Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Sùúrù Jèhófà Àti Jésù
“Ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.”—2 PÉT. 3:15.
1. Kí làwọn olóòótọ́ kan máa ń ṣàníyàn nípa rẹ̀?
ARÁBÌNRIN kan tó jẹ́ olùṣòtítọ́, tó ti ń sin Jèhófà látìgbà pípẹ́ tó sì ti fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro, béèrè pé: “Ǹjẹ́ mi ò ní kú kí òpin tó dé báyìí?” Àwọn míì tí wọ́n ti ń sin Jèhófà látìgbà pípẹ́ náà máa ń ṣàníyàn lọ́nà yìí. À ń retí ìgbà tí Ọlọ́run máa sọ ohun gbogbo di ọ̀tun, tó sì máa mú àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra nísinsìnyí kúrò. (Ìṣí. 21:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí jaburata wà tó mú ká gbà pé òpin ètò Sátánì ti sún mọ́lé gan-an, síbẹ̀ ó lè má rọrùn fún wa láti ní sùúrù títí di ìgbà tí òpin náà máa dé.
2. Àwọn ìbéèrè wo nípa sùúrù Ọlọ́run la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Síbẹ̀, Bíbélì fi hàn pé a gbọ́dọ̀ ní sùúrù. Bíi tàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó gbé láyé ṣáájú wa, a máa rí ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí gbà tá a bá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tá a sì fi sùúrù dúró de ìgbà tó máa mú àwọn ìlérí náà ṣẹ. (Ka Hébérù 6:11, 12.) Ó pẹ́ tí Jèhófà alára ti ń mú sùúrù fún wa. Ó lè fi òpin sí ìwà ibi nígbàkigbà, àmọ́ ó ń mú sùúrù kó lè fi òpin sí i ní ìgbà tó tọ́. (Róòmù 9:20-24) Kí nìdí tó fi mú sùúrù tó bẹ́ẹ̀? Báwo ni Jésù ṣe ní sùúrù bíi ti baba rẹ̀ tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa? Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé kí àwa náà máa mú sùúrù bíi ti Ọlọ́run? Àwọn ìdáhùn tá a máa rí sáwọn ìbéèrè yìí á mú ká mọ bá a ṣe lè ní sùúrù àti ìgbàgbọ́ tó lágbára, bó bá tiẹ̀ ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ń fi nǹkan falẹ̀.
KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI Ń MÚ SÙÚRÙ?
3, 4. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń mú sùúrù bó ṣe ń mú ète rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé ṣẹ? (b) Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí ìwà ọ̀tẹ̀ wáyé ní Édẹ́nì?
3 Ó ní ìdí pàtàkì tí Jèhófà fi ń mú sùúrù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló ní ọlá àṣẹ tó ga jù lọ láyé àti lọ́run lọ́jọ́ gbogbo, síbẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì mú kó pọn dandan láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè kan, àwọn ìdáhùn náà sì máa ṣe gbogbo àwọn tó ń gbé láyé àtọ̀run láǹfààní. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ń mú sùúrù torí ó mọ̀ pé ó máa gba àkókò ká tó rí ìdáhùn tó ṣe rẹ́gí sí àwọn ìbéèrè yẹn. Níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìwà àti ìṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn áńgẹ́lì tó ń gbé lọ́run àti àwa èèyàn tá à ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, ó dájú pé gbogbo ohun tó ń ṣe jẹ́ fún ire wa.—Héb. 4:13.
4 Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà kún orí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí Sátánì tan Éfà jẹ tí Ádámù sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run lẹ́yìn náà, kò torí rẹ̀ pa ohun tó ti pinnu láti ṣe tì. Kò mikàn, kò kánjú ṣèpinnu, kò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ aráyé sú òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló wá ọ̀nà tó máa gbà mú ohun tó ti pinnu pé òun máa ṣe fún aráyé àti ilẹ̀ ayé ṣẹ. (Aísá. 55:11) Kí Jèhófà lè ṣe gẹ́gẹ́ bó ṣe pinnu kó sì dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre, ó ti lo ìkóra-ẹni-níjàánu àti sùúrù púpọ̀, kódà ó ti dúró fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún kí àwọn kan lára ohun tó ti pinnu láti ṣe lè kẹ́sẹ járí.
5. Ìbùkún wo ni sùúrù Jèhófà ti mú wá?
5 Ìdí mìíràn wà tí Jèhófà fi ń mú sùúrù. Ìdí náà sì ni pé ó fẹ́ kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó ń múra sílẹ̀ láti gba “ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn là. (Ìṣí. 7:9, 14; 14:6) Ó ń tipasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wa ké sí àwọn èèyàn láti wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba rẹ̀ àti àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run sì ni ìròyìn tó dára jù lọ fún ìran èèyàn, ojúlówó “ìhìn rere” ni lóòótọ́. (Mát. 24:14) Olúkúlùkù ẹni tí Jèhófà bá fà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ á wá di ara ìjọ Ọlọ́run tó wà kárí ayé, níbi tí àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun tó tọ́ wà. (Jòh. 6:44-47) Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ máa ń ran irú àwọn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Ó tún ti ń yan àwọn kan láàárín aráyé kí wọ́n lè di ara Ìjọba rẹ̀ lókè ọ̀run. Bí àwọn olùfọkànsìn tí Ọlọ́run yàn yìí bá dé ọ̀run, wọ́n máa ran aráyé tó jẹ́ onígbọràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di pípé kí wọ́n sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Torí náà, bí Jèhófà tilẹ̀ ń mú sùúrù, kò dáwọ́ iṣẹ́ dúró kó bàa lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ fún ire wa.
6. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe mú sùúrù nígbà ayé Nóà? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú sùúrù lóde òní?
6 Ohun tí Jèhófà ṣe nígbà táwọn èèyàn ń hùwà búburú ṣáájú Ìkún-omi jẹ́ ká rí i pé ó máa ń mú sùúrù báwọn èèyàn bá tiẹ̀ ṣe ohun tó bà á nínú jẹ́. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ó ‘dun Jèhófà dé ọkàn’ torí pé àwọn èèyàn ti fi ìṣekúṣe àti ìwà ipá kún ilẹ̀ ayé, ohun tó burú ló sì ń wù wọ́n láti ṣe. (Jẹ́n. 6:2-8) Kò lè gbà kí ìwà búburú yẹn máa bá a nìṣó títí ayé, torí náà, ó pinnu pé òun máa fi ìkún-omi pa aráyé aláìgbọràn run. Ní gbogbo ìgbà tí ‘Ọlọ́run fi ń mú sùúrù ní àwọn ọjọ́ Nóà,’ ó ṣe àwọn ètò tó mú kó ṣeé ṣe fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ láti la ìparun náà já. (1 Pét. 3:20) Nígbà tí àkókò tó lójú Jèhófà, ó sọ ohun tó pinnu láti ṣe fún Nóà, ó sì sọ pé kó kan ọkọ̀ áàkì kan. (Jẹ́n. 6:14-22) Ní àfikún sí ìyẹn, Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo,” ó ń sọ fún àwọn aládùúgbò rẹ̀ nípa ìparun tó ń bọ̀ náà. (2 Pét. 2:5) Jésù sọ pé bí ọjọ́ Nóà ni àkókò wa ṣe rí. Jèhófà ti pinnu ìgbà tó máa mú ètò búburú yìí wá sí òpin. Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí òpin yìí máa dé. (Mát. 24:36) Ní báyìí, iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ ni pé ká máa kìlọ̀ fún àwọn èèyàn ká sì máa sọ fún wọn bí wọ́n ṣe lè rí ìgbàlà.
7. Ǹjẹ́ Jèhófà ń fi ìlérí rẹ̀ jáfara? Ṣàlàyé.
7 Ó ti ṣe kedere báyìí pé sùúrù Jèhófà kò túmọ̀ sí pé ńṣe ló kàn ń fi àkókò ṣòfò lásán. A kò sì gbọ́dọ̀ ronú pé ńṣe ni sùúrù rẹ̀ fi hàn pé kò rí tiwa rò tàbí pé ọ̀rọ̀ wa kò jẹ ẹ́ lógún. Àmọ́, òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ó lè ṣòro fún wa láti fi èyí sọ́kàn bí ọjọ́ ogbó ṣe ń dé tàbí bá a ṣe ń fojú winá ìṣòro nínú ètò búburú yìí. A lè rẹ̀wẹ̀sì tàbí kó máa ṣe wá bíi pé Ọlọ́run ń fi àwọn ìlérí rẹ̀ jáfara. (Héb. 10:36) A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ó ní ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi ń mú sùúrù àti pé àǹfààní àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ni àkókò tó fi sílẹ̀ yìí wà fún. (2 Pét. 2:3; 3:9) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bí Jésù pẹ̀lú ṣe ń mú sùúrù bíi ti Baba rẹ̀.
BÁWO NI JÉSÙ ṢE FI ÀPẸẸRẸ ÀTÀTÀ LÉLẸ̀ NÍPA MÍMÚ SÙÚRÙ?
8. Lábẹ́ àwọn ipò wo ni Jésù ti mú sùúrù?
8 Ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni Jésù ń ṣe, ó sì ti fi tọkàntọkàn ṣe bẹ́ẹ̀ fún àìmọye ọdún. Nígbà tí Sátánì ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà pinnu pé Ọmọ bíbí òun kan ṣoṣo máa wá sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Ronú nípa bí ìyẹn ṣe máa rí lára Jésù, ó ti ní láti dúró fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún kí àkókò yẹn tó tó. (Ka Gálátíà 4:4.) Ní gbogbo àkókò yẹn, Jésù ò wulẹ̀ káwọ́ lẹ́rán kó máa wòran; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọwọ́ rẹ̀ dí lẹ́nu iṣẹ́ tí Baba rẹ̀ yàn fún un. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tó wá sórí ilẹ̀ ayé, ó mọ̀ pé Sátánì máa ṣokùnfà ikú òun, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Jẹ́n. 3:15; Mát. 16:21) Wọ́n fìyà jẹ ẹ́, ó sì jẹ̀rora lọ́pọ̀lọpọ̀. Síbẹ̀, ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kò sí ẹni tó tíì jẹ́ adúróṣinṣin bíi tiẹ̀ rí. Kò ka ara rẹ̀ sí bàbàrà, kò sì ro ti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run. Àwa náà lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rẹ̀.—Héb. 5:8, 9.
9, 10. (a) Kí ni Jésù ti ń ṣe látìgbà tó ti ń fi sùúrù dúró de ohun tí Jèhófà máa ṣe? (b) Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àkókò tí Jèhófà ti pinnu pé káwọn nǹkan ṣẹlẹ̀?
9 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti jí Jésù dìde, ó fún un ní ọlá àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 28:18) Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń lo àṣẹ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Jèhófà bá fẹ́ kó ṣe, èyí sì máa ń jẹ́ ní àkókò tí Ọlọ́run ti pinnu. Jésù jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run títí di ọdún 1914, ó mú sùúrù títí dìgbà tí Ọlọ́run fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀. (Sm. 110:1, 2; Héb. 10:12, 13) Kò sì ní pẹ́ mọ́ tó fi máa mú òpin dé bá ètò Sátánì. Ní báyìí, Jésù ń fi sùúrù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ó sì ń ṣamọ̀nà wọn lọ síbi “omi ìyè.”—Ìṣí. 7:17.
10 Ǹjẹ́ o ti rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Jésù nípa ojú tó yẹ kó o máa fi wo àkókò tí Jèhófà ti pinnu pé káwọn nǹkan ṣẹlẹ̀? Kò sí iyè méjì pé ó wu Jésù láti ṣe ohunkóhun tí Baba rẹ̀ bá ní kó ṣe; síbẹ̀, ó máa ń fẹ́ láti dúró de àkókò tí Ọlọ́run bá ti pinnu. Bá a ṣe ń dúró de ìgbà tí ètò búburú Sátánì máa wá sópin, ó pọn dandan pé kí gbogbo wa máa ní sùúrù bíi ti Ọlọ́run, ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, ká má sì juwọ́ sílẹ̀ nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì. Kí la lè ṣe ká bàa lè máa ní sùúrù bíi ti Ọlọ́run?
BÁWO NI MO ṢE LÈ MÁA MÚ SÙÚRÙ BÍI TI ỌLỌ́RUN?
11. (a) Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe ń mú ká ní sùúrù? (b) Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára?
11 Kí Jésù tó wá sáyé, àwọn wòlíì àtàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bí àwọn èèyàn tó jẹ́ aláìpé pàápàá ṣe lè fi sùúrù lo ìfaradà. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní ló mú kí wọ́n ní sùúrù. (Ka Jákọ́bù 5:10, 11.) Bí wọn kò bá ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú ohun tí Jèhófà sọ fún wọn, ǹjẹ́ wọ́n á lè fi sùúrù dúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀? Ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ bí àkókò bá tó, torí náà ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n fara da àwọn ipò bíbanilẹ́rù tàbí ipò líle koko tó dán ìgbàgbọ́ wọn wò. (Héb. 11:13, 35-40) Kódà, ìdí púpọ̀ sí i wà tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, torí pé ní báyìí, Jésù ti di “Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.” (Héb. 12:2) Ó mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, ó sì sọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pinnu láti ṣe fún wa lọ́nà tó jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìgbàgbọ́.
12. Báwo la ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára?
12 Àwọn nǹkan wo la lè ṣe kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára ká lè túbọ̀ máa ní sùúrù? Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run sílò. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí àwọn ìdí tó fi yẹ kó o máa fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ. Ṣé o lè túbọ̀ sapá láti máa fi ìmọ̀ràn inú Mátíù 6:33 sílò? Ìyẹn lè gba pé kó o máa lo àkókò púpọ̀ sí i lóde ẹ̀rí tàbí kó o ṣe àwọn àyípadà kan nínú ìgbé ayé rẹ. Má ṣe gbàgbé pé Jèhófà ló ràn ẹ́ lọ́wọ́ débi tó o dé yìí. Ó lè ti mú kó ṣeé ṣe fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kó ti fún ẹ ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Ka Fílípì 4:7.) Bó o ṣe ń ronú lórí àwọn àǹfààní tí ìwọ fúnra rẹ ti rí gbà torí pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà, wàá túbọ̀ rí ìdí tó fi yẹ kó o máa ní sùúrù.—Sm. 34:8.
13. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe ohun tó gbà kéèyàn tó ní ìgbàgbọ́ àti sùúrù?
13 A lè fi ohun tó gbà kéèyàn tó lè ní ìgbàgbọ́ àti sùúrù wé bí àwọn àgbẹ̀ ṣe máa ń gbin irè oko, tí wọ́n máa ń tọ́jú rẹ̀, kí wọ́n tó wá kórè rẹ̀. Gbogbo ìgbà tí àgbẹ̀ kan bá kó irè oko tó pọ̀ wálé ló máa ń ní ìfọkànbalẹ̀ pé òun á tún gbin irè oko náà nígbà míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa fi sùúrù dúró di ìgbà ìkórè, kò ní torí ìyẹn sọ pé òun ò gbin irè oko mọ́, kódà ó lè fi ilẹ̀ tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ṣọ̀gbìn. Ó dá a lójú gbangba pé ó máa kórè ohun tó bá gbìn. Bákan náà, bá a ṣe ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtọ́ni Jèhófà, tá à ń tẹ̀ lé wọn, tá a sì ń jàǹfààní látinú wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bákan náà, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, á sì wá túbọ̀ rọrùn fún wa láti dúró de àwọn ìbùkún tó dá wa lójú pé a máa rí gbà.—Ka Jákọ́bù 5:7, 8.
14, 15. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìyà tó ń jẹ aráyé?
14 Ohun mìíràn tó lè mú ká túbọ̀ máa ní sùúrù ni pé ká máa wo ara wa àti ayé yìí ní ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà wò ó. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìyà tó ń jẹ àwa ẹ̀dá. Ó pẹ́ tó ti máa ń dùn ún tó bá rí i pé ìyà ń jẹ àwa èèyàn, síbẹ̀, kì í dùn ún débi pé kó má lè ṣe ohun rere. Ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sáyé láti wá “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú” kó sì mú gbogbo nǹkan tí Sátánì fi ń fa wàhálà bá aráyé kúrò. (1 Jòh. 3:8) Ńṣe ló máa dà bíi pé ìgbà kúkúrú ni ìyà náà fi wà, àmọ́ ojútùú tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ máa wà pẹ́ títí. Bákan náà, dípò tí a ó fi jẹ́ kí ìwà búburú inú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso rẹ̀ yìí sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ tàbí kí ojú máa kán wa pé ó ti yẹ kó wá sópin, ẹ jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun tí a kò rí, èyí tó máa wà títí láé. Jèhófà ti yan àkókò pàtó kan tó máa fòpin sí ìwà búburú, ó sì máa ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí àkókò bá tó.—Aísá. 46:13; Náh. 1:9.
15 Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko ti ètò àwọn nǹkan búburú yìí, ó lè pọn dandan pé ká fara da àwọn ìṣòro líle koko tó máa dán ìgbàgbọ́ wa wò. Dípò tí a ó fi máa fara ya bí wọ́n bá hùwà ipá sí wa tàbí tí ìyà bá ń jẹ èèyàn wa kan, ńṣe ló yẹ ká pinnu pé a máa ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà. Torí pé a jẹ́ aláìpé, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká rántí ohun tí Jésù ṣe, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Mátíù 26:39.—Kà á.
16. Kí la gbọ́dọ̀ yẹra fún ní àkókò tó ṣẹ́ kù yìí?
16 Ohun kan wà tó lè mú kó ṣòro fún wa láti máa mú sùúrù bíi ti Ọlọ́run. Ìyẹn tá a bá ń ronú pé ó yẹ ká tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá torí a-kì-í-bàá-mọ̀. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Bí kò bá dá ẹnì kan lójú pé òpin ti sún mọ́lé, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò tọ́ pé àwọn nǹkan lè ṣàì rí bí Jèhófà ṣe sọ pé wọ́n máa rí, torí náà ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í dá ètò tara rẹ̀ ṣe. Lédè mìíràn, ó lè máa ronú pé, ‘Jẹ́ kí n ṣì máa wò ó ná, bóyá Jèhófà máa mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.’ Lẹ́yìn náà, ó lè gbìyànjú láti ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ nínú ayé yìí, kó máa wá bó ṣe máa rí towó ṣe dípò kó fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ tàbí kó gbà pé bí òun bá fẹ́ máa gbé ìgbé ayé tó tẹ́ òun lọ́rùn ní báyìí, àfi kóun kàwé rẹpẹtẹ. Àmọ́, ká sòótọ́, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní fi hàn pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ìgbàgbọ́? Rántí pé Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká di aláfarawé àwọn olùṣòtítọ́ tí wọ́n “tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù” rí àwọn ìlérí Jèhófà gbà. (Héb. 6:12) Jèhófà kò ní jẹ́ kí ètò búburú yìí máa bá a nìṣó kọjá àkókò tó yẹ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó ti pinnu láti ṣe. (Háb. 2:3) Ní báyìí ná, a kò gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní ìṣe gbà-jẹ́-n-sinmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò ká sì máa fìtara wàásù ìhìn rere, èyí sì máa mú ká ní ìtẹ́lọ́rùn tí kò láfiwé nísinsìnyí pàápàá.—Lúùkù 21:36.
ÈRÈ WO LÓ WÀ NÍNÚ KÉÈYÀN MÁA MÚ SÙÚRÙ?
17, 18. (a) Àǹfààní wo là ń rí gbà báyìí bá a ṣe ń mú sùúrù? (b) Bá a ṣe ń mú sùúrù báyìí, àwọn ìbùkún wo la máa rí gbà lọ́jọ́ iwájú?
17 Yálà a ti sin Ọlọ́run fún oṣù díẹ̀ tàbí fún ọ̀pọ̀ ọdún, a fẹ́ láti máa sìn ín títí láé. Láìka àkókò tó kù sí kí òpin ètò àwọn nǹkan yìí fi dé, sùúrù á mú ká lè máa fara dà á títí tá a fi máa rí ìgbàlà. Jèhófà ń fún wa láǹfààní láti fi hàn pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú àwọn ìpinnu rẹ̀, bó bá sì ṣeé ṣe, ká múra tán láti jìyà ibi nítorí orúkọ rẹ̀. (1 Pét. 4:13, 14) Ọlọ́run tún ń fún wa ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa mú ká ní sùúrù títí dé òpin ká sì rí ìgbàlà.—1 Pét. 5:10.
18 Jésù ní gbogbo ọlá àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, kò sì sí ohunkóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti máa bójú tó ẹ kó sì máa dáàbò bò ẹ́, bó o bá dúró bí olóòótọ́. (Jòh. 10:28, 29) Kò sí ìdí tó o fi ní láti máa bẹ̀rù ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, ì báà jẹ́ ikú pàápàá. Àwọn tó bá fi sùúrù fara dà á títí dé òpin máa rí ìgbàlà. Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a kò jẹ́ kí ayé yìí sún wa dẹ́ṣẹ̀ kó sì sọ wá di ẹni tí kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ pinnu pé a óò mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i àti pé a máa lo àkókò tí Ọlọ́run fi ń mú sùúrù fún wa yìí lọ́nà ọgbọ́n.—Mát. 24:13; ka 2 Pétérù 3:17, 18.