Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń kó Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Aláyọ̀ Jọ

Jèhófà Ń kó Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Aláyọ̀ Jọ

“Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àtìpó.”—DIU. 31:12.

1, 2. Kí ni àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn àpéjọ àwa èèyàn Ọlọ́run?

 ỌJỌ́ pẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ti máa ń pé jọ ní àwọn àpéjọ àgbáyé àti àpéjọ àgbègbè. Ọ̀pọ̀ lára wa náà la ti lọ sí àwọn àpéjọ tó ń fúnni láyọ̀ yìí, ó sì ṣeé ṣe ká ti lọ sí ọ̀pọ̀ irú rẹ̀ láti àwọn ọdún yìí wá.

2 Àwọn èèyàn Ọlọ́run tó gbé láyé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn náà lọ sí àwọn àpéjọ mímọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn àpéjọ tí Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe, a máa rí bí wọ́n ṣe jọ àwọn àpéjọ tá à ń ṣe lónìí àti bá a ṣe lè jàǹfààní nínú lílọ sí àwọn àpéjọ náà.—Sm. 44:1; Róòmù 15:4.

ÀWỌN ÀPÉJỌ PÀTÀKÌ NÍGBÀ ÀTIJỌ́ ÀTI LÓDE ÒNÍ

3. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà àpéjọ àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà ṣe? (b) Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń mọ ìgbà tó yẹ kí wọ́n pé jọ?

3 Àpéjọ ńlá àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ wáyé nígbà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run pé jọ sí iwájú Òkè Sínáì láti gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ Jèhófà. Láìsí àní-àní, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nìyẹn jẹ́ nínú ìtàn ìjọsìn mímọ́. Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ yẹn, èyí tó dájú pé àwọn tó ṣojú wọn kò jẹ́ gbàgbé, Jèhófà mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí bí agbára òun ṣe pọ̀ tó nígbà tó fún wọn ní Òfin rẹ̀. (Ẹ́kís. 19:2-9, 16-19; ka Ẹ́kísódù 20:18; Diutarónómì 4:9, 10.) Àpéjọ yìí ló jẹ́ ká rí ìyípadà tó dé bá àjọṣe tó wà láàárín Ọlọ́run àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kò sì pẹ́ púpọ̀ sí ìgbà náà tí Jèhófà sọ ọ̀nà tí yóò máa gbà pé àwọn èèyàn náà jọ fún Mósè. Ó pàṣẹ fún Mósè pé kó ṣe kàkàkí fàdákà méjì tí yóò máa fi pe “gbogbo àpéjọ náà” láti pàdé “ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” (Núm. 10:1-4) Ẹ sì fojú inú wo bí wọ́n á ṣe máa láyọ̀ tó nígbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn bá wáyé!

4, 5. Kí nìdí tí àwọn àpéjọ tí Mósè àti Jóṣúà ṣètò fi ṣe pàtàkì gan-an?

4 Lẹ́yìn nǹkan bí ogójì ọdún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà nínú aginjù. Mósè ṣètò àpéjọ kan fún gbogbo wọn. Àpéjọ náà wáyé ní àkókò tó ṣe pàtàkì gan-an nínú ìtàn orílẹ̀-èdè tuntun yẹn torí pé wọ́n ti múra tán láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àkókò yẹn ló sì tọ́ kí Mósè rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn àtàwọn ohun tó ṣì ń bọ̀ wá ṣe.—Diu. 29:1-15; 30:15-20; 31:30.

5 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ní àpéjọ yẹn náà ni Mósè ti sọ fún wọn pé irú àpéjọ bẹ́ẹ̀ á máa wáyé déédéé àti pé Ọlọ́run á máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ní àwọn ọdún Sábáàtì nígbà Àjọyọ̀ Àwọn Àtíbàbà, àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn àtìpó tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ pé jọ sí ibì kan tí Jèhófà yàn ‘kí wọ́n lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ bí wọn yóò ṣe máa bẹ̀rù Jèhófà, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin ṣe.’ (Ka Diutarónómì 31:1, 10-12.) Torí náà, látìgbà yẹn lọ nínú ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run ló ti ṣe kedere pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa pé jọ déédéé láti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà àtàwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gba gbogbo Ilẹ̀ Ìlérí, síbẹ̀ tí àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ṣì yí wọn ká, Jóṣúà pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ láti fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Jèhófà. Látàrí èyí, àwọn èèyàn náà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé Ọlọ́run ni àwọn yóò máa sìn.—Jóṣ. 23:1, 2; 24:1, 15, 21-24.

6, 7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn àpéjọ tí àwọn èèyàn Jèhófà ń ṣe lóde òní jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì?

6 Àwọn àpéjọ tó jẹ́ mánigbàgbé tún ti wáyé nínú ìtàn àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní. Ní àwọn àpéjọ yìí ni wọ́n ti máa ń ṣèfilọ̀ àwọn ìyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run tàbí àlàyé síwájú sí i lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. (Òwe 4:18) Àpéjọ ńlá tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní wáyé lọ́dún 1919, ní Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn ló pésẹ̀ síbẹ̀, wọ́n sì ṣèfilọ̀ níbẹ̀ pé àwọn èèyàn Jèhófà yóò sapá lákànṣe láti wàásù kárí ayé. Lọ́dún 1922, nígbà àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́sàn-án tí wọ́n tún ṣe níbẹ̀, Arákùnrin Joseph F. Rutherford sọ àsọyé mánigbàgbé kan tó fi ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìwàásù. Ó wá rọ àwùjọ náà pé: “Ẹ jẹ́ ẹlẹ́rìí tòótọ́, tí ó ṣeé gbára lé fún Olúwa. Ẹ máa bá ìjà náà nìṣó títí a óò fi sọ gbogbo àwókù Bábílónì di ahoro. Ẹ polongo ìhìn iṣẹ́ náà jákèjádò. Ayé gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run àti pé Jésù Kristi ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. Ọjọ́ ńlá lọjọ́ yìí. Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tí ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Àwọn tó wà ní àpéjọ náà tó fi mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run jákèjádò ayé túbọ̀ fi kún ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

7 Lọ́dún 1931, ní ìlú Columbus, ní ìpínlẹ̀ Ohio, inú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dùn gan-an láti tẹ́wọ́ gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1935 ní ìlú Washington, D.C., Arákùnrin Rutherford ṣàlàyé lórí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ìwé Ìṣípayá sọ pé wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣí. 7:9-17) Lọ́dún 1942, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́, Arákùnrin Nathan H. Knorr sọ àsọyé alárinrin kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àlàáfíà—Ǹjẹ́ Ó Lè Wà Pẹ́?” Nínú àsọyé náà, ó ṣàlàyé lórí “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” inú ìwé Ìṣípayá orí 17, ó sì sọ pé púpọ̀ ṣì wà láti ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn ogun náà.

8, 9. Kí ló fà á tí àwọn àpéjọ kan fi wúni lórí gan-an?

8 Ní Àpéjọ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti “Àwọn Orílẹ̀-Èdè Aláyọ̀” èyí tó wáyé ní ìlú Cleveland, ní ìpínlẹ̀ Ohio lọ́dún 1946, Arákùnrin Knorr sọ àsọyé kan níbẹ̀ tó jẹ́ ìwúrí fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àkòrí àsọyé náà ni, “Àwọn Ìṣòro Àtúnkọ́ àti Ìmúgbòòrò.” Arákùnrin kan tí àsọyé náà ṣojú rẹ̀ sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn ará tó wà níbẹ̀. Ó ní: “Mo ní àǹfààní láti wà lẹ́yìn rẹ̀ lórí pèpéle ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, bó sì ṣe ṣàlàyé lórí bá a ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà àti ètò tó ti wà nílẹ̀ fún mímú Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn àti ibi ìtẹ̀wé gbòòrò sí i, ńṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wà níbẹ̀ mú àtẹ́wọ́ pa lákọ̀tun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn ò lè rí ojú àwọn ará ní kedere látorí pèpéle, ó rọrùn láti rí i pé inú wọn dùn.” Ní àpéjọ àgbáyé kan tó wáyé ní ìlú New York City lọ́dún 1950, inú àwọn tó wà láwùjọ dùn láti gba apá àkọ́kọ́ nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun tí a fi àkọtọ́ tó bóde mu kọ tó sì dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí àwọn ibi tó yẹ kó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Jer. 16:21.

