Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàáfíà Yóò Wà Fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún Àti Títí Láé!

Àlàáfíà Yóò Wà Fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún Àti Títí Láé!

“Kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”​—1 KỌ́R. 15:28.

1. Ohun tó ń múni láyọ̀ wo ló ń dúró de “ogunlọ́gọ̀ ńlá”?

 ǸJẸ́ o lè fojú inú wo bí ohun rere tí ìjọba alágbára kan máa ṣe fún àwọn èèyàn á ṣe pọ̀ tó láàárín ẹgbẹ̀rún ọdún, tó bá jẹ́ pé alákòóso náà jẹ́ olódodo àti aláàánú? Ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu ló ń dúró de “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” ìyẹn àwọn tó máa là á já nígbà tí òpin bá dé bá ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí pátápátá nígbà “ìpọ́njú ńlá.”—Ìṣí. 7:9, 14.

2. Kí ni ojú àwọn èèyàn ti rí láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún sẹ́yìn?

2 Láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn, ìrora àti ìjìyà ti fi ojú àwọn èèyàn rí màbo, látàrí bí wọ́n ṣe ń dá ṣe ìpinnu tí wọ́n sì ń jọba lórí ara wọn. Bíbélì ti sọ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníw. 8:9) Kí ni ojú àwa èèyàn ń rí lóde òní? Yàtọ̀ sí ogun àtàwọn rúkèrúdò tó ń ṣẹlẹ̀, àwọn ìṣòro míì tó ń bani nínú jẹ́ ni ipò òṣì, àrùn, bíba àyíká jẹ́, ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà lódìlódì àtàwọn nǹkan míì. Àwọn aláṣẹ ìjọba kan sì ti kìlọ̀ pé tá a bá jókòó tẹtẹrẹ láì tètè wá nǹkan ṣe sí i, ohun tó máa gbẹ̀yìn rẹ̀ á burú gan-an.

3. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

3 Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, Mèsáyà Ọba náà Jésù Kristi àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ máa ṣàtúnṣe sí gbogbo ìbàjẹ́ tó ti ṣẹlẹ̀ sí àwa èèyàn àti ilẹ̀ ayé. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, ìlérí tó ń múni lọ́kàn yọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe máa ní ìmúṣẹ. Ó sọ pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísá. 65:17) Àwọn ohun àgbàyanu tí a kò tíì rí wo là ń retí? Ẹ jẹ́ ká wo bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí díẹ̀ lára àwọn ohun àgbàyanu ‘tí a kò tíì rí’ náà.—2 Kọ́r. 4:18.

‘WỌN YÓÒ KỌ́ ILÉ, WỌN YÓÒ SÌ GBIN ỌGBÀ ÀJÀRÀ’

4. Báwo ni ọ̀rọ̀ ilé gbígbé ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí?

4 Ta ni kò ní wù pé kó ní ilé tirẹ̀, níbi tí òun àti ìdílé rẹ̀ lè forí pa mọ́ sí tí ọkàn wọn á sì balẹ̀? Àmọ́ lóde òní, kò rọrùn rárá láti rí ilé tó dára gbé. Àwọn ìlú ńláńlá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kún àkúnya. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé àwọn ilé kẹ́jẹ́bú ni wọ́n ń gbé láwọn àdúgbò táwọn akúṣẹ̀ẹ́ pọ̀ sí táwọn ilé tó wà níbẹ̀ kò sì bójú mu rárá. Fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, àlá tí kò lè ṣẹ ni ọ̀rọ̀ pé wọ́n máa ní ilé tiwọn.

5, 6. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 65:21 àti Míkà 4:4 ṣe máa ní ìmúṣẹ? (b) Báwo la ṣe lè rí ìbùkún náà gbà?

5 Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo èèyàn pátá ló máa ní ilé tirẹ̀, torí pé Ọlọ́run mú kí wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” (Aísá. 65:21) Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ pé gbogbo èèyàn máa ní ilé tirẹ̀ nìkan kọ́ ni ohun tá à ń retí. Torí pé, lóde òní pàápàá, àwọn kan wà tó ń gbé nínú ilé ara wọn, a sì rí àwọn díẹ̀ tó ń gbé nínú ilé aláruru tàbí tí wọ́n kọ́lé sórí ilẹ̀ tó fẹ̀ gan-an. Ṣùgbọ́n, ọkàn irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kì í sábàá balẹ̀ torí pé ìṣòro ìṣúnná owó lè mú kí ilé náà bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa bẹ̀rù pé àwọn adigunjalè tàbí àwọn míì tó burú ju ìyẹn lọ lè wọlé wá bá àwọn. Àmọ́, gbogbo nǹkan máa yàtọ̀ pátápátá nínú Ìjọba Ọlọ́run. Wòlíì Míkà sọ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà. 4:4.

6 Bí a ṣe ń retí ìgbà tí ohun àgbàyanu yìí máa ní ìmúṣẹ, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? Láìsí àní-àní, gbogbo wa la fẹ́ láti máa gbé nínú ilé tó dára. Síbẹ̀, dípò tí a ó fi máa wá bá a ṣe lè kọ́ irú ilé bẹ́ẹ̀ ní báyìí, bóyá nípa títọrùn bọ gbèsè rẹpẹtẹ, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká pọkàn pọ̀ sórí ìlérí Jèhófà? Ẹ rántí ohun tí Jésù sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Lúùkù 9:58) Bí Jésù bá fẹ́ kọ́ ilé tó dára jù lọ tí kò sẹ́ni tó nírú rẹ̀ rí, ó lè kọ́ ọ tàbí kó rà á. Kí nìdí tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò fẹ́ kí ohunkóhun fa ìpínyà ọkàn fún òun, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ fífi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. Ṣé àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa jíjẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan, ká má ṣe jẹ́ kí ohun ìní tara gbà wá lọ́kàn débi tí a ó fi máa ṣàníyàn?—Mát. 6:33, 34.

“ÌKOOKÒ ÀTI Ọ̀DỌ́ ÀGÙNTÀN . . . YÓÒ MÁA JÙMỌ̀ JẸUN PỌ̀”

7. Lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ẹranko àti èèyàn, ipò wo ló fi èèyàn sí?

7 Èèyàn ni Jèhófà dá gbẹ̀yìn nínú gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀, àwa la sì gbayì jù lọ lára àwọn nǹkan tó dá sáyé. Nígbà tí Jèhófà ń sọ ohun tó ní lọ́kàn nípa àwa èèyàn fún Àgbà Òṣìṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn àkọ́bí Ọmọ rẹ̀, ó ní: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa, kí wọ́n sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ ayé àti olúkúlùkù ẹran tí ń rìn ká, tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 1:26) Nípa báyìí, Jèhófà fi Ádámù àti Éfà àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn jọba lórí àwọn ẹranko.

8. Báwo làwọn ẹranko ṣe máa ń fi ìmọ̀lára wọn hàn?

8 Ṣé òótọ́ ló ṣeé ṣe kí àwa èèyàn jọba lórí gbogbo ẹranko ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn? Ohun kan ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni àwọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn, bí ajá àti ológbò, jọ ń gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. Àmọ́, àwọn ẹranko ẹhànnà ńkọ́? Ìròyìn kan sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ń ṣàkíyèsí àwọn ẹranko dáadáa ti rí i pé gbogbo ẹranko afọ́mọlọ́mú máa ń fi bí nǹkan ṣe rí lára wọn hàn.” A sábà máa ń rí àwọn ẹranko tí ẹ̀rù máa ń bà tàbí tí wọ́n máa ń di òǹrorò nígbà tí wọ́n bá halẹ̀ mọ́ wọn, àmọ́ ǹjẹ́ àwọn ẹranko yìí lójú àánú? Ìròyìn yẹn tún sọ pé: “Téèyàn bá fẹ́ rí ànímọ́ tó fani mọ́ra jù lọ tí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní, kó lọ wò wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń tọ́mọ lọ́wọ́, èèyàn á rí i pé wọ́n máa ń fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn gan-an ni.”

9. Àyípadà wo la lè retí pé ó máa wáyé láàárín àwọn ẹranko?

9 Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu nígbà tá a bá kà á nínú Bíbélì pé àlàáfíà máa jọba láàárín èèyàn àti ẹranko. (Ka Aísáyà 11:6-9; 65:25.) Kí nìdí? Ẹ rántí pé nígbà tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì lẹ́yìn Ìkún Omi, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Ìbẹ̀rù yín àti ìpayà yín yóò sì máa wà lára gbogbo ẹ̀dá alààyè ilẹ̀ ayé.” Ààbò ni èyí sì jẹ́ fún àwọn ẹranko. (Jẹ́n. 9:2, 3) Ṣé Jèhófà ò wá lè mú ìbẹ̀rù àti ìpayà yẹn kúrò lára àwọn ẹranko dé ìwọ̀n ayé kan, kí ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ lè ṣeé ṣe? (Hós. 2:18) Ẹ ò rí i pé àkókò aláyọ̀ ló ń dúró de àwọn tó bá là á já sínú ayé tuntun!

‘YÓÒ NU OMIJÉ GBOGBO NÙ KÚRÒ’

10. Kí nìdí tí omijé fi máa ń wà lójú àwa èèyàn?

10 Nígbà tí Sólómọ́nì rí “gbogbo ìwà ìninilára tí a ń hù lábẹ́ oòrùn,” ó kédàárò pé: “Wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú.” (Oníw. 4:1) Bí ipò nǹkan ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ìyẹn bí ò bá tiẹ̀ burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àbí a rí ẹnì kan nínú wa tí omijé kò tíì bọ́ lójú rẹ̀ rí fún àwọn ìdí kan? Òótọ́ ni pé, nígbà míì omijé tó bọ́ lójú èèyàn lè jẹ́ omijé ayọ̀. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà nǹkan ìbànújẹ́ ló sábà máa ń fa omijé.

11. Ìtàn wo nínú Bíbélì ló ṣe ẹ́ láàánú jù lọ?

11 Ronú nípa àwọn ìtàn tó ṣeni láàánú tá a kà nínú Bíbélì nípa àwọn tó sunkún. Nígbà tí Sárà kú lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàádóje [127], “Ábúráhámù sì wọlé láti pohùn réré ẹkún Sárà àti láti sunkún lórí rẹ̀.” (Jẹ́n. 23:1, 2) Nígbà tí Náómì ń dágbére fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ tí àwọn náà jẹ́ opó, ‘wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún,’ lẹ́yìn náà “wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún púpọ̀ sí i.” (Rúùtù 1:9, 14) Nígbà tí Hesekáyà Ọba ṣàìsàn tó sì dájú pé ó máa kú, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀,” àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé ohun tó ṣe yìí mú kí Jèhófà káàánú rẹ̀ gidigidi. (2 Ọba 20:1-5) Ta sì ni kì í káàánú Pétérù tó bá ka àkọsílẹ̀ nípa bí àpọ́sítélì náà ṣe sẹ́ Jésù? Bí Pétérù ṣe gbọ́ tí àkùkọ kọ, ó “bọ́ sóde, ó sì sunkún kíkorò.”—Mát. 26:75.

12. Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú ìtura bá aráyé?

12 Nítorí onírúurú àjálù tó ń dé bá ìran èèyàn, gbogbo wa la nílò ìtùnú àti ìtura lójú méjèèjì. Ohun tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi sì máa mú wá fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ nìyẹn: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣí. 21:4) Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó bí ọ̀fọ̀, igbe ẹ̀kún àti ìrora kò bá sí mọ́! Kì í wá ṣe ìyẹn nìkan o, Ọlọ́run tún máa mú ikú tó jẹ́ olórí ọ̀tá wa kúrò. Báwo ni ìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀?

“GBOGBO ÀWỌN TÍ WỌ́N WÀ NÍNÚ IBOJÌ ÌRÁNTÍ YÓÒ . . . JÁDE WÁ”

13. Ipa wo ni ikú ti ní lórí àwa èèyàn látìgbà tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀?

13 Látìgbà tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀ ni ikú ti ń jọba lórí gbogbo èèyàn. Ikú jẹ́ ọ̀tá alénimádẹ̀yìn, kò sẹ́ni tí ikú ò lè pa nínú àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀, ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn tó sì ń fà kọjá àfẹnusọ. (Róòmù 5:12, 14) Kódà, “ìbẹ̀rù ikú” ti fi àìmọye èèyàn “sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.”—Héb. 2:15.

14. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ikú kò bá sí mọ́?

14 Bíbélì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́r. 15:26) Àwùjọ méjì ló máa jàǹfààní látinú ìlérí yìí. Ó máa ṣeé ṣe fún àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó wà láàyè báyìí láti là á já sínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, wọ́n á sì máa wà láàyè títí láé. Ó sì tún máa ṣeé ṣe fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti kú láti jíǹde. Ẹ wo bí ayọ̀ náà ṣe máa pọ̀ tó nígbà tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” bá ń kí àwọn òkú tó jíǹde káàbọ̀ sínú ayé tuntun! Tá a bá fara balẹ̀ ka àwọn àkọsílẹ̀ kan nípa àjíǹde nínú Bíbélì, èyí lè jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa rí nígbà àjíǹde.—Ka Máàkù 5:38-42; Lúùkù 7:11-17.

15. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá rí èèyàn rẹ kan tó jíǹde?

15 Ronú lórí àwọn gbólóhùn náà “wọn kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ” àti “wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo.” Ká sọ pé o wà níbẹ̀ láwọn àkókò yìí ni, ó ṣeé ṣe kó o ní irú ìmọ̀lára kan náà. Ká sòótọ́, inú wá máa dùn gan-an tá a bá rí àwọn èèyàn wa tó ti kú tí wọ́n tún pa dà wá sí ìyè nígbà àjíǹde. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòh. 5:28, 29) Kò sí ẹnì kankan nínú wa tó tíì rí ẹnì kan tó jíǹde rí; ó dájú pé ọ̀kan lára ohun tó yani lẹ́nu jù lọ nínú “àwọn ohun tí a kò rí” ni àjíǹde máa jẹ́.

ỌLỌ́RUN YÓÒ JẸ́ “OHUN GBOGBO FÚN OLÚKÚLÙKÙ”

16. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fìtara sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tí a kò tíì rí yìí? (b) Ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì?

16 Láìsí àní-àní, ọjọ́ ọ̀la ológo ń dúró de àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lákòókò lílekoko yìí! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tíì rí àwọn ìbùkún àgbàyanu yìí, tí a bá ń fi wọ́n sọ́kàn, a ó lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun to ṣe pàtàkì ní tòótọ́, a kò sì ní jẹ́ kí àwọn ohun tó ń dán yòò nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí fa ìpínyà ọkàn fún wa. (Lúùkù 21:34; 1 Tím. 6:17-19) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìtara sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun àgbàyanu tá à ń retí yìí nígbà Ìjọsìn Ìdílé, bí àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá ń sọ̀rọ̀ tàbí nínú ìjíròrò pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àti àwọn olùfìfẹ́hàn. Èyí á jẹ́ kí ìrètí tá a ní yìí máa dán yinrin nínú ọkàn wa. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gan-an nìyẹn nígbà tó ń fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ní ìṣírí. Ó sọ ohun tó mú kí wọ́n ronú nípa nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Gbìyànjú láti ronú nípa ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà ní 1 Kọ́ríńtì 15:24, 25, 28.Kà á.

17, 18. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ “ohun gbogbo fún olúkúlùkù” nígbà tó ṣẹ̀dá èèyàn? (b) Kí ni Jésù máa ṣe láti mú kí ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ pa dà wà láàárín èèyàn àti Ọlọ́run?

17 Kò sí ọ̀rọ̀ míì tá a tún lè fi ṣàpèjúwe ohun tó jẹ́ òpin ológo náà ju pé “kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ẹ jẹ́ ká rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì nígbà tí Ádámù àti Éfà jẹ́ ẹni pípé tí wọ́n sì jẹ́ ara ìdílé alálàáfíà ti Jèhófà tó wà ní ìṣọ̀kan. Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run ló ń ṣàkóso àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní tààràtà, ìyẹn àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì. Wọ́n láǹfààní láti bá a sọ̀rọ̀ ní tààràtà, wọ́n lè sìn ín, wọ́n sì lè rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Ó jẹ́ “ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”

18 Sátánì ba àjọṣe tímọ́tímọ́ yẹn jẹ́ nígbà tó lo èèyàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ṣùgbọ́n láti ọdún 1914, Ìjọba Mèsáyà ti ń gbé ìgbésẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé kó lè dá ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ yẹn pa dà. (Éfé. 1:9, 10) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn ohun àgbàyanu “tí a kò rí” báyìí á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn náà ni “òpin” yóò dé, ìyẹn òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé,” kò ṣe tán láti gba ipò mọ́ Jèhófà lọ́wọ́. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ máa mú kó “fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́.” Ó máa lo ipò pàtàkì àti ọlá àṣẹ rẹ̀ “fún ògo Ọlọ́run.”—Mát. 28:18; Fílí. 2:9-11.

19, 20. (a) Báwo ni gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa fi hàn bóyá àwọn fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ? (b) Ohun àgbàyanu wo là ń retí?

19 Tó bá fi máa di ìgbà yẹn, àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run á ti di pípé. Wọ́n á fìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ Jésù, wọ́n á sì fínnú fíndọ̀ fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Àǹfààní á sì wà fún wọn láti fi hàn pé ohun táwọn fẹ́ ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n bá yege ìdánwò ìkẹyìn. (Ìṣí. 20:7-10) Lẹ́yìn náà, gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ ni Ọlọ́run máa pa run títí láé. Ẹ sì wo bí ìyẹn á ṣe jẹ́ àkókò aláyọ̀ àti ìdùnnú tó! Gbogbo ìdílé Ọlọ́run láyé àtọ̀run á wá máa fayọ̀ yin Jèhófà, ẹni tó máa jẹ́ “ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—Ka Sáàmù 99:1-3.

20 Ǹjẹ́ àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba ológo tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán yìí á mú kó o máa sapá gidigidi láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? Ṣé wàá kíyè sára kí ìrètí àti ìtùnú asán tí Sátánì ń fún àwọn èèyàn má bàa fa ìpínyà ọkàn fún ẹ? Ṣé wàá máa bá a nìṣó láti fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ? Ǹjẹ́ kí ìgbé ayé rẹ fi hàn pé òótọ́ ló wù ẹ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí láé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní àlàáfíà àti aásìkí fún ẹgbẹ̀rún ọdún àti títí láé!