Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ̀san Wà fún Ìgbòkègbodò Yín”

“Ẹ̀san Wà fún Ìgbòkègbodò Yín”

“Ẹ̀san Wà fún Ìgbòkègbodò Yín”

ÁSÀ ỌBA gba ibi àwọn ilẹ̀ olókè Jùdíà bó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àwọn ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà ní etíkun. Ó yára darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gba àfonífojì kan tó jìn kọjá lọ. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí àfonífojì náà ti fẹ̀ gan-an, Ásà dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì. Ó rí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá tí wọ́n pọ̀ lọ súà ní apá ìsàlẹ̀ àfonífojì náà! Gbogbo àwọn ọmọ ogun Etiópíà yẹn tó mílíọ̀nù kan. Àmọ́ díẹ̀ làwọn ọmọ ogun Ásà fi ju ìdajì iye yẹn lọ.

Pẹ̀lú bí ogun ṣe rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí, kí ni ohun tó máa gba Ásà lọ́kàn jù lọ? Ṣé àṣẹ tó máa pa fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ni? Ṣé ọ̀rọ̀ kóríyá tó máa sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni? Àbí lẹ́tà tó máa kọ sí àwọn ará ilé rẹ̀? Rárá o! Nínú ipò eléwu tí Ásà bá ara rẹ̀ yìí, ńṣe ló gbàdúrà.

Ká tó sọ̀rọ̀ nípa àdúrà tí Ásà gbà àti ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò náà, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa irú ẹni tí Ásà jẹ́. Kí ló mú kó ṣe ohun tó ṣe yìí? Ǹjẹ́ ó tọ́ bó ṣe wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run? Kí ni ìtàn Ásà kọ́ wa nípa bí Jèhófà ṣe ń bù kún ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Rẹ̀?

ÌTÀN ÁSÀ

Láàárín ogún ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín sí ìjọba méjì, ìbọ̀rìṣà ti sọ ilẹ̀ Júdà dìdàkudà. Kódà wọ́n ń bọ òrìṣà àwọn ará Kénáánì tí wọ́n gbà pé ó ń sọ àgàn di ọlọ́mọ ní ààfin nígbà tí Ásà di ọba lọ́dún 977 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ Bíbélì sọ nípa ìṣàkóso Ásà Ọba pé ó “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.” Ásà “mú àwọn pẹpẹ ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ibi gíga kúrò, ó sì fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ túútúú, ó sì ké àwọn òpó ọlọ́wọ̀ lulẹ̀.” (2 Kíró. 14:2, 3) Ásà tún mú “àwọn kárùwà ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì” tí wọ́n ń bá àwọn ọkùnrin lò pọ̀ lórúkọ ẹ̀sìn kúrò ní ilẹ̀ Júdà. Àmọ́, ó ṣe àwọn nǹkan míì yàtọ̀ sí mímú ìjọsìn èké kúrò. Ó rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n “wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn” kí wọ́n sì pa “òfin àti àṣẹ” Ọlọ́run mọ́.—1 Ọba 15:12, 13; 2 Kíró. 14:4.

Torí pé inú Jèhófà dùn sí ìtara tí Ásà ní fún ìjọsìn tòótọ́, ó mú kí àlàáfíà jọba fún ọ̀pọ̀ ọdún nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ọba náà fi lè sọ pé: “A ti wá Jèhófà Ọlọ́run wa. A ti wá a, ó sì fún wa ní ìsinmi yí ká.” Àwọn èèyàn náà lo àkókò àlàáfíà yìí láti mú kí àwọn odi tí wọ́n mọ yí ká àwọn ìlú tó wà ní Júdà lágbára sí i. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, wọ́n sì ṣe àṣeyọrí sí rere.”—2 Kíró. 14:1, 6, 7.

LÓJÚ OGUN

Látàrí ohun tí ìtàn sọ nípa Ásà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ó gbàdúrà nígbà tí àwọn ọmọ ogun tó tíì pọ̀ jù lọ nínú àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ dojú ìjà kọ ọ́. Ásà mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń san ẹ̀san fún àwọn tó bá ṣe ohun tó fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́. Nígbà tí ọba náà gbàdúrà, ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Ásà mọ̀ pé tí òun bá gbọ́kàn lé Ọlọ́run tó sì ti òun lẹ́yìn, bí àwọn ọ̀tá náà ṣe pọ̀ tó àti bí wọ́n ṣe lágbára tó kò já mọ́ nǹkan kan. Torí pé ọ̀ràn náà kan orúkọ Jèhófà, Ásà jẹ́ kí àdúrà rẹ̀ dá lórí orúkọ yẹn. Ọba náà gbàdúrà pé: “Ràn wá lọ́wọ́, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ ni a gbára lé, orúkọ rẹ sì ni a fi dojú kọ ogunlọ́gọ̀ yìí. Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú ní okun láti dojú kọ ọ́.” (2 Kíró. 14:11) Ńṣe ni ìyẹn dà bí ìgbà téèyàn sọ pé: ‘Jèhófà ìwọ ni àwọn ará Etiópíà yìí dojú ìjà kọ. Má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn lásán-làsàn tàbùkù sí orúkọ rẹ nípa gbígbà wọ́n láyè láti ṣẹ́gun àwọn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ ẹ.’ Fún ìdí yìí “Jèhófà ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà níwájú Ásà àti níwájú Júdà, àwọn ará Etiópíà sì fẹsẹ̀ fẹ.”—2 Kíró. 14:12.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn alátakò tó lágbára ń dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Jèhófà. A kò ní kó ohun ìjà ogun lọ sojú ogun láti bá wọn jà. Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣẹ́gun fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó ń jagun tẹ̀mí nítorí orúkọ rẹ̀. Ogun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa jà lè jẹ́ láti borí ìwàkiwà tó kúnnú ayé, láti jìjàkadì pẹ̀lú ìkùdíẹ̀-káàtó tiwa fúnra wa, tàbí láti dáàbò bo ìdílé wa lọ́wọ́ àwọn ìwà tó ń sọni di ẹlẹ́gbin. Àmọ́, láìka àdánwò tá a lè bá pàdé sí, àdúrà tí Ásà gbà lè fún wa ní ìṣírí. Jèhófà ló ṣẹ́gun fún un. Èyí sì jẹ́ kí àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run mọ ohun tí àwọn lè máa retí. Kò sí bí èèyàn ṣe lè lágbára tó, tó máa borí Jèhófà.

Ọ̀RỌ̀ ÌṢÍRÍ ÀTI ÌKÌLỌ̀

Lẹ́yìn tí Ásà dé látojú ogun, wòlíì Asaráyà lọ pàdé rẹ̀. Ó fún un ní ìṣírí, ó sì tún kìlọ̀ fún un. Ó ní: “Gbọ́ mi, ìwọ Ásà àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì! Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀; bí ẹ bá sì wá a, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun, ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi í sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀. . . . Ẹ jẹ́ onígboyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọwọ́ yín rọ jọwọrọ, nítorí pé ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.”—2 Kíró. 15:1, 2, 7.

Àwọn ọ̀rọ̀ yìí lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Wọ́n fi hàn pé Jèhófà yóò wà pẹ̀lú wa, tá a bá ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín. Wọ́n mú kó dá wa lójú pé ó máa gbọ́ tiwa tá a bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Asaráyà sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà.” Ó sábà máa ń gba pé ká jẹ́ onígboyà ká tó lè ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ onígboyà.

Ásà tún dojú kọ ìṣòro ńlá míì, ìyẹn ni yíyọ Máákà ìyá rẹ̀ àgbà kúrò nípò “ìyáàfin,” torí pé ó ṣe “òrìṣà bíbanilẹ́rù kan fún òpó ọlọ́wọ̀.” Ó borí ìṣòro yìí, ó sì tún dáná sun àwọn òrìṣà rẹ̀. (1 Ọba 15:13) Ọlọ́run bù kún Ásà torí pé ó fìgboyà ṣe ohun tó tọ́. Àwa náà gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà láìkù síbì kan, yálà àwọn ìbátan wa jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run tàbí wọn kì í ṣe adúróṣinṣin. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa san wá lẹ́san nítorí ìṣòtítọ́ wa.

Ara ẹ̀san tí Ọlọ́run san fún Ásà ni pé ó rí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àríwá tó ti di apẹ̀yìndà tí wọ́n ń rọ́ wá sí Júdà nígbà tí wọ́n rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n mọrírì ìjọsìn mímọ́ débi pé wọ́n yàn láti fi ilé wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè máa gbé láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Lẹ́yìn náà ni Ásà àti gbogbo Júdà wá fi ayọ̀ wọnú “májẹ̀mú láti fi gbogbo ọkàn-àyà wọn àti gbogbo ọkàn wọn wá Jèhófà.” Kí ló wá jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ọlọ́run jẹ́ “kí wọ́n rí òun; Jèhófà sì ń bá a lọ láti fún wọn ní ìsinmi yí ká.” (2 Kíró. 15:9-15) Ẹ sì wo bí inú wá ṣe máa ń dùn tó nígbà tí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo bá wá sínú ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà!

Àmọ́ ṣá o, wòlíì Asaráyà tún mẹ́nu kan ohun búburú tó lè ṣẹlẹ̀. Ó kìlọ̀ pé: “Bí ẹ bá fi [Jèhófà] sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀.” Ká má ṣe gbà kí èyí ṣẹlẹ̀ sí wa láé, torí pé àbájáde rẹ̀ kì í dára! (2 Pét. 2:20-22) Ìwé Mímọ́ kò sọ ìdí tí Jèhófà fi fún Ásà ní ìkìlọ̀ yìí, àmọ́ Ásà kò ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ náà.

“ÌWỌ TI HÙWÀ ÒMÙGỌ̀”

Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìṣàkóso Ásà, Bááṣà Ọba Ísírẹ́lì wá gbéjà ko ilẹ̀ Júdà lọ́nà rírorò. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Bááṣà kò fẹ́ kí àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀ fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Ásà àti ìjọsìn mímọ́, torí náà ó mú kí àwọn odi ìlú Rámà tó wà ní kìlómítà mẹ́jọ sí àríwá ìlú Jerúsálẹ́mù lágbára sí i. Dípò tí Ásà ì bá fi wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run bó ti ṣe nígbà tí àwọn ará Etiópíà wá gbéjà kò ó, ọ̀dọ̀ èèyàn ló wá ìrànlọ́wọ́ lọ. Ó fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ọba Síríà, ó ní kó lọ gbéjà ko ìjọba àríwá Ísírẹ́lì. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Síríà bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn ìlú tó wà ní àríwá Ísírẹ́lì, Bááṣà sá kúrò ní ìlú Rámà.—2 Kíró. 16:1-5.

Inú Jèhófà kò dùn sí ohun tí Ásà ṣe yìí, ó sì rán wòlíì Hánáánì láti lọ sọ fún un. Níwọ̀n bí Ásà ti mọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn ará Etiópíà, ó yẹ kó ti mọ̀ pé, ní ti Jèhófà, “ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Ásà gba ìmọ̀ràn tí kò tọ́ tàbí kó ronú pé Bááṣà àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò lè tu irun kankan lára òun, kó sì gbà pé òun lè dá bójú tó ọ̀ràn náà. Èyí ó wù kó jẹ́, èrò èèyàn ni Ásà tẹ̀ lé, kò gbára lé Jèhófà. Hánáánì wá sọ fún un pé: “Ìwọ ti hùwà òmùgọ̀ nípa èyí, nítorí, láti ìsinsìnyí lọ ogun yóò máa jà ọ́.”—2 Kíró. 16:7-9.

Ásà fara ya. Ó fìbínú ju wòlíì Hánáánì sínú ilé àbà. (2 Kíró. 16:10) Àbí Ásà ti lè máa ronú pé, ‘Ṣó wá yẹ kí wọ́n bá mi wí lẹ́yìn tí mo ti jẹ́ olóòótọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún?’ Ṣé ká wá sọ pé àgbà tó ti dé sí i ni kò jẹ́ kó lè ronú lọ́nà tó já geere mọ́? Bíbélì kò sọ fún wa.

Ní ọdún kọkàndínlógójì [39] ìṣàkóso Ásà, ó ní òjòjò kan ní ẹsẹ̀ rẹ̀ tó mú kó ṣàìsàn gidigidi. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Nínú àìsàn rẹ̀ pàápàá, kò wá Jèhófà ṣùgbọ́n àwọn amúniláradá ni ó ń wá.” Ní àkókò yẹn, ó jọ pé Ásà kò ka àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run sí mọ́. Kò sí àní-àní pé inú ipò tó wà yìí ló kú sí ní ọdún kọkànlélógójì [41] ìṣàkóso rẹ̀.—2 Kíró. 16:12-14.

Síbẹ̀ náà, ó jọ pé àwọn ànímọ́ rere tí Ásà ní àti ìtara rẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́ borí àwọn àṣìṣe rẹ̀. Kò ṣíwọ́ láti máa sin Jèhófà. (1 Ọba 15:14) Tá a bá fojú bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí wò ó, ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀? Ó kọ́ wa pé, ó yẹ ká máa rántí àwọn ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ti ṣe fún wa, torí pé rírántí irú nǹkan pàtàkì bẹ́ẹ̀ lè mú ká gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dojú kọ àdánwò míì. Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ ronú pé a kò nílò ìbáwí tó dá lórí Ìwé Mímọ́ torí pé a ti fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Láìka àwọn ohun rere tá a ti gbé ṣe sí, Jèhófà yóò bá wa wí tá a bá ṣàṣìṣe. A gbọ́dọ̀ fi sùúrù gba irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ kó bàa lè ṣe wá láǹfààní. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé Baba wa ọ̀run yóò wà pẹ̀lú wa bí àwa náà bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ojú Jèhófà ń wá gbogbo ilẹ̀ ayé láti rí àwọn tó ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín. Ó máa ń san wọ́n lẹ́san nípa fífi agbára rẹ̀ gbà wọ́n. Ohun tí Jèhófà ṣe fún Ásà nìyẹn, Ó sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwa náà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Jèhófà máa ń san àwọn olóòótọ́ tó ń ja ogun tẹ̀mí lẹ́san

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

A nílò ìgboyà ká lè máa ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà