Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí Jèhófà Ṣamọ̀nà Rẹ Síbi Tí Ojúlówó Òmìnira Wà

Jẹ́ Kí Jèhófà Ṣamọ̀nà Rẹ Síbi Tí Ojúlówó Òmìnira Wà

Jẹ́ Kí Jèhófà Ṣamọ̀nà Rẹ Síbi Tí Ojúlówó Òmìnira Wà

“Wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira.”​—JÁK. 1:25.

ǸJẸ́ O LÈ ṢÀLÀYÉ?

Òfin wo ló lè mú kéèyàn rí ojúlówó òmìnira, àwọn wo ló sì ń jàǹfààní nínú òfin náà?

Báwo la ṣe lè rí ojúlówó òmìnira?

Òmìnira wo ni àwọn tó bá ń tọ ọ̀nà ìyè máa gbádùn?

1, 2. (a) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí òmìnira táwọn èèyàn ní, kí sì nìdí? (b) Òmìnira wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń fojú sọ́nà fún?

 ÌWỌRA, ìwà ta-ni-yóò-mú-mi àti ìwà ipá túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní àkókò tá à ń gbé yìí. (2 Tím. 3:1-5) Láti wá nǹkan ṣe sí i, ìjọba túbọ̀ ń ṣe ọ̀pọ̀ òfin, wọ́n ń mú kí àwọn ọlọ́pàá túbọ̀ wà ní sẹpẹ́, wọ́n sì ń lo àwọn kámẹ́rà tí wọ́n fi ń ṣọ́ ohun táwọn èèyàn ń ṣe. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọmọ ìlú tí wọ́n ní ilé tiwọn túbọ̀ ń dáàbò bo ara wọn nípa fífi àwọn agogo ìdágìrì sára ilé, wọ́n á fi ọ̀pọ̀ àgádágodo ti ilẹ̀kùn, wọ́n á sì fi àwọn wáyà tó lè mú kí iná gbéni sára ọgbà tó yí ilé wọn ká. Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ jáde lálẹ́, wọn kì í sì í fẹ́ káwọn ọmọ wọn máa dá ṣeré níta, lójúmọmọ tàbí lálẹ́. Èyí mú kó ṣe kedere pé òmìnira tí àwọn èèyàn ní ti ń dín kù, ó sì dà bíi pé bí nǹkan á ṣe máa bá a nìṣó nìyẹn.

2 Nínú ọgbà Édẹ́nì, Sátánì sọ pé ohun tó lè mú kéèyàn ní ojúlówó òmìnira ni pé kó máa dá pinnu àwọn nǹkan láìsí ọwọ́ Jèhófà níbẹ̀. Ẹ ò rí i pé irọ́ tó ń bani lórúkọ jẹ́ àtèyí tó jìnnà sóòótọ́ nìyẹn! Kódà, bí àwọn èèyàn bá ṣe ń fi ojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ìlànà Ọlọ́run tó dá lórí ìwà wa àti àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni wàhálà á ṣe túbọ̀ máa bá àwùjọ ẹ̀dá tó. Ipò àwọn nǹkan tó túbọ̀ ń burú sí i yìí kan àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ní ìrètí pé láìpẹ́ aráyé kò ní jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ìwà ìbàjẹ́ máa dópin, a ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ohun tí Bíbélì pè ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Kódà, Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè gbádùn òmìnira yẹn. Lọ́nà wo?

3. Òfin wo ni Jèhófà ti fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, àwọn ìbéèrè wo la sì máa gbé yẹ̀ wò?

3 A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ohun tí òǹkọ̀wé Bíbélì náà Jákọ́bù pè ní “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira.” (Ka Jákọ́bù 1:25.) Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì túmọ̀ gbólóhùn yìí sí “òfin tí ó ń sọ wá di òmìnira” (The New English Bible) àti “òfin tí ó pé, tí í ṣe orísun òmìnira” (Ìròhìn Ayọ̀). Àmọ́, ńṣe làwọn èèyàn sábà máa ń wo òfin bí ohun tó ń káni lọ́wọ́ kò, wọn kì í wò ó bí ohun tó ń sọni di òmìnira. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ni “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira” yìí? Báwo sì ni òfin yẹn ṣe ń sọ wá di òmìnira?

ÒFIN TÓ Ń SỌNI DI ÒMÌNIRA

4. Kí ni “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira,” ta ló sì ń jàǹfààní nínú òfin náà?

4 “Òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira” kì í ṣe Òfin Mósè, torí pé ńṣe ni Òfin Mósè ń mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere, Kristi sì ti mú òfin yẹn ṣẹ. (Mát. 5:17; Gál. 3:19) Òfin wo wá ni Jákọ́bù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? “Òfin Kristi” ni Jákọ́bù ní lọ́kàn. Bíbélì sì tún pè é ní “òfin ìgbàgbọ́” àti “òfin àwọn ẹni òmìnira.” (Gál. 6:2; Róòmù 3:27; Ják. 2:12) Torí náà, “òfin pípé” náà jẹ́ àpapọ̀ gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” sì ń jàǹfààní nínú rẹ̀.—Jòh. 10:16.

5. Kí nìdí tí òfin òmìnira kì í fi í ṣe ẹrù ìnira?

5 Òfin tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ń tẹ̀ lé máa ń díjú gan-an tàbí kó dà bí ẹrù ìnira. Àmọ́, “òfin pípé” kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn àṣẹ tí kò díjú àtàwọn ìlànà tó ṣe kókó ló wà nínú rẹ̀. (1 Jòh. 5:3) Jésù sọ pé: “Àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:29, 30) Ní àfikún sí i, kò sí ìdí fún ṣíṣe àkọsílẹ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ nípa ìyà tí wọ́n máa fi jẹ ẹni tó bá rú “òfin pípé” náà, torí pé orí ìfẹ́ la gbé e kà, inú ọkàn la sì kọ ọ́ sí, kì í ṣe orí wàláà òkúta.—Ka Hébérù 8:6, 10.

BÍ “ÒFIN PÍPÉ” NÁÀ ṢE Ń SỌ WÁ DI ÒMÌNIRA

6, 7. Kí la lè sọ nípa àwọn ìlànà Jèhófà, kí sì nìdí tí òfin òmìnira yìí fi ń sọni di òmìnira?

6 Bí Jèhófà bá ní kí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye má ṣe ohun kan, àǹfààní àti ààbò wọn ló wà fún. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn òfin tó ń darí àgbáyé wa, irú bí òfin òòfà. Àwọn èèyàn kì í ṣàròyé pé àwọn òfin wọ̀nyí jẹ́ ìnira fáwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọrírì àwọn òfin náà, wọ́n sì gbà pé àlàáfíà ara wọn ni àwọn òfin náà wà fún. Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí “òfin pípe” ti Kristi ṣe fi hàn, àǹfààní àwa èèyàn ni àwọn ìlànà Jèhófà nípa ìwà híhù àti àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ wà fún.

7 Ní àfikún sí bí òfin òmìnira yìí ṣe ń dáàbò bò wá, ó tún ń mú ká lè ṣe gbogbo ohun rere tá a bá ní lọ́kàn, láìfa ìpalára kankan fún ara wa tí a kò sì ní ra kaka lé ẹ̀tọ́ àti òmìnira àwọn ẹlòmíì. Torí náà, bó bá jẹ́ pé a fẹ́ di òmìnira ní tòótọ́, ìyẹn ni pé ká lè máa ṣe ohun tó wà lọ́kàn wa, ńṣe ló yẹ ká máa ní èrò rere lọ́kàn, èrò tí kò ní ta ko irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti àwọn ìlànà rẹ̀. Lédè mìíràn, a gbọ́dọ̀ kọ́ láti fẹ́ ohun tí Jèhófà bá fẹ́ ká sì kórìíra ohun tó bá kórìíra, ohun tí òfin òmìnira sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe nìyẹn.—Ámósì 5:15.

8, 9. Àwọn àǹfààní wo ni àwọn tó bá rọ̀ mọ́ òfin òmìnira máa ń ní? Ṣàpèjúwe.

8 Torí pé a jẹ́ aláìpé, a máa ń tiraka láti borí àwọn èrò tí kò tọ́. Síbẹ̀, bá a ṣe ń fi ìṣòtítọ́ rọ̀ mọ́ òfin òmìnira bẹ́ẹ̀ náà là ń gbádùn òmìnira, àní nísinsìnyí pàápàá. A lè ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: Sìgá mímu ti di bárakú fún Jay tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé inú Ọlọ́run kò dùn sí sìgá mímu, ó rí i pé ó di dandan kí òun pinnu nǹkan tí òun máa ṣe. Ṣé á máa bá a nìṣó láti tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn àbí ó máa ṣègbọràn sí Jèhófà kó sì jáwọ́? Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni Jay ṣe. Ó yàn láti sin Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn rẹ̀ ṣì máa ń fà sí sìgá. Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó borí àṣà yìí? Ó sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Ohun àgbàyanu ló jẹ́ fún mi pé mo dòmìnira, ìdùnnú sì ṣubú layọ̀ fún mi.”

9 Jay kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i pé ńṣe ni òmìnira inú ayé, èyí tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ‘gbé èrò inú ka ẹran ara,’ máa ń sọni di ẹrú. Nígbà tó jẹ́ pé òmìnira ti Jèhófà, tó túmọ̀ sí “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí,” máa ń sọni di òmìnira, ó sì máa ń yọrí sí “ìyè àti àlàáfíà.” (Róòmù 8:5, 6) Ibo ni Jay ti rí okun tó mú kó borí sìgá mímu tó ti sọ ọ́ dẹrú? Kì í ṣe látinú agbára rẹ̀; ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni okun náà ti wá. Ó sọ pé: “Mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, mo máa ń gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́, mo sì máa ń gba ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ tí àwọn ará nínú ìjọ bá fún mi.” Àwọn ìpèsè kan náà yìí lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ bá a ṣe ń wá ojúlówó òmìnira. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.

WO INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NÍ ÀWÒFÍN

10. Kí ló túmọ̀ sí láti “wo” inú òfin Ọlọ́run “ní àwòfín”?

10 Ìwé Jákọ́bù 1:25 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn . . . yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” Èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a túmọ̀ sí ‘wò ní àwòfín’ túmọ̀ sí “láti bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ wo inú nǹkan,” èyí tó já sí pé kéèyàn sapá gan-an. Torí náà, bí a bá fẹ́ kí òfin òmìnira náà nípa lórí èrò àti ọkàn wa, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì taápọntaápọn, ká máa gbàdúrà, ká sì máa ṣe àṣàrò lórí ohun tá a bá kà.—1 Tím. 4:15.

11, 12. (a) Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká sọ òtítọ́ di tiwa? (b) Bá a ṣe fi hàn nínú àwọn àwòrán tó wà lókè yìí, ewu wo ló yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì sá fún?

11 Bá a ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, ó tún yẹ ká máa “tẹpẹlẹ mọ́ ọn” tàbí ká máa fara dà á, ká sì máa tipa bẹ́ẹ̀ sọ òtítọ́ di tiwa. Jésù sọ ohun tó jọ èyí nígbà tó sọ fún àwọn kan tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòh. 8:31, 32) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé nínú ẹsẹ yìí láti “mọ” ohun kan tún túmọ̀ sí pé kéèyàn fi ìmọrírì hàn torí pé “ohun tẹ́ni náà ‘mọ̀’ níye lórí tàbí pé ó ṣe pàtàkì sí i.” Lọ́nà yìí, a lè sọ pé a “mọ” òtítọ́ ní kíkún nígbà tá a bá sọ ọ́ di tiwa. Ìgbà náà la tó lè sọ lọ́nà tó tọ́ pé ‘ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́’ nínú wa, ó ń mú kí irú ẹni tá a jẹ́ sunwọ̀n sí i, ká bàa lè túbọ̀ máa gbé àwọn ànímọ́ Baba wa ọ̀run yọ.—1 Tẹ́s. 2:13.

12 Bi ara rẹ pé, ‘Ṣó dájú pé mo mọ òtítọ́? Ǹjẹ́ mo ti sọ ọ́ di tèmi? Àbí, mo ṣì ń wá bí mo ṣe máa ní díẹ̀ lára “òmìnira” ti ayé yìí?’ Arábìnrin kan tí àwọn òbí rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni tọ́ dàgbà ronú nípa ìgbà tó ṣì wà ní ọ̀dọ́, ó sọ pé: “Bí wọ́n bá tọ́ ẹ dàgbà nínú òtítọ́, gbogbo ìgbà ni Jèhófà á máa wà pẹ̀lú rẹ. Àmọ́, ní tèmi o, ńṣe ni Jèhófà dà bí àjèjì sí mi. Mi ò kórìíra àwọn ohun tó kórìíra. Mi ò gbà pé ohun tí mo bá ṣe kàn án. Mi ò kì í tọ̀ ọ́ lọ bí mo bá wà nínú ìṣòro. Òye ara mi ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, ìyẹn sì ti wá já jó mi lójú báyìí, torí pé mi ò mọ nǹkan kan.” Ó dùn mọ́ni pé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn arábìnrin náà rí i pé èrò tí kò tọ́ lòun ní, ó sì ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì mélòó kan. Kódà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ LÈ MÚ KÓ O DI ÒMÌNIRA

13. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe lè mú ká di òmìnira?

