Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá a Ṣe Lè Máa Fi Ìgboyà Kojú Ìpọ́njú Lóde Òní

Bá a Ṣe Lè Máa Fi Ìgboyà Kojú Ìpọ́njú Lóde Òní

“Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.”—SM. 46:1.

1, 2. Àwọn ìpọ́njú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti dojú kọ, ṣùgbọ́n kí ló wu àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run?

 ÀKÓKÒ ìpọ́njú là ń gbé yìí. Oríṣiríṣi àjálù ló ń ṣẹlẹ̀ láyé. Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń fi ojú aráyé rí màbo ni, ìmìtìtì ilẹ̀, ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun, iná, àkúnya omi, ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín, ìjì líle. Àwọn nǹkan míì tó tún ń fa ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni ìṣòro ìdílé àtàwọn ìṣòro míì tó ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan fínra. Kò sí àní-àní pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa.—Oníw. 9:11.

2 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lápapọ̀ ti kojú irú àwọn ipò tó ń fa ìrora ọkàn yìí láìbọ́hùn. Síbẹ̀, a fẹ́ láti gbára dì ká lè kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí ṣe ń sún mọ́lé. Báwo la ṣe lè máa kojú àwọn ìṣòro yìí ká má sì jẹ́ kí wọ́n kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa? Kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi ìgboyà kojú ìpọ́njú lóde òní?

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN TÓ FI ÌGBOYÀ KOJÚ ÌṢÒRO ÌGBÉSÍ AYÉ

3.Róòmù 15:4 ṣe sọ, báwo la ṣe lè rí ìtùnú tá a bá wà nínú ìṣòro tí ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro tó lágbára túbọ̀ ń da àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láàmú lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni ti ń han aráyé léèmọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan láyé àtijọ́ tí wọ́n fìgboyà kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé.—Róòmù 15:4.

4. Àwọn ìṣòro wo ló pọ́n Dáfídì lójú, kí ló sì ràn án lọ́wọ́?

4 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Dáfídì. Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló pọn Dáfídì lójú. Ọba kan bínú sí i, àwọn ọ̀tá gbéjà kò ó, wọ́n jí ìyàwó rẹ̀ gbé, àwọn kan lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàwọn ìbátan rẹ̀ hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí i, ó sì tún ní ìdààmú ọkàn. (1 Sám. 18:8, 9; 30:1-5; 2 Sám. 17:1-3; 24:15, 17; Sm. 38:4-8) Ìtàn ìgbésí ayé Dáfídì tó wà nínú Bíbélì sọ ìrora ọkàn táwọn ìṣòro yìí mú kó ní lọ́nà to ṣe kedere. Ṣùgbọ́n, wọn kò ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run pọ̀ débi tó fi sọ pé: “Jèhófà ni odi agbára ìgbésí ayé mi. Ta ni èmi yóò ní ìbẹ̀rùbojo fún?”—Sm. 27:1; ka Sáàmù 27:5, 10.

5. Kí ló ran Ábúráhámù àti Sárà lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tó lágbára?

5 Inú àgọ́ ni Ábúráhámù àti Sárà ti lo èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bí àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì. Nǹkan kò fìgbà gbogbo rọgbọ fún wọn. Síbẹ̀, wọ́n fìgboyà kojú àwọn ìṣòro bí ìyàn àti ewu látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. (Jẹ́n. 12:10; 14:14-16) Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé Ábúráhámù “ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Héb. 11:8-10) Ábúráhámù àti Sárà pa ọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wọn, wọn kò jẹ́ kí àwọn ìṣòro tó wà nínú ayé kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn.

6. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóòbù?

6 Jóòbù kojú ìṣòro tó lé kenkà. Ronú nípa bó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó dà bíi pé ìgbésí ayé rẹ̀ ti dorí kodò. (Jóòbù 3:3, 11) Ohun tó tiẹ̀ wá burú jù níbẹ̀ ni pé kò ní òye kíkún nípa ìdí tí gbogbo nǹkan náà fi ṣẹlẹ̀ sí i. Síbẹ̀, kò ṣíwọ́ láti máa sin Ọlọ́run. Ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. (Ka Jóòbù 27:5.) Àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ ká tẹ̀ lé mà lèyí o!

7. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kí ló fún un ní ìgboyà láti máa bá a nìṣó?

7 Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó dojú kọ ‘ewu nínú ìlú ńlá, nínú aginjù àti lójú òkun.’ Ó sọ̀rọ̀ nípa ‘ebi àti òùngbẹ, òtútù àti ìhòòhò.’ Pọ́ọ̀lù tún sọ pé òun lo ‘òru kan àti ọ̀sán nínú ibú, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbà tí ọkọ̀ tó wọ̀ rì. (2 Kọ́r. 11:23-27) Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, kíyè sí ohun tó sọ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run: “Èyí jẹ́ kí a má bàa ní ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú ara wa, bí kò ṣe nínú Ọlọ́run ẹni tí ń gbé òkú dìde. Láti inú irúfẹ́ ohun ńlá kan bẹ́ẹ̀ bí ikú ni òun ti gbà wá sílẹ̀, tí yóò sì gbà wá sílẹ̀.” (2 Kọ́r. 1:8-10) Ṣàṣà èèyàn nirú àwọn nǹkan burúkú tó pọ̀ tó èyí tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù yìí tíì ṣẹlẹ̀ sí rí. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí ohun tó fara jọ èyí ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ lára wa, a sì lè rí ìtùnú látinú bó ṣe fi ìgboyà kojú àwọn ìṣòro náà.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ BURÚKÚ MÚ KÓ O RẸ̀WẸ̀SÌ

8. Ipa wo làwọn ìṣòro òde òní lè ní lórí wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.

8 Nínú ayé tó kún fún àwọn àjálù, ìpèníjà àti pákáǹleke tá à ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni nǹkan ti tojú sú. Kódà, a rí àwọn Kristẹni kan ti nǹkan ti tojú sú. Arábìnrin Lani * tí òun àti ọkọ́ rẹ̀ jọ ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé nígbà tí àyẹ̀wò fi hàn pé òun ní jẹjẹrẹ ọmú, ńṣe ni àyà òun là gààrà, ó sì kó ìbànújẹ́ ńláǹlà bá òun. Ó sọ pé, “Ìtọ́jú tí mò ń gbà máa ń mú kí n ṣàárẹ̀ gan-an, mo wá rí ara mi bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.” Ohun tó tún wá mú kí ọ̀rọ̀ náà burú ni pé, ó tún ní láti máa tọ́jú ọkọ rẹ̀ tí òun náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe iṣẹ́ abẹ eegun ògóóró ẹ̀yìn. Tá a bá bára wa nírú ipò yẹn, kí la lè ṣe?

9, 10. (a) Kí la ò gbọ́dọ̀ gba Sátánì láyè láti ṣe? (b) Kí ni Ìṣe 14:22 sọ nípa ìpọ́njú, kí ló sì yẹ ká ṣe?

9 Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ńṣe ni Sátánì fẹ́ fi àwọn ìpọ́njú tó ń dé bá wa ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. Ṣùgbọ́n, a kò gbọ́dọ̀ gbà á láyè láti ba ayọ̀ wa jẹ́. Ìwé Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó máa jẹ́ ká lè fìgboyà kojú àwọn ìpọ́njú.

10 Ó tún dáa ká fi sọ́kàn pé a kò lè mú gbogbo ìṣòro kúrò. Kódà, ohun tá a lè máa retí ni. (2 Tím. 3:12) Ìwé Ìṣe 14:22 sọ fún wa pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.” Dípò tí wàá fi rẹ̀wẹ̀sì bí ìṣòro bá dé, o ò ṣe kúkú wò ó gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti fi hàn pé o jẹ́ onígboyà, kó o sì fi hàn pé o gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

11. Kí la lè ṣe tí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé kò fi ní mú wa rẹ̀wẹ̀sì?

11 Àwọn nǹkan rere ló yẹ ká máa ronú lé lórí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú máa ń ní ipa rere lórí ìrísí, ṣùgbọ́n nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.” (Òwe 15:13) Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn olùṣèwádìí nípa ọ̀ràn ìlera ti sọ pé tó bá jẹ́ pé ohun tó dára ni èèyàn ń rò, ó máa ń jẹ́ kí èèyàn ní ìlera tó dára. Ọ̀pọ̀ aláìsàn ni wọ́n ti fún ní àwọn èròjà kan lásán àmọ́ tí wọ́n sọ pé ara àwọn ti yá nítorí wọ́n rò pé oògùn tó lè wo àwọn sàn ni. Wọ́n sì tún ṣe ìwádìí kan tó jẹ́ òdì kejì èyí. Torí pé wọ́n sọ fún àwọn aláìsàn pé oògùn tí wọ́n fún wọn kò ní ṣiṣẹ́, ńṣe ni ìlera wọn burú sí i. Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tó kọjá agbára wa ní àròjù, ńṣe ni wọ́n á máa mú wa rẹ̀wẹ̀sì. Ṣùgbọ́n Jèhófà kì í fun wa ní ohun tó dà bí èròjà kan lásán nígbà ìṣòro. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó máa ń fún wa ní ojúlówó ìrànlọ́wọ́, nípasẹ̀ ìṣírí tá à ń rí gbà látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ara wa àti okun tá à ń rí gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan yìí, ó máa fún wa láyọ̀. Dípò ti wàá fi máa ronú nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú, ṣe ohun tó o bá rí i pé ó yẹ nípa ìṣòro kọ̀ọ̀kan, àwọn ohun tó bá dára nínú ìgbésí ayé rẹ ni kó o sì máa ronú lé lórí.—Òwe 17:22.

12, 13. (a) Kí ló ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti fara da ipò tí kò bára dé lẹ́yìn tí àjálù ṣẹlẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan. (b) Báwo ni àjálù ṣe máa ń fi ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ẹni hàn?

12 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn àjálù tó lágbára gan-an ṣẹlẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan. Ó gbàfiyèsí pé ọ̀pọ̀ àwọn ará tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè yìí lo ìfaradà lọ́nà tó ta yọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2010, ìmìtìtì ilẹ̀ àti ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun tó bùáyà ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Chile, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni wọ́n pàdánù ilé àtàwọn ohun ìní wọn, kódà ọ̀nà táwọn kan ń gba gbọ́ bùkátà ara wọn ti dí. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ipò tẹ̀mí àwọn ará kò yingin. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Samuel, tí ilé rẹ̀ bà jẹ́ pátápátá sọ pé: “Kódà láwọn ìgbà tí nǹkan le koko yẹn, èmi àti ìyàwó mi kò dẹ́kun wíwàásù àti lílọ sí ìpàdé. Àwọn nǹkan yìí ni kò jẹ́ ká sọ̀rètí nù.” Àwọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ará mìíràn kò jẹ́ kí àjálù kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó.

13 Ní oṣù September, ọdún 2009, àkúnya omi tó ṣẹlẹ̀ nílùú Manila, lórílẹ̀-èdè Philippines fẹ́rẹ̀ẹ́ bo gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Ọkùnrin olówó kan tó pàdánù nǹkan púpọ̀ sọ pé, “Ńṣe ni àkúnya omi yẹn pín ìṣòro kárí gbogbo wa, àtolówó àti òtòṣì ni wàhálà dé bá.” Èyí rán wa létí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jésù sọ. Ó ní: “Ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.” (Mát. 6:20) Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tara tó lè pa run lójijì lèèyàn kà sí pàtàkì jù, ìjákulẹ̀ ló sábà máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀. Ẹ ò rí bó ṣe bọ́gbọ́n mú tó pé ká jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa, torí pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀!—Ka Hébérù 13:5, 6.

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA LO ÌGBOYÀ

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo ìgboyà?

14 Jésù sọ pé ìṣòro máa wà nígbà wíwàníhìn-ín òun, àmọ́, ó ní: “Ẹ má ṣe jáyà.” (Lúùkù 21:9) Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jésù Ọba wa àti Jèhófà Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run, ọ̀kan wa balẹ̀ digbí. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.”—2 Tím. 1:7.

15. Kí ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan sọ nípa bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jèhófà ṣe lágbára tó, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?

15 Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan sọ tó fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Dáfídì sọ pé: “Jèhófà ni okun mi àti apata mi. Òun ni ọkàn-àyà mi gbẹ́kẹ̀ lé, a sì ti ràn mí lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà mi ń yọ ayọ̀ ńláǹlà.” (Sm. 28:7) Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ kan tó fi hàn pé ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó lágbára nínú Jèhófà, ó ní: “Nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ń di ajagunmólú pátápátá nípasẹ̀ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa.” (Róòmù 8:37) Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ pé Jésù mọ̀ pé wọ́n máa tó mú òun tí wọ́n á sì pa òun, ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé ó ní àjọṣe tó lágbára pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sọ pé: “Èmi kò wà ní èmi nìkan, nítorí pé Baba wà pẹ̀lú mi.” (Jòh. 16:32) Kí ló ṣe kedere nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí? Ọ̀rọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ fi hàn kedere pé wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó lágbára nínú Jèhófà. Tí àwa náà bá ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé tó lágbára bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà, a máa lè fi ìgboyà kojú ìpọ́njú èyíkéyìí lóde òní.—Ka Sáàmù 46:1-3.

JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÀWỌN OHUN TÓ MÁA MÚ KÁ MÁA BÁ A NÌṢÓ LÁTI NÍ ÌGBOYÀ

16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

16 Ti pé àwa Kristẹni ń lo ìgboyà kò túmọ̀ sí pé ńṣe la dá ara wa lójú. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé a mọ Ọlọ́run tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé e la ṣe ní ìgboyà. A lè mọ Jèhófà ká sì ní ìgboyà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Arábìnrin kan tó ní ìsoríkọ́ sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́, ó ní, “Mo sábà máa ń ka àwọn apá ibi tó ń tuni nínú gan-an ní àkàtúnkà.” Ǹjẹ́ à ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó sọ pé ká máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé? Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, a máa dà bí onísáàmù tó sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sm. 119:97.

17. (a) Kí ni ohun tó máa mú ká máa bá a nìṣó láti ní ìgboyà? (b) Sọ bí ìtàn ìgbésí ayé ẹnì kan nínú ìtẹ̀jáde wa ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́.

17 A tún ní àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, tí àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ ń mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà lágbára sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti jàǹfààní púpọ̀ nínú àwọn ìtàn ìgbésí ayé tó máa ń wà nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. Arábìnrin kan wà ní ilẹ̀ Éṣíà tó ní ìṣòro híhùwà lódìlódì. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó ka ìtàn ìgbésí ayé arákùnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀ rí tóun náà ní irú ìṣòro yìí àmọ́ tó ń rí ọgbọ́n dá sí i. Arábìnrin náà kọ̀wé pé, “Ó ti jẹ́ kí n lóye ìṣòro mi, ó sì fún mi ní ìrètí.”

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà?

18 Àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ ní ipòkípò tá a bá bára wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bó ti ṣe pàtàkì tó, ó ní: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 4:6, 7) Ǹjẹ́ a máa ń lo àǹfààní yìí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ láti gba okun nígbà tí àníyàn bá dorí wa kodò? Arákùnrin kan wà lórílẹ̀-èdè Britain tó ń jẹ́ Alex, ọjọ́ pẹ́ tó ti ní ìsoríkọ́, ó sọ pé: “Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, mo sì máa ń tẹ́tí sí i nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀.”

19. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni?

19 Lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì mìíràn tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Onísáàmù kan sọ pé: “Ọkàn mi ti ṣàfẹ́rí, ó sì ti joro lẹ́nu wíwọ̀nà fún àwọn àgbàlá Jèhófà.” (Sm. 84:2) Ṣé bó ṣe máa ń ṣe àwa náà nìyẹn? Arábìnrin Lani, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ ojú tó fi ń wo lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, ó ní: “Ó pọn dandan pé ká máa lọ sáwọn ìpàdé. Mo mọ̀ pé ó di dandan kí n máa lọ síbẹ̀ tí n bá fẹ́ kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè kojú àwọn ìṣòro mi.”

20. Báwo ni kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

20 Kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tún máa ń mú ká ní ìgboyà. (1 Tím. 4:16) Arábìnrin kan ní ilẹ̀ Ọsirélíà tí oríṣiríṣi ìṣòro ti pọ́n lójú sọ pé: “Kì í wù mí láti lọ sóde ẹ̀rí, ṣùgbọ́n alàgbà kan ní ká jọ lọ, mo sì tẹ̀ lé e. Mo rí ọwọ́ Jèhófà nínú èyí, torí pé gbogbo ìgbà tí mo bá ti lọ sóde ẹ̀rí ni inú mi máa ń dùn gan-an.” (Òwe 16:20) Ọ̀pọ̀ Kristẹni ti rí i pé bí àwọn ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, ńṣe ni ìgbàgbọ́ tiwọn náà ń lágbára sí i. Èyí ń mú kí wọ́n gbé àwọn ìṣòro tiwọn kúrò lọ́kàn, kí wọ́n sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù.—Fílí. 1:10, 11.

21. Kí ló dá wa lójú nípa àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra?

21 Jèhófà ti fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa jẹ́ ká lè máa fi ìgboyà kojú ìpọ́njú lóde òní. Tá a bá ń lo gbogbo àwọn ìpèsè yìí, tá à ń ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ àtàtà tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó lo ìgboyà fi lélẹ̀ tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, ọkàn wa máa balẹ̀ pé a lè kojú àwọn ìṣòro láìbọ́hùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí kò bára dé ṣì lè ṣẹlẹ̀ bí òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí ṣe ń sún mọ́lé, àwa náà lè sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù pé: “A gbé wa ṣánlẹ̀, ṣùgbọ́n a kò pa wá run. . . . Àwa kò juwọ́ sílẹ̀.” (2 Kọ́r. 4:9, 16) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè máa fi ìgboyà kojú ìpọ́njú lóde òní.—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:17, 18.

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

Tó o bá wà nínú ìpọ́njú, jàǹfààní látinú àwọn ohun tí Jèhófà ti pèsè láti ràn wá lọ́wọ́