ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ September 2012

Ẹ̀dà yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó kàn wá lónìí àti báa ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà àti Jèsú.

Bí Ayé Yìí Ṣe Máa Dópin

Bíbélì sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì mẹ́wàá tó máa tó ṣẹlẹ̀. Kí ni wọ́n? Báwo ló ṣe máa kàn ẹ́?

Àlàáfíà Yóò Wà Fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún Àti Títí Láé!

Wo bí Ìjọba Jésù ṣe máa mú ìtura àti ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún aráyé.

Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run—Ẹ̀rí Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa

Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Sùúrù Jèhófà Àti Jésù

Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe fi hàn pé àwọn ní sùúrù? Báwo la ṣe lè fara wé sùúrù wọn?

“Ẹ Kò Mọ Ọjọ́ Tàbí Wákàtí Náà”

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí? Kí ló yẹ kí ọ̀rọ̀ yìí sún wa láti ṣe?

Jèhófà Ń kó Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Aláyọ̀ Jọ

Báwo ni àwọn àjọyọ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe nígbà àtijọ́ ṣe jọ àwọn àpéjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lọ sáwọn àpéjọ yìí?