Ìtàn Ìgbésí Ayé
Wọ́n Ti Ń Bára Wọn Ṣọ̀rẹ́ Bọ̀ Láti Ọgọ́ta Ọdún, Síbẹ̀ Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Bẹ̀rẹ̀ Ni
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1951, àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin tí wọ́n fi díẹ̀ lé ní ogún ọdún dúró sí ìtòsí ara wọn nídìí àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ní ìlú Ithaca ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń fi fóònù pe àwọn kan tó ń gbé ibi tó jìn ní ìpínlẹ̀ Michigan, Iowa àti California. Wọ́n ní ìròyìn ayọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ fún wọn!
ṢÁÁJÚ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, ní oṣù February, àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjìlélọ́gọ́fà [122] pàdé pọ̀ ní South Lansing, ní ìpínlẹ̀ New York, fún kíláàsì kẹtàdínlógún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lára àwọn míṣọ́nnárì lọ́la yìí ni Lowell Turner, William (Bill) Kasten, Richard Kelsey àti Ramon Templeton. Kò sì pẹ́ tí Lowell àti Bill láti ìlú Michigan, Richard láti ìlú Iowa àti Ramon láti ìlú California fi di kòríkòsùn.
Ní nǹkan bí oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, inú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà dùn gan-an nígbà tí wọ́n sọ fún wọn pé Arákùnrin Nathan Knorr láti oríléeṣẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn arákùnrin mẹ́rin náà ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé tó bá ṣeé ṣe, àwọn á fẹ́ láti sìn pa pọ̀ ní orílẹ̀-èdè kan náà. Ṣé àkókò ti tó wàyí tí wọ́n máa mọ ibi tí wọ́n á ti lọ sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ òkèèrè? Bẹ́ẹ̀ ni!
Arákùnrin Knorr bá gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀, àmọ́ ara gbogbo wọn túbọ̀ wà lọ́nà bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ibi tí wọ́n ti máa lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin tí ọkàn wọn ti kó sókè yẹn ló kọ́kọ́ pè sórí pèpéle, nígbà tí wọ́n wá gbọ́ pé àwọn jọ máa sìn ní orílẹ̀-èdè kan naa, ọkàn wọn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀! Àmọ́ ibo ni wọ́n ti máa lọ sìn? Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé orílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n ń rán wọn lọ, wọ́n sì pàtẹ́wọ́ fún àkókò gígùn.
Láti ọdún 1933 tí Hitler ti ń ṣàkóso ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ìyàlẹ́nu gbáà ló máa ń jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo bí wọ́n ti ń gbọ́ nípa ìṣòtítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà rántí pé lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì àwọn máa ń di ẹrù aṣọ àti ẹrù mìíràn tó wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ aláàánú kan tí wọ́n ń pè ní CARE sínú ọkọ̀ òkun tó máa gbé àwọn ẹrù náà lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọn tó wà ní ilẹ̀ Yúróòpù. Àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní orílẹ̀-èdè Jámánì jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, wọ́n pinnu láti máa sìn ín, wọ́n sì ní ìgboyà àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Arákùnrin Lowell rántí pé òun ronú lọ́jọ́ yẹn pé, àwọn máa túbọ̀ mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n náà dáadáa. Abájọ tí inú gbogbo wọn fi ń dùn, tí wọ́n sì ń fi fóònù pe àwọn èèyàn wọn nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn!
