Ẹ Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù
“Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—FÍLÍ. 1:10.
1, 2. Kí ni Jésù sọ nípa ọjọ́ ìkẹyìn tó ṣeé ṣe kó mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe kàyéfì, kí sì nìdí?
ÌGBÀ kan wà tí Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù, àti Áńdérù nìkan wà pẹ̀lú Jésù. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù máa pa run. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn nípa ohun tó ń bọ́ wá ṣẹlẹ̀. (Máàkù 13:1-4) Torí náà, nígbà tó ku àwọn mẹ́rin náà àti Jésù nìkan, wọ́n bi í pé: “Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mát. 24:1-3) Nígbà tí Jésù ń dáhùn ìbéèrè wọn, ó sọ fún wọn nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn náà, ó tún sọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Ó sọ fún wọn pé àwọn nǹkan ìjayà bí ogun, ìyàn àti ìwà burúkú máa wà. Lẹ́yìn náà ló wá sọ ohun kan tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:7-14.
2 Ṣáájú àkókò yìí, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 8:1; 9:1, 2) Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Lúùkù 10:2) Torí náà, wọ́n ti ní láti máa ṣe kàyéfì pé: ‘Báwo la ṣe máa wàásù “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé,” ká sì jẹ́rìí fún “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè”? Ibo làwọn òṣìṣẹ́ á ti wá?’ Ká sọ pé ó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn láti rí ọjọ́ iwájú nígbà tí wọ́n wà pẹ̀lú Jésù lọ́jọ́ yẹn ni, ìyàlẹ́nu ni ì bá jẹ́ fún wọn láti rí bi ọ̀rọ̀ inú Mátíù 24:14 yẹn ṣe máa ní ìmúṣẹ.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká ka ohun tí Jésù sọ nínú Lúùkù 21:34 sí pàtàkì lóde òní? Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
3 Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ti ń ṣẹ lóde òní. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri ayé. (Aísá. 60:22) Àmọ́ Jésù tún sọ pé ó máa ṣòro fún àwọn kan láti pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Àwọn nǹkan míì á mú kí ọwọ́ wọ́n dí ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn á sì “dẹrù pa” wọ́n. (Ka Lúùkù 21:34.) À ń rí bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ lónìí pẹ̀lú, ó sì ṣe pàtàkì pé ká fiyè sí i. Ìdí ni pé àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ò fi ohun tó ṣe pàtàkì jù sí ipò kìíní mọ́. A sì ń rí èyí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu nípa iṣẹ́, ilé ẹ̀kọ́ gíga, tàbí àwọn ohun ìní tara. Àwọn míì ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí eré ìdárayá. Àwọn míì ò sì ṣe tó bó ṣe yẹ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run torí àníyàn ojoojúmọ́. Bi ara rẹ pé: ‘Èmi ńkọ́? Ǹjẹ́ bí mo ṣe máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ló máa ń jẹ mí lógún jù lọ?’
4. (a) Àdúrà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì, kí sì nìdí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó kàn? Báwo ni àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?
4 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣì ní láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gbàdúrà pé kí àwọn tó wà ní Fílípì máa “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Ka Fílípì 1:9-11.) Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni nígbà yẹn ló “túbọ̀ ń fi ìgboyà púpọ̀ sí i hàn láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.” (Fílí. 1:12-14) Bákan náà lónìí, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ń fi ìgboyà wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, nínú àpilẹ̀kọ yìí, ohun ìwúrí ló máa jẹ́ fún wa láti jíròrò bí Jèhófà ṣe ń lo ètò rẹ̀ lónìí láti mú ọ̀rọ̀ inú Mátíù 24:14 ṣẹ. Èyí á mú ká túbọ̀ máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. Kí ni ètò Jèhófà ń ṣe? Báwo lèyí sì ṣe ń fún àwa àti ìdílé wa níṣìírí? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ohun tó lè mú ká máa lo ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti bá a ṣe lè jẹ́ kí ètò Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà.
APÁ TI Ọ̀RUN LÁRA ÈTÒ JÈHÓFÀ
5, 6. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan rí ìran nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run? (b) Kí ni Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran?
5 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí Ọlọ́run kò jẹ́ kó wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, kò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé fún wa nípa ọpọlọ wa àti nípa àgbáyé. Ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ká mọ ohun tí òun fẹ́, ká lè máa ṣègbọràn sí i. (2 Tím. 3:16, 17) Torí náà, ńṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà yàn láti sọ fún wa nípa apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀, èyí tí a kò lè fojú rí! Ó múni lọ́kàn yọ̀ pé a lè ka àwọn ìsọfúnni náà nínú àwọn ìwé Bíbélì bí Aísáyà, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì àti nínú ìwé Ìṣípayá, tó sọ̀rọ̀ nípa ìran tí Jòhánù rí. (Aísá. 6:1-4; Ìsík. 1:4-14, 22-24; Dán. 7:9-14; Ìṣí. 4:1-11) Àmọ́, kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run?
6 Jèhófà fẹ́ ká máa rántí nígbà gbogbo pé a jẹ́ ara ètò kan ṣoṣo tó ń lò láyé àtọ̀run. Àwọn tó jẹ́ apá ti ọ̀run lára ètò yìí ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Ìsíkíẹ́lì rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin gìrìwò kan tó dúró fún apá Ìsík. 1:15-21) Ìsíkíẹ́lì tún rí ẹni tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Ó sọ pé: “Mo sì rí ohun kan tí ó dà bí ìpọ́nyòò àyọ́lù wúrà-òun-fàdákà, bí ìrísí iná yí ká . . . Ìrísí ti ìrí ògo Jèhófà ni.” (Ìsík. 1:25-28) Kò sí àní-àní pé ìran yìí á ya Ìsíkíẹ́lì lẹ́nu gan-an! Ó rí i pé Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló sì fi ń darí rẹ̀ lọ síbi tó bá fẹ́. Kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó wà lórí ìrìn yẹn ló ṣàpẹẹrẹ bí nǹkan ṣe ń lọ nínú apá tó jẹ́ ti ọ̀run lára ètò Jèhófà.
ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. Kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ń yára sáré, ó sì lè gba ibi tí ẹ̀mí bá darí rẹ̀ sí lójú ẹsẹ̀. (7. Báwo ni ìran tí Dáníẹ́lì rí ṣe mú wa lọ́kàn le?
7 Dáníẹ́lì náà rí ìran tó mú wa lọ́kàn le. Ó rí Jèhófà “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” tó jókòó lórí ìtẹ́ tó ní àgbá kẹ̀kẹ́. (Dán. 7:9) Jèhófà fẹ́ kí Dáníẹ́lì rí i pé ètò òun wà lórí ìrìn, ìyẹn ni pé ó ń ṣiṣẹ́ kó lè máa mú ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn ṣẹ. Lẹ́yìn náà ni Dáníẹ́lì rí “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Jésù, tó ń gba agbára tí yóò fi máa ṣàkóso apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà. Kì í ṣe ọdún díẹ̀ péré ni Jésù máa fi ṣàkóso ayé. Bíbélì sọ pé Ìjọba rẹ̀ máa jẹ́ “ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.” (Dán. 7:13, 14) Ìran yìí mú kó wù wá láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì túbọ̀ máa kíyèsí àwọn nǹkan tó ń gbé ṣe. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ọwọ́ Jèhófà ni Jésù ti gba agbára ìṣàkóso, ìran yìí á tún jẹ́ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa.
8. Báwo ló ṣe rí lára Ìsíkíẹ́lì àti Aísáyà nígbà tí wọ́n rí ìran ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run? Ipa wo ló yẹ kó ní lórí àwa náà?
Ìsík. 1:28) Wòlíì Aísáyà náà rí ìran nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run. Nígbà tó láǹfààní láti sọ fún àwọn èèyàn nípa ohun tí Jèhófà ń gbé ṣe, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà láìjáfara. (Ka Aísáyà 6:5, 8.) Torí pé Jèhófà ń ti Aísáyà lẹ́yìn, ó mọ̀ pé kò sí ohunkóhun tó lè dí òun lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún òun. Bíi ti Aísáyà, àwa náà fẹ́ máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa ṣètìlẹ́yìn fún ètò Jèhófà. Ohun ìwúrí ni fún wa pé a wà nínú ètò kan tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà.
8 Kí ló yẹ kí ètò Jèhófà tí Ìsíkíẹ́lì àti Aísáyà rí nínú ìran yìí mú ká ṣe? Bíi ti Ìsíkíẹ́lì, àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ń gbé ṣe ń wú wa lórí gan-an ni. (APÁ TI ILẸ̀ AYÉ LÁRA ÈTÒ JÈHÓFÀ
9, 10. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kí ètò Ọlọ́run ní apá ti ilẹ̀ ayé?
9 Nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jèhófà dá apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀ sílẹ̀. Apá ti ilẹ̀ ayé yìí sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú apá ti òkè ọ̀run. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kí ètò Ọlọ́run ní apá ti ilẹ̀ ayé kí ohun tí Jésù sọ ní Mátíù 24:14 tó lè ṣẹ? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́ta lára ìdí tó fi pọn dandan.
10 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa wàásù dé “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ìdí kejì ni pé àwọn tó máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà máa nílò ìtọ́ni àti ìṣírí látinú Bíbélì. (Jòh. 21:15-17) Ìdí kẹta sì ni pé wọ́n máa nílò ibi tí wọ́n á ti máa pé jọ láti sin Jèhófà kí wọ́n sì gba ìtọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù. (Héb. 10:24, 25) Kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó lè ṣe gbogbo èyí, wọ́n gbọ́dọ̀ wà létòlétò.
11. Báwo la ṣe lè máa kọ́wọ́ ti ètò Ọlọ́run?
11 Báwo la ṣe lè máa kọ́wọ́ ti ètò Ọlọ́run? Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa fọkàn tán àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Jèhófà àti Jésù fọkàn tán àwọn arákùnrin yìí, ó sì yẹ kí àwa náà fọkàn tán wọn. Àwọn arákùnrin yìí kò jẹ́ kí àwọn ohun tó ń lọ nínú ayé yìí gbà wọ́n lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni àwọn arákùnrin tó ń ṣojú fún apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run yìí máa ń gbájú mọ́. Kí lohun náà?
WỌ́N FI “ÀWỌN OHUN TÍ Ó ṢE PÀTÀKÌ JÙ” SÍ IPÒ KÌÍNÍ
12, 13. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń ṣe ojúṣe wọn? Kí nìdí tí ìyẹn fi jẹ́ ohun ìwúrí fún ẹ?
12 Kárí ayé, ètò Ọlọ́run ń lo àwọn alàgbà tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ láti ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. Bí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu, wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n máa ń fi ṣe ‘fìtílà fún ẹsẹ̀ wọn, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wọn,’ wọ́n sì máa ń gbàdúrà kíkankíkan pé kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà. Lọ́nà yìí, wọ́n ń jẹ́ kí apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà darí wọn.—Sm. 119:105; Mát. 7:7, 8.
13 “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà” ni àwọn alàgbà tó ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ní ọ̀rúndún kìíní fi sí ipò kìíní. Ohun tí àwọn alàgbà tó ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù lónìí náà ń ṣe nìyẹn. (Ìṣe 6:4) Inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí i tí iṣẹ́ ìwàásù náà ń tẹ̀síwájú ní orílẹ̀-èdè wọn àti láwọn ibi tó kù lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣe 21:19, 20) Wọn kì í ṣe òfin rẹpẹtẹ nípa báwọn èèyàn Ọlọ́run á ṣe máa ṣe gbogbo nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń jẹ́ kí Bíbélì àti ẹ̀mí Ọlọ́run darí àwọn láti ṣe ohun tó bá yẹ, kí iṣẹ́ ìwàásù náà lè máa tẹ̀síwájú. (Ka Ìṣe 15:28.) Lọ́nà yìí, àwọn arákùnrin yìí ń fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún gbogbo àwọn ará nínú ìjọ.—Éfé. 4:11, 12.
14, 15. (a) Kí ni ètò Ọlọ́run ń ṣe kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti wàásù kárí ayé? (b) Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá ń ronú nípa ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù?
14 Ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin wa ló ń ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́ láti pèsè àwọn ìtẹ̀jáde wa, àwọn mìíràn sì ń ṣètò àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ń ṣiṣẹ́ kára láti túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè tó ju ẹgbẹ̀ta [600] lọ. Látàrí èyí, ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti kọ́ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” ní èdè ìbílẹ̀ wọn. (Ìṣe 2:7-11) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti tẹ àwọn ìwé wa kí wọ́n sì tún fi ẹ̀rọ dì wọ́n pọ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá kó wọn lọ sí àwọn ìjọ, títí dé àwọn ibi tó jìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.
15 Àwọn ará tó wà nínú ìjọ ń sapá gidigidi láti ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ló ń yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àwọn míì máa ń ran àwọn tí ìjábá tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. Àwọn míì ń ṣètò àwọn àpéjọ tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, a sì rí lára àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí ètò Ọlọ́run dá sílẹ̀. Kí nìdí tá a fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ yìí? À ń ṣe iṣẹ́ yìí ká bàa lè máa wàásù ìhìn rere, kí òtítọ́ lè túbọ̀ máa jinlẹ̀ nínú wa, ká sì lè máa ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sin Jèhófà. Láìsí àní-àní, apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run ti fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù sí ipò kìíní.
MÁA TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
16. Kí lo lè ṣèwádìí lé lórí nígbà Ìjọsìn Ìdílé tàbí tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́?
16 Ǹjẹ́ a tiẹ̀ máa ń ronú nípa ohun tí ètò Jèhófà ń gbé ṣe? Tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà Ìjọsìn Ìdílé, o lè ṣèwádìí nípa ètò Ọlọ́run kó o sì ṣe àṣàrò nípa ohun tó o kọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìran tí Jèhófà fi hàn Aísáyà, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì àti Jòhánù, o máa gbádùn rẹ̀ gan-an. O tún lè rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa ètò Ọlọ́run nínú ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tàbí àwọn àwo DVD tó bá wà ní èdè rẹ.
17, 18. (a) Ki lo rí kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ?
17 Ó dára ká máa ṣe àṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe ń lo ètò rẹ̀ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà máa tẹ̀síwájú. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé a ó máa bá ètò àgbàyanu Ọlọ́run rìn, a ó sì máa fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù sí ipò kìíní. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ tiwa náà máa dà bíi ti Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ní ìbámu pẹ̀lú àánú tí a fi hàn sí wa,” àwa kò “juwọ́ sílẹ̀.” (2 Kọ́r. 4:1) Ó tún gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gál. 6:9.
18 Ǹjẹ́ àwọn ìyípadà kan wà tó yẹ kí ìwọ tàbí ìdílé rẹ ṣe, kẹ́ ẹ lè máa fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù sí ipò kìíní lójoojúmọ́? Ǹjẹ́ o lè dín àwọn nǹkan tó ń dí ẹ lọ́wọ́ kù kó o lè ní àkókó tó pọ̀ sí i fún iṣẹ́ ìwàásù? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan márùn-ún tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ lára ètò Jèhófà, ká sì jẹ́ kí iná ìtara wa máa jó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.