Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ṣé wọ́n máa ń kan àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá fẹ́ pa mọ́ igi?

Nígbà àtijọ́, láwọn ibi tó pọ̀ jù lọ láyé, tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ̀daràn, wọ́n máa ń kàn wọ́n mọ́ igi tàbí òpò, wọ́n á sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ títí ẹ̀mí á fi bọ́ lára wọn. Ó tiẹ̀ wọ́pọ̀ gan-an fún àwọn ará Róòmù láti máa de ọ̀daràn mọ́ igi tàbí kí wọ́n kàn án mọ́ igi. Wọ́n á wá fi ọ̀daràn náà sílẹ̀, á máa jẹ̀rora, láìsí omi àti oúnjẹ. Oòrùn á pa á, òjò á pa á títí ó fi máa gbẹ́mìí mì. Àwọn ọ̀daràn tí kò lẹ́nu láwùjọ làwọn ará Róòmù máa ń kàn mọ́gi, kí ojú bàa lè tì wọ́n, torí pé gbogbo èèyàn ló máa rí wọn tí wọ́n á sì mọ̀ nípa ohun tí wọ́n ṣe.

Ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì náà máa ń kan àwọn ọ̀daràn mọ́ igi? Òfin Mósè sọ pé: “Bí ó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ní ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yẹ fún ìdájọ́ ikú, tí a sì fi ikú pa á, tí ìwọ sì ti gbé e kọ́ sórí òpó igi, kí òkú rẹ̀ má ṣe wà lórí òpó igi ní gbogbo òru; ṣùgbọ́n, lọ́nàkọnà, kí ẹ sin ín ní ọjọ́ yẹn.” (Diu. 21:22, 23) Èyí mú kí ó ṣe kedere pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, bí ikú bá tọ́ sí ọ̀daràn kan, ńṣe ni wọ́n máa kọ́kọ́ pa á kí wọ́n tó gbé e kọ́ sórí igi.

Èyí bá ohun tó wà ní Léfítíkù 20:2 mu, èyí tó sọ pé: “Ọkùnrin èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti àtìpó èyíkéyìí tí ń ṣe àtìpó ní Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Mólékì, kí a fi ikú pa á láìkùnà. Kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.” Títí kan àwọn tó ní “agbára ìbẹ́mìílò tàbí ẹ̀mí ìsàsọtẹ́lẹ̀” ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi ikú pa. Irú ikú wo ni wọ́n máa ń fi pa wọ́n? Ńṣe ni wọ́n máa ń ‘sọ wọ́n ní òkúta pa.’—Léf. 20:27

Ìwé Diutarónómì 22:23, 24 náà sọ pé: “Bí ó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́mọbìnrin wúńdíá kan wà, tí ọkùnrin kan fẹ́ sọ́nà, tí ọkùnrin kan, ní ti tòótọ́, sì rí i ní ìlú ńlá, tí ó sì sùn tì í, kí ẹ mú àwọn méjèèjì jáde wá sí ẹnubodè ìlú ńlá yẹn, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta, kí wọ́n sì kú, ọ̀dọ́mọbìnrin náà fún ìdí náà pé kò lọgun nínú ìlú ńlá náà, àti ọkùnrin náà fún ìdí náà pé ó tẹ́ aya ọmọnìkejì rẹ̀ lógo. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò mú ohun tí ó jẹ́ ibi kúrò láàárín rẹ.” Èyí fi hàn pé òkúta làwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ máa ń sọ lu ọ̀daràn tó hùwà burúkú títí ó fi máa kú. *

Ó ṣe kedere pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, bí ikú bá tọ́ sí ọ̀daràn kan, ńṣe ni wọ́n máa kọ́kọ́ pa á kí wọ́n tó gbé e kọ́ sórí igi

Ìwé Diutarónómì 21:23 tún sọ pé: “ohun ègún Ọlọ́run ni ẹni tí a gbé kọ́.” Bí wọ́n ṣe máa ń gbé òkú ọ̀daràn tí Ìwé Mímọ́ pè ní “ohun ègún Ọlọ́run” kọ́ ní gbangba máa ń nípa lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù. Lọ́nà wo? Ní ti pé, bí wọ́n ṣe gbé òkú yẹn kọ́ máa jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn míì.

^ ìpínrọ̀ 6 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ohun tí Òfin sọ ni pé kí wọ́n kọ́kọ́ pa ọ̀daràn kan kí wọ́n tó gbé òkú rẹ̀ kọ́ sórí igi. Àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn kan lára àwọn Júù kan àwọn ọ̀daràn kan mọ́gi láàyè, tí wọ́n á sì kú sórí igi.