Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni

Kí Ló Ń Mú Káyé Yẹni

“Ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere . . . ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.”—JÓṢ. 1:8.

1, 2. (a) Ta ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń kà sí ẹni tí ayé yẹ? (b) Báwo lo ṣe lè mọ ẹni tó o kà sí ẹni tí ayé yẹ?

 TA NI ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń kà sí ẹni táyé yẹ? Tó o bá bi àwọn èèyàn ní ìbéèrè yìí, onírúurú ìdáhùn ni wọ́n máa fún ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ẹni táyé yẹ ni ẹni tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, tó níṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́, tó kàwé tó sì gboyè rẹpẹtẹ. Àwọn míì gbà pé kéèyàn gbayì láàárín ẹbí àtọ̀rẹ́ àti lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ló ń mú káyé yẹni. Ẹnì kan tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà sì lè gbà pé ohun tó ń mú káyé yẹni ni pé kéèyàn jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà tàbí kéèyàn ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ títí tí wọ́n fi ṣèrìbọmi.

2 Ta lo kà sí ẹni tí ayé yẹ? Bó o ṣe lè mọ̀ ni pé kó o kọ orúkọ àwọn èèyàn mélòó kan tó o gba tiwọn, tó o bọ̀wọ̀ fún, tó o sì rò pé ayé yẹ. Irú èèyàn wo ni wọ́n? Ṣé ọlọ́rọ̀ ni wọ́n àbí gbajúmọ̀? Ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí ló máa jẹ́ kó o mọ ẹni tó o kà sí ẹni tí ayé yẹ. Ìdí sì ni pé ẹni tó o bá kà sí pàtàkì lo máa fẹ́ fìwà jọ, wàá sì fẹ́ ní àfojúsùn tó jọ tirẹ̀.—Lúùkù 6:45.

3. (a) Kí ni Jóṣúà gbọ́dọ̀ ṣe kí ọ̀nà rẹ̀ lè yọrí sí rere? (b) Kí la máa jíròrò báyìí?

3 Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí Jèhófà kà wá sí ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ yọrí sí rere. Ìdí sì ni pé ìgbà yẹn la tó lè jogún ìyè ayérayé. Nígbà tí Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé kó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, ó sọ fún un pé kó máa ka Òfin Mósè ní “ọ̀sán àti ní òru” kó sì máa ṣègbọràn sí ohun tó wà nínú òfin náà. Ó wá sọ fún un pé: “Nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.” (Jóṣ. 1:7, 8) Ọ̀nà Jóṣúà sì yọrí si rere lóòótọ́. Kódà, ayé yẹ ẹ́. Ṣé àwa náà gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ẹni tí Ọlọ́run gbà pé ayé yẹ làwa náà gbà pé ayé yẹ? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìtàn ìgbésí ayé àwọn ọkùnrin méjì kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn.

ǸJẸ́ AYÉ YẸ SÓLÓMỌ́NÌ?

4. Kí ló mú kí ayé yẹ Sólómọ́nì?

4 Ayé yẹ Sólómọ́nì gan-an. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ní ìbẹ̀rù Jèhófà tó sì ṣègbọràn sí i. Látàrí ìyẹn, Jèhófà fìbùkún sí iṣẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Rántí pé nígbà tí Jèhófà ní kí Sólómọ́nì béèrè ohunkóhun tó bá fẹ́, ọgbọ́n tó máa fi ṣàkóso àwọn èèyàn náà ló béèrè. Ọlọ́run dáhùn àdúrà rẹ̀, ó sì fún un ní ọgbọ́n àti ọrọ̀. (Ka 1 Àwọn Ọba 3:10-14.) Ọgbọ́n Sólómọ́nì “pọ̀ jaburata ju ọgbọ́n gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn àti ju gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.” Òkìkí Sólómọ́nì kàn yí ká “gbogbo orílẹ̀-èdè.” (1 Ọba 4:30, 31) Ó tún ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ. Owó tó ń rí lórí wúrà nìkan lọ́dún tó bílíọ̀nù márùn-dín-lọ́gọ́jọ [155,000,000,000] náírà! (2 Kíró. 9:13) Ó kọ́ ọ̀pọ̀ ilé rírẹwà. Ó fi ọgbọ́n bá àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká lò, ó sì máa ń bá wọn ṣòwò. Ayé yẹ Sólómọ́nì ní gbogbo ìgbà tó fi ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.—2 Kíró. 9:22-24.

5. Kí ni Sólómọ́nì sọ nípa ohun tó lè mú kí ayé yẹni?

5 Ohun tí Sólómọ́nì sọ nínú ìwé Oníwàásù fi hàn pé ó mọ ohun tó ń mú káyé yẹni. Kò gbà pé ọrọ̀ àti agbára nìkan ló ń fúnni láyọ̀ tó sì ń mú káyé yẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé ẹni; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Oníw. 3:12, 13) Sólómọ́nì sì tún wá gbà pé ìgbà téèyàn bá ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan ni àwọn ohun rere tó bá rí tó lè mú kó ní ojúlówó ayọ̀. Abájọ tí Sólómọ́nì fi sọ pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníw. 12:13.

6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì ní ọrọ̀, ọgbọ́n, òkìkí àti agbára nígbà tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kí ló sọ? Kí nìyẹn kọ́ wa nípa ohun tó ń mú káyé yẹni?

6 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Sólómọ́nì fi ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó sì ṣègbọràn sí i. Bíbélì sọ pé ó “ń bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa rírìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ Dáfídì baba rẹ̀.” (1 Ọba 3:3) Nǹkan ṣẹnuure fún un ní gbogbo ìgbà yẹn. Ọlọ́run tún ní kó kọ́ tẹ́ńpìlì ńlá kan táwọn èèyàn á ti máa ṣe ìjọsìn mímọ́, ó sì tún ní kó kọ mẹ́ta lára àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì. Òótọ́ ni pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe bíi ti Sólómọ́nì. Àmọ́, bí nǹkan ṣe rí fún un nígbà tó jẹ́ olóòótọ́ á jẹ́ ká mọ ẹni tá a lè sọ pé ayé yẹ lóòótọ́ àti ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe kí ayé lè yẹ àwa náà. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti kọ̀wé nípa ọrọ̀, ọgbọ́n ayé, òkìkí àti agbára. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń rò pé ó pọn dandan kéèyàn ní àwọn nǹkan wọ̀nyẹn káyé tó lè yẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì ní wọn, ó sọ pé ńṣe ni àwọn tó bá ń ṣiṣẹ́ àṣekára kí wọ́n lè ní àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ‘ń lépa ẹ̀fúùfù,’ tàbí pé ńṣe ni wọ́n ń wá bí ọwọ́ wọn ṣe máa tẹ ohun tí kò lè fún wọn ní ojúlówó ayọ̀. Òótọ́ nìyẹn. Torí pé owó kì í tó olówó. Àwọn olówó sì máa ń bẹ̀rù pé káwọn má di olówó àná. Àti pé bópẹ́ bóyá, àwọn míì ló máa jogún gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n kó jọ.—Ka Oníwàásù 2:8-11, 17; 5:10-12.

7, 8.  Báwo ni Sólómọ́nì ṣe di aláìṣòótọ́? Kí ni àìṣòótọ́ rẹ̀ yọrí sí?

7 Nígbà tí Sólómọ́nì di arúgbó, ó di aláìṣòótọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń darúgbó lọ pé àwọn aya rẹ̀ alára ti tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà Dáfídì baba rẹ̀. . . . Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.”—1 Ọba 11:4-6.

8 Inú Jèhófà kò dùn sí ohun tí Sólómọ́nì ṣe yìí, ó sì sọ fún un pé: “Nítorí ìdí náà pé . . . ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ìlànà àgbékalẹ̀ mi tí mo gbé kalẹ̀ ní àṣẹ fún ọ, láìkùnà, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, dájúdájú, èmi yóò sì fi í fún ìránṣẹ́ rẹ.” (1 Ọba 11:11) Àgbákò ńlá gbáà mà lèyí o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì ti ṣe àṣeyọrí ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, ó pàpà ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́. Látàrí èyí, ó kùnà láti máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. A lè wá bi ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa fi ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì ṣe àríkọ́gbọ́n?’

OHUN TÓ Ń MÚ KÁYÉ YẸNI

9. Ǹjẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé máa gbà pé ayé yẹ Pọ́ọ̀lù? Ṣàlàyé.

9 Ìgbésí ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yàtọ̀ pátápátá sí ti Sólómọ́nì Ọba. Pọ́ọ̀lù ò gbé láàfin ọba, kò sì bá àwọn ọba ṣe fàájì. Kódà, àwọn ìgbà míì wà tí ebi pa á, tí òùngbẹ gbẹ ẹ́, tí òtútù mú un, tó sì tún wà ní ìhòòhò. (2 Kọ́r. 11:24-27) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, àwọn ẹlẹ́sìn Júù ò fojúure wò ó mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù kórìíra rẹ̀. Wọ́n fi í sẹ́wọ̀n, wọ́n fi ọ̀pá nà án, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta. Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ àtàwọn Kristẹni yòókù pé wọ́n kẹ́gàn àwọn, wọ́n ṣenúnibíni sáwọn, wọ́n sì ba àwọn lórúkọ jẹ́. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “A ti wá dà bí pàǹtírí ayé, ohun ìtanù nínú ohun gbogbo, títí di ìsinsìnyí.”—1 Kọ́r. 4:11-13.

10. Àǹfààní wo ni Pọ́ọ̀lù ní, àmọ́ kí ló ṣe?

10 Látìgbà tí Pọ́ọ̀lù ti wà ní ọ̀dọ́ ló ti jọ pé ó ní àǹfààní láti rí towó ṣe. Ó jọ pé inú ìdílé tó gbajúmọ̀ ni wọ́n bí i sí. Ó kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì, tó jẹ́ olùkọ́ òfin táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún. Ó wá sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Mo sì ń ní ìtẹ̀síwájú púpọ̀ nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn ojúgbà mi.” (Gál. 1:14) Pọ́ọ̀lù mọ èdè Hébérù àti Gíríìkì sọ dáadáa. Ó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Róòmù, èyí tó mú kó ní ọ̀pọ̀ àǹfààní àti ẹ̀tọ́ táyé ń fẹ́. Bó bá jẹ́ pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe máa rọ́wọ́ mú nínú ayé ló ń wá ni, ó ṣeé ṣe kó ti dé ipò ọlá kó sì ti lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ohun tó yàtọ̀ síyẹn ló yàn láti fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Látàrí ìyẹn, ó jọ pé àwọn kan lára àwọn ìbátan rẹ̀ pàápàá rò pé orí rẹ̀ ti yí. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù yàn láti ṣe ohun tó yàtọ̀?

11. Kí ni Pọ́ọ̀lù kà sí pàtàkì? Kí ni Pọ́ọ̀lù fi ṣe àfojúsùn rẹ̀?

11 Pọ́ọ̀lù kò fẹ́ láti di ọlọ́rọ̀ àti olókìkí. Ìdí sì ni pé ó fẹ́ràn Jèhófà, ó sì wù ú kó rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Nígbà tó lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì àwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà nígbà yẹn kò mọ̀ tàbí tí wọn kò kà sí pàtàkì. Irú bí ẹbọ ìràpadà Kristi, iṣẹ́ ìwàásù àti àǹfààní láti bá Jésù jọba lọ́run. Pọ́ọ̀lù tún mọ̀ pé Sátánì ti fi ẹ̀sùn kan gbogbo ẹ̀dá pé bí wọ́n bá rí ìṣòro, wọn ò ní sin Jèhófà mọ́. Ó sì mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ sapá kóun lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Jóòbù 1:9-11; 2:3-5) Torí náà, Pọ́ọ̀lù fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ pé òun á máa sin Ọlọ́run òtítọ́ láìyẹsẹ̀ àti láìka ìṣòro yòówù kó dé bá òun sí. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó fẹ́ ṣàṣeyọrí kì í fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe àfojúsùn wọn.

12. Kí nìdí tó o fi gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?

12 Ṣé ìwọ náà ní irú àfojúsùn tí Pọ́ọ̀lù ní? Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́, tá a bá jẹ́ olóòótọ́, inú Jèhófà máa dùn sí wa, a ó sì rí ìbùkún rẹ̀. Irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ ló sì máa ń jẹ́ káyé yẹni. (Òwe 10:22) Ìbùkún yẹn ò wá ní mọ sí àkókò tá a wà yìí nìkan, a óò tún máa gbádùn rẹ̀ nìṣó lọ́jọ́ iwájú. (Ka Máàkù 10:29, 30.) Torí náà, kò yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé “ọrọ̀ àìdánilójú.” Ọlọ́run tó “ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa” ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú gbangba pé á máa jogún “ìyè tòótọ́” tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún wa. (1 Tím. 6:17-19) Láìsí àní-àní, ní ọgọ́rùn-ún ọdún sígbà tá a wà yìí, kódà ní ẹgbẹ̀rún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti rántí bá a ṣe gbé ìgbé ayé wa nísinsìnyí, ká sì sọ pé, “Ayé yẹ mí lóòótọ́!”

IBI TÍ ÌṢÚRA RẸ BÁ WÀ

13. Kí ni Jésù sọ nípa títo ìṣúra pa mọ́?

13 Jésù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. Nítorí pé ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.”—Mát. 6:19-21.

14. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn tó ìṣúra jọ lórí ilẹ̀ ayé?

14 Owó nìkan kọ́ ni ìṣúra tí ẹnì kan lè tò jọ lórí ilẹ̀ ayé. Ó lè jẹ́ èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tí Sólómọ́nì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, táwọn èèyàn sì rò pé òun ló ń mú káyé yẹni. Irú bí ipò iyì, òkìkí, tàbí agbára. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fara jọ èyí tí Sólómọ́nì sọ nínú ìwé Oníwàásù. Ọrọ̀ téèyàn bá tò jọ lórí ilẹ̀ ayé kì í tọ́jọ́. Gbogbo wa la sì mọ̀ pé ọrọ̀ tó wà lónìí lè pòórá tó bá dọ̀la. Ọ̀jọ̀gbọ́n F. Dale Bruner ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa títo ìṣúra jọ. Ó ní: “Òkìkí ò láyọ̀lé. Ẹni táyé ń fẹ́ lónìí lè dẹni ìgbàgbé bó dọ̀la. Ẹni tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ lónìí lè dẹni tí ń ráágó bó dọ̀la. . . . Torí pé [Jésù] fẹ́ràn àwa èèyàn, ó kìlọ̀ fún wa nípa ìbànújẹ́ ọkàn téèyàn máa ń ní bí ọlá bá wọmi. ‘Ojoojúmọ́ làwọn tó ń lépa ọrọ̀ àti òkìkí máa ń ti ìka àbámọ̀ bọnu.’ Jésù ò sì fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà pé kò sírọ́ nínú àlàyé tí ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ṣe. Àmọ́, ẹni mélòó ló máa torí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ṣíwọ́ ṣíṣe kìràkìtà nítorí àtidi ọlọ́rọ̀? Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Jésù yìí mú kó o tún èrò ara rẹ pá?

15. Tá a bá fẹ́ káyé yẹ wá, kí ló yẹ ká máa fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún?

15 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan máa ń wàásù fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kì í ṣe ohun tó dáa kéèyàn máa sapá láti wá bí nǹkan á ṣe ṣẹnuure fúnni. Àmọ́ Jésù kò sọ pé ó burú láti wá bí nǹkan á ṣe ṣẹnuure fúnni o! Ohun tó ń sọ ni pé ohun tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bí ẹni táyé yẹ ló yẹ kí wọ́n máa fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé kí wọ́n to “ìṣúra” tí kì í bà jẹ́ “jọ pa mọ́ fún ara [wọn] ní ọ̀run.” Ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún ni pé kí Jèhófà kà wá sí ẹni táyé yẹ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ rán wa létí pé ọwọ́ wa ló kù sí láti pinnu ohun tá a máa fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún. Òótọ́ tó sì wà níbẹ̀ ni pé ohun tó bá wà lọ́kàn wa tàbí ohun tá a bá kà sí pàtàkì, la sábà máa ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún.

16. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?

16 Tá a bá fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ ká lè ṣe ohun tó wu Jèhófà, ó yẹ kó dá wa lójú pé ó máa fún wa ní àwọn ohun tá a bá ṣaláìní. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìgbà míì wà tí ebi lè pa wá tàbí kí òùngbẹ gbẹ wá. (1 Kọ́r. 4:11) Síbẹ̀, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé: “Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mát. 6:31-33.

BÓ O ṢE LÈ DI ẸNI TÁYÉ YẸ LÓJÚ ỌLỌ́RUN

17, 18. (a) Kí ló ń mú káyé yẹni? (b) Àwọn nǹkan wo ni kò pọn dandan kéèyàn ní káyé tó yẹni?

17 Ohun tó yẹ ká rántí ni pé kì í ṣe bí àwọn ohun ńlá tá a gbé ṣe ṣe pọ̀ tó tàbí bá a ti ṣe pàtàkì tó ló ń fi hàn pé ayé yẹ wá. Bákan náà, kì í ṣe bí ojúṣe tá a ní nínú ìjọ ṣe pọ̀ tó ló ń mú káyé yẹni. Bá a ṣe ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run tá a sì jẹ́ olóòótọ́ ló ń mú ká ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí a ń retí nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn ní olùṣòtítọ́.” (1 Kọ́r. 4:2) A sì gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mát. 10:22) Àbí ayé tún lè yẹ èèyàn ju pé kó rí ìgbàlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

18 Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé ohun tó ń mú káyé yẹni ni pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la sì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, láìka ipò tá a wà sí. Kò dìgbà tá a bá lókìkí, tá a bá kàwé rẹpẹtẹ tàbí tá a lówó lọ́wọ́ bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ká tó lè jẹ́ olóòótọ́. Kódà, bá ò tiẹ̀ gbajúmọ̀ láwùjọ, tá ò ní òye àti ẹ̀bùn tó pọ̀, tàbí tí a kò fi bẹ́ẹ̀ já fáfá, a ṣì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ní ọ̀rúndún kìíní, àtolówó àti òtòṣì ló wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ pé kí wọ́n ‘máa ṣe rere, kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí wọ́n má ṣahun, kí wọ́n sì múra tán láti ṣe àjọpín.’ Àmọ́, àtàwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn òtòṣì ni “wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tím. 6:17-19) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Àǹfààní kan náà ni gbogbo wa ní, ojúṣe kan náà la sì ní. Ìyẹn ni pé ká máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ ká sì “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá máa kà wá sí ẹni tí ayé yẹ, a ó sì máa láyọ̀ pé à ń ṣe ohun tó wù ú.—Òwe 27:11.

19. Kí lo pinnu láti ṣe káyé lè yẹ ọ́?

19 A lè má lè ṣe ohunkóhun nípa ojú tí ayé fi ń wò wá, àmọ́ ohun tá a lè ṣe wà nípa ojú tá a fi ń wo ara wa. Yálà o jẹ́ olówó tàbí òtòṣì, ayé lè yẹ ọ́, bó o bá ṣáà ti ń sapá kó o bàa lè jẹ́ olóòótọ́. O ò sì ní kábàámọ̀ pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe. Wàá rí ìbùkún tó pọ̀ gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, nísinsìnyí àti títí láé. Má ṣe gbàgbé pé Jésù sọ fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.” (Ìṣí. 2:10) Àṣeyọrí ńlá mà nìyẹn o!