Ṣé Josephus Ló Kọ Ọ́ Lóòótọ́?
Nínú ìwé ìtàn tí òpìtàn Flavius Josephus kọ nípa àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní, ó mẹ́nu kan ikú “Jákọ́bù, arákùnrin Jésù tí wọ́n tún ń pè ní Kristi náà.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́, ìwé ìtàn yẹn sọ nǹkan míì nípa Jésù tí àwọn kan kò gbà pé ó jẹ́ òótọ́. Ìsọ̀rí tí gbólóhùn yìí wà nínú ìwé náà ni wọ́n ń pè ní Testimonium Flavianum. Ó kà pé:
“Ní àkókò yẹn, èèyàn kan wà tó jẹ́ ọlọgbọ́n tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésù, ìyẹn bó bá tọ́ ká pè é ní èèyàn, torí pé ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Inú ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń dùn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti Kèfèrí ló sọ di Kristẹni. Òun ni Kristi náà. Nígbà tí àwọn sàràkí-sàràkí tó wà láàárín wa sún Pílátù láti pàṣẹ pé kí wọ́n kan Kristi mọ́ àgbélébùú, àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ kò pa á tì. Ó sì fara hàn wọ́n nígbà tó jíǹde lọ́jọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì Ọlọ́run ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ míì tí wọ́n sọ nípa rẹ̀ tún ní ìmúṣẹ. Àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣì wà títí dòní.”—Josephus—The Complete Works, tí ọ̀gbẹ́ni William Whiston túmọ̀.
Nígbà tí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ń parí lọ, àwọn tó gbà pé Josephus ló kọ ọ̀rọ̀ yìí àtàwọn tí kò gbà pé òun ló kọ ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn gan-an. Ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó jẹ́ òpìtàn àti òǹkọ̀wé, Serge Bardet, ti ń wá bó ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ tó ta kókó tó sì ti mu ọ̀pọ̀ èèyàn lómi fún ohun tó lé ní irínwó [400] ọdún. Ó ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà, ó sì ṣe ìwé kan tó dá lórí ìwádìí rẹ̀.
Àbájáde ìwádìí rẹ̀ mú kó ṣe kedere pé ìtàn tó dá lórí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́ ni Josephus máa ń kọ. Òǹkọ̀wé ìtàn àwọn Júù ni. Torí náà, ohun tó fa àríyànjiyàn jù lọ ni bí Josephus ṣe pe Jésù ní “Kristi náà.” Nínú ìwádìí tí Bardet ṣe, ó sọ pé “bí àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì ṣe máa ń lo ọ̀rọ̀ atọ́ka tó ṣe pàtó ṣáájú orúkọ àwọn èèyàn nìyẹn.” Bardet tún sọ pé tá a bá ní ká fojú ohun tí ẹ̀sìn Júù àti ti Kristẹni fi kọ́ni nípa bó ṣe jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jésù gbé láyé rí wo ọ̀rọ̀ náà, “kò yẹ kó yani lẹ́nu pé Josephus lo ọ̀rọ̀ náà Christos,” kò sì yẹ kí àwọn “alárìíwísí yẹn gbójú fo kókó pàtàkì yìí.”
Àbí ó lè jẹ́ pé òǹkọ̀wé kan ló dọ́gbọ́n kọ̀wé bíi ti Josephus, tó wá fi àwọn ọ̀rọ̀ tara rẹ̀ kún un? Lẹ́yìn tí Bardet ṣe ìwádìí ìtàn náà àti ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ọ́, ó sọ pé ó máa ṣòro fún ẹnikẹ́ni láti ṣe irú awúrúju bẹ́ẹ̀, torí pé tá a bá ní ká sọ̀rọ̀ nípa bí Josephus ṣe máa ń kọ̀wé, kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
Kí nìdí táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n fi ń ṣiyè méjì nípa ìwé náà? Bardet sọ pé ohun tó mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé tó pọ̀ máa ṣiyè méjì nípa ìwé náà ju àwọn ìwé àtijọ́ míì lọ ni pé ọ̀pọ̀ nínú wọn kò fẹ́ láti gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi náà.
A ò tíì mọ̀ bóyá àlàyé Bardet máa yí èrò táwọn ọ̀mọ̀wé ní nípa Testimonium Flavianum pa dà tàbí kò ní yí i pa dà. Àmọ́, àlàyé Bardet ti yí Ọ̀gbẹ́ni Pierre Geoltrain lérò pa dà. Ọkùnrin yìí jẹ́ ọ̀mọ̀wé tó mọ̀ nípa ìsìn àwọn Júù àti ìsìn àwọn Kristẹni ìjímìjí dáadáa. Ó ti kọ́kọ́ rò pé àwọn kan ló ki ìsọ̀rí tí gbólóhùn yẹn wà bọ inú ìwé náà, yẹ̀yẹ́ ló sì ń fi àwọn tó bá fara mọ́ ohun tó wà nínú ìwé náà ṣe. Àmọ́, èrò rẹ̀ ti yí pa dà báyìí. Ó sì sọ pé ìwádìí tí Ọ̀gbẹ́ni Bardet ṣe ló yí òun lérò pa dà. Ọ̀gbẹ́ni Geoltrain wá sọ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ sọ pé Josephus kọ́ ló kọ ìwé náà mọ́.
Bó ti wù kó rí, ó dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé Jésù ni Kristi náà, torí pé ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro wà nínú Bíbélì tó fi hàn bẹ́ẹ̀.—2 Tím. 3:16.