ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ December 2012

Ẹ̀dà yìí sọ ohun tó túmọ̀ sí káyé yẹni, ó sì ṣàlàyé bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará wọn kárí ayé.

Ṣé Òótọ́ Ni Bíbélì Ní Agbára Àràmàǹdà

Àwọn kan gbàgbọ́ pé Bíbélì ní agbára àràmàǹdà. Kí lèrò rẹ? Báwo lo ṣe lè jàǹfààní nínu ohun tí Bíbélì fi kọ́ni?

Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni

Kí ló túmọ̀ sí pé káyé yẹni? Gbé àpẹẹrẹ Sólómọ́nì Ọba àti ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò.

Ìríjú Tá A Fọkàn Tán Ni Ẹ́!

Ìríjú ni gbogbo àwa tá à ń sin Ọlọ́run. Ìlànà mẹ́ta wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe yìí?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo dídá ẹyin tó ti di ọmọ sí? Báwo làwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè tóótun láti ṣèrìbọmi tí òfin ò bà gbà wọ́n láyè láti fi orúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣé o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Olùgbé Fún Ìgbà Díẹ̀” Ni Wá

Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ “olùgbé fún ìgbà díẹ̀” nínú ayé yìí? Kí ló yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa ṣe?

“Àwọn “Olùgbé Fún Ìgbà Díẹ̀” Ń Sin Jèhófà Ní Ìṣọ̀kan

Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará wọn kárí ayé?

Ilé Ìṣọ́ Tá A Fi Èdè Gẹ̀ẹ́sì Tó Rọrùn Kọ—Kí Nìdí Tá A Fi Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Tẹ̀ Ẹ́?

Kà nípa bí tọmọdé tàgbà ṣe ti ń jàǹfàní nínú kíka ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ yìí.

Atọ́ka Àwọn Àkòrí fún Ilé Ìṣọ́ 2012

Atọ́ka gbogbo àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 2012.