Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Jèhófà Dárí Jì ẹ́?
“Jèhófà [jẹ́] Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú . . . , ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.”—Ẹ́KÍS. 34:6, 7.
1, 2. (a) Irú Ọlọ́run wo ni Jèhófà fi hàn pé òun jẹ́ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (b) Ìbéèrè wo la máa rí ìdáhùn sí nínú àpilẹ̀kọ yìí?
NÍGBÀ ayé Nehemáyà, àwọn àlùfáà kan tó ń gbàdúrà níwájú àwọn Júù sọ pé léraléra làwọn baba ńlá àwọn “kọ̀ láti fetí sílẹ̀” sí àwọn àṣẹ Jèhófà. Àmọ́, Jèhófà fi hàn wọ́n léraléra pé òun jẹ́ ‘Ọlọ́run tó máa ń dárí jini, olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, tó ń lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.’ Bákan náà, Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn Júù ìgbà ayé Nehemáyà.—Neh. 9:16, 17.
2 A lè wá bi ara wa pé: ‘Bí mo bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì mí, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe?’ Ká tó lè dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọba méjì tí Jèhófà dárí jì, ìyẹn Dáfídì àti Mánásè.
DÁFÍDÌ DÁ Ẹ̀ṢẸ̀ TÓ BURÚ JÁÌ
3-5. Ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì wo ni Dáfídì dá? Ṣàlàyé.
3 Dáfídì ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, síbẹ̀ ó dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Ó ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó sì pa Ùráyà ọkọ rẹ̀. Wàhálà tí ẹ̀ṣẹ̀ náà dá sílẹ̀ kúrò ní kékeré. Síbẹ̀, ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá Dáfídì wí fi ọ̀pọ̀ nǹkan hàn wá nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀.
4 Dáfídì rán àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì lọ sí Rábà, olú ìlú Ámónì pé kí wọ́n lọ sàga tì í. Apá ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù ní ìsọdá Odò Jọ́dánì ni Rábà wà, ó sì fi nǹkan bí ọgọ́rin [80] kìlómítà jìn síbẹ̀. Lọ́jọ́ kan Dáfídì wà lórí òrùlé ààfin rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, látibẹ̀ ló ti rí Bátí-ṣébà tó ń wẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó. Ọkọ obìnrin náà kò sí nílé, àmọ́ ọkàn Dáfídì fà sí i débi tó fi ní kí wọ́n lọ mú un wá sí ààfin, ó sì bá a ṣe panṣágà.—2 Sám. 11:1-4.
5 Nígbà tí Dáfídì mọ̀ pé Bátí-ṣébà ti lóyún, ó ní kí wọ́n sọ fún ọkọ rẹ̀ pé kó wá sí Jerúsálẹ́mù, èrò rẹ̀ ni pé tó bá dé ó máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀. Dáfídì gbìyànjú pé kí Ùráyà lọ sùn ti ìyàwó rẹ̀, àmọ́ kò tiẹ̀ yọjú sí ìyàwó rẹ̀ rárá. Torí náà, ọba kọ̀wé àṣírí kan ránṣẹ́ sí olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó ní kó fi Ùráyà “sí iwájú ibi tí ìjà ogun ti gbóná jù lọ” kó sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa dà lẹ́yìn rẹ̀. Èyí mú kí ọwọ́ tètè ba Ùráyà, ó sì kú sójú ogun, bí Dáfídì ṣe pète. (2 Sám. 11:12-17) Bí Dáfídì ṣe dá ọ̀ràn mọ́ràn nìyẹn o, ó ṣe panṣágà ó sì tún pa Ùráyà láìṣẹ̀ láìrò.
