Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú ní Ecuador

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú ní Ecuador

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú ní Ecuador

ỌKÀN arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Ítálì kò balẹ̀. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ilé ẹ̀kọ́ girama ni, èsì ìdánwò rẹ̀ ló sì dára jù lọ ní kíláàsì rẹ̀, torí náà àwọn ìbátan àtàwọn olùkọ́ rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ pé kó lọ kàwé sí i ní ilé ẹ̀kọ́ gíga. Àmọ́, ní ọdún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, Bruno ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ti ṣèlérí pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lòun máa fi sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé òun. Kí ló wá yàn láti ṣe? Ó ṣàlàyé pé: “Mo sọ fún Jèhófà nínú àdúrà pé màá mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ mi ṣẹ, màá sì fi Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Àmọ́, mo tún mẹ́nu kàn án nínú àdúrà mi pé ìgbésí ayé tó kún fún onírúurú ìgbòkègbodò nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ni mo fẹ́.”

Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Bruno bá ara rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Ecuador tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Ó sọ pé: “Jèhófà dáhùn àdúrà mi dáadáa ju bí mo ṣe rò lọ.” Nígbà tó dé orílẹ̀-èdè Ecuador, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un láti bá ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mìíràn pàdé tí àwọn náà wá síbẹ̀ kí wọ́n lè túbọ̀ sin Jèhófà ní kíkún.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ TÍ WỌ́N ‘DÁN JÈHÓFÀ WÒ’

Ńṣe ni Bruno náà ṣe bíi ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ mìíràn kárí ayé tí wọ́n dáhùn sí ìkésíni Jèhófà pé: “Kí ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò . . . bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín.” (Mál. 3:10) Ìfẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ yìí ní sí Ọlọ́run mú kí wọ́n pinnu láti ‘dán Jèhófà wò’ nípa yíyọ̀ǹda àkókò wọn, okun wọn àtàwọn ohun ìní wọn tinútinú láti fi ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i.

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí àwọn òṣìṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú yìí dé sí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn tuntun, wọ́n rí i pé “ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.” (Mát. 9:37) Bí àpẹẹrẹ, Jaqueline tó wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì fi ìtara kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Ecuador pé: “Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé ní ọdún méjì báyìí tí mo ti ń sìn lórílẹ̀-èdè Ecuador, mo sì ti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tàlá [13], mẹ́rin lára wọn sì máa ń wá sí ìpàdé déédéé. Ṣé ìyẹn ò ti lọ wà jù?” Orílẹ̀-èdè Kánádà ni Chantal ti wá. Ó sọ pé: “Ní ọdún 2008, mo lọ sí agbègbè kan tó wà ní etíkun Ecuador tó jẹ́ pé ìjọ kan ṣoṣo ló wà níbẹ̀. Ní báyìí, ìjọ mẹ́ta àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó lé ní ọgbọ̀n [30] ló wà níbẹ̀. Kò sí ohun tó dà bíi kéèyàn máa rí bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ṣe ń tẹ̀ síwájú!” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Láìpẹ́ yìí ni mo kó lọ sí ìlú kan tó wà lórí Òkè Andes tí gíga rẹ̀ jẹ́ òjì-lé-ní-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá ó lé mẹ́ta mítà [2,743], ìyẹn ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] ẹsẹ̀ bàtà. Àwọn tó ń gbé nínú ìlú náà ju ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́rin [75,000] lọ, àmọ́ ìjọ kan ṣoṣo ló wà níbẹ̀. Àwọn èèyàn máa ń gbọ́rọ̀ wa gan-an ní ìpínlẹ̀ ìwàásù náà! Mo sì ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi dáadáa.”

ÀWỌN OHUN TÓ JẸ́ ÌPÈNÍJÀ FÚN WA

Àmọ́ ṣá o, àwọn ìpèníjà pàtàkì kan wà tí àwọn tó ń sìn ní ilẹ̀ òkèèrè máa ń dojú kọ. Kódà, kó tiẹ̀ tó di pé àwọn ọ̀dọ́ kan gbéra ni wọ́n ti bá àwọn ìdíwọ́ kan pàdé. Kayla láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ojú tí kò dára tó táwọn arákùnrin kan tí wọn kò mọ̀ ọ́n sí àìdáa fi máa ń wo ọ̀ràn náà nínú ìjọ tá a ti wá máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni. Wọn kò lóye ìdí tí mo fi fẹ́ lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà míì, ìyẹn ti mú kí n ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé ìpinnu tó tọ́ ni mo fẹ́ ṣe yìí?’” Síbẹ̀, Kayla pinnu láti lọ. Ó ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ àdúrà tí mo gbà sí Jèhófà àti ọ̀rọ̀ àjọsọ tó gba àkókò gígùn tí mo ní pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ló jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà máa ń bù kún ẹni tó bá yọ̀ǹda ara rẹ̀ tinútinú.”

Kíkọ́ èdè tuntun ló máa ń jẹ́ ìṣòro ọ̀pọ̀ àwọn míì. Siobhan tó wá láti orílẹ̀-èdè Ireland rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ìṣòro ló jẹ́ fún mi pé kí n mọ ohun tí màá sọ ṣùgbọ́n kí n má mọ bí màá ṣe sọ ọ́. Torí náà, ó gba pé kí n máa ṣe sùúrù, kí n sapá taápọntaápọn láti kọ́ èdè náà, kí n sì fi ara mi rẹ́rìn-ín bí mo bá ṣe àṣìṣe.” Ní àfikún sí ìyẹn, Anna tó wá láti orílẹ̀-èdè Estonia sọ pé: “Ó rọrùn láti fara da ooru tó máa ń mú ní ilẹ̀ olóoru, ọ̀pọ̀ eruku àti kéèyàn máà rí omi gbígbóná fi wẹ̀ ju kéèyàn kọ́ èdè Sípáníìṣì lọ. Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n dẹ́kun kíkọ́ èdè náà. Àmọ́, mo kọ́ láti máa gbọ́kàn kúrò lórí àwọn àṣìṣe mi kí n sì máa pọkàn pọ̀ sórí ibi tí mo tẹ̀ síwájú dé.”

Ohun tí kò tún ṣeé gbójú fò dá ni bí àárò ilé ṣe máa ń sọni. Jonathan tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Láìpẹ́ tí mo débẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi torí pé mi ò sí nítòsí àwọn ọ̀rẹ́ mi àti ìdílé mi mọ́. Àmọ́ bí mo ṣe máa ń pọkàn pọ̀ sórí dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo sì máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù mú kí n borí àárò ilé tó máa ń sọ mí. Kò sì pẹ́ tí àwọn ìrírí tó ń múni láyọ̀ tí mo ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní nínú ìjọ fi mú kí n tún máa láyọ̀.”

Ìpèníjà míì ni ti ibùgbé. Ó ṣeé ṣe kí ibi téèyàn máa gbé yàtọ̀ sí irú ibi téèyàn ń gbé kó tó lọ síbẹ̀. Beau tó wá láti orílẹ̀-èdè Kánádà sọ fún wa pé: “Ní orílẹ̀-èdè tó o ti wá, o lè má fi bẹ́ẹ̀ ka àwọn ohun tó wọ́pọ̀ bí iná mànàmáná àti omi ẹ̀rọ sí. Àmọ́ níbí, ìgbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́ ni wọ́n máa ń mú iná àti omi lọ.” Ipò òṣì, àwọn ohun ìrìnnà tí kò tuni lára àti àìmọ̀wé wọ́pọ̀ gan-an ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Bí Ines tó wá láti orílẹ̀-èdè Austria ṣe máa ń kojú àwọn ipò yìí ni pé ó máa ń pọkàn pọ̀ sórí ànímọ́ rere táwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ ní. Ó sọ pé: “Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlejò gan-an, èèyàn jẹ́jẹ́ ni wọ́n, wọ́n máa ń ranni lọ́wọ́, wọ́n sì níwà ìrẹ̀lẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó máa ń wù wọ́n gan-an láti mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run.”

‘ÌBÙKÚN TÍTÍ KÌ YÓÒ FI SÍ ÀÌNÍ MỌ́’

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tó ń sìn ní orílẹ̀-èdè Ecuador yìí ti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan, wọ́n ti rí i pé Jèhófà máa ń pèsè fún wọn ‘lọ́pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun’ tí wọ́n lérò pé àwọn lè rí gbà. (Éfé. 3:20) Kódà, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọ́n ti ‘rí ìbùkún gbà títí tí kò fi sí àìní mọ́.’ (Mál. 3:10) Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ṣe rí lára wọn rèé:

Bruno: “Ibi odò Amazon tó jẹ́ àgbègbè tó fani mọ́ra ni mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn mi ní orílẹ̀-èdè Ecuador. Nígbà tó yá, mo bá àwọn tó ń kọ́lé ṣiṣẹ́ nígbà ìmúgbòòrò ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Ecuador. Ní báyìí, mo ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tí mo ṣì wà ní Ítálì, mo pinnu láti fi Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́, ó sì ń jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn mi ní ìmúṣẹ pé màá fẹ́ láti fi ìgbésí ayé mi ṣe onírúurú àwọn nǹkan tó lárinrin nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.”

Beau: “Mo ti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà torí pé ní orílẹ̀-èdè Ecuador, ó ṣeé ṣe fún mi láti máa lo gbogbo àkókò mi fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Ní àfikún sí ìyẹn, mo tún ti ní àǹfààní láti máa rìnrìn àjò lọ sí àwọn ibi tó fani mọ́ra, ó sì ti pẹ́ tí èyí ti máa ń wù mí.”

Anna: “Gẹ́gẹ́ bí arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ, mi ò rò pé ó máa ṣeé ṣe fún mi lọ́jọ́ kan láti bára mi nípò tó dà bíi tàwọn míṣọ́nnárì. Àmọ́, mo ti wá mọ̀ báyìí pé ó ṣeé ṣe. Mo dúpẹ́ pé Jèhófà ń bù kún ìsapá mi. Inú mi dùn gan-an pé mò ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, mò ń bá wọn kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo sì ń ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun.”

Elke: “Ní orílẹ̀-èdè Austria tí mo ti wá, mo sábà máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí n ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan péré. Àmọ́ níbí, mo ti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15]! Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń tẹ̀ síwájú ṣe ń láyọ̀ máa ń mú kí n ní ìtẹ́lọ́rùn tó pọ̀.”

Joel: “Ìrírí ńlá gbáà ló jẹ́ pé kéèyàn lọ sí ibi tí kò mọ̀ kó lè lọ máa sin Jèhófà níbẹ̀. Ó máa mú kéèyàn túbọ̀ gbára lé Ọlọ́run. Ó sì máa ń múni lórí yá láti rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún ìsapá ẹni! Ní ọdún àkọ́kọ́ tí mo débí láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, akéde mẹ́fà ló wà nínú àwùjọ tí mò ń dára pọ̀ mọ́, àmọ́ ní báyìí a ti di mọ́kànlélógún. Àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi sì jẹ́ àádọ́fà [110].”

ÌWỌ NÁÀ ŃKỌ́?

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin tí ẹ jẹ́ ọ̀dọ́, ǹjẹ́ ipò yín yọ̀ǹda fún yín láti lọ sìn ní ilẹ̀ tí wọ́n ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i? Àmọ́ ṣá o, ṣíṣe irú ìpinnu ńlá bẹ́ẹ̀ máa gba pé kẹ́ ẹ fara balẹ̀ wéwèé bẹ́ ẹ ṣe máa ṣe é. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà àti aládùúgbò yín kẹ́ ẹ tó lè lọ sìn níbòmíràn. Tẹ́ ẹ bá ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ sì tún kúnjú ìwọ̀n, ẹ gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà pé ẹ máa fẹ́ láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Síwájú sí i, ẹ sọ ohun tẹ́ ẹ ní lọ́kàn láti ṣe fún àwọn òbí yín tí wọ́n jẹ́ Kristẹni àti àwọn alàgbà ìjọ. Lẹ́yìn èyí, ẹ lè wá rí i pé ẹ̀yin pẹ̀lú lè kópa nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó gbádùn mọ́ni tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn yìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

“Ọ̀pọ̀ àdúrà tí mo gbà sí Jèhófà àti ọ̀rọ̀ àjọsọ tó gba àkókò gígùn tí mo ní pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ló jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà máa ń bù kún ẹni tó bá yọ̀ǹda ara rẹ̀ tinútinú.” —Kayla láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Bó o ṣe lè múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn ní ilẹ̀ òkèèrè

• Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́

• Ṣe àtúnyẹ̀wò Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2011, ojú ìwé 5 sí 7

• Bá àwọn míì tí wọ́n ti sìn ní ilẹ̀ òkèèrè sọ̀rọ̀

• Ṣe ìwádìí nípa àṣà àti ìtàn orílẹ̀-èdè náà

• Kọ́ díẹ̀ lára èdè wọn

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Kí àwọn kan tí wọ́n ń sìn ní ilẹ̀ òkèèrè lè gbọ́ bùkátà àrà wọn . . .

• wọ́n máa ń lọ ṣiṣẹ́ fún oṣù mélòó kan lọ́dọọdún ní orílẹ̀-èdè wọn

• wọ́n máa ń fi ilé wọn tàbí yàrá tí wọ́n ń gbé háyà, tàbí kí wọ́n fa okòwò wọn lé ẹlòmíì lọ́wọ́

• wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

1 Jaqueline láti orílẹ̀-èdè Jámánì

2 Bruno láti orílẹ̀-èdè Ítálì

3 Beau láti orílẹ̀-èdè Kánádà

4 Siobhan láti orílẹ̀-èdè Ireland

5 Joel láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

6 Jonathan láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

7 Anna láti orílẹ̀-èdè Estonia

8 Elke láti orílẹ̀-èdè Austria

9 Chantal láti orílẹ̀-èdè Kánádà

10 Ines láti orílẹ̀-èdè Austria