“Àwòrán Yìí Mà Dára Gan-an O!”
Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí rí, bóyá nígbà tó ò ń yẹ ẹ̀dà tuntun ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ wò. Ńṣe ni wọ́n gbé àwọn àwòrán tí wọ́n fara balẹ̀ yà wọ̀nyẹn síbẹ̀ fún ìdí pàtàkì kan. Àrànṣe ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n, tó ń mú ká túbọ̀ ronú jinlẹ̀, kí ohun tá à ń kọ́ sì wọ̀ wá lọ́kàn. Wọ́n máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tá à ń kọ́ nígbà tá a bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti nígbà tá a bá ń dáhùn nípàdé.
Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwòrán tó máa ń wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Bi ara rẹ pé, kí nìdí tí wọ́n fi lo àwòrán yìí? Kí ni àwòrán yìí ń sọ? Ṣé ó tan mọ́ àkòrí àpilẹ̀kọ náà tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ tá a gbé àpilẹ̀kọ náà kà? Àwọn àwòrán míì tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà ńkọ́? Ó yẹ ká máa ronú nípa bí wọ́n ṣe kan kókó tí àpilẹ̀kọ náà dá lé àti ibi tó ti kan àwa fúnra wa.
Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ máa fún àwùjọ láǹfààní láti sọ bí àwọn àwòrán yẹn ṣe yé wọn sí, bó ṣe kan ohun tí wọ́n ń jíròrò àti ohun tí wọ́n rí kọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àlàyé ṣókí máa ń wà pẹ̀lú àwọn àwòrán míì, ó sì tún lè tọ́ka sí ìpínrọ̀ tó ṣàlàyé àwòrán náà. Níbi tí wọn ò bá sì ti tọ́ka sí ìpínrọ̀ pàtó tí àwòrán kan tan mọ́, olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lè pe àfiyèsí àwùjọ sí ìpínrọ̀ tó ṣàlàyé irú àwòrán bẹ́ẹ̀. Èyí á mú kí àwùjọ lè túbọ̀ ronú jinlẹ̀, kí wọ́n sì túbọ̀ lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Arákùnrin kan sọ pé, “Lẹ́yìn téèyàn bá ka àpilẹ̀kọ kan tó gbádùn mọ́ni tán, àwọn àwòrán yẹn gan-an ló máa ń jẹ́ kí òye rẹ̀ túbọ̀ yéni kedere.”