Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ni Ibùgbé Wa

Jèhófà Ni Ibùgbé Wa

“Jèhófà, ìwọ tìkára rẹ ti jẹ́ ibùgbé gidi fún wa ní ìran dé ìran.”—SM. 90:1.

1, 2. Báwo ni ohun tó ń lọ nínú ayé yìí ṣe rí lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run? Irú ilé wo ni wọ́n ní?

 NÍNÚ ayé búburú tá à ń gbé yìí, ṣé ọkàn rẹ máa ń balẹ̀, ṣé ara sì máa ń tù ẹ́? Tó bá jẹ́ pé ọkàn rẹ kì í balẹ̀, a jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ṣe rí lára ìwọ náà. Ọjọ́ pẹ́ tí gbogbo àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà tọkàntọkàn ti máa ń wo ara wọn gẹ́gẹ́ bí àjèjì nínú ayé. Bí àpẹẹrẹ, bó ṣe rí lára àwọn olóòótọ́, ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣí káàkiri ilẹ̀ Kénáánì náà nìyẹn. Bíbélì sọ pé wọ́n “polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.”—Héb. 11:13.

2 Ọ̀run ni ilé àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. Látàrí ìyẹn, àwọn náà máa ń wo ara wọn gẹ́gẹ́ bí “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀” nínú ayé yìí. (Fílí. 3:20; 1 Pét. 2:11) “Àwọn àgùntàn mìíràn” náà “kì í ṣe apá kan ayé” bí Jésù kì í ti í ṣe apá kan ayé. (Jòh. 10:16; 17:16) Àmọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run náà ní ilé, ó kàn jẹ́ pé kì í ṣe ilé tá a lè fojú rí ni. Síbẹ̀, ilé yìí ni ibi tó fini lọ́kàn balẹ̀ jù lọ, ibẹ̀ sì ni ìfẹ́ ti gbilẹ̀ jù lọ. Ilé wo nìyẹn ná? Mósè sọ pé: “Jèhófà, ìwọ tìkára rẹ ti jẹ́ ibùgbé gidi fún wa ní ìran dé ìran.” (Sm. 90:1) Jèhófà jẹ́ “ibùgbé gidi,” tàbí ilé, fún àwọn tó ń sìn ín ní òótọ́ àtòdodo. Ǹjẹ́ o mọ ọ̀nà tí Jèhófà gbà jẹ́ ibùgbé fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà àtijọ́? Ọ̀nà wo ló gbà jẹ́ ibùgbé fáwọn èèyàn rẹ̀ lónìí? Báwo ló sì ṣe máa jẹ́ ilé aláàbò kan ṣoṣo tó wà fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

JÈHÓFÀ JẸ́ “IBÙGBÉ GIDI” FÚN ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ RẸ̀ NÍGBÀ ÀTIJỌ́

3. Kí ni Sáàmù 90:1 fi Jèhófà wé, kí sì nìdí?

3 Nígbà míì, Bíbélì máa ń fi Jèhófà wé àwọn nǹkan tá a lè fojú rí ká lè túbọ̀ lóye irú ẹni tó jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 90:1 fi Jèhófà wé “ibùgbé” tàbí ilé. Ilé sábà máa ń jẹ́ ibi tí ìfẹ́, àlàáfíà àti ààbò ti ń jọba. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní ibùgbé? Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Ó tún sọ pé ó jẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà àti pé ó máa ń pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ́. (Sm. 4:8) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe dà bí ilé fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù, tí wọ́n sìn ín ní òótọ́ àti òdodo.

4, 5. Báwo ni Ọlọ́run ṣe bù kún Ábúráhámù tó sì tún dáàbò bò ó?

4 Ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù ti máa ṣe kàyéfì nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.” Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ tẹ̀ lé e ti ní láti tù ú nínú gidigidi. Ó sọ fún un pé: “Èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ, èmi yóò sì mú kí orúkọ rẹ di ńlá.” Kò tán síbẹ̀. Ó tún fi kún un pé: “Èmi yóò sì súre fún àwọn tí ń súre fún ọ, ẹni tí ó sì ń pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí rẹ ni èmi yóò fi gégùn-ún.”—Jẹ́n. 12:1-3.

5 Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún Ábúráhámù àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. (Jẹ́n. 26:1-6) Ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, kò jẹ́ kí Fáráò ọba Íjíbítì àti Ábímélékì ọba Gérárì pa Ábúráhámù, kò sì jẹ́ kí wọ́n gba Sárà, ìyàwó rẹ̀. Ó tún dáàbò bo Ísákì àti Rèbékà. (Jẹ́n. 12:14-20; 20:1-14; 26:6-11) Bíbélì sọ pé Jèhófà ò “gba ẹ̀dá ènìyàn kankan láyè láti lù wọ́n ní jìbìtì, ṣùgbọ́n ó fi ìbáwí tọ́ àwọn ọba sọ́nà ní tìtorí wọn, pé: ‘Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi, ẹ má sì ṣe ohun búburú kankan sí àwọn wòlíì mi.’”—Sm. 105:14, 15.

“Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀”

6. Kí ni Ísákì sọ pé kí Jékọ́bù ṣe? Èrò wo ló ṣeé ṣe kó wá sí Jékọ́bù lọ́kàn?

6 Jèhófà tún bójú tó Jékọ́bù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù. Nígbà tí àkókò tó fún Jékọ́bù láti fẹ́ ìyàwó, bàbá rẹ̀, Ísákì, sọ fún un pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì. Dìde, lọ sí Padani-árámù sí ilé Bẹ́túélì baba ìyá rẹ, ibẹ̀ ni kí o sì ti mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Lábánì arákùnrin ìyá rẹ.” (Jẹ́n. 28:1, 2) Jékọ́bù ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ sọ fún un. Ó fi bàbá àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ ní Kénáánì, ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà lọ sí Háránì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun nìkan ló dá lọ. (Jẹ́n. 28:10) Ó ṣeé ṣe kó máa rò ó lọ́kàn pé: ‘Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí n tó pa dà sílé?’ Ṣé inú ẹ̀gbọ́n ìyá mi máa dùn láti rí mi? Ṣé màá rí aya tó fẹ́ràn Jèhófà? Àmọ́, nígbà tí Jékọ́bù dé Lúsì, ìyẹn ibi tó fi ọgọ́rùn-ún kìlómítà jìn sí Bíá-Ṣébà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kó dẹ́kun àníyàn ṣíṣe. Kí lohun náà?

7. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Ọlọ́run sọ fún Jékọ́bù?

7 Nígbà tí Jékọ́bù dé Lúsì, Jèhófà fara hàn án lójú àlá, ó sì sọ fún un pé: “Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà tí ìwọ ń lọ, èmi yóò sì mú ọ padà sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí èmi yóò fi ṣe ohun tí mo ti sọ fún ọ ní tòótọ́.” (Jẹ́n. 28:15) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yẹn á tu Jékọ́bù nínú gan-an ni! Kò sí àní-àní pé ńṣe ni Jékọ́bù á máa fojú sọ́nà látìgbà yẹn, kó lè rí bí Jèhófà ṣe máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Tó bá jẹ́ pe ńṣe lo fi ilé àti ọ̀nà sílẹ̀ tó o sì ń sìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ṣàníyàn bíi ti Jékọ́bù. Àmọ́, wàá ti rí i báyìí pé Jèhófà ń bójú tó ẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà.

8, 9. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ “ibùgbé gidi” fún Jékọ́bù? Kí nìyẹn sì kọ́ wa?

