ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ April 2013

Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti bá a ṣe lè máa lo ọgbọ́n Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa àti nínú ìgbé ayé wa.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—ní Mẹ́síkò

Wo ohun tó mú kí àwọn ọ̀dọ́ kan borí oríṣiríṣí ìṣòro kí wọ́n lé ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.

Jàǹfààní Kíkún Látinú Kíka Bíbélì Déédéé

Ìgbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń fi ohun tá à ń kọ́ sílò ló tó máa ṣe wá láǹfààní. Kọ́ bóo ṣe lé túbọ̀ jàǹfààní látinú kíká Bíbélì.

Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ran Ara Rẹ Àti Àwọn Míì Lọ́wọ́

Ṣé o ká Bíbélì sí ìwé kan tó ṣeyebíye? Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà ní 2 Tímótì 3:16, ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú ẹ̀bùn tí Jèhófà fún ẹ yìí túbọ̀ lágbára.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Fi Àádọ́ta Ọdún Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Ní Ilẹ̀ Olótùútù

Ka ìtan ìgbésí ayé Aili àti Annikki Mattila tí wọ́n kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ aṣáájù-ọ̀nà ní àríwá Finland.

Ẹ Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù

Ọlá ńlá ló jẹ́ fún wa pé a wà nínú ètò Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè máa kọ́wọ́ ti ètò Ọlọ́run?

Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Àárẹ̀ Mú Yín

Báwo la ṣe lè máa bá ètò Ọlọ́run rìn kí ìtara wa má sì dín kù?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Jésù sọ pé wọ́n máa pa tẹ́ńpìlì Jèhófà run pátápátá. Ǹjẹ́ wọ́n tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́ lẹ́yìn ọdún 70 Sànmánì Kristẹni?