Àṣẹ́kùsílẹ̀ Wọn Dí Àìnító Kan
NÍ ỌDÚN 49 Sànmánì Kristẹni, Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù, “tí wọ́n dà bí ọwọ̀n” nínú ìjọ, rán àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ ní iṣẹ́ pàtàkì kan. Wọ́n sọ pé kí wọ́n lọ wàásù fún àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n sì ní kí wọ́n fi àwọn Kristẹni tó jẹ́ òtòṣì sọ́kàn. (Gál. 2:9, 10) Báwo ni wọ́n ṣe ṣe iṣẹ́ tí wọ́n rán wọn yìí?
Àlàyé nípa bí wọ́n ṣe bójú tó iṣẹ́ náà wà nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ. Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Ní ti àkójọ tí ó wà fún àwọn ẹni mímọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin tìkára yín ṣe pẹ̀lú. Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí, kí ó lè jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé, àkójọ kì yóò wáyé nígbà náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá dé, àwọn ọkùnrin yòówù tí ẹ bá tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà, àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò rán láti gbé ẹ̀bùn inú rere yín lọ sí Jerúsálẹ́mù.”—1 Kọ́r. 16:1-3.
Nínú lẹ́tà kejì tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó pa dà mẹ́nu kan ohun tí àkójọ náà wà fún. Ó ní: “Nípasẹ̀ ìmúdọ́gba, kí àṣẹ́kùsílẹ̀ yín nísinsìnyí gan-an lè dí àìnító wọn.”—2 Kọ́r. 8:12-15.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn ará ní Róòmù ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, àkójọ náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Ó sọ pé: “Mo máa tó rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́. Nítorí àwọn tí ń bẹ ní Makedóníà àti Ákáyà ni ó ti dùn mọ́ nínú láti ṣe àjọpín àwọn nǹkan wọn nípasẹ̀ ọrẹ fún àwọn òtòṣì àwọn ẹni mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.” (Róòmù 15:25, 26) Kò pẹ́ sí ìgbà yẹn tí Pọ́ọ̀lù parí iṣẹ́ tí wọ́n rán an. Nígbà tí wọ́n fi àṣẹ ọba mú un lẹ́yìn tó pa dà dé Jerúsálẹ́mù, ó sọ fún Fẹ́líìsì, tó jẹ́ Gómìnà ìlú Róòmù pé: “Mo dé láti mú àwọn ẹ̀bùn àánú wá fún orílẹ̀-èdè mi, àti àwọn ọrẹ ẹbọ.”—Ìṣe 24:17.
Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ará Makedóníà mú kó ṣe kedere pé ọ̀làwọ́ ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Ó sọ pé ‘wọ́n ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere.’ Pọ́ọ̀lù wá rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn. Ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” Kí ló mú kí àwọn ará ìjọ wọ̀nyẹn fi irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ hàn? Kì í wulẹ̀ ṣe “láti pèsè fún àìní àwọn ẹni mímọ́ lọ́pọ̀ yanturu ṣùgbọ́n láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run pẹ̀lú.” (2 Kọ́r. 8:4; 9:7, 12) A lè fi hàn pé ohun táwa náà fẹ́ ṣe nìyí tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́. Tá a bá fi irú ẹ̀mí rere àti ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ hàn, ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run máa bù kún wa, ìbùkún rẹ̀ ló sì ń sọni di ọlọ́rọ̀ ní tòótọ́.—Òwe 10:22.
Ọ̀NÀ TÁWỌN KAN Ń GBÀ ṢÈTỌRẸ FÚN IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ
Bó ṣe rí nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń “ya ohun kan sọ́tọ̀,” tàbí kí wọ́n ya iye owó kan sọ́tọ̀, kí wọ́n sì fi owó náà sínú àpótí ìjọ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí. (1 Kọ́r. 16:2) Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. O sì tún lè fi ọrẹ ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ mọ orúkọ àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin, jọ̀wọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè rẹ. O lè rí àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì lórí ìkànnì www.pr418.com. Lára àwọn ọrẹ tó o lè fi ránṣẹ́ sí wa ní tààràtà rèé:
Ẹ̀BÙN
O lè fi owó, ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ.
Kọ lẹ́tà kó o sì fi ránṣẹ́ pẹ̀lú owó tàbí ọrẹ náà láti fi hàn pé ẹ̀bùn ló jẹ́.
ỌRẸ TÓ ṢEÉ GBÀ PA DÀ
O lè fi owó síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí wọ́n máa lò ó. Àmọ́, àjọ náà á dá owó náà pa dà bí ẹni tó ni ín bá béèrè fún un.
Kọ lẹ́tà láti fi hàn pé ńṣe lo fi owó náà síkàáwọ́ àjọ náà títí dìgbà tó o máa fẹ́ láti gbà á pa dà.
ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ
Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fi owó tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Ọ̀nà yòówù kó o fẹ́ láti gbà ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ kí wọ́n lè jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó bófin mu tó o lè gbà ṣe é. Ohun tí òfin sọ nípa ọrẹ máa ń yàtọ̀ síra, ó ṣe pàtàkì pé kó o fi ọ̀rọ̀ lọ amòfin tó mọ̀ nípa ẹ̀ dáadáa kó o tó yan ọ̀nà tó o máa gbà ṣètọrẹ. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ṣètọrẹ rèé.
Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.
Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí àjọ náà máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.
Ìpín Ìdókòwò, Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó: A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lọ́rẹ. A sì lè ní kí ẹ̀tọ́ náà di ti àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni.
Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbé inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè.
Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé àjọ náà ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.
Gbólóhùn náà, “ọrẹ téèyàn wéwèé” fi hàn pé ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ gbọ́dọ̀ ronú dáadáa kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o fi nọ́ńbà tẹlifóònù tó wà níbi àdírẹ́sì náà pè wá, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ..