Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Bá A Nìṣó Gẹ́gẹ́ Bí Ọmọ Ìjọba Ọlọ́run!

Ẹ Máa Bá A Nìṣó Gẹ́gẹ́ Bí Ọmọ Ìjọba Ọlọ́run!

Ẹ Máa Bá A Nìṣó Gẹ́gẹ́ Bí Ọmọ Ìjọba Ọlọ́run!

“Máa ṣe ìṣe ọmọ ìlú.”—FÍLÍ. 1:27, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?

Àwọn wo ló lè di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run?

Kí la gbọ́dọ̀ ṣe nípa èdè, ìtàn àti àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run?

Báwo ni àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run?

1, 2. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì fi ní ìtumọ̀ pàtàkì?

 ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ gba ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì níyànjú pé kí wọ́n “máa hùwà lọ́nà tí ó yẹ ìhìn rere.” (Ka Fílípì 1:27.) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò, tá a túmọ̀ sí “hùwà” lédè Yorùbá, tún lè túmọ̀ sí “máa ṣe ìṣe ọmọ ìlú.” Gbólóhùn yẹn ní ìtumọ̀ pàtàkì fún ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kí ìlú Fílípì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú mélòó kan tí àwọn olùgbé ibẹ̀ ti rí oríṣi àǹfààní kan tàbí òmíràn gbà láti jẹ́ ọmọ ìlú Róòmù. Àwọn ọmọ ìlú Róòmù tó wà ní ìlú Fílípì àti jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù máa ń fi àǹfààní tí wọ́n ní yìí yangàn, òfin ilẹ̀ Róòmù sì máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́nà àkànṣe.

2 Àwọn ará ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì tún wá ní ìdí tó ju ìyẹn lọ láti máa yangàn. Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ẹni àmì òróró wọ́n ní ẹ̀tọ́ jíjẹ́ aráàlú “ní ọ̀run.” (Fílí. 3:20) Ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n, wọ́n kì í ṣe ọmọ Ilẹ̀ Ọba èèyàn kan lásán. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n gbádùn ààbò àti ọ̀pọ̀ àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́.—Éfé. 2:19-22.

3. (a) Àwọn wo ló láǹfààní láti jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lókè ọ̀run ni Pọ́ọ̀lù dìídì gbà níyànjú pé kí wọ́n “máa ṣe ìṣe ọmọ ìlú.” (Fílí. 3:20) Àmọ́, a tún lè lò ó fún àwọn tó máa jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọba kan náà, Jèhófà, ni gbogbo àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ń sìn, ìlànà kan náà ló sì wà fún gbogbo wọn. (Éfé. 4:4-6) Lóde òní, àwọn èèyàn ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè di ọmọ orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Torí náà, àǹfààní ńlá ni fún wa láti jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run, ó sì yẹ ká mọrírì rẹ̀! Ká lè túbọ̀ mọrírì àǹfààní yìí, ẹ jẹ́ ká wo bí ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó di ọmọ orílẹ̀-èdè kan ṣe jọra pẹ̀lú ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run. A óò kọ́kọ́ ṣe àyẹ̀wò díẹ̀ lára ọ̀nà tí wọ́n gbà jọra, lẹ́yìn náà ni a óò wá jíròrò ohun mẹ́ta tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó láti jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.

ÀWỌN OHUN TÁ A GBỌ́DỌ̀ ṢE LÁTI DI ỌMỌ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN

4. Kí ni èdè mímọ́, kí ló sì túmọ̀ sí láti máa sọ ọ́?

4 Kọ́ èdè. Àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan fòté lé e pé káwọn tó bá fẹ́ di ọmọ orílẹ̀-èdè àwọn kọ́ èdè tó gbawájú jù lọ tí wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè náà. Kódà lẹ́yìn táwọn kan bá ti di ọmọ orílẹ̀-èdè kan, ó máa ń gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó lè mọ èdè ibẹ̀ sọ dáadáa. Wọ́n lè yára kọ́ àwọn ìlànà gírámà èdè náà, àmọ́ ó lè pẹ́ kí èdè náà tó yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. Bákan náà, àwọn tó bá fẹ́ di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́ èdè tí Bíbélì pè ní “èdè mímọ́ gaara.” (Ka Sefanáyà 3:9.) Kí ni èdè mímọ́ yìí? Èdè mímọ́ náà ni òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Ohun tó túmọ̀ sí láti máa sọ èdè mímọ́ náà ni pé ká jẹ́ kí ìwà tá à ń hù bá àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run mu. Àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run lè tètè lóye àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àmọ́, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe ìrìbọmi, wọ́n ṣì gbọ́dọ̀ sapá kí wọ́n tó lè máa sọ èdè mímọ́ náà lọ́nà tó já geere. Lọ́nà wo? Olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà tí Bíbélì fi kọ́ wa sílò.

5. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ kọ́ gbogbo ohun tá a bá lè kọ́ nípa ìtàn ètò Jèhófà?

5 Kọ́ ìtàn. Bí ẹnì kan bá fẹ́ di ọmọ orílẹ̀-èdè kan, ó lè gba pé kó mọ̀ nípa ìtàn ìjọba orílẹ̀-èdè náà. Bákan náà, ó dára kí àwọn tó bá fẹ́ di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run mọ gbogbo ohun tí wọ́n bá lè mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. A lè ronú nípa àwọn ọmọ Kórà, tí wọ́n sin Jèhófà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Wọ́n fẹ́ràn Jerúsálẹ́mù àti ibi ìjọsìn tó wà níbẹ̀ gan-an ni, ó sì máa ń wù wọ́n láti sọ ìtàn ìlú náà. Kì í ṣe àwọn òkúta tí wọ́n fi mọ ògiri ìlú yẹn ló gbà wọ́n lọ́kàn jù lọ bí kò ṣe ohun tí ìlú náà àti ibi ìjọsìn tó wà níbẹ̀ dúró fún. Jerúsálẹ́mù ni “ìlú Ọba títóbi lọ́lá” náà, Jèhófà, torí pé ibẹ̀ ni ojúkò ìjọsìn tòótọ́. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Jèhófà. Àwọn èèyàn tí Ọba Jerúsálẹ́mù ṣàkóso lé lórí ni Jèhófà fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn sí. (Ka Sáàmù 48:1, 2, 9, 12, 13.) Ṣó wu ìwọ náà láti kọ́ ìtàn nípa apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà, kó o sì máa sọ ìtàn náà fáwọn èèyàn? Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ètò Ọlọ́run àti bí Jèhófà ṣe ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ni Ìjọba Ọlọ́run á ṣe túbọ̀ máa jẹ́ ohun gidi lójú rẹ. Á sì túbọ̀ máa wù ẹ́ látọkànwá pé kó o máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Jer. 9:24; Lúùkù 4:43.

6. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé Jèhófà fẹ́ ká kọ́ àwọn òfin àti àwọn ìlànà Ìjọba Ọlọ́run ká sì máa pa wọ́n mọ́?

6 Mọ òfin. Àwọn ìjọba máa ń fòté lé e pé káwọn tó ń gbé nílùú wọn kọ́ òfin orílẹ̀-èdè wọn kí wọ́n sì máa pa á mọ́. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé Jèhófà fẹ́ kí àwa náà kọ́ àwọn òfin àti àwọn ìlànà tí àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ká sì máa pa wọ́n mọ́. (Aísá. 2:3; Jòh. 15:10; 1 Jòh. 5:3) Àwọn òfin tí àwọn èèyàn ń ṣe sábà máa ń ní àbùkù, ó sì lè máà bára dé. Àmọ́, “òfin Jèhófà pé.” (Sm. 19:7) Ǹjẹ́ a ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run, ṣé a sì ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́? (Sm. 1:1, 2) Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà mọ òfin Ọlọ́run ni pé kí àwa fúnra wa máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ìyẹn kì í ṣe ohun tí ẹlòmíràn lè ṣe fún wa.

ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN

7. Ìlànà wo ni àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé?

7 Ká lè máa jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run, ká sì tún nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ìjọba èèyàn ń ṣàkóso lé lórí máa ń sọ pé àwọn fara mọ́ àwọn òfin àtàwọn ìlànà orílẹ̀-èdè táwọn ń gbé. Àmọ́, bí òfin kan kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n á rú òfin náà tí wọ́n bá rí i pé kò sẹ́ni tó ń wo àwọn. Lọ́pọ̀ ìgbà “olùwu ènìyàn” ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. (Kól. 3:22) Ìlànà Ọlọ́run ni àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé. Tayọ̀tayọ̀ la fi ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kódà bí kò bá sí èèyàn kankan tó ń wò wá. Kí nìdí? Ìdí ni pé a nífẹ̀ẹ́ Ẹni tó fún wa lófin.—Aísá. 33:22; ka Lúùkù 10:27.

8, 9. Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Ọlọ́run?

8 Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Ọlọ́run? Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tó o máa ṣe bí ẹnì kan bá fún ẹ nímọ̀ràn lórí irú aṣọ tó o yàn láti wọ̀ tàbí ọ̀nà tó o gbà múra. Kó o tó di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ràn láti máa wọṣọ wúruwùru tàbí lọ́nà tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe. Àmọ́, bó o ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, o kọ́ láti máa múra lọ́nà tó ń bọlá fún un. (1 Tím. 2:9, 10; 1 Pét. 3:3, 4) O lè rò pé o ti wá ń múra lọ́nà tó bójú mu gan-an báyìí. Àmọ́ ká ní alàgbà kan wá sọ fún ẹ pé àwọn kan nínú ìjọ lérò pé ìmúra rẹ kò bójú mu ńkọ́? Kí lo máa ṣe? Ṣé ńṣe lo máa wí àwíjàre tàbí wàá di kùnrùngbùn tàbí wàá kọtí ikún? Ọ̀kan lára àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. (1 Pét. 2:21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àpẹẹrẹ Jésù pé: “Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:2, 3) Kí àlàáfíà lè máa jọba nínú ìjọ, Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ kò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú.—Róòmù 14:19-21.

9 Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó méjì míì tó ṣe pàtàkì: ìyẹn ni èrò wa nípa ìbálòpọ̀ àti ojú tá a fi ń wo ìgbéyàwó. Àwọn tí kò tíì di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run lè fàyè gba ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, wọ́n lè ka wíwo ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe sí ohun tí kò léwu nínú, wọ́n sì lè máa ronú pé ọ̀ràn ara ẹni ni panṣágà àti ìkọ̀sílẹ̀. Àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ti jáwọ́ nínú irú ìwà àìláròjinlẹ̀ àti ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ti fìgbà kan rí jẹ́ oníṣekúṣe, ní báyìí wọ́n ti ń wo ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn Ọlọ́run. Wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Jèhófà, wọ́n sì gbà tọkàntọkàn pé àwọn tí kò jáwọ́ nínú ìṣekúṣe kò yẹ láti jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 6:9-11) Àmọ́, wọ́n tún gbà pé ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè. (Jer. 17:9) Torí náà, wọ́n mọyì gbígba àwọn ìkìlọ̀ pàtó tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà tó yẹ ká máa hù.

ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA Ń GBA ÌKÌLỌ̀

10, 11. Àwọn ìkìlọ̀ tó bọ́ sákòókò wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa ń fún wa, ojú wo lo sì fi ń wo irú àwọn ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀?

