Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?

Ǹjẹ́ Ó Wù Ẹ́ Láti Mọ Jèhófà?

“Ẹ ti wá mọ Ọlọ́run.”—GÁL. 4:9.

1. Kí nìdí tí àwọn awakọ̀ òfuurufú fi máa ń ní àkọsílẹ̀ kan tí wọ́n fi máa ń ṣàyẹ̀wò ọkọ̀ kí wọ́n tó gbéra?

GBOGBO ìgbà tí awakọ̀ òfuurufú kan bá fẹ́ gbéra, ó máa ń yẹ ọkọ̀ náà wò dáadáa. Ó máa lo àkọsílẹ̀ kan tó máa jẹ́ kó rántí gbogbo ohun tó gbọ́dọ̀ yẹ̀ wò lára ọkọ̀ náà kó lè rí i dájú pé ọkọ̀ náà ti wà ní sẹpẹ́ láti gbéra. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, jàǹbá burúkú lè ṣẹlẹ̀. Kódà, awakọ̀ òfuurufú tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ náà fún ọ̀pọ̀ ọdún gbọ́dọ̀ yẹ gbogbo ohun tó wà lórí àkọsílẹ̀ náà wò kínníkínní.

2. Àyẹ̀wò wo ló yẹ ká máa ṣe?

2 Kó o lè rí i dájú pé ìgbàgbọ́ rẹ lágbára débi tí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà kò fi ní bà jẹ́ nígbà tí ìṣòro bá dé, ìwọ náà gbọ́dọ̀ ṣe bíi ti awakọ̀ òfuurufú yẹn. Yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ni o tàbí a ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa wò ó bóyá ìgbàgbọ́ wa ṣì lágbára. Tá ò bá yẹ ìgbàgbọ́ wa wò, tó jẹ́ pé ńṣe la wulẹ̀ rò pé ó ṣì lágbára, bí àdánwò líle koko bá dé, ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.”—1 Kọ́r. 10:12.

3. Kí ló yẹ kí àwọn Kristẹni tó wà ní Gálátíà ṣe?

3 Ẹbọ ìràpadà Jésù ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni láti wá mọ Ọlọ́run lọ́nà kan tó yàtọ̀. Lọ́lá ẹbọ yìí ni Ọlọ́run fi máa yan àwọn èèyàn kan, tó sì máa sọ wọ́n di ọmọ. Àmọ́, ó yẹ kí àwọn Kristẹni tó wà ní Gálátíà máa ṣàyẹ̀wò ìgbàgbọ́ wọn. (Gál. 4:9) Àwọn kan wà nínú ìjọ tí wọ́n ń sọ pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú káwọn Kristẹni jẹ́ olódodo ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé Òfin Mósè. Àmọ́, Ọlọ́run kò retí pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́, àwọn Kèfèrí ò sì fìgbà kan wà lábẹ́ Òfin yẹn. Torí náà, ó pọn dandan pé kí àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó wà nínú ìjọ túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ sí i. Ó ṣì yẹ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé títẹ̀lé Òfin Mósè kọ́ ló máa mú kí wọ́n jẹ́ olódodo.

BÁ A ṢE MỌ ỌLỌ́RUN

4, 5. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Gálátíà? Kí nìdí tí lẹ́tà tó kọ sí wọn fi ṣe pàtàkì fún wa?

4 Lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Gálátíà rán gbogbo wọn létí pé kí wọ́n má ṣe fi òtítọ́ tí wọ́n ti kọ́ nínú Bíbélì sílẹ̀. Kí wọ́n má sì ṣe pa dà sídìí àwọn nǹkan tí wọ́n ti fi sílẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nítorí àwọn Kristẹni tó wà ní Gálátíà nìkan ni Ọlọ́run ṣe mí sí Pọ́ọ̀lù pé kó kọ lẹ́tà náà. Lẹ́tà náà lè ran gbogbo àwa tá à ń sin Ọlọ́run lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó láìyẹsẹ̀.

5 Ó yẹ kí gbogbo wa máa rántí ìgbà tá a pinnu láti máa sin Jèhófà. Ronú nípa àwọn ìbéèrè méjì yìí: Ǹjẹ́ o rántí àwọn ìgbésẹ̀ tó o gbé kó o tó ṣèrìbọmi? Ǹjẹ́ o rántí bó ṣe rí lára rẹ nígbà tó o wá mọ Ọlọ́run tí Ọlọ́run sì wá mọ ìwọ náà?

6. Àkọsílẹ̀ wo la máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

6 Ìgbésẹ̀ mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbogbo wa gbé ká tó wá sínú òtítọ́. (Wo àpótí náà,  “Àwọn Ìgbésẹ̀ Tá A Gbé Ká Tó Ṣèrìbọmi Lè Mú Ká Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí.”) A lè máa wo àwọn ìgbésẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ tá a gbọ́dọ̀ máa gbé yẹ̀ wò kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, ká má bàa pa dà sídìí àwọn nǹkan tó wà nínú ayé. Bí awakọ̀ òfuurufú tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà ṣe máa ń yẹ àkọsílẹ̀ rẹ̀ wò kó tó gbéra, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí àwa náà máa ṣe àyẹ̀wò àwọn ìgbésẹ̀ yìí.

ÒYE ÒTÍTỌ́ TÚBỌ̀ Ń YÉ ÀWỌN TÍ ỌLỌ́RUN MỌ̀

7. “Àpẹẹrẹ” wo la gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé? Kí nìdí tó fi yẹ ka fiyè sí bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ náà?

7 Bí awakọ̀ òfuurufú ṣe máa ń lo àkọsílẹ̀ rẹ̀ láti ṣe àwọn àyẹ̀wò tó yẹ ní gbogbo ìgbà tó bá fẹ́ gbéra, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí àwa náà máa ṣàyẹ̀wò bá a ṣe ń ṣe sí látìgbà tá a ti ṣèrìbọmi. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tí ìwọ gbọ́ lọ́dọ̀ mi mú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (2 Tím. 1:13) Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti lè rí “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” yẹn. (1 Tím. 6:3) Kò dìgbà tí ayàwòrán kan bá parí iṣẹ́ lára àwòrán kan pátápátá kéèyàn tó mọ ohun tó ń yà. Bákan náà, ‘àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́’ máa ń jẹ́ ká lè fòye mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe, ká sì máa ṣègbọràn sí i. Ní báyìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbésẹ̀ tá a gbé ká tó ṣèrìbọmi ká lè mọ̀ bóyá a ṣì ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí bó ṣe yẹ.

8, 9. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí òye tá a ní àti ìgbàgbọ́ wa máa pọ̀ sí i? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwa Kristẹni máa tẹ̀ síwájú? Báwo ni ìtẹ̀síwájú wa ṣe dà bí igi tó ń dàgbà?

8 Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tá a gbé ni pé a gba ìmọ̀. Ìmọ̀ yìí ló mú ká ní ìgbàgbọ́. Àmọ́, kò yẹ ká dáwọ́ dúró láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ó sì yẹ ká túbọ̀ máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun. (2 Tẹs. 1:3) Lẹ́yìn tá a bá ti ṣe ìrìbọmi, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní dà bí omi adágún, àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run á sì máa sunwọ̀n sí i.

Tá a bá ń tẹ̀ síwájú, ńṣe la máa dà bí irúgbìn tó dàgbà di igi ràgàjì

9 A lè fi ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí wé bí igi ṣe máa ń dàgbà. Ó máa ń jọ wá lójú gan-an tá a bá rí àwọn igi tó ga fíofío, pàápàá tó bá ní gbòǹgbò tó nípọn tó sì ta káàkiri. Bí àpẹẹrẹ, àwọn igi kédárì rírẹwà tó wà ní ìlú Lẹ́bánónì lè ga tó ilé alájà méjìlá. Wọ́n sì máa ń tóbi débi pé bí èèyàn mẹ́wàá bá fi ọwọ́ kọ́ra tí wọ́n sì dúró yí igi kédárì kan po, ọwọ́ wọn lè má ká a. (Orin Sól. 5:15) Bí igi bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í hù, ó máa ń yára dàgbà. Bí gbòǹgbò igi náà bá ṣe ń wọnú ilẹ̀, tó sì ń ta káàkiri, á bẹ̀rẹ̀ sí í tóbi á sì máa ga sí i. Lẹ́yìn ìyẹn, èèyàn lè má tètè rí bí igi náà ṣe ń dàgbà sókè mọ́. Bí ìtẹ̀síwájú àwa Kristẹni náà ṣe rí nìyẹn. A lè ti ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó tó di pé a ṣèrìbọmi. Àwọn ará nínú ìjọ rí bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ètò Ọlọ́run. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe ká gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí ká máa bójú tó àwọn iṣẹ́ míì nínú ìjọ. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn míì lè má kíyè sí ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí mọ́. Àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Èyí sì gbà pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun títí tá a fi máa “di géńdé ọkùnrin.” Tàbí lédè mìíràn, títí òtítọ́ fi máa jinlẹ̀ nínú wa. (Éfé. 4:13) Torí náà, tá a bá ń tẹ̀ síwájú, ńṣe la máa dà bíi hóró irúgbìn tó wá dàgbà di igi ràgàjì.

10. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn fi gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú?

