òkèèrè, kí n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí n sì fún wọn ní ìṣírí. Ó máa ń fún mi ní ìṣírí gan-an nígbà tí mo bá ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn orílẹ̀-èdè kan tí mo sì rí àwọn tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àti àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ torí pé wọ́n fi tọkàntọkàn ṣègbọràn sí Jèhófà.

IṢẸ́ TÍ À Ń ṢE BÁYÌÍ

Lọ́dún 2001, lẹ́yìn tá a dé láti ìbẹ̀wò tá a lọ ṣe sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì nílẹ̀ òkèèrè, tó sì ti rẹ̀ wá gan-an, mo bá lẹ́tà kan tí wọ́n fi pè mí sí Brooklyn, New York, láti wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èmi àti Elsie gbàdúrà nípa rẹ̀, a sì fi tayọ̀tayọ̀ gba iṣẹ́ tuntun yìí. Ó ti lé ní ọdún mọ́kànlá báyìí tá a ti wà ní Brooklyn.

Mo láyọ̀ pé mo ní ìyàwó tí inú rẹ̀ máa ń dùn láti ṣe ohunkóhun tí Jèhófà bá fẹ́. Èmi àti Elsie ìyàwó mi ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún báyìí, síbẹ̀ a ṣì ní ìlera tó dáa dé ìwọ̀n àyè kan. A nírètí láti máa gbádùn ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa títí ayérayé àtàwọn ìbùkún rẹpẹtẹ tí àwọn tó ń bá a nìṣó láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ máa gbádùn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Lọ́sẹ̀ kan mo lè wọ bọ́ọ̀sì, ọ̀sẹ̀ míì sì wà tí màá wọ bọ́ọ̀sì ojú irin, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí kí n gun alùpùpù, màá ru báàgì aṣọ mi, màá sì fa báàgì òde ẹ̀rí mi lọ́wọ́

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

A nírètí láti máa gbádùn ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa títí ayérayé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Apá òsì: Ìgbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ àyíká ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà Apá ọ̀tún: Èmi àti àwọn òbí mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa, December 31, 1957