10 Àwọn ìjọba èèyàn máa ń kìlọ̀ fáwọn aráàlú nípa àwọn oúnjẹ àti àwọn oògùn tó léwu fún ìlera. Síbẹ̀, ó dájú pé kì í ṣe gbogbo àwọn oúnjẹ àtàwọn oògùn ni kò dára. Ṣùgbọ́n, bí irú oúnjẹ tàbí oògùn kan bá lè pani lára, ìjọba lè kìlọ̀ nípa rẹ̀ kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn aráàlú. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìjọba lè jẹ̀bi àìka-nǹkan-sí. Bákan náà, Ìjọba Ọlọ́run máa ń fún wa ní àwọn ìkìlọ̀ tó bọ́ sákòókò nípa àwọn ohun tó lè pa wá lára nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, Íńtánẹ́ẹ̀tì ti di ohun èlò tó wúlò gan-an fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́, eré ìnàjú àti kíkàn sáwọn èèyàn. Ètò Ọlọ́run máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ọ̀pọ̀ ohun gidi ni wọ́n sì ti fi ṣe láṣeyọrí. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì léwu gan-an fún àwọn tó fẹ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́, tí wọn kò sì fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń gbé àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe lárugẹ lè ṣàkóbá fún àjọṣe táwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ní pẹ̀lú Jèhófà. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ ti ń kìlọ̀ fún wa nípa irú àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀. Àfi ká máa dúpẹ́ pé à ń rí àwọn ìkìlọ̀ tó dá lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run yìí gbà!

11 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, irú ìkànnì mìíràn kan ti wá gbajúmọ̀ gan-an lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó jẹ́ ìkànnì tó wúlò tá a bá fìṣọ́ra lò ó. Àwọn ìkànnì yìí ni wọ́n ń pè ní ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn ìkànnì náà lè ṣèpalára fúnni lọ́nà tó burú jáì, wọ́n sì lè jẹ́ kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 15:33) Abájọ tí ètò Ọlọ́run fi ń fún wa ní àwọn ìkìlọ̀ tí kò pọ̀n síbì kan nípa irú àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o ti ka gbogbo àpilẹ̀kọ tí ẹrú olóòótọ́ gbé jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa bá a ṣe lè lo àwọn ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ẹ ò rí i pé kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu láti lo irú àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ pé a kọ́kọ́ ka àwọn àpilẹ̀kọ yẹn! * Ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn lo oògùn tó lágbára gan-an láì kọ́kọ́ ka àlàyé tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ará ìgò rẹ̀ nípa béèyàn ṣe máa lò ó.

12. Kí nìdí tí ṣíṣàìka ìkìlọ̀ sí fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀?

12 Àwọn tí kò bá gba ìkìlọ̀ tó ń wá látọ̀dọ̀ ẹrú olóòótọ́ máa fa wàhálà wá sórí ara wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan wọn. Àwọn kan ti jingíri sídìí wíwo àwọn ohun tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ti ṣèṣekúṣe, àmọ́ wọ́n ń tan ara wọn jẹ bí wọ́n ti ń ronú pé Jèhófà kò lé rí ohun tí àwọn ń ṣe. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ fún wa láti gbà pé a lè fi ìwà wa pa mọ́ fún Jèhófà! (Òwe 15:3; ka Hébérù 4:13.) Ọlọ́run fẹ́ ran irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, ó sì ń mú kí àwọn aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Gál. 6:1) Àmọ́ ṣá o, bí ìjọba èèyàn ṣe lè gba àǹfààní jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ ẹnì kan tó hùwà àìtọ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa gba àǹfààní jíjẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ àwọn tí kò pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́ tí wọn kò sì ronú pìwà dà. * (1 Kọ́r. 5:11-13) Àmọ́, aláàánú ni Jèhófà o. Àwọn tó ronú pìwà dà tí wọ́n sì yí pa dà tún lè ní àjọṣe rere pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n sì máa bá a nìṣó láti jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 2:5-8) Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ fún wa láti máa jọ́sìn irú Ọba onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀!

ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN KA Ẹ̀KỌ́ SÍ PÀTÀKÌ

13. Báwo ni àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń fi hàn pé àwọn ka ẹ̀kọ́ sí pàtàkì?

13 Ọ̀pọ̀ ìjọba èèyàn máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè pèsè ẹ̀kọ́ ìwé fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọn. Wọ́n máa ń dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ kí àwọn èèyàn lè mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, wọ́n sì tún ń kọ́ wọn ní iṣẹ́ ọwọ́. Àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run mọrírì àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí, níbẹ̀ ni wọ́n ti máa ń kọ́ láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, kí wọ́n sì tún kọ́ iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe jẹun. Èyí tí wọ́n tún wá kà sí pàtàkì jù lọ ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń rí gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ìjọba Ọlọ́run. Nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni, Jèhófà ń kọ́ wa láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. A sì tún máa ń gba àwọn òbí níyànjú níbẹ̀ pé kí wọ́n máa kàwé fáwọn ọmọ wọn kéékèèké. Lóṣooṣù, ẹrú olóòótọ́ máa ń tẹ àwọn ìsọfúnni tó dá lórí Bíbélì jáde nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Tó o bá ń ka nǹkan bí ojú ìwé mélòó kan lára àwọn ìsọfúnni náà lójoojúmọ́, tó o sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóṣooṣù, wàá máa jàǹfààní látinú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń pèsè.

14. (a) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo la máa ń rí gbà? (b) Àwọn àbá wo nípa Ìjọsìn Ìdílé lo fẹ́ràn láti máa lò?

14 Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìpàdé ìjọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó ti lé ní ọgọ́ta [60] ọdún báyìí tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ń ran àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà lọ́wọ́ láti máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó múná dóko. Ǹjẹ́ o ti forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ẹrú olóòótọ́ ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa létí pé ká máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé. Ìṣètò yìí ń mú kí ìdílé túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Ǹjẹ́ ó ti ṣeé ṣe fún ẹ láti lo àwọn àbá tá a ti tẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé wa? *

15. Kí ni ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a ní?

15 Àwọn tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan máa ń gbẹnu sọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú ní gbangba, kódà wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti ojúlé dé ojúlé. Ní ọ̀nà tó tún wá ju ìyẹn lọ fíìfíì, àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa ń lo gbogbo okun wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run ní òpópónà àti láti ilé dé ilé. Kódà, bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ṣáájú èyí, ní báyìí Ilé Ìṣọ́ tí ń kéde Ìjọba Jèhófà ni ìwé ìròyìn tó tíì délé dóko jù lọ lórí ilẹ̀ ayé! Ọ̀kan lára àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a ní ni pé ká máa sọ fún àwọn ẹlòmíì nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ò ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?—Mát. 28:19, 20.

16. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìjọba Ọlọrun?

16 Láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ìjọba kan ṣoṣo tí yóò máa ṣàkóso ayé. Òun ni yóò máa bójú tó gbogbo apá ìgbésí ayé wa, nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Ṣé ojúlówó ọmọ Ìjọba Ọlọ́run lo máa jẹ́ nígbà yẹn? Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi irú ẹni tó o máa jẹ́ hàn. Nínú gbogbo ìpinnu tó o bá ń ṣe lójoojúmọ́, máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Jèhófà, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fi hàn pé o jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 10:31.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Bí àpẹẹrẹ, wo Jí! January–March 2012, ojú ìwé 16 sí 19 àti ojú ìwé 26 sí 29; àti Jí! February 2012, ojú ìwé 3 sí 9 [Gẹ̀ẹ́sì].

^ Wo Ilé Ìṣọ́, August 15, 2011, ojú ìwé 6 àti 7 àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2011, ojú ìwé 3 sí 6.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Ǹjẹ́ o máa ń fi àwọn ìkìlọ̀ tó dá lórí Bíbélì nípa lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì sílò?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Bíi ti àwọn ọmọ Kórà, ǹjẹ́ inú rẹ máa ń dùn sí ìjọsìn tòótọ́ àti ìtàn nípa rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìjọsìn Ìdílé yín lè mú kí ìwọ àti àwọn tó o nífẹ̀ẹ́ di ojúlówó ọmọ Ìjọba Ọlọ́run