9 Àwọn àpéjọ tí àwọn olùṣòtítọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣe lẹ́yìn tí inúnibíni tàbí ìfòfindè bá kásẹ̀ nílẹ̀ máa ń jẹ́ ìwúrí fún wọn. Adolf Hitler ti lérí pé òun máa pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì run, àmọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́fà [107,000] lára wọn ló wà níbi àpéjọ tí wọ́n ṣe ní ìlú Nuremberg ní ọdún 1955, ní gbàgede tí àwọn ọmọ ogun Hitler ti máa ń yan. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà ní àpéjọ náà ló bú sẹ́kún ayọ̀! Ní ọdún 1989, àwọn ará tó lọ síbi àpéjọ mẹ́ta ti “Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run,” tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Poland jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélọ́gọ́rin àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méjìdínlógún [166,518]. Ọ̀pọ̀ lára wọn wá láti orílẹ̀-èdè Soviet Union àtijọ́ àti orílẹ̀-èdè Czechoslovakia àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àwọn kan lára wọn lọ sí ìpàdé tí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó pé jọ síbẹ̀ ti ju mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí ogún lọ. Ẹ sì fojú inú wo bí àwọn ará ṣe láyọ̀ tó ní Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ti ọdún 1993, tó wáyé ní ìlú Kiev, lórílẹ̀-èdè Ukraine. Àwọn tó ṣèrìbọmi níbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje àti irínwó ó lé méjì [7,402], tó jẹ́ iye Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó pọ̀ jù lọ tí wọ́n tíì ṣèrìbọmi rí.—Aísá. 60:22; Hág. 2:7.

10. Àwọn àpéjọ wo ló jẹ́ mánigbàgbé fún ẹ, kí sì nìdí?

10 Ó ṣeé ṣe kí àwọn àpéjọ àgbègbè tàbí àpéjọ àgbáyé kan wà tí o kò jẹ́ gbàgbé. Ṣó o rántí àpéjọ tó o kọ́kọ́ lọ tàbí àpéjọ tó o ti ṣèrìbọmi? Pàtàkì làwọn àpéjọ wọ̀nyẹn jẹ́ fún ẹ bó o ṣe ń jọ́sìn Jèhófà. Kò sì yẹ kó o gbàgbé irú àpéjọ bẹ́ẹ̀!—Sm. 42:4.

ÀWỌN ÀJỌYỌ̀ ỌDỌỌDÚN TÍ Ń MÚNI LÁYỌ̀

11. Àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún wo ni Ọlọ́run ní kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ṣe?

11 Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ṣe àjọyọ̀ mẹ́ta lọ́dọọdún ni ìlú Jerúsálẹ́mù, irú bí Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú, Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (tó wá di Pẹ́ńtíkọ́sì nígbà tó yá) àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà. Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn àjọyọ̀ yìí pé: “Ní ìgbà mẹ́ta nínú ọdún, gbogbo ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ yóò fara hàn níwájú Olúwa tòótọ́, Jèhófà.” (Ẹ́kís. 23:14-17) Ọ̀pọ̀ àwọn olórí ìdílé tó mọyì ìjẹ́pàtàkì àwọn àjọyọ̀ ńlá tẹ̀mí wọ̀nyí máa ń kó gbogbo ìdílé wọn lọ síbẹ̀.—1 Sám. 1:1-7; Lúùkù 2:41, 42.

12, 13. Báwo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń sapá tó kí wọ́n bàa lè lọ síbi àjọyọ̀ ọdọọdún?

12 Ronú nípa bí ìdílé kan ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe ní láti sapá tó kí wọ́n bàa lè lọ síbi àjọyọ̀ ọdọọdún náà. Bí àpẹẹrẹ, Jósẹ́fù àti Màríà máa ń rin ìrìn àjò tí ó tó ọgọ́rùn-ún kìlómítà láti Násárétì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Báwo lo ṣe rò pé ó máa pẹ́ tó kó o tó débẹ̀, bó bá jẹ́ pé ìwọ àtàwọn ọmọ kéékèèké lẹ jọ ń rìn? Ohun tí Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù nígbà tó wà lọ́mọdé jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìbátan àtàwọn ojúlùmọ̀ lè rin irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ pa pọ̀. Ó ti ní láti gbádùn mọ́ wọn láti rìnrìn-àjò, kí wọ́n jọ gbọ́únjẹ, kí wọ́n sì ṣètò ibi tó dára tí wọ́n lè sùn sí ní ibi tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀. Síbẹ̀, bí ipò nǹkan ṣe rí níbẹ̀ ṣì mú kó rọrùn fún wọn láti fún Jésù ní òmìnira dé ìwọ̀n àyè kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún méjìlá ni. Ẹ sì wo bí irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ ṣe máa jẹ́ mánigbàgbé tó, pàápàá jù lọ fún àwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀!—Lúùkù 2:44-46.

