Máa Gbé Orúkọ Ńlá Jèhófà Ga
“Èmi yóò sì máa yin orúkọ rẹ lógo fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—SM. 86:12.
1, 2. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run, báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yàtọ̀ sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pátá ló ti pa orúkọ Ọlọ́run tì. Wọn kò lo orúkọ náà mọ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì kan, àwọn tó túmọ̀ Bíbélì náà sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ tó wà níbẹ̀ pé “kò bójú mu rárá” pé kí àwọn Kristẹni máa fi orúkọ èyíkéyìí pe Ọlọ́run.—Bíbélì Revised Standard Version.
2 Àmọ́, tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀. Ohun ìwúrí ni fún wa láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run ká sì tún máa gbé orúkọ náà ga. (Ka Sáàmù 86:12; Aísáyà 43:10.) Bákan náà, àǹfààní ńlá la kà á sí pé a mọ ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run, a sì tún mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká sọ orúkọ náà di mímọ́. (Mát. 6:9) Ká má bàa gbàgbé pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti mọ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta kan: Kí ló túmọ̀ sí láti mọ orúkọ Ọlọ́run? Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ni orúkọ ńlá náà tọ́ sí lóòótọ́? Báwo la sì ṣe lè máa “rìn ní orúkọ Jèhófà”?
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI MỌ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN
3. Kí ló túmọ̀ sí láti mọ orúkọ Ọlọ́run?
3 Ṣé ohun tó túmọ̀ sí láti mọ orúkọ Ọlọ́run ni pé kéèyàn ṣáà ti mọ ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà”? Rárá o. Ohun tó túmọ̀ sí láti mọ orúkọ Ọlọ́run ni pé kéèyàn mọ irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì tún wé mọ́ ọn. Lára rẹ̀ ni pé kéèyàn mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀, ohun tó ti pinnu láti ṣe àti irú ọwọ́ tó fi máa ń mú àwọn èèyàn rẹ̀. Bí Ọlọ́run ṣe ń ṣe àwọn ohun tó ti pinnu pé òun máa ṣe, bẹ́ẹ̀ la túbọ̀ ń mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́. (Òwe 4:18) A mọ̀ pé Ọlọ́run sọ orúkọ rẹ̀ fún Ádámù àti Éfà, torí pé Éfà lo orúkọ náà lẹ́yìn tó bí Kéènì. (Jẹ́n. 4:1) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olóòótọ́, irú bíi Nóà, Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù náà mọ orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n túbọ̀ wá mọ irú ẹni tó jẹ́ bó ṣe ń bù kún wọn, bó ṣe ń bójú tó wọn àti bó ṣe ń sọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún wọn. Nígbà tó yá, Ọlọ́run sọ ohun pàtàkì kan fún Mósè nípa ohun tí orúkọ Rẹ̀ túmọ̀ sí.
4. Kí nìdí tí Mósè fi béèrè orúkọ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa dá wọn nídè?
4 Ka Ẹ́kísódù 3:10-15. Nígbà tí Mósè pé ẹni ọgọ́rin [80] ọdún, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Mú àwọn ènìyàn mi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.” Lẹ́yìn náà ni Mósè bi Ọlọ́run ní ìbéèrè kan tó mọ́gbọ́n dání. Ó ní: ‘Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá wá bi mí pé kí ni orúkọ rẹ, kí ni kí n sọ fún wọn?’ Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run ti mọ orúkọ rẹ̀, kí wá nìdí tí Mósè fi ń béèrè orúkọ Ọlọ́run? Ìdí ni pé ó fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́. Mósè fẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa dá wọn nídè lóòótọ́. Kò sì ṣòro fún wa láti lóye ìyẹn, torí pé ó ti pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà lóko ẹrú, wọ́n sì ti lè máa ṣiyè méjì pé bóyá ni Ọlọ́run lè dá àwọn nídè. Kódà, àwọn kan lára wọn ti ń sin àwọn òrìṣà ilẹ̀ Íjíbítì.—Ìsík. 20:7, 8.
