Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìríjú Tá A Fọkàn Tán Ni Ẹ́!

Ìríjú Tá A Fọkàn Tán Ni Ẹ́!

“Ẹ kì í ṣe ti ara yín.”—1 KỌ́R. 6:19.

1. Àwọn wo làwọn èèyàn mọ̀ sí ẹrú?

 NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn, òǹkọ̀wé eré onítàn kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì sọ pé: “Tìpátìkúùkù ni wọ́n fi ń ti àjàgà bọ ẹrú lọ́rùn.” Títí di báyìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé òótọ́ ni ohun tí ọ̀gbẹ́ni yìí sọ. Wọ́n máa ń fìyà jẹ ẹrú. Wọ́n máa ń fipá mú wọn sìnrú fáwọn olówó wọn. Ńṣe làwọn ẹrú máa ń bá oníṣẹ́ ṣiṣẹ́, àwọn ọ̀gá wọn sì máa ń jẹ gàba lé wọn lórí.

2, 3. (a) Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú àwọn ẹrú rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò báyìí?

2 Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jẹ́ ìránṣẹ́, tàbí ẹrú. Àmọ́, kì í ṣe ẹrú tí à ń tẹ̀ lórí ba tàbí ẹrú tá à ń fìyà jẹ ni Jésù ní lọ́kàn pé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa jẹ́ o! Ọ̀gá wọn máa fọkàn tán wọn, ó sì máa buyì kún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tí Jésù sọ nípa “ẹrú” kan. Kó tó kú, ó sọ pé òun máa yanṣẹ́ fún ẹrú “olóòótọ́ àti olóye.”—Mát. 24:45-47.

3 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹrú yìí kan náà nínú ìwé Lúùkù, ó pè é ní “ìríjú.” (Ka Lúùkù 12:42-44.) Lóde òní, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tòótọ́ kò sí lára olóòótọ́ ìríjú tí Jésù sọ náà. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwa tá à ń sin Ọlọ́run la jẹ́ ìríjú. Kí ni ojúṣe wa? Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí ìríjú? Láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí àwọn ìríjú máa ń ṣe láyé àtijọ́.

OJÚṢE ÀWỌN ÌRÍJÚ

4, 5. Kí ni ojúṣe àwọn ìríjú láyé àtijọ́? Àwọn àpẹẹrẹ wo la rí nínú Bíbélì?

4 Láyé àtijọ́, ẹrú tí ọ̀gá rẹ̀ fọkàn tán tó ń bójú tó ilé tàbí iṣẹ́ ọ̀gá rẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń pè ní ìríjú. Ó máa ń bójú tó àwọn ohun ìní àti owó ọ̀gá rẹ̀, ó sì ní àṣẹ lórí àwọn ìránṣẹ́ yòókù. Àpẹẹrẹ kan ni ti Élíésérì. Ábúráhámù yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni Ábúráhámù tún rán lọ sí Mesopotámíà láti lọ wá ìyàwó fún ọmọ rẹ̀, Ísáákì. Iṣẹ́ ńlá mà nìyẹn o!—Jẹ́n. 13:2; 15:2; 24:2-4.

5 Jósẹ́fù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù ni Pọ́tífárì yàn láti máa ṣe àbójútó agbo ilé rẹ̀. (Jẹ́n. 39:1, 2) Nígbà tó yá, Jósẹ́fù alára ní ìríjú kan tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ “olórí ilé Jósẹ́fù.” Ìríjú yìí ló ṣètò bí Jósẹ́fù ṣe gba àwọn arákùnrin rẹ̀ mẹ́wàá lálejò. Òun sì ni Jósẹ́fù ni kó fi ife fàdákà òun sínú àpò Bẹ́ńjámínì. Èyí jẹ́ ká rí bí àwọn ọ̀gá ṣe máa ń fọkàn tán àwọn ìríjú wọn tó.—Jẹ́n. 43:19-25; 44:1-12.

6. Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà?

6 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí Títù pé “ìríjú Ọlọ́run” ni àwọn alàgbà. (Títù 1:7) Àwọn alàgbà yìí ni olùṣọ́ àgùntàn “agbo Ọlọ́run.” Torí náà, àwọn ló máa ń bójú tó ìjọ. (1 Pét. 5:1, 2) Lóde òní, onírúurú ọ̀nà ni iṣẹ́ táwọn alàgbà máa ń bójú tó nínú ètò Ọlọ́run pín sí. Bí àpẹẹrẹ, ìjọ kan ṣoṣo ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ń bójú tó. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń bójú tó àwọn ìjọ tó pọ̀. Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sì máa ń bójú tó gbogbo ìjọ tó wà ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sìn. Síbẹ̀, gbogbo wọn gbọ́dọ̀ bójú tó iṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, torí pé wọ́n máa ‘jíhìn’ fún Ọlọ́run.—Héb. 13:17.

7. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìríjú ni gbogbo àwa Kristẹni?

7 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin ló wà tí wọn kì í ṣe alàgbà. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìríjú ni àwọn náà? Àpọ́sítélì Pétérù sọ nínú ìwé tó kọ sí gbogbo àwọn Kristẹni pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” (1 Pét. 1:1; 4:10) Ọlọ́run fi inú rere hàn sí gbogbo wa. Ó fún wa ní onírúurú àǹfààní tàbí ẹ̀bùn tá a lè fi ran àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́. Látàrí ìyẹn, ìríjú ni gbogbo àwa tá à ń sin Ọlọ́run. Ó fọkàn tán wa, ó buyì kún wa, ó sì retí pé ká lo àǹfààní àti ẹ̀bùn tó fún wa lọ́nà rere.

TI ỌLỌ́RUN NI WÁ

8. Kí ló yẹ káwa ìríjú máa rántí?

8 Ní báyìí, a máa jíròrò ohun mẹ́ta tó yẹ káwa ìríjú máa rántí. Èkíní: Ti Ọlọ́run ni wá, òun la sì máa jíhìn fún. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ kì í ṣe ti ara yín, nítorí a ti rà yín ní iye kan.” Iye tá a fi rà wá yẹn ni ẹ̀jẹ̀ Jésù tó fi rúbọ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. (1 Kọ́r. 6:19, 20) Ti Jèhófà ni wá, torí náà a gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Àwọn àṣẹ rẹ̀ kò sì nira. (Róòmù 14:8; 1 Jòh. 5:3) A tún jẹ́ ẹrú Kristi. Àwọn tó jẹ́ ìríjú nígbà àtijọ́ ní òmìnira, àwa náà sì ní òmìnira. Àmọ́, kì í ṣe òmìnira láti máa ṣe ìfẹ́ inú ara wa o! A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa. Bó ti wù kí iṣẹ́ tá à ń bójú tó nínú ètò Ọlọ́run pọ̀ tó, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Kristi ṣì ni gbogbo wa.

9. Kí ni Jésù sọ nípa ohun tí ọ̀gá kan á máa retí pé kí ẹrú rẹ̀ ṣe?

9 Jésù jẹ́ ká mọ ohun tí ọ̀gá kan á máa retí pé kí ẹrú rẹ̀ ṣe. Ó sọ ìtàn kan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ẹrú kan tó ti ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ tó wá darí wálé lẹ́yìn tó ṣe tán. Ṣé ọ̀gá ẹrú náà sọ fún un nígbà tó dé pé: “Tètè wá joko jẹun”? Rárá o. Ńṣe ló sọ fún ẹrú náà pé: “Tọ́jú ohun ti n óò jẹ́. Ṣe gírí kí o gbé ońjẹ fún mi. Nígbà tí mo bá jẹ tán, tí mo mu tán, kí o wá jẹun tìrẹ.” Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fi ìtàn náà kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Ó ṣàlàyé pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ ṣe. Nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pa láṣẹ fún yín tán, kí ẹ sọ pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ ni wá. Ohun tí a ṣe kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọpẹ́. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ti ṣe.’”—Lúùkù 17:7-10, Ìròhìn Ayọ̀.

10. Kí ló fi hàn pé Jèhófà mọyì gbogbo bá a ṣe ń sapá láti sìn ín?

10 Jèhófà mọyì gbogbo bá a ṣe ń sapá láti sìn ín. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Héb. 6:10) Jèhófà kì í sọ pé ká ṣe ohun tí agbára wa kò gbé. Àǹfààní ara wa làwọn ohun tó bá ní ká ṣe máa ń wà fún, kì í fi wọ́n ni wá lára. Síbẹ̀, ìtàn tí Jésù sọ kọ́ wa pé ẹrú ò gbọ́dọ̀ máa ṣe tinú ara rẹ̀. Ohun tí ọ̀gá rẹ̀ bá fẹ́ ló gbọ́dọ̀ máa fi sí ipò àkọ́kọ́. Ìyẹn fi hàn pé nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ńṣe la pinnu pé ohun tó wù ú la ó máa fi sípò àkọ́kọ́. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

KÍ NI JÈHÓFÀ FẸ́ KÍ GBOGBO WA MÁA ṢE?

11, 12. Ìwà wo ló yẹ kí àwa ìríjú máa hù? Irú ìwà wo ni kò yẹ ká bá lọ́wọ́ wa?

11 Ohun kejì tó yẹ káwa ìríjú máa rántí nìyí: Ìlànà kan náà ni gbogbo àwa tá a jẹ́ ìríjú ń tẹ̀ lé. Òótọ́ ni pé gbogbo Kristẹni kọ́ ló ní ohun tí wọ́n ń bójú tó nínú ìjọ. Àmọ́ àwọn ohun kan wà tí Jèhófà fẹ́ kí gbogbo Kristẹni máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe pàtàkì pé kí àwa tá a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi àti Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, fẹ́ràn ara wa. Jésù sọ pé ohun táwọn èèyàn á fi máa dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ ni pé wọ́n á fẹ́ràn ara wọn. (Jòh. 13:35) Àmọ́ kì í ṣe àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan la fẹ́ràn o. A tún máa ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbogbo wa la lè fi irú ìfẹ́ yìí hàn sáwọn èèyàn, ó sì yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀.

12 Ọlọ́run tún fẹ́ ká máa ṣe ohun tó tọ́ ká má sì ṣe bá àwọn ìwà tí Bíbélì sọ pé kò dára lọ́wọ́ wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 6:9, 10) Ó gba ìsapá kéèyàn tó lè ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́. Àmọ́ tá a bá sa gbogbo ipá wa, a máa jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní kó àrùn torí pé a rú òfin Ọlọ́run, àlàáfíà máa jọba láàárín àwa àtàwọn míì, a ó sì ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.—Ka Aísáyà 48:17, 18.

13, 14. Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run gbé lé gbogbo àwa Kristẹni lọ́wọ́? Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo iṣẹ́ náà?

13 Yàtọ̀ sí pé kí ìríjú máa bójú tó àwọn ohun ìní ọ̀gá rẹ̀, ó tún ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe. Bákan náà, àwa pẹ̀lú ní púpọ̀ láti ṣe. Jèhófà fún wa ní ẹ̀bùn iyebíye ní ti pé ó jẹ́ ká lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Ó sì fẹ́ ká kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tá a mọ̀. (Mát. 28:19, 20) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ènìyàn díwọ̀n wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ́ Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 4:1) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun ní láti sọ “àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀,” tàbí ohun tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni fún àwọn èèyàn. Ohun tí Jésù Kristi tó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe nìyẹn.—1 Kọ́r. 9:16.

14 Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ràn wọn. Àmọ́, àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ò dọ́gba torí pé ipò wa yàtọ̀ síra. Jèhófà náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Torí náà, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á rí i pé tara wa nìkan kọ́ la mọ̀. Wọ́n á gbà pé a fẹ́ràn Ọlọ́run, a sì fẹ́ràn àwọn náà.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

15-17. (a) Kí nìdí tí ìríjú fi gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́? (b) Kí ni Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá jẹ́ aláìṣòótọ́?

15 Ohun kẹta tó yẹ kí àwa ìríjú máa rántí nìyí: A gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ìríjú kan lè ní ìwà tó dáa kó sì tún já fáfá, síbẹ̀ gbogbo èyí ò ní já mọ́ nǹkan kan bó bá ya aláìgbọràn tó sì ń ṣe ìmẹ́lẹ́. Bí ìríjú kan bá fẹ́ ṣàṣeyọrí tó sì fẹ́ rí ojúure ọ̀gá rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́. Rántí pé Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun tí a ń retí nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn ní olùṣòtítọ́.”—1 Kọ́r. 4:2.

16 Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, ó dájú pé Ọlọ́run á san wá lẹ́san rere. Àmọ́, tá a bá jẹ́ aláìṣòótọ́, a kò ní rí ojú rere Ọlọ́run. Èyí ṣe kedere nínú ìtàn tí Jésù sọ nípa àwọn ẹrú tí ọ̀gá wọn fún ní tálẹ́ńtì. Ọ̀gá àwọn ẹrú náà yin àwọn ẹrú rẹ̀ tó jẹ́ olùṣòtítọ́, tí wọ́n fi owó rẹ̀ “ṣòwò,” ó sì yàn wọ́n sípò lórí ohun tó pọ̀. Àmọ́ ó sọ fún ẹrú tó ṣàìgbọràn náà pé ó jẹ́ “ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra.” Ó sì tún sọ pé ó jẹ́ ẹrú “tí kò dára fún ohunkóhun.” Ọ̀gá rẹ̀ gba tálẹ́ńtì kan yẹn kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n gbé ẹrú náà jù síta.—Ka Mátíù 25:14-18, 23, 26, 28-30.

17 Jésù tún sọ ìtàn míì tó jẹ́ ká mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tá a bá jẹ́ aláìṣòótọ́. Ó sọ pé: “Ọkùnrin kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, ó sì ní ìríjú kan, a sì fi ẹ̀sùn kan ẹni yìí lọ́dọ̀ rẹ̀ pé ó ń fi àwọn ẹrù rẹ̀ ṣòfò. Nítorí náà, ó pè é, ó sì wí fún un pé, ‘Kí ni ohun tí mo gbọ́ nípa rẹ yìí? Gbé àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìríjú rẹ wá, nítorí ìwọ kò lè mójú tó ilé yìí mọ́.’” (Lúùkù 16:1, 2) Torí pé ẹrú yìí fi àwọn ohun ìní ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò, ọ̀gá rẹ̀ lé e dà nù. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ìtàn yìí kọ́ wa ni pé ká máa jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá ní ká ṣe.

ṢÓ DÁA KÁ MÁA FI ARA WA WÉ ÀWỌN ẸLÒMÍÌ?

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì?

18 Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa bi ara rẹ̀ pé, ‘Irú ìríjú wo ni mo jẹ́?’ Àmọ́ kò yẹ ká máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.” (Gál. 6:4) Dípò tí a ó fi máa fi ohun tá à ń ṣe wé tàwọn ẹlòmíì, ńṣe ló yẹ ká máa wá bá a ṣe lè sunwọ̀n sí i. Ìyẹn ò ní jẹ́ ká di agbéraga tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì. Ohun kan ni pé a lè má lè ṣe tó bá a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nítorí àìsàn, ọjọ́ ogbó, tàbí àwọn ohun àìgbọ́dọ̀máṣe mìíràn. Àmọ́ bí àyè bá ṣí sílẹ̀ fún wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ńkọ́? Ṣé a kúkú lè gbìyànjú láti ṣe púpọ̀ sí i?

19. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì bí a kò bá tíì ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?

19 Kò tún yẹ ká máa fi ara wa wé àwọn tó ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó wu àwa náà pé ká ní. Bí àpẹẹrẹ, ó lè wu arákùnrin kan pé kó di alàgbà tàbí kó jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ ní àwọn àpéjọ àkànṣe, àyíká àti ti àgbègbè. Kò sí ohun tó burú níbẹ̀ tá a bá sapá gidigidi ká lè ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí. Àmọ́ kò yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì bí a kò bá ní wọn nígbà tá a fojú sí. Nítorí àwọn ìdí tó lè má ṣe kedere sí wa, ó lè pẹ́ ká tó ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. Rántí pé Mósè ti rò pé ó ti tó àkókò tí òun máa kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Àmọ́ ó ṣì ní láti dúró fún ogójì ọdún lẹ́yìn ìgbà náà. Ní gbogbo ìgbà tó fi ń dúró yẹn, ó kẹ́kọ̀ọ́ ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù àtàwọn ànímọ́ míì tó máa nílò lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn kó tó lè jẹ́ aṣáájú fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ àti alágídí.—Ìṣe 7:22-25, 30-34.

20. Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tí Jónátánì ṣe?

20 Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tiẹ̀ lè má tẹ̀ wá lọ́wọ́ rárá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónátánì nìyẹn. Òun ni ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù tó yẹ kó di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀. Àmọ́ Dáfídì tó kéré sí i ni Ọlọ́run yàn pé kó jọba. Kí ni Jónátánì ṣe? Ó fara mọ́ ìpinnu Ọlọ́run, kódà ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè ran Dáfídì lọ́wọ́. Ó sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ ni yóò sì jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ.” (1 Sám. 23:17) Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí Jónátánì ṣe yìí? Jónátánì ò ráhùn pé òun ni ipò ọba tọ́ sí. Kò sì dà bíi bàbá rẹ̀ tó jowú Dáfídì. Dípò tí a ó fi máa jowú àwọn ẹlòmíì torí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ní, ó yẹ kí gbogbo wa gbájú mọ́ iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún wa, ká sì máa wá bá a ṣe lè túbọ̀ já fáfá. Ó dájú pé nínú ayé tuntun, gbogbo ohun rere táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fẹ́ ló máa ṣe fún wọn.

21. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo iṣẹ́ ìríjú wa?

21 Ẹ jẹ́ ká máa rántí nígbà gbogbo pé ìríjú tá a fọkàn tán ni wá, a kì í ṣe ẹrú tí wọ́n ń fipá mú láti sìnrú fún ọ̀gá rírorò. Jèhófà fọkàn tán wa ó sì fi iṣẹ́ pàtàkì dá wa lọ́lá. Ó ní ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí títí tí òun fi máa sọ pé ó tó. Ó tún fún wa ní òmìnira láti yan ọ̀nà tá a máa gbà bójú tó iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́. Torí náà, gẹ́gẹ́ bí ìríjú, ẹ jẹ́ ká jẹ́ olùṣòtítọ́. Ká má sì ṣe gbàgbé láé pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ fún wa láti máa sin Jèhófà, Ẹni títóbi lọ́lá jù lọ láyé àtọ̀run.