8 Nígbà tí Jékọ́bù dé Háránì, ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó fi Léà àti Rákélì fún un gẹ́gẹ́ bí aya. Àmọ́, nígbà tó yá, Lábánì bẹ̀rẹ̀ sí yan Jékọ́bù jẹ, ó sì yí owó ọ̀yà rẹ̀ pa dà nígbà mẹ́wàá. (Jẹ́n. 31:41, 42) Síbẹ̀, Jékọ́bù fara da gbogbo èyí torí pé ó ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà máa tọ́jú òun. Látàrí èyí, Jèhófà bù kún Jékọ́bù. Lọ́nà wo? Nígbà tí Jèhófà fi máa sọ fún un pé kó pa dà sí ilẹ̀ Kénáánì, ó ti ní “ọ̀pọ̀ agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” (Jẹ́n. 30:43) Inú Jékọ́bù dùn, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà láti dúpẹ́ oore tó ṣe fún un. Ó ní: “Èmi kò yẹ fún gbogbo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti gbogbo ìṣòtítọ́ tí o ti ṣe sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí pẹ̀lú ọ̀pá mi nìkan ṣoṣo ni mo sọdá Jọ́dánì yìí, mo sì ti di ibùdó méjì nísinsìnyí.”—Jẹ́n. 32:10.

9 Gbogbo èyí wá jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ohun tí Mósè sọ nípa Ọlọ́run pé: “Jèhófà, ìwọ tìkára rẹ ti jẹ́ ibùgbé gidi fún wa ní ìran dé ìran”! (Sm. 90:1) Jèhófà ò tíì yí pa dà. Ó ṣì nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín ní òótọ́ àti òdodo lóde òní. Ó ń pa àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ́, ó sì ń bójú tó wa. (Ják. 1:17) Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe ń ṣe é.

JÈHÓFÀ JẸ́ “IBÙGBÉ GIDI” FÚN WA LÓNÌÍ

10. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Jèhófà á máa bá a nìṣó láti jẹ́ “ibùgbé gidi” fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

10 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe kan: Jẹ́ ká sọ pé o wà nílé ẹjọ́. Ò ń jẹ́rìí lòdì sí ọkùnrin alágbára kan tó gbọ́n féfé. Onírọ́ paraku àti apààyàn ni ọkùnrin náà, ó sì ní àwọn tó ń ṣojú fún un káàkiri ayé. Tí ẹjọ́ bá parí tó o sì ń pa dà lọ sílé, ṣé ọkàn rẹ máa balẹ̀? Bóyá ni! Ńṣe ni wàá máa wá bó o ṣe máa dáàbò bo ara rẹ, kí àwọn tó ń ṣojú fún ọkùnrin burúkú yẹn má bàa ṣe ọ́ ní jàǹbá. Bí ọ̀rọ̀ àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn. Àwa là ń jẹ́rìí lòdì sí ẹni ibi tó jẹ́ ọ̀tá Jèhófà, ìyẹn Sátánì. (Ka Ìṣípayá 12:17.) Sátánì ti gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu mọ́. Ṣé ọwọ́ rẹ̀ ti wá tẹ ohun tó ń wá? Rárá o! Kódà, ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé túbọ̀ ń tẹ́tí sí ìwàásù wa. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Kò sí ohun méjì tó fà á ju pé Jèhófà jẹ́ “ibùgbé gidi” fún wa. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Ọlọ́run ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń bù kún wọn. (Ka Aísáyà 54:14, 17.) Àmọ́ ṣá o, ohun tó lè mú kí Jèhófà máa bá a nìṣó láti jẹ́ “ibùgbé gidi” fún wa ni pé ká má ṣe fàyè gba Sátánì láti tàn wá jẹ.

Àwọn áńgẹ́lì ń ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn, wọ́n sì ń dáàbò bò wọ́n

11. Ẹ̀kọ́ mìíràn wo la lè rí kọ́ lára Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù?

11 Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ míì tá a tún lè kọ́ lára Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbé ní ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, wọ́n sì kórìíra ohun búburú tí àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ń ṣe. (Jẹ́n. 27:46) Kò sẹ́ni tó fún wọn ní òfin gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ kí wọ́n tó mọ rere yàtọ̀ sí búburú. Wọ́n mọ ohun tí Jèhófà fẹ́, wọ́n sì mọ ohun tó kórìíra. Torí náà, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa di apá kan ayé. Àpẹẹrẹ rere ni wọ́n mà jẹ́ fún wa o! Ṣé o máa ń sa gbogbo ipá rẹ láti fìwà jọ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run yẹn? Ṣé àwọn tó ò ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́ àti irú eré ìdárayá tó ò ń ṣe fi hàn pé o kò fẹ́ láti jẹ́ apá kan ayé? Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni ṣì ń fi hàn, láwọn ọ̀nà kan, pé ayé Sátánì yìí ń gbádùn mọ́ àwọn. Ṣé ayé Sátánì yìí ń gbádùn mọ́ ìwọ náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àfi kó o tètè bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má ṣe gbà gbé pé Sátánì ló ń ṣàkóso ayé yìí. Tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àǹfààní kankan tó lè ṣe fún wa!—2 Kọ́r. 4:4; Éfé. 2:1, 2.

12. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́? (b) Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́?

12 Bí a kò bá fẹ́ kí Sátánì tàn wá jẹ, a gbọ́dọ̀ máa jàǹfààní látinú gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ gbà nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ, ìjọsìn ìdílé àti àwọn alàgbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wa tí wọ́n sì ń tì wá lẹ́yìn ká lè máa fara da àwọn ìṣòro inú ayé. (Éfé. 4:8-12) Arákùnrin George Gangas tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún ọ̀pọ̀ ọdún fẹ́ràn láti máa wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì sọ bó ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Ó ní: “Bí mo bá wà láàárín àwọn ará, mo gbà pé ilé mi ni mo wà, ará sì máa ń tù mí pẹ̀sẹ̀.” Ìwọ ńkọ́?

13. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ ní Hébérù 11:13?

13 A tún rí ohun pàtàkì mìíràn kọ́ lára Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Ìyẹn ni pé, ká má ṣe máa bẹ̀rù pé a kò fẹ́ dá yàtọ̀ sí àwọn èèyàn ayé. A rí i kà ní  ìpínrọ̀ kìíní pé nígbà àtijọ́, àwọn olóòótọ́, ìránṣẹ́ Ọlọ́run polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.” (Héb. 11:13) Ṣé ìwọ náà ń fi hàn pé o yàtọ̀ sí àwọn èèyàn ayé? Kì í rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Àmọ́ Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin náà sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má ṣe gbàgbé pé o lẹ́ni lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n ó ti di dandan fún gbogbo ẹní tó bá fẹ́ sin Jèhófà láti wọ̀yá ìjà pẹ̀lú Sátánì àti ayé yìí. (Éfé. 6:12) Àmọ́, a lè ja àjàṣẹ́gun tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì fi ṣe ibùgbé wa.

14. “Ìlú” wo ni Ábúráhámù ń dúró dè?

14 Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ábúráhámù, ká sì máa fi èrè náà sọ́kàn. (2 Kọ́r. 4:18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Ábúráhámù “ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Héb. 11:10) “Ìlú” yẹn ni Ìjọba Ọlọ́run. Ábúráhámù ní láti dúró títí “ìlú” yẹn fi máa dé. Àmọ́, àwa ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa dúró de ìlú náà ní tiwa. Torí pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ lókè ọ̀run. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sì fi hàn ní kedere pé gbogbo ayé máa tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Ǹjẹ́ bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ fi hàn pé o gbà lóòótọ́ pé gbogbo ayé máa tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run? Ṣé ò ń fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé o sì ń ya ara rẹ sọ́tọ̀ nínú ayé yìí?—Ka 2 Pétérù 3:11, 12.