5. Kí ni Jèhófà sọ fún Mósè nípa orúkọ rẹ̀?
5 Ìdáhùn wo ni Jèhófà fún Mósè? Ó ní kí Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín . . . ni ó rán mi sí yín.” Ó tún ní kí Mósè sọ fún wọn pé: “ÈMI YÓÒ JẸ́ ti rán mi sí yín.” * Ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè yìí jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì kan nípa irú Ọlọ́run tó jẹ́. Ó lè di ohunkóhun tó bá fẹ́ tàbí kó ṣe ohunkóhun tó bá yẹ kó ṣe kí àwọn ìlérí rẹ̀ bàa lè ní ìmúṣẹ. Ó jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìdí nìyẹn tó fi sọ síwájú sí i pé: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí á wọ Mósè lọ́kàn gan-an, á sì fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun!
JÈHÓFÀ FI HÀN PÉ ÒUN NI ORÚKỌ NÁÀ TỌ́ SÍ
6, 7. Báwo ni Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
6 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ tó fi mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè. Ó mú kí àwọn ará Íjíbítì rí ìyọnu mẹ́wàá, èyí tó mú kí wọ́n mọ̀ pé Fáráò àti àwọn òrìṣà rẹ̀ kò lágbára kankan. (Ẹ́kís. 12:12) Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí Òkun Pupa pínyà, ó mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, ó sì mú kí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ rì sínú òkun. (Sm. 136:13-15) Nínú aginjù, Jèhófà pèsè jíjẹ àti mímu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pọ̀ níye yẹn. Kódà, aṣọ wọn àti sálúbàtà wọn kò gbó. (Diu. 1:19; 29:5) Gbogbo èyí fi hàn pé kò sí ohun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ tí kò fi ní mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó sọ fún wòlíì Aísáyà pé: “Èmi—èmi ni Jèhófà, yàtọ̀ sí mi, kò sí olùgbàlà kankan.”—Aísá. 43:11.
7 Jóṣúà tó di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn ikú Mósè náà rí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Jèhófà ṣe ní ilẹ̀ Íjíbítì àti nígbà tí wọ́n wà ní aginjù. Torí náà, kí òun pẹ̀lú tó kú, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” (Jóṣ. 23:14) Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, torí pé Jèhófà mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ lónìí?
8 Bákan náà, Jèhófà ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ lónìí. Ó tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ sọ fún wa pé, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, a ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Jèhófà nìkan ló lè sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, òun nìkan ló sì lè mú irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣẹ. Àwọn èèyàn táráyé ò kà sí ló sì ń lò láti ṣe iṣẹ́ náà. (Ìṣe 4:13) Torí náà, bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ńṣe là ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹn ṣẹ. À ń bọlá fún Bàbá wa, a sì ń fi hàn pé òótọ́ la fẹ́ ‘kí orúkọ rẹ̀ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ̀ dé. Kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’—Mát. 6:9, 10.
ORÚKỌ ỌLỌ́RUN KÒ NÍ ÀFIWÉ
9, 10. Kí la tún rí kọ́ látinú àjọṣe Jèhófà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
9 Kò pẹ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì tí Jèhófà fi jẹ́ kí wọ́n mọ púpọ̀ sí i nípa irú ẹni tí òun jẹ́. Jèhófà bá wọn dá májẹ̀mú Òfin, ó sì ṣèlérí fún wọn pé òun á máa tọ́jú wọn bí ọkọ ṣe ń tọ́jú aya rẹ̀. (Jer. 3:14) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run, torí náà ńṣe ni wọ́n dà bí aya fún Jèhófà. (Aísá. 54:5, 6) Bí wọ́n bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, ó máa bù kún wọn, ó máa dáàbò bò wọ́n, ó sì máa mú kí wọ́n wà ní àlàáfíà. (Núm. 6:22-27) Gbogbo orílẹ̀-èdè á wá mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run mìíràn tó dà bíi Jèhófà. (Ka Diutarónómì 4:5-8; Sáàmù 86:7-10.) Ní gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn wá láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kí wọ́n lè máa sin Jèhófà pẹ̀lú wọn. Wọ́n ṣe bíi ti Rúùtù ará Móábù tó sọ fún Náómì pé: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.”—Rúùtù 1:16.
Ẹ́kís. 34:5-7) Àmọ́, sùúrù Jèhófà ní ààlà o. Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kọ̀ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù tí wọ́n sì pa á, Jèhófà ò jẹ́ kí wọ́n jẹ́ orúkọ mọ́ òun mọ́. (Mát. 23:37, 38) Lójú Jèhófà, ńṣe ni wọ́n dà bí òkú igi tí ewé rẹ̀ ti rẹ̀ dà nù. (Lúùkù 23:31) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, irú ojú wo ni wọ́n wá fi ń wo orúkọ Ọlọ́run?
