Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Láàárọ̀ ọjọ́ Wednesday, September 5, 2012, wọ́n ṣe ìfilọ̀ kan fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ti Kánádà pé wọ́n ti fi ẹnì kan kún Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mark Sanderson ni orúkọ arákùnrin náà. September 1, 2012 ló sì di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí Arákùnrin Sanderson, ìlú San Diego, ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó sì ṣèrìbọmi ní February 9, 1975. Ó di aṣáájú-ọ̀nà ní September 1, 1983 nílùú Saskatchewan, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ní December 1990, ó wà lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì keje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ (tá à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n báyìí) tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tó di oṣù April 1991 ètò Ọlọ́run yan Arákùnrin Sanderson gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ó sì sìn ní erékùṣù Newfoundland, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ó tún sìn gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká kó tó di pé ètò Ọlọ́run pè é sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà ní oṣù February 1997. Nígbà tó fi máa di November 2000, wọ́n pè é sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Níbẹ̀, ó ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn, lẹ́yìn náà, ó ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn.

Ní oṣù September ọdún 2008, Arákùnrin Sanderson lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Tó Jẹ́ Ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Ìgbà tó parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ni wọ́n ní kó lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Philippines. Ní oṣù September 2010, wọ́n ní kó pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti wá máa ran Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn tó jẹ́ ara ẹ̀ka Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́.