Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Mo Wà Pẹ̀lú Yín”

“Mo Wà Pẹ̀lú Yín”

“Mo Wà Pẹ̀lú Yín”

“Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.”​—DÁN. 12:4.

BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?

Báwo la ṣe ṣàwárí “ìmọ̀ tòótọ́” lóde òní?

Báwo ni àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ ṣe di “púpọ̀”?

Báwo ni ìmọ̀ pípéye ṣe di “púpọ̀ yanturu”?

1, 2. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù wà pẹ̀lú àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí báyìí àti pé ó máa wà pẹ̀lú wọn ní ọjọ́ iwájú? (b) Kí ni Dáníẹ́lì 12:4 sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ táwọn kan bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́?

 FOJÚ inú wò ó pé o wà nínú Párádísè. Bó o ṣe ń jí láràárọ̀, ara ń tù ẹ́ o sì ń fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ rẹ. Kò sí títa ríro kankan. Àìlera èyíkéyìí tó o ní tẹ́lẹ̀ sì ti di àwátì. O lè ríran kedere, o lè gbọ́ràn, o lè gbóòórùn, o lè mọ bí nǹkan ṣe rí tó o bá fọwọ́ kàn án tàbí tó o bá tọ́ ọ wò. Ò ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún, ò ń gbádùn iṣẹ́ rẹ, o ní àwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀, gbogbo ohun tó ń gbé ẹ lọ́kàn sókè kò sí mọ́. Irú àwọn ìbùkún tó o máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nìyẹn. Kristi Jésù, Ọba tí Ọlọ́run yàn, máa bù kún àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí, yóò sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ Jèhófà.

2 Ní àkókò yẹn, Jèhófà máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá ni Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ti ń wà pẹ̀lú àwọn olóòótọ́. Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó mú kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin lójú pé òun máa wà pẹ̀lú wọn. (Ka Mátíù 28:19, 20.) Kí ìlérí tí Jésù ṣe yìí lè túbọ̀ dá wa lójú, ẹ jẹ́ ká jíròrò gbólóhùn kan péré nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Ọlọ́run mí sí wòlíì Dáníẹ́lì láti kọ sílẹ̀ ní ìlú Bábílónì ìgbàanì ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn. Nígbà tó ń kọ̀wé nípa “àkókò òpin” tí à ń gbé yìí, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” (Dán. 12:4) Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa, ó ti wá yé wa pé ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a pè ní “lọ káàkiri” lédè Yorùbá túmọ̀ sí ni pé kéèyàn ṣe àyẹ̀wò fínnífínní. Ẹ sì wo ìbùkún àgbàyanu tí irú lílọ káàkiri bẹ́ẹ̀ máa yọrí sí! Àwọn tó bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ máa ní ìmọ̀ tòótọ́, tàbí ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn yóò tẹ́wọ́ gba “ìmọ̀ tòótọ́.” Àti pé irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò pọ̀ yanturu. Ó máa tàn kálẹ̀ dé ibi gbogbo, ó sì máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn. Ní báyìí, a máa ṣàyẹ̀wò bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ, a sì máa rí i pé Jésù wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí àti pé Jèhófà máa mú gbogbo ohun tó ti ṣèlérí ṣẹ láìkùnà.

A ṢÀWÁRÍ “ÌMỌ̀ TÒÓTỌ́”

3. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí “ìmọ̀ tòótọ́” lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì?

3 Ìpẹ̀yìndà kúrò nínú ojúlówó ìsìn Kristẹni, èyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀, bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, ó sì yára tàn kálẹ̀ bí iná tí ń jó. (Ìṣe 20:28-30; 2 Tẹs. 2:1-3) Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, “ìmọ̀ tòótọ́” ò tíì di púpọ̀ yanturu láàárín àwọn tí kò ní ìmọ̀ Bíbélì àtàwọn tó pera wọn ní Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó jẹ́ aṣáájú nínú ẹ̀sìn àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ńṣe ni wọ́n ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ èké, ìyẹn “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù” tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run. (1 Tím. 4:1) Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn lóye òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lára ẹ̀kọ́ èké táwọn apẹ̀yìndà yìí fi ń kọ́ni ni pé Ọlọ́run jẹ́ mẹ́talọ́kan, pé ọkàn kìí kú àti pé Ọlọ́run máa ń dá àwọn ọkàn kan lóró títí ayérayé nínú iná ọ̀run àpáàdì.

4. Báwo ni àwùjọ àwọn Kristẹni kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wá “ìmọ̀ tòótọ́” láàárín ọdún 1870 sí ọdún 1879?

4 Àmọ́, láàárín ọdún 1870 sí ọdún 1879, ní nǹkan bí ogójì ọdún kí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tó bẹ̀rẹ̀, àwùjọ kékeré kan ti àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n wà ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í pàdé pọ̀ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì taápọntaápọn kí wọ́n sì wá “ìmọ̀ tòótọ́.” (2 Tím. 3:1) Wọ́n pera wọn ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn wọ̀nyí kọ́ ni “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye” tí Jésù sọ pé Ọlọ́run máa fi ìmọ̀ pa mọ́ fún. (Mát. 11:25) Wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn. Wọ́n fara balẹ̀ ka Ìwé Mímọ́, wọ́n jíròrò rẹ̀, wọ́n sì ṣàṣàrò lórí rẹ̀ tàdúràtàdúrà. Wọ́n tún fi àwọn ẹsẹ Bíbélì wéra, wọ́n sì ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àwọn míì tí wọ́n ti ṣe irú ìwádìí bẹ́ẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí bẹ̀rẹ̀ sí í fi òye mọ àwọn òtítọ́ tó ti ṣókùnkùn sí wọn fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún.

5. Kí nìdí tí wọ́n fi tẹ ọ̀wọ́ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tó ní àkọlé náà, The Old Theology?

5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ń kọ́ wú wọn lórí, wọn ò jẹ́ kí ohun tuntun tí wọ́n mọ̀ yìí mú kí wọ́n máa gbéra ga; wọn ò sì máa fọ́nnu nítorí rẹ̀. (1 Kọ́r. 8:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n tẹ ọ̀wọ́ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tó dá lórí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi kọ́ni, ìyẹn The Old Theology. Ìdí tí wọ́n fi tẹ̀ ẹ́ ni pé kí àwọn tó bá kà á lè mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ti wà nínú Ìwé Mímọ́. Èyí àkọ́kọ́ nínú àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yìí mú káwọn èèyàn rí “ohun púpọ̀ sí i láti kà, èyí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè kọ gbogbo ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tó jẹ́ èké sílẹ̀ kí wọ́n sì ní ìmọ̀ pípéye nípa ẹ̀kọ́ tí Olúwa wa àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi kọ́ni.”—The Old Theology, No. 1, April 1889, ojú ìwé 32.

6, 7. (a) Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ wo la lóye rẹ̀ láàárín ọdún 1870 sí ọdún 1879? (b) Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ wo ló dùn mọ́ ẹ jù lọ pé o mọ̀?

6 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣàwárí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àgbàyanu látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ níbi kékeré léyìí tó ti ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ báyìí. * Ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ̀nyí yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ ìwé tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn máa ń jiyàn lé lórí. Wọ́n jẹ́ òtítọ́ tó wúni lórí, tó lani lóye, tó jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, tó sì mú ká ní ìrètí àti ayọ̀. Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ànímọ́ onífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀. Wọ́n mú kí ipa tí Jésù kó túbọ̀ ṣe kedere, wọ́n ṣàlàyé ìdí tó fi wá sáyé, ìdí tó fi kú àti ohun tó ń ṣe ní báyìí. Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye yìí jẹ́ ká mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, ìdí tá a fi ń kú, bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà àti bá a ṣe lè ní ayọ̀ tòótọ́.

7 Ní báyìí, a lè wá lóye ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti jẹ́ “àṣírí” fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ tí wọ́n ń ní ìmúṣẹ ní àkókò òpin yìí. (Dán. 12:9) A lè rí àwọn kan lára wọn nínú Ìwé Mímọ́, pàápàá jù lọ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere àti ìwé Ìṣípayá. Kódà, Jèhófà ti mú ká lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò lè fojú rí, irú bíi, bí Jésù ṣe gorí ìtẹ́, ogun tó wáyé ní ọ̀run àti bí a ṣe fi Sátánì sọ̀kò sorí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 12:7-12) Ọlọ́run tún ti mú ká mọ ìtumọ̀ àwọn ohun tí a fojú rí, ìyẹn bí àwọn ogun, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ àti bí àwọn èèyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń ṣe àwọn nǹkan búburú tó ń mú kí àkókò wa jẹ́ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.”—2 Tím. 3:1-5; Lúùkù 21:10, 11.

8. Ta ló yẹ ká fi ògo fún nítorí àwọn nǹkan tá a ti rí tá a sì ti gbọ́?

8 Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ojú tí ó rí àwọn ohun tí ẹ ń rí. Nítorí mo wí fún yín, Ọ̀pọ̀ wòlíì àti àwọn ọba fẹ́ láti rí àwọn ohun tí ẹ ń rí ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn, àti láti gbọ́ àwọn ohun tí ẹ ń gbọ́ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ wọn.” (Lúùkù 10:23, 24) Àwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù lónìí náà fara mọ́ ohun tó sọ yìí. Jèhófà Ọlọ́run là ń fi ògo fún pé ó jẹ́ ká rí àwọn nǹkan yìí ká sì gbọ́ nípa wọn. A kún fún ọpẹ́ gidigidi pé Ó ti rán “olùrànlọ́wọ́ náà,” ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ láti ṣamọ̀nà wa “sínú òtítọ́ gbogbo.” (Ka Jòhánù 16:7, 13.) Ǹjẹ́ ká máa fi hàn nígbà gbogbo pé a mọyì “ìmọ̀ tòótọ́” ká sì máa fi kọ́ àwọn èèyàn!

“Ọ̀PỌ̀” TẸ́WỌ́ GBA “ÌMỌ̀ TÒÓTỌ́”

9. Kí la ké sí àwọn èèyàn láti ṣe nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí tí a tẹ̀ jáde ní oṣù April, ọdún 1881?

9 Kò tíì pé ọdún méjì tá a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì tó fi gbé àpilẹ̀kọ kan jáde ní oṣù April ọdún 1881, èyí tó fi béèrè fún àwọn oníwàásù tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan [1,000]. Àpilẹ̀kọ náà kà pé: “Fún àwọn wọnnì tó bá ní àǹfààní láti ya ìdajì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sọ́tọ̀ pátápátá lára àkókò wọn fún lílò nínú iṣẹ́ Olúwa, a ní àbá kan . . . , ìyẹn ni pé: Kí ẹ jáde lọ sínú àwọn ìlú ńlá tàbí àwọn ìlú kéékèèké, bí agbára yín bá ṣe gbé e tó, láti ṣe iṣẹ́ Apínwèé-ìsìn-kiri tàbí iṣẹ́ Ajíhìnrere, ní gbogbo ibi tẹ́ ẹ bá lọ, ẹ ṣe àwárí àwọn Kristẹni olùfọkànsìn, ẹ máa rí i pé ọ̀pọ̀ lára wọn ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀; ẹ wá bí ẹ ṣe máa jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe ṣàǹfààní tó láti jọlá oore ọ̀fẹ́ Baba Wa àti adùn inú ọ̀rọ̀ Rẹ̀.”

10. Kí làwọn èèyàn ṣe lẹ́yìn tí wọ́n ké sí wọn pé kí wọ́n wá di oníwàásù alákòókò-kíkún?

10 Ìpè yẹn fi hàn pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára iṣẹ́ táwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣe. Àmọ́ nígbà yẹn, ọgọ́rùn-ún mélòó kan péré làwọn tó ń wá sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí náà iye àwọn tó jẹ́ ìpè náà kò tó ẹgbẹ̀rún kan. Àmọ́, lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ti ka ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìròyìn, wọ́n máa ń rí i pé àwọn ti rí òtítọ́, wọ́n á sì fẹ́ láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan kọ̀wé láti ìlú London lórílẹ̀-èdè England lẹ́yìn tó ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ [Gẹ̀ẹ́sì] àti ìwé kékeré kan tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ jáde ní ọdún 1882. Ó sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́ mi bí mo ṣe lè wàásù àti ohun tí màá wàásù rẹ̀, kí n lè ṣàṣeparí iṣẹ́ tó ní ìbùkún tí Ọlọ́run fẹ́ kó di ṣíṣe yìí.”

11, 12. (a) Irú àfojúsùn tá a ní wo ni àwọn apínwèé-ìsìn-kiri náà ní? (b) Báwo ni àwọn apínwèé-ìsìn-kiri ṣe dá “àwọn kíláàsì,” tàbí àwọn ìjọ sílẹ̀?

11 Nígbà tó fi máa di ọdún 1885, nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn apínwèé-ìsìn-kiri. Àfojúsùn tá a ní lónìí làwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkun wọ̀nyẹn náà ní, ìyẹn ni sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Àmọ́, ọ̀nà ti wọ́n gbà wàásù yàtọ̀ sí tiwa. Lóde òní, ọ̀kọ̀ọ̀kan la máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, èyí á sì fún ẹni tá à ń kọ́ láǹfààní láti gba ìtọ́ni ní tààràtà. Lẹ́yìn náà la óò ké sí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà láti máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ńṣe làwọn apínwèé-ìsìn-kiri máa ń mú ìwé lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn, lẹ́yìn náà ni wọ́n á kó gbogbo àwọn tó bá fìfẹ́ hàn jọ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Dípò kí wọ́n máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan, ńṣe ni wọ́n máa ń dá “àwọn kíláàsì,” tàbí àwọn ìjọ sílẹ̀.

12 Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1907 àwùjọ àwọn apínwèé-ìsìn-kiri kan lọ káàkiri ìlú kan láti wá àwọn tí wọ́n ti ní ẹ̀dà ìwé Millennial Dawn (tá a tún ń pè ní Studies in the Scriptures). Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “Wọ́n kó [àwọn olùfìfẹ́hàn] yìí jọ sí ìpàdé kékeré kan tí wọ́n ṣe nínú ilé ọ̀kan lára wọn. Odindi ọjọ́ Sunday kan ni Apínwèé-ìsìn-kiri náà fi bá wọn sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, ‘Divine Plan of the Ages’ (Ìwéwèé Ọlọ́run Láti Ayébáyé), nígbà tó sì di Sunday ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe ìpàdé déédéé.” Ní ọdún 1911, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀nà míì láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àwọn àkànṣe òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò méjìdínlọ́gọ́ta [58] bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọyé káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà. Àwọn arákùnrin yìí gba orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n wá gbọ́ àwọn àsọyé, wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe máa pàdé pọ̀ nínú àwọn ilé àdáni kí wọ́n lè dá “àwọn kíláàsì,” tàbí àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀. Ní ọdún 1914, ìjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà kárí ayé ti di ẹgbẹ̀fà [1,200].

13. Kí ló wú ẹ lórí nípa ibi tí “ìmọ̀ tòótọ́” gbòòrò dé lónìí?

13 Lóde òní, ìjọ tó tó ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárùn-ún àti irínwó [109,400] ló wà kárí ayé, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí iye wọn tó ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ àti ẹgbẹ̀rin [895,800] ló sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Ní báyìí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ èèyàn ló ti tẹ́wọ́ gba “ìmọ̀ tòótọ́,” wọ́n sì ń fi í sílò nínú ìgbésí ayé wọn. (Ka Aísáyà 60:22.) * Èyí wúni lórí gan-an ni, torí pé Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jẹ́ “ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn” nítorí orúkọ òun. Ó tún sọ pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn òun, wọ́n á fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n á sì pa wọ́n. (Lúùkù 21:12-17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àtàwọn èèyàn tó ń ṣàtakò ti gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìwàásù dúró, àwọn èèyàn Jèhófà ń ṣàṣeyọrí lọ́nà tó pabanbarì lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́. Lóde òní, wọ́n ń wàásù ní “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé,” láti àwọn ibi igbó kìjikìji tí ojú ọjọ́ ti móoru títí fi dé àwọn ilẹ̀ oníyìnyín tó tutù nini, lórí àwọn òkè, ní àwọn aṣálẹ̀, ní àwọn ìlú àti ní àwọn ibi àdádó jíjìnnà réré. (Mát. 24:14) Bí kì í bá ṣe pé Ọlọ́run ń tì wọ́n lẹ́yìn ni, wọ́n kì bá tí lè ṣe gbogbo èyí láṣeyọrí.

“ÌMỌ̀ TÒÓTỌ́” DI “PÚPỌ̀ YANTURU”

14. Báwo ni àwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe mú kí “ìmọ̀ tòótọ́” di púpọ̀ yanturu?

14 “Ìmọ̀ tòótọ́” ti di púpọ̀ yanturu nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń polongo ìhìn rere. Ó sì tún ti di púpọ̀ yanturu nípasẹ̀ àwọn ìwé tí a ń tẹ̀ jáde. Ní oṣù July, ọdún 1879 ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́kọ́ tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde, orúkọ rẹ̀ nígbà yẹn ni Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence tá à ń pè ní Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà báyìí. Ilé iṣẹ́ kan ló bá wọn tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ yẹn, iye tí wọ́n sì tẹ̀ jáde jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan. Arákùnrin Charles Taze Russell tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ni wọ́n fi ṣe olóòtú, nígbà tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì márùn-ún mìíràn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn máa ń kópa déédéé nínú kíkọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ń jáde nínú ìwé ìròyìn náà. Èdè tá a fi ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ báyìí jẹ́ igba ó dín márùn-ún [195]. Òun ni ìwé ìròyìn tí ìpínkiri rẹ̀ pọ̀ jù lọ láyé, iye ẹ̀dà tá à ń tẹ̀ jáde lẹ́ẹ̀kan jẹ́ mílíọ̀nù méjìlélógójì àti ẹgbàá mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [42,182,000]. Èyí tó tún ṣìkejì rẹ̀ ni ìwé ìròyìn Jí! tí iye ẹ̀dà rẹ̀ tá à ń tẹ̀ jáde jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kànlélógójì àti ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì [41,042,000], ó sì wà ní èdè mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84]. Ní àfikún sí i, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ìwé àti Bíbélì là ń tẹ̀ jáde lọ́dọọdún.

15. Báwo la ṣe ń rí owó tá a fi ń tẹ àwọn ìtẹ̀jáde wa?

15 Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí. (Ka Mátíù 10:8.) Ìyẹn nìkan ti tó ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn tó ní ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé, torí pé wọ́n mọ iye tó ń náni láti ra àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, bébà, yíǹkì àti àwọn ohun èlò míì. Arákùnrin kan tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ mọ́ bíbá wa ra àwọn ohun èlò káàkiri àgbáyé sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún àwọn oníṣòwò tó bá wá sí àwọn ilé ìtẹ̀wé wa láti rí i pé ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún irú iṣẹ́ ìtẹ̀wé bẹ́ẹ̀, tá à ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí wọ́n fi ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣe, tá a sì ń tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dà lẹ́ẹ̀kan náà. Ó tún máa ń wú wọn lórí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́, wọ́n sì máa ń láyọ̀.”

ILẸ̀ AYÉ YÓÒ KÚN FÚN ÌMỌ̀ ỌLỌ́RUN

16. Kí nìdí tí Jèhófà fi mú ká ní “ìmọ̀ tòótọ́”?

16 Ìdí rere kan wà tí “ìmọ̀ tòótọ́” fi pọ̀ yanturu. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí a “gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ kí wọ́n lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó yẹ, kí wọ́n sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Nípasẹ̀ “ìmọ̀ tòótọ́” tí Jèhófà mú ká ní yìí, ó ti ṣeé ṣe fún un láti kó àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ jọ. Ó tún ń kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kan jọ láti inú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” àwọn wọ̀nyí sì ní ìrètí láti máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣí. 7:9.

17. Kí ni ìmúgbòòrò ìjọsìn tòótọ́ fi hàn?

17 Bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe ń gbòòrò sí i láti àádóje [130] ọdún sẹ́yìn ń fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé Ọlọrun àti Ọba tó yàn sípò, ìyẹn Jésù Kristi ti wà pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n ń darí wọn, wọ́n ń dáàbò bò wọ́n, wọ́n ń ṣètò wọn, wọ́n sì ń kọ́ wọn. Bí wọ́n sì ṣe ń pọ̀ sí i tún fi hàn lọ́nà tó dájú pé àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú máa ní ìmúṣẹ. “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísá. 11:9) Ẹ sì wo bí ìbùkún tí aráyé máa gbádùn nígbà náà á ṣe pọ̀ tó!

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ O máa mọ púpọ̀ sí i tó o bá wo àwọn fídíò tá a ṣe sórí àwo DVD náà, Jehovah’s Witnesses—Faith in Action, Part 1: Out of Darkness àti Jehovah’s Witnesses—Faith in Action, Part 2: Let the Light Shine.

^ Wo ìwé Asọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, ojú ìwé 320.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó ń wá bí wọ́n ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jèhófà mọrírì bó o ṣe ń sapá láti mú kí “ìmọ̀ tòótọ́” látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