10 Fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan àtààbọ̀ [1,500], àjọṣe tí Jèhófà ní pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún jẹ́ ká mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣàìgbọràn sí i léraléra, ó fi àánú púpọ̀ hàn sí wọn, ó sì tún ní sùúrù fún wọn. (11. Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi lo orúkọ Ọlọ́run mọ́?
11 Nígbà tó ṣe, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò tọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n ronú pé orúkọ Ọlọ́run ti mọ́ kọjá ohun téèyàn lè máa fi ẹnu lásán pè. (Ẹ́kís. 20:7) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bó ṣe di pé wọn kò lo orúkọ Ọlọ́run mọ́ nìyẹn. Ó ti ní láti dun Ọlọ́run gan-an pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbé orúkọ òun ga. (Sm. 78:40, 41) Ọwọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni Jèhófà fi mú orúkọ rẹ̀. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé ó máa ń jowú nítorí orúkọ rẹ̀. Àmọ́, nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbé orúkọ náà ga, wọn kò yẹ láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 34:14) Èyí jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ẹlẹ́dàá.
ÀWỌN ÈÈYÀN TÁ A FI ORÚKỌ ỌLỌ́RUN PÈ
12. Àwọn wo la wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi orúkọ Ọlọ́run pè?
12 Nípasẹ̀ Jeremáyà, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bá orílẹ̀-èdè tuntun kan “dá májẹ̀mú tuntun.” Gbogbo àwọn tó jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tuntun yìí, “láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn àní dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn,” máa “mọ Jèhófà.” (Jer. 31:31, 33, 34) Ìgbà wo ni Ọlọ́run bá wọn dá májẹ̀mú yìí? Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni. Àwọn wo sì ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú náà? Nínú Bíbélì, a pè wọ́n ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè. Jèhófà pè wọ́n ní “àwọn ènìyàn tí a fi orúkọ mi pè.”—Gál. 6:16; ka Ìṣe 15:14-17; Mát. 21:43.
13. (a) Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lo orúkọ Ọlọ́run? Ṣàlàyé. (b) Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá ń lo orúkọ Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
13 Àwọn tó kọ́kọ́ di ara orílẹ̀-èdè tuntun yìí lo orúkọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lo orúkọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. * Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù bá ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn aláwọ̀ṣe tó wá sí Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀ nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó lo orúkọ Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà. (Ìṣe 2:14, 20, 21, 25, 34) Nítorí pé àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni yìí gbé orúkọ Ọlọ́run ga, Jèhófà rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù wọn. Bí àwa náà bá sọ orúkọ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn tá a sì fi hàn wọ́n nínú Bíbélì, Jèhófà máa fìbùkún rẹ̀ sí iṣẹ́ wa. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ fún wa láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run. Orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n mọ̀ yẹn lè mú kí wọ́n ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ lè máa lágbára sí i, ó sì lè máa bá a nìṣó títí láé.
14, 15. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kò jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ di ìgbàgbé?
14 Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, pàápàá jù lọ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀kọ́ èké ba ìjọ Kristẹni jẹ́. (2 Tẹs. 2:3-7) Kódà, àwọn tó ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni yìí tún ń tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù pé káwọn èèyàn má ṣe lo orúkọ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ Ọlọ́run gbà kí wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ di ìgbàgbé? Rárá o! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé orúkọ Ọlọ́run ṣì wà títí dòní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má mọ bí wọ́n ṣe ń pè é ní ìgbà àtijọ́. Tipẹ́tipẹ́ ni orúkọ Ọlọ́run ti wà nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì àti nínú ìwé tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé kọ. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1757, Charles Peters sọ pé ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí ló ṣàlàyé irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ fún wa ju orúkọ oyè èyíkéyìí lọ. Nínú ìwé kan tó dá lórí ìjọsìn Ọlọ́run, èyí tí Hopton Haynes ṣe lọ́dún 1797, ó sọ pé Jèhófà ni orúkọ táwọn Júù ń pe Ọlọ́run. Ó tún sọ pé: “Òun nìkan ni wọ́n ń sìn; ohun tí Kristi àti àwọn Àpọ́sítélì náà sì ṣe nìyẹn.” Henry Grew, tó gbé ayé láàárín ọdún 1781 sí ọdún 1862 lo orúkọ Ọlọ́run, ó tún mọ̀ pé àwọn èèyàn ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run, a sì gbọ́dọ̀ ya orúkọ náà sí mímọ́. Bákan náà, George Storrs, tó gbé ayé láàárín ọdún 1796 sí ọdún 1879 àti Charles T. Russell, tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ lo orúkọ Ọlọ́run.
15 Ọdún mánigbàgbé ni ọdún 1931 jẹ́ fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Kó tó di ọdún yẹn, orúkọ táwọn èèyàn máa ń pè wọ́n ni International Bible Students, ìyẹn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n wà káàkiri àgbáyé. Àmọ́, ní ọdún yẹn, wọ́n gba orúkọ tuntun náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísá. 43:10-12) Wọ́n jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé ohun ìwúrí ni fún àwọn láti jẹ́ “ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” àti láti máa gbé orúkọ rẹ̀ ga. (Ìṣe 15:14) Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà kò ṣe jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ di ìgbàgbé, ó máa rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ inú Málákì 1:11 pé: “Láti yíyọ oòrùn àní dé wíwọ̀ rẹ̀, orúkọ mi yóò tóbi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”
MÁA RÌN NÍ ORÚKỌ JÈHÓFÀ
16. Báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa táwọn èèyàn bá ń pè wá ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
16 Wòlíì Míkà sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ pé Ọlọ́run gbà káwọn èèyàn rẹ̀ nígbà yẹn máa jẹ́ orúkọ mọ́ ọn. Àmọ́, èyí tó tún wá ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ni pé ó mú kó dá wọn lójú pé inú Ọlọ́run ń dùn sí wọn. (Ka Málákì 3:16-18.) Ìwọ ńkọ́? Ṣé ò ń ṣiṣẹ́ kára kó o lè máa “rìn ní orúkọ Jèhófà”?
17. Kí ló túmọ̀ sí láti máa “rìn ní orúkọ Jèhófà”?
17 Ó kéré tán, ohun mẹ́ta la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè máa rìn ní orúkọ Jèhófà. Ohun àkọ́kọ́ ni pé a gbọ́dọ̀ sọ orúkọ náà fáwọn èèyàn, torí pé kìkì àwọn tó bá “ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Róòmù 10:13) Èkejì, a gbọ́dọ̀ fìwà jọ Jèhófà, pàápàá jù lọ ká ní ìfẹ́. Ẹ̀kẹta, a gbọ́dọ̀ máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ tọkàntọkàn, ká sì máa tipa bẹ́ẹ̀ gbé orúkọ Bàbá wa ga. (1 Jòh. 4:8; 5:3) Ṣé wàá máa bá a nìṣó láti “rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa” títí láé?
18. Kí nìdí tí ọkàn àwọn tó ń gbé orúkọ Jèhófà ga fi balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?
18 Gbogbo àwọn ti kò fi ti Jèhófà ṣe tàbí tí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀ máa tó mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. (Ìsík. 38:23) Ńṣe ni wọ́n dà bíi Fáráò tó sọ pé: “Ta ni Jèhófà, tí èmi yóò fi ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀.” Kò sì pẹ́ tó fi mọ bí agbára Jèhófà Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. (Ẹ́kís. 5:1, 2; 9:16; 12:29) A ti pinnu láti mọ Jèhófà ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ohun ìwúrí ló jẹ́ fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀, ká máa ṣègbọràn sí i, ká sì tún máa jẹ́ orúkọ mọ́ ọn. Ọkàn wa balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára, a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí rẹ̀ tó wà ní Sáàmù 9:10 pé: “Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ, nítorí tí ìwọ, Jèhófà, kì yóò fi àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀ dájúdájú.”
^ ìpínrọ̀ 5 Orúkọ náà jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe Hébérù kan tó túmọ̀ sí “di,” ìyẹn ni pé Ọlọ́run lè “di” ohunkóhun tó bá wù ú kó lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Látàrí ìyẹn, orúkọ náà, “Jèhófà” túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.”—Jẹ́n. 2:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
^ ìpínrọ̀ 13 Orúkọ Jèhófà wà nínú ìwé mímọ́ lédè Hébérù táwọn Kristẹni lò ní ọ̀rúndún kìíní. Ẹ̀rí tún fi hàn pé orúkọ náà wà nínú ìtumọ̀ Septuagint, tó jẹ́ Ìwé Mímọ́ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì.