Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Dúró Gbọn-in Kẹ́ Ẹ Sì Sá Fún Àwọn Ohun Tí Sátánì Fi Ń Múni!

Ẹ Dúró Gbọn-in Kẹ́ Ẹ Sì Sá Fún Àwọn Ohun Tí Sátánì Fi Ń Múni!

Ẹ Dúró Gbọn-in Kẹ́ Ẹ Sì Sá Fún Àwọn Ohun Tí Sátánì Fi Ń Múni!

“Ẹ . . . dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”​—ÉFÉ. 6:11.

BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?

Kí ni ẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lè ṣe kó má bàa kó sínú ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì?

Kí ló lè ran Kristẹni kan tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́ kó má bàa kó sínú ọ̀fìn panṣágà?

Kí nìdí tó o fi gbà pé ó ṣàǹfààní kéèyàn má ṣe fàyè gba ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìṣekúṣe?

1, 2. (a) Kí nìdí tí Sátánì kò fi láàánú àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” lójú? (b) Àwọn ohun tí Sátánì fi ń múni wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 SÁTÁNÌ ÈṢÙ kò láàánú àwọn èèyàn lójú, pàápàá jù lọ àwọn tó ń sin Jèhófà. Ká sòótọ́, ńṣe ni Sátánì ń bá àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró jagun. (Ìṣí. 12:17) Àwọn Kristẹni adúróṣinṣin yìí ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lóde òní, wọ́n sì ń tú àṣírí Sátánì pé òun ni olùṣàkóso ayé yìí. Bákan náà, Èṣù kò nífẹ̀ẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n sì nírètí láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tó ti bọ́ mọ́ Sátánì lọ́wọ́. (Jòh. 10:16) Abájọ tó fi ń bínú kíkan-kíkan! Yálà a ní ìrètí láti lọ sí ọ̀run tàbí láti wà lórí ilẹ̀ ayé, ire wa kò jẹ Sátánì lógún, bó ṣe máa sọ wá di ẹran ọdẹ rẹ̀ ló ń wá.—1 Pét. 5:8.

2 Kí ọwọ́ Sátánì lè tẹ̀ wá, ó ti dẹ onírúurú páńpẹ́ tàbí ìdẹkùn. Níwọ̀n bó sì ti “fọ́ èrò inú” àwọn aláìgbàgbọ́, wọn kì í fẹ́ gba ìhìn rere, wọn ò sì lè rí àwọn ìdẹkùn yìí. Àmọ́ ṣá o, Èṣù tún ń dẹkùn mú àwọn kan tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 4:3, 4) Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ bá a ṣe lè sá fún mẹ́ta lára àwọn ohun tí Sátánì fi ń múni, ìyẹn (1) sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù, (2) ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àti (3) ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè dúró gbọin-in lòdì sí méjì míì lára àwọn ohun tí Sátánì fi ń múni, ìyẹn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìdánwò láti ṣe panṣágà.

ÌFẸ́ ỌRỌ̀ ÀLÙMỌ́Ọ́NÌ, OKÙN TÍ Ń FÚNNI PA

3, 4. Báwo ni àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí ṣe lè mú ká máa nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì?

3 Nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jésù, ó sọ̀rọ̀ nípa irúgbìn tí wọ́n gbìn sáàárín ẹ̀gún. Ó ṣàlàyé pé ẹnì kan lè gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ‘ṣùgbọ́n kí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, kó sì di aláìléso.’ (Mát. 13:22) Ó dájú pé ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì jẹ́ ọ̀kan lára ìdẹkùn tí Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá wa ń lò.

4 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé ohun méjì ló fún ọ̀rọ̀ náà pa. Èyí àkọ́kọ́ ni “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí.” Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kó o máa ṣàníyàn. (2 Tím. 3:1) Nítorí bí àwọn nǹkan ṣe túbọ̀ ń gbówó lórí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò sì níṣẹ́ lọ́wọ́, ó lè ṣòro fún ẹ láti máa wá jíjẹ mímu. O tún lè máa ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, kó o sì máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ màá máa rí owó tó pọ̀ tó ná lẹ́yìn tí mo bá fẹ̀yìn tì?’ Bí àwọn kan ṣe ń ṣàníyàn ti mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lépa ọrọ̀, wọ́n ronú pé bí àwọn bá lówó lọ́wọ́ ọkàn àwọn á balẹ̀.

5. Báwo ni ‘agbára ọrọ̀’ ṣe lè tanni jẹ?

5 Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa ohun kejì, ìyẹn ni “agbára ìtannijẹ ọrọ̀.” Èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú àníyàn, lè fún ọ̀rọ̀ náà pa. Òótọ́ ni Bíbélì sọ pé ‘owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ (Oníw. 7:12) Àmọ́, kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa lépa ọrọ̀. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé bí àwọn ṣe ń sapá tó láti kó ọrọ̀ jọ, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì túbọ̀ ń dẹkùn mú àwọn. Àwọn kan tiẹ̀ ti di ẹrú fún ọrọ̀.—Mát. 6:24.

6, 7. (a) Kí ló lè mú kéèyàn di ẹni tó ní ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì níbi tó ti ń ṣiṣẹ́? (b) Bí wọ́n bá ní kí Kristẹni kan wá máa ṣe àfikún iṣẹ́, kí làwọn ohun tó yẹ kó gbé yẹ̀ wò?

6 Ìfẹ́ láti di ọlọ́rọ̀ lè bẹ̀rẹ̀ bí ohun kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ẹni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ wá bá ẹ ó sì sọ fún ẹ pé: “Mo ní ìròyìn ayọ̀ kan fún ẹ! Wọ́n ti gbé iṣẹ́ ńlá kan fún ilé iṣẹ́ wa. Èyí túmọ̀ sí pé ní báyìí títí di oṣù mélòó kan, wàá máa ṣe àfikún iṣẹ́ lemọ́lemọ́. Àmọ́, mo fẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá ṣe iṣẹ́ náà owó tó jọjú ló máa wọlé fún ẹ.” Bó bá jẹ́ ìwọ ni wọ́n fi irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀, kí lo máa ṣe? Òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì kó o gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ, àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ni ojúṣe tó o ní. (1 Tím. 5:8) Àwọn ohun mélòó kan tún wà tó o gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò. Báwo ni àfikún iṣẹ́ tí wàá máa ṣe á ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ á jẹ́ kó o lè máa lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, tó fi mọ́ àwọn ìpàdé ìjọ àti Ìjọsìn Ìdílé?

7 Tó o bá ń ronú nípa ohun tó o máa ṣe, kí lo máa kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ṣé bí owó táá máa wọlé fún ẹ á ṣe pọ̀ tó ni àbí ipa tó máa ní lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run? Ṣé bó o ṣe ń fẹ́ láti ní owó púpọ̀ sí i á mú kó o jáwọ́ nínú fífi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ? Ǹjẹ́ o rí bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ṣe máa nípa lórí rẹ bí o kò bá fọwọ́ pàtàkì mú ipò tẹ̀mí rẹ àti ti ìdílé rẹ? Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ ní báyìí, báwo lo ṣe lè dúró gbọn-in, kó o má sì ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì fún ẹ pa?—Ka 1 Tímótì 6:9, 10.

8. Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa?

8 Bí o kò bá fẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì fún ẹ pa, ó yẹ kó o máa ṣàyẹ̀wò bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ déédéé. Ó dájú pé o kò ní fẹ́ dà bí Ísọ̀, tí ìwà rẹ̀ fi hàn pé kò ka àwọn nǹkan tẹ̀mí sí pàtàkì! (Jẹ́n. 25:34; Héb. 12:16) Ó sì dájú pé o kò ní fẹ́ dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tí wọ́n sọ fún pé kó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, kó fi owó tó rí tọrẹ fáwọn òtòṣì, kó sì máa tọ Jésù lẹ́yìn. Àmọ́, dípò tí ọkùnrin náà ì bá fi ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lo “lọ kúrò pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.” (Mát. 19:21, 22) Torí pé ọrọ̀ ti dẹkùn mú ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà, kò ṣeé ṣe fún un láti máa tọ Jésù tó jẹ́ ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí lẹ́yìn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní ńlá! Ṣọ́ra kó o má bàa pàdánù àǹfààní jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi.

9, 10. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn nǹkan tara?

