Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Jẹ́ Ká Bá Àwọn Arìnrìn-Àjò Ìsìn Lọ Sóde Ẹ̀rí

Ẹ Jẹ́ Ká Bá Àwọn Arìnrìn-Àjò Ìsìn Lọ Sóde Ẹ̀rí

Látinú Àpamọ́ Wa

Ẹ Jẹ́ Ká Bá Àwọn Arìnrìn-Àjò Ìsìn Lọ Sóde Ẹ̀rí

“MI Ò lè wá máa ti ilé kan lọ sí ìkejì!” Bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nìyí tí wọ́n bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún àwọn tí wọn kò mọ̀. Àmọ́ arákùnrin kan tó jẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ tó sì máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower tí wọn kò sì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ ń wá bí wọ́n ṣe máa dara pọ̀ mọ́ àwọn tí òùngbẹ òtítọ́ Bíbélì ń gbẹ bíi tiwọn. Ìwé ìròyìn náà rọ àwọn tó ń kà á pé kí wọ́n ṣàwárí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ ṣíṣeyebíye bíi tiwọn kí wọ́n sì máa pé jọ déédéé láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láti nǹkan bí ọdún 1894 ni àjọ Watch Tower Society ti bẹ̀rẹ̀ sí í rán àwọn aṣojú tó máa ń rìnrìn-àjò lọ sọ́dọ̀ àwùjọ tó bá béèrè fún irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Àwọn aṣojú yìí la wá mọ̀ sí arìnrìn-àjò ìsìn, wọ́n ní ìrírí wọ́n sì máa ń tẹra mọ́ṣẹ́. A yàn wọ́n bí aṣojú torí pé wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn tútù, wọ́n ní ìmọ̀ Bíbélì, wọ́n jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́, wọ́n ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà. Ọwọ́ wọn máa ń dí gan-an tí wọ́n bá wá ṣe ìbẹ̀wò, wọn kì í sì í lò ju ọjọ́ kan tàbí méjì lọ. Ọ̀pọ̀ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n pín ìwé tí wọ́n fi pe àwọn èèyàn wá gbọ́ àsọyé arìnrìn-àjò ìsìn ni wọ́n kọ́kọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Lẹ́yìn tí Arákùnrin Hugo Riemer, tó wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, parí àsọyé tó sọ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì títí di ìdájí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́, ó láyọ̀, ó sì sọ pé ìpàdé náà “lárinrin.”

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé ohun pàtàkì tí ìbẹ̀wò àwọn arìnrìn-àjò ìsìn wà fún ni pé kí wọ́n lè gbé “agbo ilé ìgbàgbọ́” ró nípasẹ̀ àwọn ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe nínú ilé àwọn onígbàgbọ́. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ní àgbègbè kan náà máa ń wá láti gbọ́ àsọyé kí wọ́n sì lóhùn sí apá tó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn Kristẹni wọ̀nyí á ṣe ara wọn lálejò. Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, ọmọdébìnrin kan tó ń jẹ́ Maude Abbott lọ gbọ́ àsọyé, lẹ́yìn àsọyé náà gbogbo àwọn tó wá síbẹ̀ jókòó sídìí tábìlì gbọọrọ kan tó wà nínú ọgbà ilé náà. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ oúnjẹ aládùn ló wà níbẹ̀, irú bí itan ẹlẹ́dẹ̀, adìyẹ díndín, onírúurú búrẹ́dì, ìpápánu àti kéèkì! Gbogbo wa la jẹ àjẹtẹ́rùn, nígbà tó sì di nǹkan bí aago méjì ọ̀sán, a pé jọ láti gbọ́ àsọyé míì. Àmọ́ oorun ti bẹ̀rẹ̀ sí í kun gbogbo wa.” Benjamin Barton tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn sọ nígbà kan pé ‘Tó bá jẹ́ pé gbogbo oúnjẹ aládùn tí wọ́n ń fún mi nígbà yẹn ni mò ń jẹ ni, màá ti kú tipẹ́tipẹ́.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò rere làwọn arábìnrin tó ń pèsè àwọn oúnjẹ yìí ní lọ́kàn, nígbà tó yá lẹ́tà kan láti oríléeṣẹ́ ní Brooklyn jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tó sàn jù ni pé kí wọ́n fún àwọn arìnrìn-àjò ìsìn ní “ìwọ̀nba oúnjẹ òòjọ́” tí kò ní máa “dí oorun wọn lọ́wọ́.”

Àwọn arìnrìn-àjò ìsìn dáńgájíá nínú kíkọ́ni àti lílo àwọn àtẹ ìsọfúnni, wọ́n tún máa ń lo àwọn ohun àfiṣàpẹẹrẹ tàbí ohunkóhun tó lè mú kí àlàyé wọn ṣe kedere. Bí Arákùnrin R. H. Barber bá ń sọ àsọyé, ó “máa ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó gbádùn mọ́ni.” Ohùn àgbà ni Arákùnrin W. J. Thorn fi máa ń sọ̀rọ̀. Á sì dà bí ìgbà tí “baba ńlá ìgbàanì kan” ń báni sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n ń fi mọ́tò Model A Ford gbé Arákùnrin Shield Toutjian lọ síbì kan, ó ṣàdédé ké jáde pé, “Ẹ dúró!” Ó bẹ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ náà, ó já àwọn òdòdó kan nínú igbó, ó sì yára fi wọ́n kọ́ àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ náà lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá.

Ìṣòro tí àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn ń dojú kọ máa ń mú kí àwọn nǹkan túbọ̀ nira fún àwọn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogójì sí ọgọ́ta ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, ohun tó dán ìgbàgbọ́ àwọn kan lára wọn wò jù lọ ni ìyípadà tó dé bá iṣẹ́ wọn. Wọ́n ní láti máa mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé. Ilé Ìṣọ́ March 15, 1924 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé “ọ̀kan pàtàkì lára iṣẹ́ àyànfúnni” àwọn Kristẹni tòótọ́ “ni láti jẹ́rìí nípa ìjọba Ọlọ́run. Nítorí èyí la ṣe ń rán àwọn arìnrìn-àjò ìsìn jáde.”

Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan lára àwọn arìnrìn-àjò ìsìn náà kò fara mọ́ ìyípadà yìí torí pé wọ́n fi iṣẹ́ arìnrìn-àjò sílẹ̀, àwọn kan tó ya aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn nínú wọn tiẹ̀ lọ dá ẹ̀sìn tiwọn sílẹ̀. Arákùnrin Robie D. Adkins rántí bí arìnrìn-àjò ìsìn kan tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ ṣe ráhùn pé: “Gbogbo ohun tí mo mọ̀ kò ju bí mo ṣe lè wàásù látorí pèpéle. Mi ò lè wá máa ti ilé kan lọ sí ìkejì!” Arákùnrin Adkins sọ pé: “Àpéjọ àgbègbè tá a ṣe ní ọdún 1924 ní ìlú Columbus, ní ìpínlẹ̀ Ohio ni mo tún ti bá a pàdé. Láàárín gbogbo àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀, ó hàn lára rẹ̀ pé òun nìkan ni kò láyọ̀, ó dá wà ní ibòji lábẹ́ igi kékeré kan, ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò láàárín ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará tó kún fún ayọ̀. Mi ò rí i mọ látìgbà yẹn. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tó fi kúrò nínú ètò Ọlọ́run.” Àmọ́, “ọ̀pọ̀ àwọn ará tí inú wọn ń dùn ń kó àwọn ìwé kọjá lọ sí ìdí ọkọ̀ wọn,” ó sì dájú pé wọ́n ti ṣe tán láti lọ máa wàásù láti ilé dé ilé.—Ìṣe 20:20, 21.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò ìsìn náà ni iṣẹ́ ìwàásù ń já láyà bíi ti àwọn tí wọ́n ní kí wọ́n lọ fún ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ wọ́n fi ìtara ṣe iṣẹ́ náà. Arákùnrin Maxwell G. Friend (Freschel) tó jẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn tó ń sọ èdè Jámánì sọ nípa ìwàásù ilé-dé-ilé pé, “Apá yìí nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn máa ń fi kún àwọn ìbùkún tí à ń rí lẹ́nu iṣẹ́ náà.” Arákùnrin John A. Bohnet tó jẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn ròyìn pé àwọn ará lápapọ̀ gbà tọkàntọkàn pé ó yẹ ká máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ó ní ọ̀pọ̀ nínú wọn ni “iná ìtara wọn ń jó lala, wọ́n sì ń fẹ́ láti jẹ́ òléwájú nínú iṣẹ́ náà.”

Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni àwọn arákùnrin olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ arìnrìn-àjò ti ń nípa rere lórí àwọn ará. Arákùnrin Norman Larson, tó ti ń sìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sọ pé: “Ìjẹ́pàtàkì àti àǹfààní àwọn arìnrìn-àjò ìsìn kọjá àfẹnusọ, kódà èmi tí mo jẹ́ ọmọdé nígbà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe bẹbẹ láti tọ́ mi lọ́nà tó tọ́.” Títí dòní, irú àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n sì lẹ́mìí ìfara ẹni rúbọ bẹ́ẹ̀ ń ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sọ pé, “Ó ṣeé ṣe fún wa láti wàásù láti ilé dé ilé!”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 32]

Inú wa máa ń dùn táwọn arìnrìn-àjò ìsìn bá wá bẹ̀ wá wò!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àkọsílẹ̀ Arákùnrin Benjamin Barton lọ́dún 1905, tó sọ ibi àádọ́sàn-án [170] tó máa ṣèbẹ̀wò sí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Walter J. Thorn jẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn, wọ́n sì máa ń pè é ní “Pappy” [Baba] torí pé ó fìwà jọ Kristi, ó sì máa ń ṣe bíi bàbá onífẹ̀ẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

J. A. Browne tí wọ́n rán lọ sí orílẹ̀-èdè Jàmáíkà ní nǹkan bí ọdún 1902 láti lọ fún àwọn àwùjọ kékeré mẹ́rìnlá tó wà níbẹ̀ lókun àti ìṣírí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Iṣẹ́ àwọn arìnrìn-àjò ìsìn gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró, ó mú káwọn Kristẹni túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan, ó sì mú kí àwọn ará túbọ̀ sún mọ́ ètò Ọlọ́run