WỌ́N LỌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ JÁMÁNÌ
Ní July 27, ọdún 1951 ọkọ̀ ojú omi kan tí wọ́n ń pè ní SS Homeland gbéra láti èbúté rẹ̀ ní East River
ní ìpínlẹ̀ New York. Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin náà sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ mọ́kànlá sí orílẹ̀-èdè Jámánì. Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, Arákùnrin Albert Schroeder, tó wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ti kọ́ wọn ní àwọn gbólóhùn mélòó kan tó yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ mọ̀ lédè Jámánì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Jámánì mélòó kan wà nínú ọkọ ojú omi tí wọ́n wọ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n kọ́ gbólóhùn díẹ̀ sí i. Àmọ́, irú èdè Jámánì táwọn yẹn ń sọ yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n kọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ náà wá tojú sú wọn!Lẹ́yìn tí àwọn arákùnrin náà ti ṣòjòjò fún ìgbà díẹ̀, tí òòyì kọ́ wọn, tí èébì sì gbé wọn, wọ́n gúnlẹ̀ sí ìlú Hamburg, lórílẹ̀-èdè Jámánì ní òwúrọ̀ ọjọ́ Tuesday, August 7. Kò tíì ju ọdún mẹ́fà lọ tí ogun ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní orílẹ̀-èdè Jámánì, gbogbo ibi ni wọ́n sì ti ń rí ọṣẹ́ tí ogun ṣe. Ohun tí wọ́n rí bà wọ́n nínú jẹ́, torí náà wọ́n wọ ọkọ̀ ojú irin, wọ́n sì rin ìrìn àjò alẹ́ lọ sí ìlú Wiesbaden, níbi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wà nígbà yẹn.
Ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Wednesday, wọ́n pàdé Hans. Òun ni Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì tí wọ́n kọ́kọ́ bá pàdé, orúkọ rẹ̀ sì fi hàn pé ọmọ ilẹ̀ Jámánì pọ́ńbélé ni! Hans gbé wọn láti ibùdó ọkọ̀ ojú irin lọ sí Bẹ́tẹ́lì, nígbà tí wọ́n débẹ̀ ó fà wọ́n lé arábìnrin àgbàlagbà kan tó máa ń dúró lórí ìpinnu rẹ̀ àmọ́ tí kò gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́. Obìnrin yìí rò pé béèyàn bá ṣe lè sọ̀rọ̀ sókè tó ni ẹlòmíì á fi gbọ́ èdè tó ń sọ. Àmọ́, bí ohùn rẹ̀ ṣe ń ròkè tó, bẹ́ẹ̀ ni agara túbọ̀ ń dá òun àtàwọn arákùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Arákùnrin Erich Frost tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka dé, ó sì fi ọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìgbà yẹn lara wọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í wálẹ̀.
Ní apá ìparí oṣù August, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ sí àpéjọ àgbègbè wọn àkọ́kọ́ lédè Jámánì, ìyẹn Àpéjọ “Ìsìn Mímọ́” ní ìlú Frankfurt am Main. Ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́ta àti òjì-lé-nírínwó dín mẹ́jọ [47,432] èèyàn tó lọ sí àpéjọ yẹn ni iye èèyàn tó tíì pọ̀ ju lọ rí tó lọ sí àpéjọ lórílẹ̀-èdè náà. Ti pé àwọn tó ṣèrìbọmi jẹ́ egbèjìlá dín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [2,373] tún wá sọ ìtara àti ìfẹ́ táwọn míṣọ́nnárì náà ní fún iṣẹ́ ìwàásù dọ̀tun. Àmọ́, ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Arákùnrin Knorr sọ fún wọn pé Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n á máa gbé àti pé wọ́n á yan iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe níbẹ̀ fún wọn.
Bí wọ́n ṣe ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe mú kó túbọ̀ dá wọn lójú pé kò sígbà kan tí Jèhófà kì í mọ ohun tó dára jù lọ fún wọn
Nígbà kan tí Ramon ní àǹfààní láti lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kò lọ torí pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì
ló wù ú. Richard àti Bill pàápàá kò fìgbà kan rò ó rí pé àwọn á sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, bí wọ́n ṣe ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe wá mú kó túbọ̀ dá wọn lójú pé kò sígbà kan tí Jèhófà kì í mọ ohun tó dára jù lọ fún wọn. Ẹ sì wo bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé ká máa gba ibi tí Jèhófà bá darí wa sí dípò tí a ó fi máa ṣe ohun tá a fẹ́. Ẹni tó bá gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí, á múra tán láti sin Jèhófà níbikíbi, á sì ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ yòówù tí wọ́n bá ní kó ṣe.ÈÈWỌ̀!
Inú ọ̀pọ̀ lára àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Jámánì dùn láti rí i pé àwọn ará Amẹ́ríkà tí wọ́n lè jọ máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ti wà láàárín wọn. Àmọ́, láàárọ̀ ọjọ́ kan nínú yàrá ìjẹun, wọ́n rí i pé ọ̀nà ò gba ibi táwọn fojú sí. Arákùnrin Frost bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara sọ̀rọ̀ kíkankíkan bó ṣe sábà máa ń ṣe, àmọ́ ó jọ pé ọ̀rọ̀ tó ń fi èdè Jámánì sọ náà le díẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́, wọ́n sì tẹjú mọ́ abọ́ oúnjẹ wọn. Ohun tó ń sọ kò yé àwọn arákùnrin mẹ́rin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yẹn, àmọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ọ̀rọ̀ tó ń sọ yẹn kan àwọn. Nígbà tó yá, Arákùnrin Frost lọgun pé, “VERBOTEN!” (“Èèwọ̀!”) bẹ́ẹ̀ ló ń pariwo tó sì ń tẹnu mọ́ ọn, ara àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kò sì balẹ̀ mọ́. Kí ni wọ́n ì báà ṣe, tó lè fa irú ọ̀rọ̀ líle bẹ́ẹ̀?
Lẹ́yìn oúnjẹ, kíá ni gbogbo wọn gba yàrá wọn lọ. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, arákùnrin kan wá ṣàlàyé fún àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pé: “Kẹ́ ẹ tó lè ràn wá lọ́wọ́, ẹ gbọ́dọ̀ mọ èdè Jámánì sọ. Ìdí nìyẹn tí Arákùnrin Frost fi sọ pé ÈÈWỌ̀ ni fún ẹnikẹ́ni láti báa yín sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì títí tẹ́ ẹ máa fi mọ èdè Jámánì sọ.”
Lójú ẹsẹ̀ ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó sọ. Èyí mú kí àwọn arákùnrin mẹ́rin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé náà tètè mọ èdè Jámánì sọ, wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ pé tí arákùnrin onífẹ̀ẹ́ kan bá fún wa nímọ̀ràn ó lè kọ́kọ́ ṣòro láti fi sílò, àmọ́ ire wa làwọn ìmọ̀ràn náà wà fún. Ìmọ̀ràn tí Arákùnrin Frost fún wọn fi hàn pé bí nǹkan á ṣe máa lọ déédéé nínú ètò Jèhófà ló jẹ ẹ́ lógún, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin rẹ̀. * Ìdí nìyẹn táwọn arákùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀!
A KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN Ọ̀RẸ́ WA
A lè rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ lára àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, èyí á sì jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Àwọn arákùnrin mẹ́rin náà kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lára àwọn ará Jámánì lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, tá ò lè máa dárúkọ wọn níkọ̀ọ̀kan, wọ́n sì tún rí ẹ̀kọ́ kọ́ lọ́dọ̀ ara wọn. Richard sọ pé: “Lowell ti gbọ́ èdè Jámánì díẹ̀ tẹ́lẹ̀, torí náà kò nira fún un, àmọ́ ńṣe làwa yòókù ń tiraka. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun náà ló dàgbà jù láàárín wa, òun la máa ń lọ bá bí ohun kan bá rú wa lójú nínú èdè náà, ó sì tún máa ń múpò
iwájú.” Ramon rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Lẹ́yìn tá a ti lo ọdún kan lórílẹ̀-èdè Jámánì, inú mi dùn gan-an nígbà tí arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Switzerland sọ pé a lè lọ lo ìsinmi wa àkọ́kọ́ ní ilé òun kékeré tí wọ́n fi igi kọ́ ní orílẹ̀-èdè Switzerland! Mo ronú pé a tiẹ̀ máa bọ́ lọ́wọ́ èdè Jámánì yìí fún ọ̀sẹ̀ méjì! Ṣùgbọ́n mi ò ro ti Lowell mọ́ tèmi. Ńṣe ló takú pé èdè Jámánì ni ká máa lò fún kíkà àti jíjíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ láràárọ̀! Àmọ́, ó dùn mí gan-an pé kò yí ìpinnu rẹ̀ pa dà. Síbẹ̀, a rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́ látinú ohun tó ṣe yẹn. Ẹ̀kọ́ náà sì ni pé bí àwọn tó ní ire wa lọ́kàn bá ń tọ́ wa sọ́nà, ó dáa ká tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà náà kódà nígbà tí kò bá tẹ́ wa lọ́rùn. Ríronú lọ́nà yìí ti ràn wá lọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún ó sì ti mú kó rọrùn fún wa láti máa gba ibi tí ètò Ọlọ́run bá darí wa sí.”Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin yìí tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ káwọn máa mọyì àwọn ànímọ́ tó dáa tí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ni. Ìyẹn sì wà ní ìbámu pẹ̀lú Fílípì 2:3, tó sọ pé: “Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” Torí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn mẹ́ta tó kù máa ń buyì kún Bill nípa jíjẹ́ kó bójú tó àwọn nǹkan tí wọ́n mọ̀ pé ó mọ̀ ọ́n ṣe jù wọ́n lọ. Lowell rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Bí ọ̀ràn tó le bá yọjú tó sì ń béèrè ojútùú tó nira, Bill la máa ń ké sí. Bí gbogbo wa bá gbà pé ọ̀nà kan wà tó yẹ ká gbà bójú tó ìṣòro èyíkéyìí, ṣùgbọ́n tí a kò ní ìgboyà láti bójú tó o tàbí tí agbára wa kò gbé e, ó máa ń mọ ohun tó yẹ ká ṣe.”
ÌGBÉYÀWÓ ALÁYỌ̀
Nígbà tó yá, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pinnu lọ́kọ̀ọ̀kan pé àwọn máa fẹ́yàwó. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti bí wọ́n ṣe fẹ́ láti máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ló mú kí wọ́n máa bára wọn ṣọ̀rẹ́, ìyẹn náà ló sì mú kí wọ́n pinnu pé ẹni tó bá fi Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ làwọn máa fẹ́. Ohun tí wọ́n ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti mú kí wọ́n rí i pé fífúnni lérè nínú ju rírígbà lọ àti pé ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọba Ọlọ́run ló tọ́ káwọn fi ṣáájú ohun táwọn bá fẹ́. Èyí ló mú kí wọ́n yan àwọn arábìnrin tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìdílé tó wà ní ìṣọ̀kan tó sì jẹ́ aláyọ̀.
Kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tàbí ìgbéyàwó kan tó lè wà pẹ́ títí, àwọn tọ́ràn kàn gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. (Oníw. 4:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó Bill àti Ramon kú nígbà tó yá, síbẹ̀ àwọn méjèèjì láyọ̀, wọ́n sì rí ìtìlẹ́yìn téèyàn máa ń gbádùn bó bá ní aya tó jẹ́ olóòótọ́. Lowell àti Richard ṣì ń gbádùn irú ìtìlẹ́yìn yẹn, Bill fẹ́yàwó míì, ó sì ṣe yíyàn tó tọ́ kó bàa lè máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìṣó.
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, iṣẹ́ ìsìn wọn mú kí wọ́n lọ sí onírúurú ibi, pàápàá jù lọ ní Jámánì, Austria, Luxembourg, Kánádà àti Amẹ́ríkà. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ṣeé ṣe fún àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà láti wà pa pọ̀ tó bí wọn ì bá ṣe fẹ́. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà wọn jìn síra, wọ́n máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ déédéé, wọ́n máa ń bára wọn yọ̀, wọ́n sì máa ń bára wọn kẹ́dùn. (Róòmù 12:15) Ńṣe ló yẹ ká máa mọyì irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀, kò yẹ ká fojú kéré wọn. Ẹ̀bùn iyebíye ni wọ́n jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Òwe 17:17) Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣọ̀wọ́n gan-an nínú ayé tá à ń gbé yìí! Àmọ́, gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ la ní ọ̀rẹ́ tòótọ́ lọ́pọ̀ yanturu. Torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, à ń gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa kárí ayé, pabanbarì rẹ̀ wá ni pé a tún jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi.
Bí ìṣòro ṣe máa ń bá gbogbo wa fínra làwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí náà ṣe ní ìṣòro tí wọ́n dojú kọ, irú bí ẹ̀dùn ọkàn nígbà tí aya ẹni bá kú, ìnira tí àìsàn líle koko máa ń fà, wàhálà bíbójú tó àwọn òbí àgbà, àwọn ìṣòro tó rọ̀ mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kéèyàn sì tún máa tọ́ ọmọ, ẹ̀rù tó máa ń bani téèyàn bá gba iṣẹ́ àyànfúnni tuntun nínú ètò Ọlọ́run àti ìṣòro ọjọ́ ogbó tí wọ́n ṣì ń kojú báyìí. Àmọ́, àwọn arákùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí tún ti mọ̀ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn kí wọ́n lè fara da ìṣòro yòówù tí wọ́n bá dojú kọ, yálà àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ wà nítòsí tàbí níbi tó jìn.
Ọ̀RẸ́ TÍTÍ AYÉ
Ó wúni lórí pé nígbà tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Lowell jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún, Ramon jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, Bill jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá, Richard sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nígbà tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàdínlógún sí mọ́kànlélógún. Ohun tí Oníwàásù 12:1 sọ ni wọ́n ṣe. Ó ní: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”
Tó o bá jẹ́ Kristẹni ọ̀dọ́kùnrin tí kò sì sí ohun tó ń dí ẹ lọ́wọ́, jẹ́ ìpè Jèhófà pé kó o bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Bíi ti àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin yìí, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà lè mú kí ìwọ náà rí ayọ̀ tó wà nínú sísìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, alábòójútó àgbègbè tàbí alábòójútó láti ilẹ̀ òkèrè; o lè rí ayọ̀ tó wà nínú sísìn ní Bẹ́tẹ́lì títí kan sísìn gẹ́gẹ́ bí ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tàbí olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Àtàwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tàbí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà àti sísọ àsọyé ní àwọn àpéjọ ńlá àti kékeré. Ẹ wo bí inú àwọn mẹ́rin yìí á ṣe dùn tó láti mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti jàǹfààní látinú ohun tí wọ́n ti ṣe! Àṣeyọrí yìí wáyé kìkì nítorí pé láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n ti jẹ́ ìpè Jèhófà pé kí wọ́n fi tọkàntọkàn sin Òun.—Kól. 3:23.
Arákùnrin Lowell, Richard àti Ramon ti ń padà sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Jámánì tó wà ní Selters báyìí. Ó bani nínú jẹ́ pé, Bill kú ní ọdún 2010 nígbà tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún táwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti ń ṣọ̀rẹ́ bọ̀, ọ̀kan nínú wọn kú! Àmọ́ Ọlọ́run wa, Jèhófà, kì í gbàgbé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó dájú pé àwọn Kristẹni tí ikú bá fòpin sí àjọṣe wọn fúngbà díẹ̀ á ṣì máa bá àjọṣe wọn nìṣó lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run.
“Ní gbogbo ọgọ́ta ọdún tá a ti ń bára wa ṣọ̀rẹ́ bọ̀, mi ò kábàámọ̀ rí pé a jọ ń ṣọ̀rẹ́”
Kété ṣáájú kí Bill tó kú, ó kọ̀wé pé: “Ní gbogbo ọgọ́ta [60] ọdún tá a ti ń bára wa ṣọ̀rẹ́ bọ̀, mi ò kábàámọ̀ rí pé a jọ ń ṣọ̀rẹ́. Gbogbo ìgbà ni àjọṣe wa máa ń ṣe pàtàkì gan-an sí mi.” Torí pé ó dá àwọn mẹ́ta tó kù lójú pé àwọn á máa bá àjọṣe àwọn nìṣó nínú ayé tuntun, wọ́n yára kín ọ̀rọ̀ Bill lẹ́yìn pé: “A ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.”
^ Ìtàn tó lárinrin nípa ìgbésí ayé Arákùnrin Frost wà nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ April 15, 1961, ojú ìwé 244 sí 249 [Gẹ̀ẹ́sì].