ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ October 2012

Ìwé yìí sọ báa ṣe lè kojú ìṣòro, àwọn èrò àti ìwà tó yẹ kí àwọn Kristẹni yẹra fún àti ohun táa lè ṣe ká lè jàǹfààní látinú àwọn ìlérí Ọlọ́run.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Brazil

Ka àwọn ìrírí tó ń gbéni ró nípa àwọn tí wọ́n kó lọ síbò míì kí wọ́n lè túbọ̀ sin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

Bá a Ṣe Lè Máa Fi Ìgboyà Kojú Ìpọ́njú Lóde Òní

Báwo la ṣe lè ní ìgboyà ká sì máa ronú nípa ohun rere láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa sí?

Irú Ẹ̀mí Wo Lò Ń fi Hàn?

Ṣé ó fẹ́ máa wa lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn? Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ rere àti búburú tó wà nínú Bíbélì.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Wọ́n Ti Ń Bára Wọn Ṣọ̀rẹ́ Bọ̀ Láti Ọgọ́ta Ọdún, Síbẹ̀ Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Bẹ̀rẹ̀ Ni

Ká ìtàn àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin tí wọ́n fi ayé wọn sin Jèhófà.

Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Kí o Sì Jàǹfààní Nínú Àwọn Ìlérí Tó Fi Ìbúra Ṣe

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, ìlérí tí Ọlọ́run fi ìbúra ṣe àti àwọn májẹ̀mú?

Jẹ́ Kí Bẹ́ẹ̀ Ni Rẹ Jẹ́ Bẹ́ẹ̀ Ni

Kí ni àwọn nǹkan tó wà lára jíjẹ́ olóòótọ́. Báwo la ṣe lè mú ìlérí tó ṣe pàtàkì jú lọ táa ṣe fún Ọlọ́run ṣẹ?

Ìṣírí “Láti Ẹnu Àwọn Ọmọdé”

Kà nípa ohun tí àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ṣe láti fún àwọn ọmọdé ní Rọ́ṣíà níṣìírí.