13 Nínú 2 Kọ́ríńtì 3:17, a kà pé: “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń pa kún òmìnira wa? Lára àwọn ọ̀nà tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ń mú ká ní àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè ní òmìnira, irú bí “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gál. 5:22, 23) Láìsí àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn, ní pàtàkì jù lọ ìfẹ́, kò sí àwùjọ ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè ní ojúlówó òmìnira. Òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro sì nìyẹn jẹ́ báyìí nínú ayé. Ṣùgbọ́n, ó fani lọ́kàn mọ́ra pé, lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti to èso tẹ̀mí lẹ́sẹẹsẹ, ó fi kún un pé: “Kò sí òfin kankan lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.” Kí ló ní lọ́kàn? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé kò sí òfin èyíkéyìí tó lè dín ìdàgbàsókè èso ẹ̀mí Ọlọ́run kù. (Gál. 5:18) Àti pé kí tiẹ̀ ni irú òfin bẹ́ẹ̀ máa wà fún? Ìfẹ́ Jèhófà ni pé ká ní àwọn ànímọ́ bíi ti Kristi ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, ká sì máa fi wọ́n ṣèwà hù láìsí ìdíwọ́ kankan.

14. Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀mí ayé ń gbà sọ àwọn tó bá fàyè gbà á di ẹrú?

14 Àwọn tí ẹ̀mí ayé bá ti gbà lọ́kàn torí pé wọ́n fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara lè máa ronú pé àwọn wà lómìnira. (Ka 2 Pétérù 2:18, 19.) Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀rọ̀ ò rí bí wọ́n ṣe rò. Ó máa gba pé kí ọ̀pọ̀ òfin àti ìlànà wà tí yóò máa darí wọn kí wọ́n tó lè ki ọwọ́ ìfẹ́ gbígbóná àti ìwàkíwà wọn bọlẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A kò gbé òfin kalẹ̀ fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ aláìlófin àti ewèlè.” (1 Tím. 1:9, 10) Wọ́n tún jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ ọ̀gá rírorò, a sì ń sún wọn láti ṣe “àwọn ohun tí ẹran ara fẹ́.” (Éfé. 2:1-3) A lè fi irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wé àwọn kòkòrò tí wọ́n rìn wọ inú abọ́ oyin, àmọ́ tí wọn kò lè jáde mọ́. Tó wá já sí pé ohun tí wọ́n mọ̀ ọ́n jẹ ló pa wọ́n.—Ják. 1:14, 15.

A SỌ WÁ DI ÒMÌNIRA LÁÀÁRÍN ÌJỌ KRISTẸNI

15, 16. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ, òmìnira wo la sì ń gbádùn?

15 Nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni, kì í ṣe ẹgbẹ́ kan táwọn èèyàn dá sílẹ̀ lo dara pọ̀ mọ́. Ńṣe lo wá sínú ìjọ torí pé Jèhófà fà ẹ́. (Jòh. 6:44) Kí ló mú kí Jèhófà fà ẹ́? Ṣé torí pé o jẹ́ olódodo àti ẹni tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni? O lè sọ pé: “Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá!” Kí wá ni Ọlọ́run rí tó fi fà ẹ́? Ó rí ọkàn tó múra tán láti ṣègbọràn sí òfin rẹ̀ tó ń sọni di òmìnira, tó sì ṣe tán láti fara mọ́ ibi tí Ọlọ́run bá fi inú rere darí rẹ̀ sí. Láàárín ìjọ, Jèhófà ti fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn rẹ nípa bíbọ́ ẹ nípa tẹ̀mí, ó ti sọ ẹ di òmìnira kúrò nínú àwọn irọ́ tí ẹ̀sìn èké fi ń kọ́ni àti ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán, ó sì tún ti kọ́ ẹ ní ọ̀nà tó o lè máa gbà fi àwọn ànímọ́ bíi ti Kristi ṣèwà hù. (Ka Éfésù 4:22-24.) Nítorí èyí, o ní àǹfààní láti wà láàárín àwọn èèyàn tá a lè sọ ní tòótọ́ pé àwọn nìkan ni wọ́n jẹ́ “àwọn ẹni òmìnira.”—Ják. 2:12.