13 Nígbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní àwọn ìlú tó wà káàkiri ẹ̀yìn odi ìlú ìbílẹ̀ wọn, láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni ọ̀pọ̀ nínú wọn ti máa ń wá síbi àjọyọ̀ náà. Nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n mọrírì àjọyọ̀ yìí rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti àwọn ìlú bí Ítálì, Líbíà, Kírétè, Éṣíà Kékeré àti Mesopotámíà.—Ìṣe 2:5-11; 20:16.

14. Àǹfààní wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí nínú lílọ síbi àjọyọ̀ ọdọọdún náà?

14 Ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olùṣòtítọ́ kà sí pàtàkì jù lọ, tó sì máa ń gbádùn mọ́ wọn gan-an nínú ìrìn àjò yìí ni bó ṣe máa ń fún wọn láǹfààní láti sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn mìíràn tí wọ́n mọrírì àjọyọ̀ náà. Báwo lèyí ṣe máa ń rí lára àwọn tó wá síbi àjọyọ̀ náà? A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ìtọ́ni tí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ nípa Àjọyọ̀ Àtíbàbà. Ó sọ pé: “Kí o sì máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ọmọ Léfì àti àtìpó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ. Ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi ṣe àjọyọ̀ náà fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà yóò yàn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò bù kún ọ nínú gbogbo èso rẹ àti nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, kí ìwọ sì kún fún ìdùnnú.”—Diu. 16:14, 15; ka Mátíù 5:3.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MỌRÍRÌ ÀWỌN ÀPÉJỌ WA LÓDE ÒNÍ?

15, 16. Àwọn ìsapá wo lo máa ń ṣe kó o bàa lè lọ sí àwọn àpéjọ? Kí nìdí tí o kò fi kábàámọ̀ pé ó sapá láti lọ?

15 Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn àpéjọ ìgbàanì yìí jẹ́ fún àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ti yí pa dà láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, àwọn apá pàtàkì lára àwọn àpéjọ wa kò tíì yí pa dà. Ní àwọn àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn máa ń sapá gan-an kí wọ́n lè lọ sí àwọn àpéjọ. Ohun tí ọ̀pọ̀ nínú wa sì ń ṣe lónìí náà nìyẹn. Síbẹ̀, àǹfààní tó wà níbẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àkókò tó máa ń fúnni láǹfààní láti sin Jèhófà làwọn àkókò pàtàkì yìí jẹ́, ìyẹn ò sì tíì yí pa dà títí dòní. Ní àwọn àpéjọ náà, a máa ń gbọ́ àwọn ìsọfúnni tó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì tún máa ń lóye bí àwọn ìsọfúnni náà ti ṣe pàtàkì tó. Àwọn àpéjọ máa ń mú ká fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò, wọ́n ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè sá fún ìṣòro, wọ́n sì ń fún wa níṣìírí láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn àfojúsùn tó máa mú ara tù wá dípò ká máa lépa àwọn ohun tó máa dẹrù pa wá.—Sm. 122:1-4.

16 Àwọn tó máa ń lọ sí àwọn àpéjọ máa ń láyọ̀ gan-an ni. A gbọ́ ìròyìn nípa àpéjọ ńlá kan tó wáyé lọ́dún 1946. Ìròyìn náà sọ pé: “Ó múni lọ́kàn yọ̀ láti rí ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà pa pọ̀ ní ìrọwọ́rọsẹ̀, èyí tó tiẹ̀ wá múni láyọ̀ jù lọ ni ti ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi ohun èlò kọrin àti ọ̀pọ̀ àwọn ará tó ń fayọ̀ kọ orin Ìjọba Ọlọ́run láti fi yin Jèhófà.” Ìròyìn náà fi kún un pé: “A rí lára àwọn tó wá sí àpéjọ náà tí wọ́n fi orúkọ sílẹ̀ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni kí wọ́n bàa lè ṣiṣẹ́ ní gbogbo ẹ̀ka yòókù tó wà ní àpéjọ náà kìkì nítorí pé inú wọn dùn láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlẹ́rìí bíi tiwọn.” Ṣé ìwọ náà ti ní ayọ̀ tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí ní àwọn àpéjọ àgbègbè tàbí àpéjọ àgbáyé?—Sm. 110:3; Aísá. 42:10-12.

17. Lóde òní, àwọn nǹkan wo ló ti yí pa dà nínú bá a ṣe ń ṣètò àwọn àpéjọ?

17 Àwọn ohun kan ti yí pa dà nínú bá a ṣe ń ṣètò àwọn àpéjọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run lè rántí pé ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ọjọ́ mẹ́jọ la fi ń ṣe àpéjọ! Apá mẹ́ta ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ máa ń pín sí: òwúrọ̀, ọ̀sán àti ìrọ̀lẹ́. Lílọ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá sì máa ń wáyé déédéé ní àwọn àpéjọ wa. Nígbà míì, ìpàdé máa ń bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀, á sì máa bá a nìṣó títí di aago mẹ́sàn-án alẹ́. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ máa ń ṣiṣẹ́ kára láti pèsè oúnjẹ àárọ̀, ọ̀sán àti alẹ́ fún àwọn tó wá sí àpéjọ. Àmọ́, ní báyìí, ọjọ́ tá a fi ń ṣe àpéjọ kì í pọ̀ tó ìyẹn mọ́, níwọ̀n bí ìdílé kọ̀ọ̀kan sì ti máa ń ṣètò oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ sílẹ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, ìyẹn máa ń mú kí wọ́n lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ìpèsè tẹ̀mí tá à ń gbádùn níbẹ̀.

18, 19. Kí lo sábà máa ń fojú sọ́nà fún nígbà àpéjọ, kí sì nìdí?

18 Àwọn ohun kan wà tó ti máa ń ṣẹlẹ̀ tipẹ́ tá a sábà máa ń fojú sọ́nà fún nígbà àpéjọ. Lára wọn ni ‘oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,’ èyí tá à ń pèsè rẹ̀ fún wa nípasẹ̀ àwọn àsọyé àtàwọn ìtẹ̀jáde tuntun tó ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtàwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì. (Mát. 24:45) Irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ ohun èlò tó ń ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti mọrírì àwọn òtítọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni. Àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lárinrin máa ń fún tọmọdé tàgbà níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò ìdí tí wọ́n fi ń sin Jèhófà, ó sì máa ń mú kí wọ́n ṣọ́ra fún èrò ayé tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu àti ipa tó máa ń ní lórí ẹni. Bákan náà, àsọyé ìrìbọmi máa ń fún gbogbo wa ní àǹfààní láti ṣàtúnyẹ̀wò ohun tá a fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa, ká sì tún láyọ̀ bá a ṣe ń rí i táwọn míì ń fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà hàn.

19 Dájúdájú, ọjọ́ pẹ́ tí àwọn àpéjọ ti jẹ́ ara ìjọsìn mímọ́, wọ́n sì ń mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn Jèhófà láti sìn ín lọ́nà tó tọ́ ní àwọn àkókò líle koko yìí. Irú àwọn àpéjọ bẹ́ẹ̀ máa ń mú ká fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà, wọ́n máa ń fún wa láǹfààní láti bá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun pàdé, wọ́n máa ń jẹ́ ká mọrírì ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé, wọ́n sì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí Jèhófà ń gbà rọ̀jò ìbùkún sórí àwa èèyàn rẹ̀ àti ọ̀nà pàtàkì tó gbà ń bójú tó wa. Dájúdájú, olúkúlùkù wa máa fẹ́ láti ṣètò àwọn ìgbòkègbodò wa ká bàa lè máa lọ sí àwọn àpéjọ ká sì jàǹfààní nínú gbogbo apá ìpàdé náà.—Òwe 10:22.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àpéjọ àgbáyé ti ọdún 1950, tó wáyé ní ìlú New York City

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

MÒSÁŃBÍÌKÌ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

SOUTH KOREA