Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí èmi àti ìyàwó mi tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ojú ọmọ pọ́n wa díẹ̀. Torí náà, a gbà kí àwọn dókítà da àtọ̀ mi àti ẹyin ara ìyàwó mi pọ̀ kí wọ́n sì gbé e sínú ìgò. Nígbà tó di ọlẹ̀, wọ́n fi ọgbọ́n ìṣègùn gbé e sínú ilé ọmọ ìyàwó mi. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ọlẹ̀ náà ni wọ́n lò tán. Wọ́n tọ́jú díẹ̀ tó kù sínú yìnyín. Ṣé kí wọ́n ṣì tọ́jú rẹ̀ ni àbí kí wọ́n dà á nù?

Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn tó máa ń ṣòro fún àwọn tọkọtaya láti ṣèpinnu lé lórí tí wọ́n bá yàn láti bímọ lọ́nà yìí. Ó kù sọ́wọ́ tọkọtaya kọ̀ọ̀kan láti ronú lórí ohun tí Jèhófà fẹ́, kí wọ́n tó pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Àmọ́, ó máa dáa kí wọ́n mọ báwọn dókítà ṣe máa ń ṣe é.

Ọdún 1978 ni obìnrin kan kọ́kọ́ bí ọmọ lọ́nà yìí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ibi tí ẹyin ń gbà dé ilé ọmọ obìnrin náà ti dí, àtọ̀ ò sì lè ráyè dà pọ̀ mọ́ ẹyin. Àwọn dókítà ṣe iṣẹ́ abẹ fún un. Wọ́n mú ẹyin nínú ilé ẹyin rẹ̀, wọ́n da àtọ̀ látara ọkọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n wá gbé e sínú ìgò níbi tó ti di ọlẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi ọgbọ́n ìṣègùn gbé ọlẹ̀ yìí látinú ìgò sínú ilé ọmọ obìnrin náà, kó lè máa dàgbà nìṣó níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó doyún, ó sì fi bí ọmọbìnrin kan. Bó ṣe di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀nà yìí àtàwọn ọ̀nà míì tó jọ ọ́ láti gbé ọlẹ̀ sínú àwọn obìnrin kí wọ́n lè finú ṣoyún nìyẹn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń ṣe é ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, ọ̀nà tó wọ́pọ̀ jù lọ tí wọ́n ń gbà ṣe é nìyí: Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ kí wọ́n tó ṣe é fún obìnrin kan, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fún un ní àwọn oògùn tó máa jẹ́ kí ilé ẹyin rẹ̀ mú ẹyin tó pọ̀ jáde. Wọ́n á ní kí ọkọ obìnrin náà da àtọ̀ rẹ̀ sínú ìgò kékeré kan kó sì gbé e wá. Wọ́n á wá lo ọgbọ́n ìṣègùn láti da ẹyin àti àtọ̀ náà pọ̀ mọ́ra wọn. Ẹyin tó máa di ọlẹ̀ lè ju ẹyọ kan lọ. Wọ́n á jẹ́ kó wà níbẹ̀ fún bí ọjọ́ kan. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá fara balẹ̀ yẹ̀ wọ́n wò kí wọ́n lè mọ àwọn tí kò dára àtàwọn tó dà bíi pé wọ́n lè di ọlẹ̀. Tó bá fi máa tó ọjọ́ kẹta, wọ́n á wá gbé ọlẹ̀ náà sínú ilé ọmọ obìnrin náà. Ọlẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta tó dára jù lọ ni wọ́n sábà máa ń gbé sínú obìnrin náà. Wọ́n gbà pé tí ọ̀kan ò bá yè, òmíràn á yè. Bí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára ọlẹ̀ náà bá dúró lára obìnrin náà, á lóyún, nígbà tó bá sì yá, á bímọ.

Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọlẹ̀ tó ṣẹ́ kù, tó fi mọ́ àwọn tó dà bíi pé kò lera tó tàbí tó lábùkù? Tí wọn kò bá lò wọ́n, wọn kò ní pẹ́ kú. Ìyẹn ni wọ́n fi máa ń kó wọn sínú yìnyín kí wọ́n má bàa bà jẹ́. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń tọ́jú àwọn ọlẹ̀ tó ṣẹ́ kù? Ìdí ni pé bí ọlẹ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ gbé sínú obìnrin kan kò bá dúró sí i lára, wọ́n lè lò lára èyí tó kù, ìyẹn ò sì ní ná wọn lówó púpọ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló máa ń jẹ yọ látàrí èyí. Bíi ti tọkọtaya tó béèrè ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló máa ń ṣòro fún láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ kí àwọn dókítà ṣe nípa àwọn ọlẹ̀ tó ṣẹ́ kù tí wọ́n tọ́jú sínú yìnyín. Ìdí sì ni pé wọ́n lè máà fẹ́ bímọ míì. Wọ́n lè ti dàgbà jù láti máa ṣe wàhálà ọmọ títọ́. Ó sì lè jẹ́ pé wọn kò ní owó mọ́ láti fi ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kódà, ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé wọ́n lè fi oyún náà bí ìbejì tàbí iye ọmọ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ. * Ìṣòro tún lè wáyé bí ọkọ tàbí ìyàwó bá kú, tàbí tí ọ̀kan nínú wọn bá lọ fẹ́ ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni kò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe lórí ọ̀ràn yìí, torí náà ńṣe ni wọ́n ń san owó fáwọn dókítà láti máa tọ́jú àwọn ọlẹ̀ náà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Lọ́dún 2008, ọ̀gá àgbà kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọlẹ̀ sọ nínú ìwé ìròyìn The New York Times, pé ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti pinnu bí wọ́n ṣe máa ṣe àwọn ọlẹ̀ tó ṣẹ́ kù. Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé: “Ó kéré tán, ọlẹ̀ tí ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà irinwó [400,000] ni wọ́n ṣì tọ́jú sínú yìnyín ní àwọn ilé ìwòsàn ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ojoojúmọ́ ló sì ń pọ̀ sí i . . . Bí wọ́n bá tọ́jú ọlẹ̀ sínú yìnyín bó ṣe yẹ, ó lè wà níbẹ̀ fún ọdún mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí kò sì ní bà jẹ́. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ló máa ń yè nígbà tí wọ́n bá gbé wọn kúrò nínú yìnyín.” Gbólóhùn tó gbẹ̀yìn yẹn fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ọlẹ̀ náà ló máa ń yè nígbà tí wọ́n bá gbé wọn kúrò nínú yìnyín. Èyí ti mú kí àwọn Kristẹni kan rí i pé ọ̀rọ̀ yìí gbàrònú gan-an ni. Kí nìdí?

Tó bá ṣòro fún tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe lórí ọ̀ràn yìí, ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n ronú lórí ọ̀ràn ìṣègùn míì tó yàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè pọn dandan pé kí Kristẹni kan pinnu ohun tó máa ṣe sí ọ̀rọ̀ èèyàn rẹ̀ kan tó ń kú lọ, tó sì jẹ́ pé ẹ̀rọ ló fi ń mí. Ìdí sì ni pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi ìlera wọn ṣeré. Kódà, nítorí ohun tó wà ní Ẹ́kísódù 20:13 àti Sáàmù 36:9, ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi mú ọ̀ràn ẹ̀mí. Ìwé ìròyìn Jí! sọ pé: “Àwọn tó ń fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì gbà pé Ọlọ́run ka ẹ̀mí èèyàn sí pàtàkì. Àwọn náà fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀mí èèyàn nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn àti nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣègbọràn sí àṣẹ ìjọba. Látàrí èyí, wọn kò ní gbà kí dókítà lo ọgbọ́n ìṣègùn láti gbẹ̀mí aláìsàn, yàtọ̀ sí pé ó kú fúnra rẹ̀.” (Jí! May 8, 1974, Gẹ̀ẹ́sì.) Ìgbà míì sì lè wà tí ipò èèyàn wa kan máa le débi pé, tí wọ́n bá fi lè yọ ẹ̀rọ tó fi ń mí kúrò lára rẹ̀, ńṣe ló máa kú. Èyí lè gba pé kí àwọn mọ̀lẹ́bí aláìsàn náà pinnu bóyá kí wọ́n ṣì jẹ́ kó máa fi ẹ̀rọ mí tàbí kí wọ́n jẹ́ kí dókítà yọ ọ́ kúrò lára rẹ̀.

Òótọ́ ni pé ọ̀rọ̀ àwọn tó fẹ́ bímọ, tí wọ́n sì bá wọn tọ́jú ọlẹ̀ sínú yìnyín, yàtọ̀ sí ti ẹni tó ń fi ẹ̀rọ mí. Àmọ́, àbá kan tí wọ́n lè dá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni pé, kí wọ́n gbà kí dókítà bá wọn gbé ọlẹ̀ náà kúrò nínú yìnyín. Bí ọlẹ̀ náà bá sì ti kúrò nínú yìnyín, á bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́. Nígbà tó bá yá, á kú. Àwọn tọkọtaya ló máa pinnu bóyá kí wọ́n fara mọ́ àbá yìí tàbí kí wọ́n má fara mọ́ ọn.—Gál. 6:7.

Bí tọkọtaya kan bá fẹ́ láti lo ọgbọ́n ìṣègùn yìí, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti bímọ, wọ́n lè pinnu pé àwọn á máa sanwó ìtọ́jú àwọn ọlẹ̀ tó bá ṣẹ́ kù tàbí kí wọ́n yàn láti lò wọ́n nígbà tí wọ́n bá tún fẹ́ bímọ. Ṣùgbọ́n tọkọtaya míì lè pinnu pé àwọn ò lè máa náwó lórí ìtọ́jú àwọn ọlẹ̀ náà mọ́, torí wọ́n kà á sí pé ńṣe lọ̀rọ̀ náà dà bíi ti aláìsàn kan tó ń fi ẹ̀rọ mí, tí àwọn èèyàn rẹ̀ lè pinnu bóyá kí dókítà yọ ẹ̀rọ náà tàbí kó má yọ ọ́. Àwọn Kristẹni tó bá wà ní ipò yìí gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu tí kò sì lòdì sí ìlànà Ìwé Mímọ́. Wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu táá máa da ẹ̀rí ọkàn wọn àti ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú.—1 Tím. 1:19.

Àwọn Kristẹni tó bá wà ní ipò yìí gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu tí kò sì lòdì sí ìlànà Ìwé Mímọ́.

Dókítà kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà máa ń wúwo lọ́kàn èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tọkọtaya, ó sì máa ń ṣòro fún wọn láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe sí àwọn ọlẹ̀ tí wọ́n bá wọn tọ́jú sínú yìnyín.” Ohun tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Lójú ọ̀pọ̀ tọkọtaya, ó máa ń dà bíi pé kò sí ìpinnu tá a lè sọ pé ó sàn.”

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé tí Kristẹni kan bá fẹ́ bímọ nípa lílo ọgbọ́n ìṣègùn tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó gbọ́dọ̀ ronú dáadáa nípa ọ̀pọ̀ ìṣòro tó lè jẹ yọ. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.

Ọkùnrin àtobìnrin kan tí wọ́n ti jọ ń gbé pọ̀ láì ṣègbéyàwó tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ́ láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, kò ṣeé ṣe fún wọn láti ṣègbéyàwó lọ́nà tó bófin mu torí pé ọkọ ò ní ìwé àṣẹ ìgbélùú. Ìjọba kò sì fọwọ́ sí i pé kí àwọn tó ń gbé ìlú láìgbàṣẹ ṣègbéyàwó. Ǹjẹ́ wọ́n lè kọ́kọ́ ṣe ìwé àdéhùn pé àwọn ò ní dalẹ̀ ara wọn tí àwọn bá ṣègbéyàwó, lẹ́yìn náà kí wọ́n sì ṣèrìbọmi?

Ọ̀pọ̀ lè ronú pé tí wọ́n bá ti buwọ́ lu ìwé àdéhùn náà níwájú àwọn ẹlẹ́rìí, ọ̀rọ̀ ti bùṣe nìyẹn. Àmọ́, kò bá Ìwé Mímọ́ mu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà yẹn. Ká lè lóye ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ ohun tí ìwé àdéhùn náà wà fún, bó ṣe yẹ ká lò ó àti ibi tá a ti lè lò ó.

Ọkùnrin àti obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ ṣègbéyàwó ṣùgbọ́n tí òfin orílẹ̀-èdè kò fàyè gbà wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń buwọ́ lu ìwé àdéhùn yìí níwájú àwọn ẹlẹ́rìí, nítorí ìdí tá a ṣàlàyé rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Nínú ìwé àdéhùn náà, wọ́n máa jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn ò ní dalẹ̀ ara wọn àti pé àwọn máa fẹsẹ̀ ìgbéyàwó àwọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin tí àwọn bá ti láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, ó máa wà lákọọ́lẹ̀ pé àwọn méjèèjì ti ṣàdéhùn níwájú Ọlọ́run àti èèyàn pé àwọn kò ní dalẹ̀ ara wọn. Èyí á sì mú káwọn èèyàn lè máa wo ìgbéyàwó wọn bí èyí tó bá òfin ìjọba mu.

Kí ni ìwé àdéhùn náà wà fún, ìgbà wo la sì lè lò ó? Jèhófà ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀, ọwọ́ pàtàkì ló sì fi mú un. Jésù sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:5, 6; Jẹ́n. 2:22-24) Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè [ìṣekúṣe], tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mát. 19:9) Torí náà “àgbèrè,” ìyẹn ìṣekúṣe, ni ìdí kan ṣoṣo tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí tọkọtaya fi lè kọra wọn sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọkùnrin kan ṣe ìṣekúṣe, aya ọkùnrin náà lè yàn láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tàbí kó dárí jì í. Bó bá yàn láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fẹ́ ọkùnrin míì.

Àmọ́ ṣá o, àwọn orílẹ̀-èdè kan wà, pàápàá nígbà àtijọ́, tó jẹ́ pé àwọn ẹ̀sìn tó gbilẹ̀ jù lọ níbẹ̀ kò fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó lè mú kí tọkọtaya kọra wọn sílẹ̀. Ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn èèyàn ni pé kò sí ìdí èyíkéyìí tí tọkọtaya fi lè kọra wọn sílẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ní àwọn ilẹ̀ kan tí ẹnu àwọn ẹlẹ́sìn ti tólẹ̀, ìjọba ò ṣe òfin kankan tó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀, kódà bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣe àgbèrè. Láwọn ilẹ̀ míì sì rèé, ìjọba fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó máa ń pẹ́ kéèyàn tó rí ìwé ìkọ̀sílẹ̀ gbà. Ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kéèyàn tó rí i gbà. Èyí mú kó jọ pé ńṣe ni ẹ̀sìn tó gbilẹ̀ àti ìjọba ń “dí” àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí òfin Ọlọ́run fàyè gbà.—Ìṣe 11:17.

Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan lè máa gbé ní orílẹ̀-èdè kan tí wọn ò ti lè kọra wọn sílẹ̀ tàbí tó ti ṣòro láti rí ìwé ìkọ̀sílẹ̀ gbà, tàbí kó tiẹ̀ gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó lè rí i gbà. Kí ni wọ́n lè ṣe? Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó ṣe láti kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ àtijọ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ní òmìnira tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti fẹ́ ẹlòmíì, wọ́n lè buwọ́ lu ìwé àdéhùn kan tó máa fi hàn pé wọn kò ní dalẹ̀ ara wọn. Ètò tó fi àánú hàn lèyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni tó bá ń gbé ní irú orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, a kò ṣe ètò yìí nítorí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣeé ṣe láti rí ìwé ìkọ̀sílẹ̀ gbà, kódà bí gbígbà ìwé ìkọ̀sílẹ̀ bá máa ná wọn lówó gọbọi tàbí kó gba ọ̀pọ̀ wàhálà.

Àwọn kan tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè tí ìjọba ti fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀ kò lóye ohun tí ìwé àdéhùn yìí wà fún, torí náà wọ́n máa ń fẹ́ láti buwọ́ lù ú nítorí kò rọrùn láti rí ìwé ìkọ̀sílẹ̀ gbà lọ́dọ̀ ìjọba.

Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká pa dà sórí ìbéèrè tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ọkùnrin àti obìnrin tó ń bára wọn gbé pọ̀ náà fẹ́ láti ṣègbéyàwó. Àwọn méjèèjì ní òmìnira láti ṣègbéyàwó ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn méjèèjì tó ní ọkọ tàbí aya mìíràn. Àmọ́, ọkùnrin náà kò ní ìwé àṣẹ ìgbélùú, ìjọba ò sì fọwọ́ sí i pé kí ẹni tó ń gbé ìlú láìgbàṣẹ ṣègbéyàwó. (Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn aláṣẹ máa ń gbà pé kí ọkùnrin àti obìnrin ṣègbéyàwó bí ọ̀kan nínú wọn tàbí àwọn méjèèjì kò bá tiẹ̀ ní ìwé àṣẹ ìgbélùú.) Ṣùgbọ́n ní ti ọkùnrin tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, orílẹ̀-èdè tó wà fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀. Látàrí ìyẹn, kò sí ìdí láti buwọ́ lu ìwé àdéhùn. Torí kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ gba ìwé ìkọ̀sílẹ̀ àmọ́ tí wọn kò rí i gbà. Àwọn méjèèjì lómìnira láti ṣe ìgbéyàwó. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ni wọ́n lè ṣe níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe ní ọkùnrin náà ń gbé ìlú láìgbàṣẹ? Wọ́n lè lọ sí ibòmíì tí ọkùnrin náà kò ti nílò ìwé àṣẹ ìgbélùú, tàbí kí wọ́n ṣègbéyàwó ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ọkùnrin náà bá ṣe tán láti gba ìwé àṣẹ ìgbélùú.

Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa ṣeé ṣe fún àwọn méjèèjì láti pa òfin Ọlọ́run àti ti Késárì mọ́. (Máàkù 12:17; Róòmù 13:1) A nírètí pé wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa tóótun láti ṣèrìbọmi.—Héb. 13:4.

^ Tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé abirùn ọmọ ni wọ́n máa fi oyún náà bí ńkọ́? Tàbí, tó bá fi hàn pé wọn máa fi oyún náà bí ìbejì tàbí iye ọmọ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ ńkọ́? Bí tọkọtaya kan bá fọwọ́ sí i pé kí dókítà mú kí oyún náà wálẹ̀, a jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́yún nìyẹn. Nítorí pé ọgbọ́n ìṣègùn yìí máa ń mú kí wọ́n gbé ọlẹ̀ tó ju ẹyọ kan lọ sínú obìnrin, ó sábà máa ń mú kí wọ́n ní oyún ìbejì tàbí iye ọmọ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí léwu gan-an, ó lè mú kí obìnrin náà bímọ ní kògbókògbó tàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa dà lára rẹ̀. Tí obìnrin kan bá ní oyún ìbejì tàbí iye ọmọ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn dókítà lè rọ̀ ọ́ pé kó jẹ́ káwọn pa ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ọlẹ̀ náà. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́yún. Wọ́n sì ti di apààyàn nìyẹn.—Ẹ́kís. 21:22, 23; Sm. 139:16.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Àwọn Kristẹni tó bá wà ní ipò yìí gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu tí kò sì lòdì sí ìlànà Bíbélì