16 Gbé èyí yẹ̀ wò: Tó o bá wà láàárín àwọn tí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn fẹ́ràn Jèhófà, ǹjẹ́ ẹ̀rù máa ń bà ẹ́? Ǹjẹ́ o máa ń wò káàkiri tìfuratìfura? Bí ìwọ àti ẹnì kan bá ń sọ̀rọ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣó o máa ń gbá ohun tó o bá gbé wá sípàdé mọ́ra gbágbáágbá, kó má bàa di àfẹ́kù? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ara rẹ á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, ohunkóhun ò sì ní í kó ẹ lọ́kàn sókè. Bó bá jẹ́ pé ibi ayẹyẹ kan lo lọ, ṣé bí ara rẹ ṣe máa ń balẹ̀ náà nìyẹn? Kò dájú! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìtọ́wò lásán ni òmìnira tó ò ń gbádùn báyìí láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ ní ìfiwéra pẹ̀lú òmìnira tó o máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú.

“ÒMÌNIRA OLÓGO TI ÀWỌN ỌMỌ ỌLỌ́RUN”

17. Báwo ni òmìnira aráyé ṣe tan mọ́ “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run”?

17 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń jíròrò bí Jèhófà ṣe máa sọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé di òmìnira, ó sọ pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà ló wá fi kún un pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:19-21) “Ìṣẹ̀dá” túmọ̀ sí aráyé tí wọ́n ní ìrètí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n sì máa jàǹfààní látinú “ìṣípayá” àwọn ọmọ Ọlọ́run tí a fi ẹ̀mí bí. Ìṣípayá yẹn máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá jí “àwọn ọmọ” yìí dìde sí òkè ọ̀run, tí wọ́n sì ran Kristi lọ́wọ́ láti pa gbogbo àwọn ẹni ibi tó wà lórí ilẹ̀ ayé run, tí wọ́n sì pa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” mọ́ láàyè wọnú ètò àwọn nǹkan tuntun.—Ìṣí. 7:9, 14.

18. Báwo ni òmìnira tí àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn ní á ṣe máa pọ̀ sí i, òmìnira wo ni wọ́n sì máa gbádùn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn?

18 Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn tá a ti rà pa dà á wá jèrè òmìnira tí kò láfiwé kúrò lọ́wọ́ Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù. (Ìṣí. 20:1-3) Ìtura ńlá gbáà nìyẹn á mà jẹ́ o! Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], tí wọ́n máa jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi yóò máa bá a nìṣó láti mú kí aráyé di òmìnira nípa mímú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà títí tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti àìpé kò fi ní nípa lórí aráyé mọ́. (Ìṣí. 5:9, 10) Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn bá ti dúró bí olóòótọ́ lábẹ́ ìdánwò, wọ́n á ní òmìnira pípé tí Jèhófà ní lọ́kàn fún wọn, ìyẹn gan-an sì ni “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Ronú nípa bí irú òmìnira bẹ́ẹ̀ á ṣe rí! Kò ní sí ìdí kankan fún ẹ mọ́ láti máa jìjàkadì láti ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run, torí pé gbogbo ẹ̀yà ara rẹ á ti di pípé, wàá sì lè máa fi ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù.

19. Kí ni a gbọ́dọ̀ máa ṣe báyìí ká lè máa bá a nìṣó láti gbádùn ojúlówó òmìnira?

19 Ǹjẹ́ ò ń fojú sọ́nà fún gbígbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run”? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira” máa darí èrò rẹ àti ọkàn rẹ. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ taápọntaápọn. Máa fi òtítọ́ ṣèwà hù, sọ ọ́ di tìrẹ. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Máa lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé, kó o sì rí i pé ò ń jàǹfààní látinú oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè. Má ṣe jẹ́ kí Sátánì tàn ẹ́ jẹ bó ṣe tan Éfà jẹ tó sì mú kó máa ronú pé ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ti máa ń káni lọ́wọ́ kò jù. Má ṣe gbàgbé pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni Sátánì. Àmọ́, bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, kò di dandan kí Sátánì fi “ọgbọ́n àyínìke borí wa, nítorí àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.”—2 Kọ́r. 2:11.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣé mo ṣì ń fẹ́ láti ní díẹ̀ lára “òmìnira” ti ayé?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ǹjẹ́ mo ti sọ òtítọ́ di tèmi?