ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ November 2012

Ìwé yìí sọ ìdí tí orúkọ Jèhófà, òfin rẹ̀ àti ohunt tó ní lọkàn fi ṣe pàtàkì. Ó tún sọ ìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ fi ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì máa dárí jini.

“Kọ́ Mi Láti Máa Ṣe Ìfẹ́ Rẹ”

Báwo la ṣe lè máa fi ojú tí Jèhófà fí ń wo nǹkan wò ó bíi ti Dáfídì?

Àṣẹ́kùsílẹ̀ Wọn Dí Àìnító Kan

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ya ọrẹ sọ́tọ̀ fún àwọn aláìní. Báwo ni àwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Jésù Kọ́ Wa Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Jèsú Kristi nípa bó ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

Máa Hùwà Bí Ẹni Tó Kéré Jù

Báwo la ṣe lè máa hùwà bí ẹni tó kéré jù tá a bá ń bá àwọn èèyàn lò?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àwọn tó yàn láti má ṣe lọ́kọ tàbí láya túmọ̀ sí?

Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Jèhófà Dárí Jì ẹ́?

Bí Jèhófà spe bá àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ sí i nígbà àtijọ́ lò lè kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa bó ṣe ṣe tán láti dárí jini.

Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà

Wo bí a ṣe lè fara wé Jèhófà tó bá dọ̀ràn ká máa dárí jini.

‘Ìwàásù Tí Wọn Kò Gbọ́ Irú Rẹ̀ Rí’

Nígbà tó fi máa di ọdún 1926, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ táà ń pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, ti ní ilé-iṣẹ́ rédíò tiwọn ní ìlú mẹ́rin ní Kánádà.