DÁFÍDÌ RONÚ PÌWÀ DÀ
6. Kí ni Ọlọ́run ṣe nígbà tí Dáfídì dẹ́ṣẹ̀? Kí nìyẹn jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
6 Jèhófà rí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. Kò sí ohun tí ojú rẹ̀ kò tó. (Òwe 15:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì pàpà fẹ́ Bátí-ṣébà, ‘ohun tó ṣe burú ní ojú Jèhófà.’ (2 Sám. 11:27) Kí wá ni Ọlọ́run ṣe nígbà tí Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì yẹn? Ó rán Nátánì, wòlíì rẹ̀, sí Dáfídì. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń dárí jini, ó fẹ́ láti mọ̀ bóyá òun máa rí ìdí tó fi yẹ kí òun ṣàánú Dáfídì. Ọ̀nà tí Jèhófà gbé ọ̀rọ̀ gbà yìí mà wúni lórí gan-an ni o! Kò fi ipá mú Dáfídì láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ńṣe ló wulẹ̀ mú kí Nátánì sọ ìtàn kan fún un tó jẹ́ kó rí bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣe burú tó. (Ka 2 Sámúẹ́lì 12:1-4.) Ẹ sì wo bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bójú tó ọ̀ràn ẹlẹgẹ́ náà ṣe dára tó!
7. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó gbọ́ ìtàn tí Nátánì sọ?
7 Ìtàn tí Nátánì sọ fún Dáfídì dá lórí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó fọwọ́ ọlá gbá ẹnì kan lójú. Inú bí Dáfídì gan-an nígbà tó gbọ́ ìtàn náà, ó sì sọ pé ó yẹ kí ọkùnrin náà jìyà ohun tó ṣe. Ó wá sọ fún Nátánì pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, ikú tọ́ sí ọkùnrin tí ó ṣe èyí!” Dáfídì tún sọ pé ó yẹ kí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà san ohun tó gbà pa dà. Lẹ́yìn náà ni gudugbẹ̀ ọ̀rọ̀ wá já bọ́ lẹ́nu Nátánì. Ó sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ni ọkùnrin náà!” Ó tún wá sọ pé nítorí ohun tó ṣe yẹn, “idà” kò ní kúrò ní ilé rẹ̀, àjálù yóò máa bá ìdílé rẹ̀, ó sì máa dẹni ìtìjú lójú gbogbo èèyàn. Dáfídì wá rí i pé ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lòun dá, ó sì sọ pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.”—2 Sám. 12:5-14.
DÁFÍDÌ GBÀDÚRÀ, ỌLỌ́RUN SÌ DÁRÍ JÌ Í
8, 9. Báwo ni Sáàmù 51 ṣe jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn Dáfídì, kí ló sì kọ́ wa nípa Jèhófà?
8 Àwọn ọ̀rọ̀ orin kan tí Dáfídì Ọba kọ lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá ṣe dùn ún tó. Ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá tó bẹ Jèhófà wà nínú Sáàmù 51, ó sì fi hàn kedere pé ó gbà pé òun dẹ́ṣẹ̀, ó sì tún ronú pìwà dà. Dáfídì ò fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe òun pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Ó sọ pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí.” Ó bẹ Jèhófà pé: “Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. . . . Mú ayọ̀ ńláǹlà ìgbàlà rẹ padà bọ̀ sípò fún mi, kí o sì fi ẹ̀mí ìmúratán pàápàá tì mí lẹ́yìn.” (Sm. 51:1-4, 7-12) Bí ìwọ náà bá ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún Jèhófà, ṣé o máa ń sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an láìfi ohunkóhun pa mọ́?
9 Jèhófà fàyè gba Dáfídì láti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kódà ńṣe ló ń bá a yí títí tó fi kú. Àmọ́, nítorí pé Dáfídì ní “ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀,” Jèhófà dárí jì í. (Ka Sáàmù 32:5; Sm. 51:17) Ọlọ́run Olódùmarè mọ ẹni tá a jẹ́ àti ohun tó fà á tá a fi ń dẹ́ṣẹ̀. Dípò tí Jèhófà ì bá fi jẹ́ káwọn onídàájọ́ pa Dáfídì àti Bátí-ṣébà gẹ́gẹ́ bí Òfin Mósè ṣe sọ, ó ṣàánú wọn ó sì bá wọn dá sí ọ̀ràn náà. (Léf. 20:10) Sólómọ́nì tí Bátí-ṣébà bí fún Dáfídì ló wá di ọba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ́yìn ikú Dáfídì.—1 Kíró. 22:9, 10.
10. (a) Kí ló ṣeé ṣe kò fà á tí Jèhófà fi dárí ji Dáfídì? (b) Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe?
