ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ January 2013

Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà nínú Bíbélì.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní Norway

Báwo ni ìbéèrè kan tó wá láìròtẹ́lẹ̀ ṣe mú kí ìdílé kan kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i?

Jẹ́ Onígboyà, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!

O lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jóṣúà, Jèhóádà, Dáníẹ́lì àtàwọn míì tó ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n sì nígboyà.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú ẹ Jìnnà Sí Jèhófà

Wàá rí ohun tá jẹ́ kó o ṣèpinnu tó tó nípa iṣẹ́, eré ìnàjú àti ọ̀rọ̀ ìdílé.

Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà

Báwo la ṣe lè sún mọ́ Jèhófà nípa fífi ọwọ́ tó tọ́ mú ẹ̀rọ ìgbàlódé, ọ̀rọ̀ ìlera àti owó? Kí ni kò ní jẹ́ ká di agbéraga?

O Lè Sin Jèhófà Kó o Má Sì Kábàámọ̀

Nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó ṣe àwọn àṣìṣe ńlá, ó sì tún ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ rẹ̀?

Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’

Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà gbà ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

Ọmọbìnrin Kan Lo Ìdánúṣe

Kà nípa bí ọmọbìnrin kan lórílẹ̀-èdè Chile tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá ṣe ṣiṣẹ́ kára láti pé gbogbo àwọn tó ń sọ èdè Mapudungun níléèwé rẹ̀ wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan.