Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Látinú Àpamọ́ Wa

‘Ìwàásù Tí Wọn Kò Gbọ́ Irú Rẹ̀ Rí’

‘Ìwàásù Tí Wọn Kò Gbọ́ Irú Rẹ̀ Rí’

ÀWỌN igi gẹdú kan wà tí wọ́n tò jọ sí ibi tí wọ́n ń kó ohun ìjà ogun sí ní ìlú Saskatoon. Ẹkùn-ìpínlẹ̀ Saskatchewan ní orílẹ̀-èdè Kánádà ni ìlú yìí wà. Nígbà tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ George Naish rí àwọn igi náà, ó béèrè pé: “Kí ni wọ́n ń fi àwọn igi yẹn ṣe?” Wọ́n sọ fún un pé àwọn igi yẹn ni wọ́n fi kọ́ ilé atọ́nà ọkọ̀ ojú irin nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Lẹ́yìn náà, ó ní: “Mo ronú pé a lè fi àwọn igi gẹdú yẹn kan òpó tá a lè so àwọn ohun èlò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́, ìgbà yẹn sì ló kọ́kọ́ sọ sí wa lọ́kàn pé ká ní ilé iṣẹ́ rédíò kan tí a ó ti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” Ní ọdún kan lẹ́yìn náà, ìyẹn, lọ́dún 1924, wọ́n dá ilé iṣẹ́ rédíò kan tí wọ́n pè ní CHUC sílẹ̀. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ rédíò tó kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn sáfẹ́fẹ́ lórílẹ̀-èdè Kánádà.

Orílẹ̀-èdè Kánádà tóbi gan-an, torí náà, ó dára láti fi rédíò wàásù níbẹ̀. Arábìnrin Florence Johnson, tó ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ rédíò náà sọ pé: “Ìwàásù tá à ń ṣe lórí rédíò ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ṣeé ṣe ká má lè dé ọ̀dọ̀ wọn gbọ́ ìwàásù. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé rédíò ṣẹ̀ṣẹ̀ dé nígbà yẹn ni, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti gbọ́ rédíò.” Nígbà tó fi máa di ọdún 1926, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn) ti ní ilé iṣẹ́ rédíò tiwọn sí ìlú mẹ́rin ní orílẹ̀-èdè Kánádà. *

Kí lo máa gbọ́ tó o bá yí rédíò rẹ sí ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ yìí? Wàá gbọ́ tí àwọn ará ìjọ ń kọrin pẹ̀lú àwọn mélòó kan tó jẹ́ ẹgbẹ́ akọrin àtàwọn tó ń lo ohun èlò orin. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin máa ń wàásù, wọ́n sì máa ń jíròrò Bíbélì. Arábìnrin Amy Jones, tó kópa nínú irú ìjíròrò yẹn rí sọ pé, “Bí mo bá wà lóde ẹ̀rí, lẹ́yìn tí mo bá ti sọ orúkọ mi fún onílé, wọ́n máa ń sọ fún mi nígbà míì pé, ‘Mo ti rántí, mo gbóhùn rẹ lórí rédíò.’”

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ní ìlú Halifax, ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Nova Scotia tún máa ń ṣe ohun kan tó yàtọ̀. Nígbà tí wọ́n bá wà lórí afẹ́fẹ́, wọ́n máa ń fún àwọn tó ń tẹ́tí sí wọn lórí rédíò láǹfààní láti tẹ̀ wọ́n láago kí wọ́n sì béèrè àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì. Arákùnrin kan sọ pé: “Àwọn tó ń gbádùn irú ìwàásù yìí pọ̀ gan-an débi pé a kì í lè dá gbogbo àwọn tó ń pè lórí fóònù lóhùn.”

Ńṣe ni ọ̀rọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí dà bí ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí àwọn kan tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí àwọn míì sì kọ etí ikún sí i. (Ìṣe 17:1-5) Àwọn kan fẹ́ràn láti máa gbọ́ ìwàásù wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Hector Marshall gbọ́ tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìwé Studies in the Scriptures lórí rédíò, ó ní kí wọ́n fi apá kìíní sí apá kẹfà ìwé náà ránṣẹ́ sí òun. Lẹ́yìn ìgbà náà ló wá sọ pé: “Ńṣe ni mo rò pé màá máa fi ìwé náà kọ́ àwọn ọmọdé ní ṣọ́ọ̀ṣì.” Àmọ́, nígbà tí Hector fi máa ka Apá Kìíní ìwé náà tán, ó pinnu pé òun kò ní lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Ó di ajíhìnrere tó ń fi ìtara wàásù. Ó sì ń bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó títí tó fi kú lọ́dún 1998. Lọ́jọ́ kejì lẹ́yìn tí wọ́n gbé àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ijọba Na, Ireti Aiye” jáde sáfẹ́fẹ́ ní ìlà oòrùn ẹkùn-ìpínlẹ̀ Nova Scotia, ọ̀gágun kan tó ń jẹ́ J. A. MacDonald sọ fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa pé: “Àwọn tó ń gbé ní Erékùṣù Cape Breton gbọ́ ìwàásù kan lánàá tí wọ́n kò gbọ́ irú rẹ̀ rí.”

Àmọ́, ńṣe ni inú bí àwọn àlùfáà. Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan tiẹ̀ sọ pé àwọn máa ju bọ́ǹbù sí ilé iṣẹ́ rédíò táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ti ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́. Lẹ́yìn tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti sọ̀rọ̀ sí ìjọba létí, ìjọba kéde pé àwọn ò ní sọ ìwé àṣẹ tó fàyè gba àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ní ilé iṣẹ́ rédíò dọ̀tun mọ́. Àwọn ará kò fara mọ́ ohun tí ìjọba ṣe yìí. Torí náà, wọ́n pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Who Owns the Air? [Ta Ló Ni Afẹ́fẹ́?] fáwọn èèyàn. Wọ́n fi ṣàlàyé pé ohun tí ìjọba ṣe yìí kò bófin mu rárá. Síbẹ̀, ìjọba kọ̀ láti sọ ìwé àṣẹ tí wọ́n fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ dọ̀tun.

Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn Ẹlẹ́rìí kéréje tó wà ní orílẹ̀-èdè Kánádà? Arábìnrin Isabel Wainwright sọ pé: “Ńṣe ló kọ́kọ́ dà bíi pé àwọn ọ̀tá wa ti ṣẹ́gun wa. Àmọ́ mo mọ̀ pé tó bá jẹ́ pé ó wu Jèhófà pé ká ṣì máa wàásù lórí rédíò ni, ìjọba ò ní lè ti ilé iṣẹ́ rédíò wa. Torí náà, ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà fẹ́ ká wá ọ̀nà míì tó dára ju ìyẹn láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” Dípò tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ní orílẹ̀-èdè Kánádà ì bá fi máa rò pé orí rédíò nìkan làwọn ti lè máa wàásù fáwọn èèyàn, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ wàásù fún wọn nínú ilé wọn. Ní gbogbo ìgbà tí a fi ń wàásù lórí rédíò, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbọ́ ‘ìwàásù tí wọn kò gbọ́ irú rẹ̀ rí.’—Látinú àpamọ́ wa ní orílẹ̀-èdè Kánádà.

^ Àwọn ará lórílẹ̀-èdè Kánádà tún máa ń sanwó fáwọn ilé iṣẹ́ rédíò kí wọ́n lè wàásù lórí rédíò wọn.