JÈHÓFÀ NI “IBÙGBÉ GIDI” FÚN WA TÍTÍ LÁÉ

15. Kí ló máa gbẹ̀yìn àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ayé Sátánì yìí?

15 Bí ayé Sátánì yìí ṣe ń lọ sópin, ńṣe ni àwọn ìṣòro inú ayé á máa pọ̀ sí i. (Mát. 24:7, 8) Tí ìpọ́njú ńlá bá sì bẹ̀rẹ̀, ńṣe ni ayé yìí á túbọ̀ le koko. Ìdàrúdàpọ̀ á wà, àwọn ètò amáyédẹrùn láwọn orílẹ̀-èdè gbogbo á kógbá sílé, ẹ̀rù á sì máa bá àwọn èèyàn. (Háb. 3:16, 17) Bíbélì sọ pé ayé á nira fáwọn èèyàn débi pé wọ́n á máa wá ààbò lọ sínú “àwọn hòrò àti sínú àwọn àpáta ràbàtà àwọn òkè ńlá.” (Ìṣí. 6:15-17) Àmọ́ kò sí hòrò, ìyẹn ihò inú àpáta tàbí ihò inú ilẹ̀, tó máa dàábò bò wọ́n. Bákàn náà, kò ní sí ètò ìṣòwò tàbí ètò ìṣèlú, tó dà bí àpáta ràbàtà, tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.

16. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìjọ Ọlọ́run? Kí sì nìdí?

16 Jèhófà máa pa wá mọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá. Bíi ti wòlíì Hábákúkù, àwa náà máa “kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà” wa. (Háb. 3:18) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà máa gbà pa wá mọ́ ní àkókò líle koko yẹn? Ó dìgbà náà ká tó mọ̀. Àmọ́, ó dá wa lójú pé àwọn èèyàn Jèhófà ṣì máa wà létòlétò. Àti pé bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, àwa náà á ṣì máa rí ìtọ́ni gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Ka Ẹ́kísódù 13:18; Ìṣí. 7:9) Báwo ni Jèhófà á ṣe máa fún wa ní ìtọ́ni? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìjọ la ó ti máa gbọ́ àwọn ohun tó yẹ ká ṣe. Ìwé Aísáyà 26:20 sọ̀rọ̀ nípa àwọn ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’ tó máa pèsè ààbò fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ àwọn ìjọ kárí ayé ni ibi yìí ń sọ. (Ka Aísáyà 26:20.) Ǹjẹ́ ò ń fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpàdé ìjọ? Ṣé gbogbo ìgbà lo máa ń ṣe ohun tí Jèhófà bá sọ fún ẹ nípasẹ̀ ìjọ?—Héb. 13:17.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ “ibùgbé gidi” fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó ti kú pàápàá?

17 Jèhófà á ṣì máa bá a nìṣó láti jẹ́ “ibùgbé gidi” fún àwọn olóòótọ́ tó ṣeé ṣe kí wọ́n kú kí ìpọ́njú ńlá tó dé. Lọ́nà wo? Ó máa jí wọn dìde. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ti kú, Jèhófà sọ fún Mósè pé òun ṣì jẹ́ Ọlọ́run wọn. (Ẹ́kís. 3:6) Jésù náà lo gbólóhùn yẹn, ṣùgbọ́n ó fi kún un pé: “Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:38) Èyí wá mú kí àjíǹde àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ dájú débi pé lójú Jèhófà ńṣe ló dà bíi pé wọ́n wà láàyè.—Oníw. 7:1.

18. Báwo ni Jèhófà ṣe máa di “ibùgbé gidi” fún àwọn èèyàn rẹ̀ nínú ayé tuntun?

18 Nínú ayé tuntun, Jèhófà máa di “ibùgbé gidi” fún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìwé Ìṣípayá 21:3 sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé.” Jèhófà máa lo Jésù Kristi láti ṣàkóso ilẹ̀ ayé fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún náà, Jésù á ti mú kí ayé rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí, á wá gbé Ìjọba pa dà fún Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:28) Jèhófà á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àwọn ẹ̀dá pípé ní tààràtà. Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu ló ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ yìí! Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́. Kí àwa náà máa fi Jèhófà ṣe “ibùgbé gidi” wa.