9 Kó o má bàa máa ṣe àníyàn jù nípa àwọn nǹkan tara, ó dára kó o fi ìmọ̀ràn Jésù sílò. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—Mát. 6:31, 32; Lúùkù 21:34, 35.

10 Dípò tí wàá fi kó sínú ìdẹkùn agbára ìtannijẹ ọrọ̀, ńṣe ni kó o wo ọ̀rọ̀ náà bíi ti Ágúrì tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì. Ó sọ pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi.” (Òwe 30:8) Ó ṣe kedere pé Ágúrì mọ̀ pé owó lè dáàbò boni àti pé ọrọ̀ lágbára láti tanni jẹ. Ó yẹ kó o mọ̀ pé àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Tó o bá ń ṣàníyàn láìnídìí nípa àwọn nǹkan tara, ó lè gba àkókò rẹ, ó lè tán ẹ lókun, o lè má fi bẹ́ẹ̀ wá Ìjọba Ọlọ́run mọ́ tàbí kó o ṣíwọ́ láti máa wá a. Torí náà, pinnu pé o kò ní jẹ́ kí Sátánì fi ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì dẹkùn mú ẹ!—Ka Hébérù 13:5.

PANṢÁGÀ, Ọ̀FÌN TÓ FARA SIN

11, 12. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè kó sínú ọ̀fìn ṣíṣe panṣágà níbi iṣẹ́ rẹ̀?

11 Bí àwọn ọdẹ bá fẹ́ mú ẹranko kan tó lágbára, wọ́n lè gbẹ́ kòtò sí ojú ọ̀nà tó sábà máa ń gbà, wọ́n á wá to àwọn igi tẹ́ẹ́rẹ́ sórí kòtò náà, wọ́n á sì da iyẹ̀pẹ̀ bò ó. Ọ̀fìn yìí la lè fi wé irú ìdẹwò kan tí Sátánì máa ń lò jù lọ láti mú ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ohun tí kò tọ́, ìyẹn ni ìṣekúṣe. (Òwe 22:14; 23:27) Àwọn Kristẹni kan ti jìn sínú ọ̀fìn yìí torí pé wọ́n fira wọn sípò tó ti rọrùn láti ṣèṣekúṣe. Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó máa ń fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn mọ́ra, èyí sì ti mú kí wọ́n ṣe panṣágà.

12 O lè bẹ̀rẹ̀ sí í fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀ mọ́ra níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́. Kódà, ìwádìí kan fi hàn pé iye tó ju ìdajì lọ nínú àwọn obìnrin àti nǹkan bíi mẹ́ta nínú àwọn ọkùnrin mẹ́rin tó ń ṣe panṣágà ló jẹ́ pé ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ni wọ́n bá ṣèṣekúṣe. Ṣé iwọ àtàwọn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ lẹ jọ ń ṣiṣẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, irú àjọṣe wo ló wà láàárín yín? Ǹjẹ́ o ti ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí ohun tó máa dà yín pọ̀ kọjá iṣẹ́? Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí arábìnrin kan bá ti ń bá òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọkùnrin sọ ọ̀rọ̀ tí kò jẹ mọ́ iṣẹ́ léraléra, ó lè sọ ọkùnrin náà di alábàárò rẹ̀ kó sì tún wá máa sọ àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ nínú ìgbéyàwó rẹ̀ fún un. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, bí arákùnrin kan bá ń yan obìnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́, ó lè máa ronú pé: “Ó máa ń ka ọ̀rọ̀ mi sí, ó sì máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa tí mo bá ń bá a sọ̀rọ̀. Ó sì tún mọyì mi. Ì bá wù mí ká sọ pé bí ìyàwó mi ṣe ń ṣe sí mi nílé rèé!” Ǹjẹ́ o ti wá rí bó ṣe rọrùn tó fún irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ láti ṣe panṣágà?

13. Báwo lèèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í fa ojú ẹlòmíì mọ́ra nínú ìjọ?

13 Ó lè ṣẹlẹ̀ pé kí àwọn tó wà nínú ìjọ máa fa ojú ara wọn mọ́ra. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan rèé. Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni Daniel àti Sarah * ìyàwó rẹ̀. Alàgbà ni Daniel, ṣùgbọ́n ó sọ pé òun ò mọ béèyàn ṣe ń kọ nǹkan. Ó máa ń yá a lára láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún un nínú ìjọ. Gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Daniel darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àwọn ọ̀dọ́kùnrin márùn-ún, mẹ́ta lára wọn sì ti ṣe ìrìbọmi. Àwọn arákùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi yìí nílò ẹni tí wọ́n á máa fi ọ̀ràn lọ̀. Àmọ́, torí pé onírúurú iṣẹ́ tí Daniel ń bójú tó nínú ìjọ máa ń jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ dí, Sarah ló máa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá nílò fún wọn. Bó ṣe di pé Sarah di alábàárò àwọn tí ọkọ rẹ̀ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí nìyẹn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn pẹ̀lú sì di alábàárò Sarah. Ó wá dà bí ìgbà tí Sarah ń rìn ní bèbè ọ̀fìn ńlá kan. Daniel sọ pé: “Ọ̀pọ̀ oṣù ni ìyàwó mi fi gbọ́ tàwọn arákùnrin yìí. Ìyẹn ò jẹ́ kó fi bẹ́ẹ̀ ráyè kẹ́kọ̀ọ́ mọ́, kò sì rẹ́ni sọ tinú rẹ̀ fún. Èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú bí mi ò ṣe ráyè gbọ́ tiẹ̀, wá mú kí wàhálà ṣẹlẹ̀. Ìyàwó mi ṣe panṣágà pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ilé kan náà la jọ ń gbé, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ti jó rẹ̀yìn pátápátá. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń bójú tó nínú ìjọ sì ti gbà mí lọ́kàn débi pé mi ò kíyè sí i.” Kí lo lè ṣe tí irú èyí ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ẹ?

14, 15. Àwọn nǹkan wo ló lè ran àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́ tí wọn kò fi ní kó sínú ọ̀fìn panṣágà?

14 Kó o má bàa kó sínú ọ̀fìn panṣágà, ronú nípa àdéhùn tó o ṣe pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ. Jésù sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:6) Má ṣe ronú pé àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní ṣe pàtàkì ju ọkọ tàbí aya rẹ lọ. Kó o sì tún rántí pé tó o bá sábà máa ń fi ọkọ tàbí aya rẹ sílẹ̀ láti lọ jókòó sídìí àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, ìyẹn lè fi hàn pé ìdè ìgbéyàwó yín kò lágbára mọ́, èyí lè fa ìdẹwò, ó sì lè yọrí sí dídá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì.

15 Tó o bá jẹ́ alàgbà, kí lo máa ṣe nípa agbo? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.” (1 Pét. 5:2) Ó dájú pé kò yẹ kó o pa àwọn ará ìjọ tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ tì. Àmọ́, o kò gbọ́dọ̀ pa ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkọ tì torí kó o lè bójú tó ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn. Kò sídìí tó o fi ní láti gbájú mọ́ fífi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ ìjọ nígbà tí “ebi” tẹ̀mí ń pa ìyàwó rẹ nílé, kódà ó léwu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Daniel sọ pé, “Gbígbé ìgbé ayé tó dára ò túmọ̀ sí pé kéèyàn pa ìdílé rẹ̀ tì torí kó lè máa bójú tó àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn.”

16, 17. (a) Àwọn nǹkan wo làwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó lè ṣe níbi iṣẹ́ tó máa fi hàn kedere pé wọn ò gbà kéèyàn fa ojú àwọn mọ́ra? (b) Ìtẹ̀jáde wo ló lè ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa ṣe panṣágà?

16 Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó lè ran àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa kó sínú ìdẹkùn panṣágà la ti tẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí àpẹẹrẹ, Ilé Ìṣọ́ September 15, 2006, fúnni ní ìmọ̀ràn yìí: “Tó o bá wà níbi iṣẹ́ tàbí láwọn ibòmíì, yẹra fún àwọn ipò tó lè mú kí ọkàn rẹ máa fà sí obìnrin tàbí ọkùnrin míì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá dúró lẹ́yìn iṣẹ́ láti ṣe àfikún iṣẹ́ tó sì jẹ́ pé obìnrin tàbí ọkùnrin mìíràn lẹ jọ fẹ́ ṣiṣẹ́ ọ̀hún, èyí lè jẹ́ ìdẹwò fún ọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti lọ́kọ tàbí tó ti níyàwó, tó o bá wà níbi iṣẹ́, ó yẹ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ pé o ò gbàgbàkugbà. Ó dájú pé ìwọ tó ò ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ò ní fẹ́ fa ojú ẹlòmíràn mọ́ra nípa bíbá a tage tàbí nípa wíwọṣọ tàbí mímúra lọ́nà tí kò bójú mu. . . . Tó o bá fi fọ́tò ọkọ tàbí aya rẹ àti tàwọn ọmọ rẹ sí ibi iṣẹ́ rẹ, èyí á jẹ́ kí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì máa rántí pé ìdílé rẹ ló ṣe pàtàkì sí ọ jù. Pinnu pé o ò ní ṣe ohun táá jẹ́ kí ẹlòmíì fẹ́ láti fa ojú rẹ mọ́ra, tẹ́nì kan bá sì wá fẹ́ fa ojú ẹ mọ́ra, má ṣe gbà fún un.”

17 Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Jí! April–June 2009 tó ní àkòrí náà, “Kí Ló Túmọ̀ sí Pé Kí Ọkọ Tàbí Aya Má Dalẹ̀ Ara Wọn?” sọ pé kò dára kéèyàn máa ronú pé òun ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀ lò pọ̀. Àpilẹ̀kọ náà fi hàn pé bí ẹnì kan bá ń ronú pé òun ń bá ẹlòmíì lò pọ̀, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ rọrùn fún un láti ṣe panṣágà. (Ják. 1:14, 15) Tó o bá ti ṣe ìgbéyàwó, ohun tó máa mọ́gbọ́n dání ni pé kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jọ máa jíròrò irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ látìgbàdégbà. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, ohun mímọ́ ló sì jẹ́. Tó o bá ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó yín, ńṣe lò ń fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan mímọ́.—Jẹ́n. 2:21-24.

18, 19. (a) Àwọn nǹkan wo ni panṣágà máa ń yọrí sí? (b) Kí ni jíjẹ́ olóòótọ́ nínú ìgbéyàwó máa ń yọrí sí?

18 Tó o bá rí i pé ọkàn rẹ ti ń fẹ́ máa fà sí ẹnì kan tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ, ronú nípa bí ṣíṣe àgbèrè àti panṣágà ṣe máa ń yọrí sí ibi tí kò dáa. (Òwe 7:22, 23; Gál. 6:7) Téèyàn bá ṣèṣekúṣe, ó máa ń dun Jèhófà, yóò sì ṣèpalára fún ọkọ tàbí aya onítọ̀hún àtẹni tó ṣèṣekúṣe náà. (Ka Málákì 2:13, 14.) Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o máa ronú lórí àwọn àǹfààní tí àwọn tó jẹ́ oníwà mímọ́ máa ní. Kì í ṣe pé wọ́n máa ní ìrètí láti wà láàyè títí láé nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún máa gbádùn ìgbésí ayé tó dára jù lọ báyìí, wọ́n á sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.—Ka Òwe 3:1, 2.

19 Onísáàmù náà kọrin pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ [Ọlọ́run], kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.” (Sm. 119:165) Torí náà, nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, kó o sì “máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí [o] ṣe ń rìn” ní àwọn àkókò búburú tá à ń gbé yìí “kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n.” (Éfé. 5:15, 16) Ojú ọ̀nà tá à ń tọ̀ kún fún àwọn ìdẹkùn tí Sátánì fẹ́ láti fi mú àwọn olùjọsìn tòótọ́. Àmọ́, a ti ní ọ̀pọ̀ nǹkan tá a lè fi dáàbò bo ara wa. Jèhófà ti fún wa ní ohun tá a nílò láti “dúró gbọn-in gbọn-in” ká lè “paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà”!—Éfé. 6:11, 16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè fúnni pa nípa tẹ̀mí. Má ṣe jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ láé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Tó o bá ń tage tàbí tó ò ń jẹ́ kí wọ́n bá ẹ tage, ó lè mú kó o ṣe panṣágà