10 Ṣùgbọ́n ìtẹ̀síwájú wa kò gbọ́dọ̀ parí síbẹ̀ yẹn o! Ńṣe ni ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a ní àti ìgbàgbọ́ wa dà bíi gbòǹgbò tó ń fún wa lókun tó sì ń jẹ́ ká fìdí múlẹ̀ ṣinṣin. Ó ṣe pàtàkì pé kí gbòǹgbò yìí máa lágbára sí i. (Òwe 12:3) Nínú ìjọ Kristẹni, ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń bá a nìṣó láti máa tẹ̀ síwájú. Arákùnrin kan tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún sọ̀rọ̀ kan tó fi hàn pé ó ṣì ń tẹ̀ síwájú síbẹ̀. Ó ní: “Mo ti wá mọyì Bíbélì báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ojoojúmọ́ ni mò ń rí onírúurú ọ̀nà tí mo lè gbà máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, kí n sì máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ńṣe ni mo túbọ̀ ń mọyì iṣẹ́ ìwàásù gan-an báyìí.”

JẸ́ KÍ ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN TÚBỌ̀ FÌDÍ MÚLẸ̀

11. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ máa fìdí múlẹ̀?

11 Tá a bá fẹ́ máa tẹ̀ síwájú, ńṣe ló yẹ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà. Ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ bíi ti ọmọ kan tó wà lọ́dọ̀ òbí tó mọyì ọmọ. Ó sì fẹ́ kí ara tù wá bí ìgbà tá a wà lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Àmọ́ ṣá o, ó máa gba àkókò àti ìsapá ká tó lè sún mọ́ Jèhófà débi tí ọkàn wa á fi balẹ̀ dáadáa tí a ó sì máa jọlá ìfẹ́ tó ní sí wa. Torí náà, rí i dájú pé ò ń wá àyè lójoojúmọ́ láti fi ka Bíbélì. Kó o sì máa ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! pẹ̀lú àwọn ìwé wa míì tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Èyí á mú kó o túbọ̀ mọ Jèhófà, àjọṣe tó o ní pẹ̀lú rẹ̀ á sì fìdí múlẹ̀ ṣinṣin.

12. Kí la gbọ́dọ̀ mọ̀ tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó fìdí múlẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run?

12 Ohun tó tún lè mú kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run fìdí múlẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà ká sì tún ní àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere. (Ka Málákì 3:16.) Bí àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run bá gbàdúrà sí i, ó máa ń tẹ́tí sí “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pét. 3:12) Jèhófà máa ń tẹ́tí sí wa tá a bá ké pè é, torí náà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà nígbà gbogbo. (Róòmù 12:12) Kò sí bí òtítọ́ ṣe lè jinlẹ̀ nínú wa láìjẹ́ pé Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́. Tí a kò bá gbàdúrà sí Ọlọ́run mọ́, kò sí bó ṣe máa fún wa ní agbára tá a nílò. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé búburú yìí lè mú wa rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí wọ́n mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. Ṣùgbọ́n tá a bá bẹ Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́, ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Tó o bá ń gbàdúrà, ṣé o máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bó o ṣe máa ń bá ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o fọkàn tán sọ̀rọ̀? Ǹjẹ́ o lè mú àdúrà rẹ sunwọ̀n sí i?—Jer. 16:19.

13. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa lọ sí ìpàdé déédéé tá ò bá fẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run bà jẹ́?

13 A gbọ́dọ̀ máa lọ sí ìpàdé déédéé ká lè máa pé jọ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Jèhófà fẹ́ràn àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí torí pé wọ́n ń “wá ibi ìsádi lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Náh. 1:7) Torí pé àwọn nǹkan tó ń bani nínú jẹ́ pọ̀ láyé yìí, ó yẹ ká máa wà pẹ̀lú àwọn ará wa, ká lè jọ máa gbé ara wa ró. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará wa, wọ́n á fún wa ní ìṣírí láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì, a ó sì lè máa ṣe “àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24, 25) Kò ní ṣeé ṣe fún wa láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò àyàfi tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Torí náà, máa rí i dájú pé ò ń lọ sí ìpàdé déédéé, kó o sì máa lóhùn sí apá tó bá jẹ́ ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ.

14. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa ronú pìwà dà ká sì tún máa yí pa dà?

14 Nígbà tá a fẹ́ láti di Kristẹni, a ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a sì tún yí pa dà, ìyẹn ni pé a jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Àmọ́, a ṣì gbọ́dọ̀ máa ronú pìwà dà ká sì tún máa ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ nínú ìgbésí ayé wa. Níwọ̀n bá a ti jẹ́ aláìpé, tí àìpé sì máa ń mú wa ṣe ohun tí kò tọ́, ó máa ń rọrùn fún wa láti dẹ́ṣẹ̀. Ńṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ dà bí ejò tó ṣe tán láti buni ṣán nígbàkigbà tó bá fẹ́. (Róòmù 3:9, 10; 6:12-14) Torí náà, a ò lè máa díbọ́n pé a kò ní àléébù kankan. Àmọ́, Jèhófà ń mú sùúrù fún wa bá a ṣe ń sá fún ẹ̀ṣẹ̀ tá a sì ń ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ. (Fílí. 2:12; 2 Pét. 3:9) Ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa fi àkókò àti okun wa ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, dípò tí a ó fi máa lò ó láti gbọ́ tara wa nìkan. Arábìnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú òtítọ́ rò pé ó yẹ kóun máa bẹ̀rù jìnnìjìnnì nítorí Jèhófà. Ó tún rò pé kò sí ohun tóun lè ṣe tó lè tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Kò rí Ọlọ́run bí ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe àṣìṣe tó pọ̀. Ó sọ pé: “Kì í ṣe pé mi ò fẹ́ràn Jèhófà, àmọ́ mi ò mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an.” Torí náà, ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà díẹ̀díẹ̀. Ó wá sọ pé: “Ó wá dà bíi pé ńṣe ni Jèhófà fà mí lọ́wọ́ bí ọmọ kékeré. Ó ń mú kí n borí àwọn ìṣòro náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Kò fọwọ́ líle koko mú mi, àmọ́ ó ń jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n ṣe.”

15. Kí ni Jésù àti Bàbá rẹ̀ ń kíyè sí?

15 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti mú Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lọ́nà ìyanu, áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n ‘máa bá a nìṣó ní sísọ̀rọ̀’ nípa ìhìn rere. (Ìṣe 5:19-21) Torí náà, iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò kí ìgbàgbọ́ wa má bàa di ahẹrẹpẹ. Jésù àti Bàbá rẹ̀ máa ń kíyè sí bá a ṣe ní ìgbàgbọ́ tó, inú wọn sì máa ń dùn sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. (Ìṣí. 2:19) Torí náà, ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù wa.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ìyàsímímọ́ wa?

16 Máa ronú nípa ìyàsímímọ́ rẹ. Àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a ní. Jèhófà mọ gbogbo àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. (Ka Aísáyà 44:5.) Máa ṣàyẹ̀wò bí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà ṣe rí, kó o sì máa gbàdúrà sí i pé kó jẹ́ kí àjọṣe náà lè máa sunwọ̀n sí i. Tún máa ronú nípa ìrìbọmi rẹ, kó o má sì ṣe gbàgbé ọjọ́ pàtàkì yẹn. Ìrìbọmi tó o ṣe ló mú káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn ìpinnu téèyàn lè ṣe.

A NÍLÒ ÌFARADÀ KÁ TÓ LÈ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ

17. Kí nìdí tá a fi nílò ìfaradà tá a bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà?

17 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Gálátíà, ó tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n ní ìfaradà. (Gál. 6:9) Ó yẹ kí àwa tá a jẹ́ Kristẹni lónìí náà ní ìfaradà, torí pé a máa dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Àmọ́ Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀. Tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó máa fún wa lọ́pọ̀ yanturu. Ẹ̀mí mímọ́ yìí ló sì máa jẹ́ ká ní ìdùnnú àti àlàáfíà, bó bá tiẹ̀ já sí pé ìṣòro tó ń bá wa fínra ò tíì kúrò. (Mát. 7:7-11) Tiẹ̀ rò ó wò ná: Jèhófà ń bójú tó àwọn ẹyẹ. Àmọ́ ó fẹ́ràn rẹ ju àwọn ẹyẹ lọ. Ó fẹ́ láti máa tọ́jú rẹ torí pé o fẹ́ràn rẹ̀ o sì ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún un. (Mát. 10:29-31) Kódà, tó o bá ní àwọn ìṣòro tó lágbára gan-an, má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Má ṣe fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ torí àwọn nǹkan tó o ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ fún wa pé Jèhófà mọ̀ wá!

18. Kí ló yẹ kí gbogbo àwọn tó bá mọ Ọlọ́run ṣe ní báyìí?

18 Tó bá jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tó o ṣèrìbọmi, kí ló yẹ kó o ṣe báyìí? Máa bá a nìṣó láti túbọ̀ mọ Jèhófà, kó o sì máa tẹ̀ síwájú títí tí òtítọ́ a fi túbọ̀ jinlẹ̀ nínú rẹ. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ tó o ti ṣèrìbọmi ńkọ́? Ìwọ pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè túbọ̀ mọ Jèhófà. A kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé a ti mọ̀ ọ́n tán àti pé àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run yẹn náà ti tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ohun tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí látìgbàdégbà, kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Baba wa, Ọ̀rẹ́ wa àti Ọlọ́run wa.—Ka 2 Kọ́ríńtì 13:5, 6.