10 Bóyá ohun míì tó fà á tí Jèhófà fi dárí ji Dáfídì ni pé òun náà ti ṣàánú Sọ́ọ̀lù rí. (1 Sám. 24:4-7) Jésù ṣàlàyé pé ohun tá a bá ṣe sáwọn ẹlòmíì ni Jèhófà máa ṣe sí wa. Ó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́; àti òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n fún yín.” (Mát. 7:1, 2) Ẹ wo bó ti fini lọ́kàn balẹ̀ tó pé Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, títí kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì bíi panṣágà tàbí ìpànìyàn! Ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, tá a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún un, tá a sì kọ ìwà búburú sílẹ̀. “Àwọn àsìkò títunilára” tún máa ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà látọkàn wá.—Ka Ìṣe 3:19.
MÁNÁSÈ DẸ́ṢẸ̀ TÓ BURÚ JÁÌ ÀMỌ́ Ó RONÚ PÌWÀ DÀ
11. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Ọba Mánásè gbà ṣe ohun tó burú lójú Ọlọ́run?
11 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ìtàn míì nínú Ìwé Mímọ́ tó kọ́ wa pé Jèhófà lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá jini. Ní nǹkan bí okòó-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún [320] ọdún lẹ́yìn tí Dáfídì ti ṣàkóso, Mánásè di ọba Júdà. Jálẹ̀ gbogbo ọdún márùndínlọ́gọ́ta [55] tó fi ṣàkóso ló fi ń hùwà tó burú jáì, àwọn ìwà tí ń kóni nírìíra náà sì mú kí Jèhófà bínú sí i. Bí àpẹẹrẹ, Mánásè gbé pẹpẹ kalẹ̀ fún ìjọsìn Báálì, ó ń jọ́sìn “gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run,” ó mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ la iná kọjá, ó sì gbé àṣà ìbẹ́mìílò lárugẹ. “Ní ìwọ̀n tí ó bùáyà ni ó ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.”—2 Kíró. 33:1-6.
12. Báwo ni Mánásè ṣe “padà sọ́dọ̀ Jèhófà”?
12 Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n mú Mánásè kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ sí Bábílónì, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó ṣeé ṣe kó rántí ohun tí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Nígbà tí o bá wà nínú hílàhílo, tí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì gbá ọ mú ní òpin àwọn ọjọ́ náà, nígbà náà ni ìwọ yóò padà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tí ìwọ yóò sì fetí sí ohùn rẹ̀.” (Diu. 4:30) Ní tòótọ́, Mánásè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ báwo ló ṣe pa dà? Ó “ń bá a nìṣó ní rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi” ó sì “ń gbàdúrà” sí Ọlọ́run (bó ṣe wà nínú àwòrán ojú ìwé 21). (2 Kíró. 33:12, 13) Àwọn ọ̀rọ̀ pàtó tí Mánásè sọ nígbà tó gbàdúrà kò sí lákọọ́lẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jọ àdúrà tí Dáfídì Ọba gbà nínú Sáàmù 51. Bó ti wù kó rí, Mánásè ronú pìwà dà.
13. Kí nìdí tí Jèhófà fi dárí ji Mánásè?
13 Kí ni Jèhófà ṣe lẹ́yìn tí Mánásè gbàdúrà? “Ó jẹ́ kí [Mánásè] pàrọwà sí òun, Ó sì gbọ́ ìbéèrè rẹ̀ fún ojú rere.” Bíi ti Dáfídì, Mánásè wá rí i pé ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lòun dá, ó sì ronú pìwà dà látọkàn wá. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi dárí ji Mánásè tó sì dá a pa dà sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní Jerúsálẹ́mù. “Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.” (2 Kíró. 33:13) Ẹ ò rí i pé ìtàn Mánásè yìí náà tún jẹ́ ká rí i pé aláàánú ni Ọlọ́run wa, ó sì máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn!
ṢÉ GBOGBO ÌGBÀ NI JÈHÓFÀ MÁA Ń DÁRÍ JINI?
14. Bí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀, kí ló gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà lè dárí jì í?
14 Agbára káká la fi máa rí lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní tó máa dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì bíi ti Dáfídì àti Mánásè. Síbẹ̀, pé Jèhófà dárí ji àwọn ọba méjèèjì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ṣe tán láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.
15. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini?
15 Èyí kò wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni Jèhófà kàn ṣáà máa ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ jì wọ́n o. Kí ohun tá à ń sọ lè ṣe kedere, ẹ jẹ́ ká fi ohun tí Dáfídì àti Mánásè ṣe wéra pẹ̀lú tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn èèyàn Júdà tí wọ́n jẹ́ aṣetinú-ẹni. Nígbà tí Dáfídì dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run rán Nátánì sí i kó lè fún un láǹfààní láti yí pa dà. Dáfídì mọyì àǹfààní tí Ọlọ́run fún un, ó sì yí pa dà. Nígbà tí ìnira bá Mánásè náà, ó ronú pìwà dà látọkàn wá. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn olùgbé Júdà kò ronú pìwà dà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí wọn léraléra láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun kórìíra ìwà àìgbọràn wọn. Torí náà, Jèhófà kò dárí jì wọ́n. (Ka Nehemáyà 9:30.) Kódà, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó láti máa rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, bí Ẹ́sírà àlùfáà àti wòlíì Málákì, sí wọn. Nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, wọ́n máa ń láyọ̀.—Neh. 12:43-47.
16. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì torí pé wọn kò ronú pìwà dà? (b) Àǹfààní wo ni Ọlọ́run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
16 Lẹ́yìn tí Jèhófà ti rán Jésù wá sáyé láti fi ẹ̀mí rẹ̀ rú ẹbọ ìràpadà pípé kan ṣoṣo náà, kò tẹ́wọ́ gba ẹbọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń fi ẹran rú mọ́. (1 Jòh. 4:9, 10) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi wo àwọn Júù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn. Ó ní: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ.” Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mát. 23:37, 38) Látàrí èyí, Ọlọ́run fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tẹ̀mí rọ́pò orílẹ̀-èdè tó ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò sì ronú pìwà dà náà. (Mát. 21:43; Gál. 6:16) Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ńkọ́? Ọlọ́run lè ṣàánú wọn kó sì dárí jì wọ́n bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù Kristi. Jèhófà tún máa dárí ji àwọn kan tí kò ronú pìwà tí wọ́n fi kú, àmọ́ tí wọ́n jí dìde sínú Párádísè.—Jòh. 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
OHUN TÁ A GBỌ́DỌ̀ ṢE TÁ A BÁ FẸ́ KÍ JÈHÓFÀ DÁRÍ JÌ WÁ
17, 18. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?
17 Níwọ̀n bí Jèhófà ti múra tán láti dárí jì wá, kí ló yẹ ká ṣe? Ńṣe ló yẹ ká ṣe bíi ti Dáfídì àti Mánásè. A gbọ́dọ̀ gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ká ronú pìwà dà, ká fi taratara bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá, kó má sì jẹ́ ká máa gba èròkerò láyè. (Sm. 51:10) Tá a bá sì ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, a tún gbọ́dọ̀ tọ àwọn alàgbà lọ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. (Ják. 5:14, 15) Bá a bá tiẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ọkàn wa máa balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ tá a bá rántí pé Jèhófà ò tíì yí pà dá. Ó sọ fún Mósè pé òun jẹ́ ‘Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, tó ń lọ́ra láti bínú, tó pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, tó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó sì ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.’—Ẹ́kís. 34:6, 7.
18 Jèhófà ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ronú pìwà dà pé òun máa fọ àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò pátápátá. Kódà, bí ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n bá pọ́n bí “aṣọ rírẹ̀dòdò,” ó sọ pé òun á sọ ọ́ di funfun bí “ìrì dídì.” (Ka Aísáyà 1:18.) Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìṣìnà wa jì wá pátápátá tá a bá fi hàn pé a moore Ọlọ́run tá a sì ronú pìwà dà.
19. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Níwọ̀n bí Jèhófà ti máa ń dárí jì wá, báwo la ṣe lè fìwà jọ ọ́? Báwo la ṣe lè máa dárí ji àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì àmọ́ tí wọ́n ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó wà lọ́kàn wa, ká lè túbọ̀ dà bíi Baba wa, Jèhófà, tó ‘jẹ́ ẹni rere, tó sì ṣe tán láti dárí jini.’—Sm. 86:5.