Ilé Ìṣọ́ Tá A Fi Èdè Gẹ̀ẹ́sì Tó Rọrùn Kọ—Kí Nìdí Tá A Fi Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Tẹ̀ Ẹ́?
FÚN ọ̀pọ̀ ọdún la ti ń gbé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Tọ́kùnrin tóbìnrin kárí ayé ló mọrírì àwọn ìtẹ̀jáde náà, ó sì máa ń ṣe wọ́n láǹfààní. Ní oṣù July, ọdún 2011, a mú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àkọ́kọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ jáde. A sọ nínú ìwé ìròyìn tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí pé: “Ọdún kan la fẹ́ fi dán ìṣètò tuntun yìí wò ká tó lè mọ̀ bóyá yóò máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.”
Inú wa dùn láti sọ fún yín pé a ti pinnu láti máa tẹ̀ ẹ́ nìṣó. Àmọ́ ní báyìí o, a óò tún máa gbé Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Faransé, Potogí àti Sípáníìṣì tó rọrùn kọ jáde.
KÍ LÓ MÚ KÁWỌN ÈÈYÀN FẸ́RÀN RẸ̀?
Lẹ́yìn tí àwọn ará wa tó wà ní Gúúsù Pàsífíìkì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìwé ìròyìn tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ sọ pé: “Ìgbà yìí gan-an ni ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yé àwọn ará dáadáa.” Lẹ́tà míì sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, a máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti wá ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó. A tún máa ń ṣàlàyé àwọn gbólóhùn tó ṣòro lóye nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Àmọ́, ní báyìí, a ti ń fi àkókò yẹn ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ ká lè lóye àlàyé tí wọ́n ṣe nípa kókó tá à ń jíròrò.”
Obìnrin kan tó gboyè jáde ní yunifásítì kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọdún méjìdínlógún ni mo fi sọ òyìnbó ńláńlá tó ṣòroó lóye tí mo kọ́ ní yunifásítì, òun náà sì ni mò ń kọ sílẹ̀. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá kí n tó ronú kan ohun tí mo máa sọ, ọ̀rọ̀ mi sì máa ń ṣòroó lóye. Mo wá rí i pé mo ní láti yí ọ̀nà tí mò ń gbà ronú àti ọ̀nà tí mò ń gbà sọ̀rọ̀ pa dà.” Ní báyìí, ó ti di àkéde onítara, ó wá sọ pé: “Ilé
Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ gan-an látinú bí wọ́n ṣe máa ń kọ̀wé lọ́nà tó rọrùn.”Arábìnrin kán tó wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà sọ èrò rẹ̀ nípa ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àkọ́kọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣèrìbọmi láti ogójì ọdún sẹ́yìn, ó sọ pé: “Nígbà tí mo kà á, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà jókòó tì mí tó sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àfi bíi pé bàbá jókòó ti ọmọ rẹ̀ tó sì ń sọ ìtàn alárinrin fún un.”
Ó ti lé ní ogójì ọdún tí arábìnrin kan tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti ṣèrìbọmi. Òun náà sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìtẹ̀jáde náà máa ń jẹ́ kóun túbọ̀ lóye àwọn nǹkan tí òun kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí ibi tí wọ́n ti ṣàlàyé ìtumọ̀ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ inú àpilẹ̀kọ náà. Nínú ẹ̀dà ti September 15, 2011, wọ́n ṣàlàyé pé ohun tí gbólóhùn náà, “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” tó wà nínú Hébérù 12:1, túmọ̀ sí ni pé àwọn ẹlẹ́rìí náà “pọ̀ débi pé a kò lè kà wọ́n.” Arábìnrin náà wá sọ pé: “Ńṣe lèyí mú kí n túbọ̀ lóye ẹsẹ yẹn.” Ó tún sọ nípa àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ pé: “Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n fi èdè Gẹ̀ẹ́sì àjùmọ̀lò kọ ló wà lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ará. Torí náà, bí ọmọ kan bá tiẹ̀ ka ìdáhùn jáde ní tààràtà láti inú èyí tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ, ńṣe ló máa dà bíi pé ó dáhùn lọ́rọ̀ ara rẹ̀.”
Arábìnrin míì tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ gbọ́ ìdáhùn àwọn ọmọdé tó wà nínú ìjọ. Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ máa ń mú kí wọ́n dáhùn lọ́nà tó fi hàn pé ohun tí
wọ́n ń sọ dá wọn lójú. Ìdáhùn wọn máa ń wú mi lórí.”Arábìnrin kan tó ti ṣèrìbọmi láti ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n sọ nípa Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé torí tèmi gan-an ni wọ́n ṣe kọ ọ́. Ó máa ń jẹ́ kí ohun tí mò ń kà tètè yé mi. Ní báyìí, ọkàn mi máa ń balẹ̀ láti dáhùn nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.”
ÀWỌN ÒBÍ MỌYÌ RẸ̀ GAN-AN
Ìyá ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méje sọ pé: “Tá a bá ń múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀, ó máa ń gbà mí lákòókò láti ṣàlàyé àwọn gbólóhùn tí kò bá yé ọmọ mi fún un, ó sì máa ń sú mi lọ́pọ̀ ìgbà.” Báwo ní Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? Ìyá ọmọ náà kọ̀wé pé: “Ó yà mí lẹ́nu pé ó lè ka àwọn ìpínrọ̀ náà kó sì lóye ohun tí wọ́n sọ níbẹ̀. Ìdí sì ni pé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ kò ta kókó, àwọn gbólóhùn náà kò sì gùn jù. Ní báyìí, ó máa ń dá múra àwọn ìpàdé sílẹ̀. Ó sì máa ń pọkàn pọ̀ títí tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà á fi parí.”
Ìyá ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ńṣe la máa ń sọ ìdáhùn fún un. Àmọ́, ó ti ń rí ìdáhùn fúnra rẹ̀ báyìí. A kì í sábà ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣòro fún un mọ́ bíi tìgbà kan. Ó ti wá ń gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ báyìí torí pé àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ máa ń yé e.”
KÍ LÀWỌN ỌMỌDÉ SỌ?
Ọ̀pọ̀ ọmọdé ló gbà pé àwọn ni wọ́n ṣe Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ fún. Ọmọ ọdún méjìlá kan tó ń jẹ́ Rèbékà sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máa tẹ̀ ẹ́ nìṣó! Mo fẹ́ràn láti máa lọ wo ibi tí wọ́n ti ṣàlàyé ìtumọ̀ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ inú àpilẹ̀kọ náà. Ó rọrùn fáwa ọmọdé gan-an.”
Nicolette tó jẹ́ ọmọ ọdún méje, sọ pé: “Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n fi èdè Gẹ̀ẹ́sì àjùmọ̀lò kọ kì í yé mi rárá. Mo ti ń dáhùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ báyìí.” Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan tó ń jẹ́ Emma sọ pé: “Ó ti ran èmi àti àbúrò mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà lọ́wọ́ gan-an ni. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò yé wa tẹ́lẹ̀ ti ń yé wa báyìí. Ẹ ṣeun gan-an ni!”
Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jàǹfààní látinú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a ti lo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye àti àwọn gbólóhùn tó ṣe ṣókí. Ó dájú pé ó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa. A ó máa bá a nìṣó láti tẹ Ilé Ìṣọ́ tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì tó rọrùn kọ. A kò sì ní dá èyí tá a fi èdè Gẹ̀ẹ́sì àjùmọ̀lò kọ dúró torí pé ó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ọdún 1879 tá a ti ń tẹ̀ ẹ́.