Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Wò ó! Mo Wà Pẹ̀lú yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”

“Wò ó! Mo Wà Pẹ̀lú yín ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”

“Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—MÁT. 28:20.

1. (a) Ní ṣókí, sọ àkàwé àlìkámà àti èpò. (b) Báwo ni Jésù ṣe túmọ̀ àkàwé náà?

Ọ̀KAN lára àwọn àkàwé tí Jésù ṣe nípa Ìjọba Ọlọ́run ni èyí tó sọ nípa afúnrúgbìn kan tó fúnrúgbìn àlìkámà àmọ́ tí ọ̀tá kan lọ gbin èpò sáàárín irúgbìn rere náà. Èpò yìí dàgbà gan-an débi pé ó bo àlìkámà náà mọ́lẹ̀. Àmọ́, afúnrúgbìn náà sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé kí wọ́n “jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀ títí di ìkórè.” Nígbà ìkórè, wọ́n fi iná sun àwọn èpò náà, wọ́n sì kó àlìkámà jọ. Jésù alára náà ló sọ ìtumọ̀ àkàwé yìí. (Ka Mátíù 13:24-30, 37-43.) Kí la rí kọ́ nínú àkàwé yìí? (Wo àpótí tó ní àkòrí náà, “Àlìkámà àti Èpò.”)

2. (a) Kí làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú oko afúnrúgbìn inú àkàwé náà jẹ́ ká mọ̀? (b) Apá wo nínú àkàwé náà la máa jíròrò?

2 Kókó méjì ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní oko afúnrúgbìn yìí jẹ́ ká mọ̀. Àkọ́kọ́ ni bí Jésù ṣe máa kó àwọn tó fi wé àlìkámà yìí jọ láàárín aráyé. Àwọn tó fi wé àlìkámà yìí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀. Kókó kejì ni ìgbà tó máa kó wọn jọ. Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀ sí í fún irúgbìn náà. Kíkó àwọn àlìkámà jọ máa parí nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù ní òpin ètò àwọn nǹkan yìí bá gba èdìdì wọn ìkẹyìn lẹ́yìn èyí tí wọ́n á wá lọ sí ọ̀run. (Mát. 24:31; Ìṣí. 7:1-4) Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá gorí òkè téńté, ó máa rọrùn láti rí ibi tó jìnnà níwá-lẹ́yìn àti lọ́tùn-ún-lósì, bẹ́ẹ̀ ni àkàwé yìí ṣe mú ká lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láàárín nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì gbáko. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run wo la ti wá lóye? Àkàwé náà sọ nípa ìgbà tá a fún irúgbìn, ìgbà tó dàgbà àti ìgbà ìkórè. Àmọ́ ìgbà ìkórè yẹn nìkan la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. *

ABẸ́ ÀBÓJÚTÓ JÉSÙ LÓ WÀ

3. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì? (b) Bó ṣe wà nínú Mátíù 13:28, àwọn wo ló béèrè ìbéèrè? Kí ni wọ́n sì béèrè? (Tún wo àfikún àlàyé.)

3 Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni ni “àwọn èpò fara hàn,” nígbà táwọn Kristẹni afàwọ̀rajà bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀. (Mát. 13:26) Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin, àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò yìí ti wá pọ̀ gan-an ju àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ. Ẹ rántí pé nínú àkàwé Jésù, àwọn ẹrú náà sọ pé kí ọ̀gá náà jẹ́ káwọn lọ tu èpò tó wà nínú oko yẹn dà nù. * (Mát. 13:28) Kí ni ọ̀gá wọn sọ?

4. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ Ọ̀gá náà, ìyẹn Jésù fi hàn? (b) Ìgbà wo ni àwọn Kristẹni tá a fi wé àlìkámà wá fara hàn kedere?

4 Nínú àkàwé àlìkámà àti èpò, Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀ títí di ìkórè.” Ohun tí ọ̀gá yìí sọ fáwọn ẹrú rẹ̀ fi hàn pé kò sígbà kan tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tá a fi wé àlìkámà kò sí lórí ilẹ̀ ayé, láti ọ̀rúndún kìíní títí di àkókò wa yìí. Ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ó sọ pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Èyí fi hàn pé Jésù máa pa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ́ títí di àkókò òpin. Àmọ́, látàrí bí àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò ṣe pọ̀ gan-an jù wọ́n lọ, a ò lè fi ìdánilójú sọ pé ẹni báyìí wà lára àwọn ojúlówó Kristẹni tá a fi wé àlìkámà ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi dàgbà pọ̀ yẹn. Bó ti wù kó rí, ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ṣáájú àkókò ìkórè, àwọn ojúlówó Kristẹni tá a fi wé àlìkámà wá fara hàn kedere. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà fara hàn kedere?

OŃṢẸ́ KAN “TÚN Ọ̀NÀ ṢE”

5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Málákì ṣe ṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?

5 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí Jésù tó ṣàkàwé àlìkámà àti èpò, Jèhófà ti mí sí wòlíì Málákì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó tan mọ́ àkàwé Jésù. (Ka Málákì 3:1-4.) Jòhánù Oníbatisí ni ońṣẹ́ tàbí ìránṣẹ́ tó palẹ̀ ọ̀nà mọ́. (Mát. 11:10, 11) Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, ó ṣe kedere pé àkókò tí Ọlọ́run máa dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ ti sún mọ́lé. Jésù ni ońṣẹ́ kejì. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fọ tẹ́ńpìlì mọ́. Àkọ́kọ́, lápá ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ẹ̀ẹ̀kejì, lápá ìparí. (Mát. 21:12, 13; Jòh. 2:14-17) Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ tí Jésù ṣe gba sáà àkókò kan.

6. (a) Ìmúṣẹ tó gbòòrò wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Málákì ní? (b) Ìgbà wo ni Jésù ṣèbẹ̀wò sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí? (Tún wo àfikún àlàyé.)

6 Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Málákì ṣe ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò? Láwọn ọdún tó ṣáájú ọdún 1914, arákùnrin C. T.  Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ló ṣiṣẹ́ tó jọ ti Jòhánù Oníbatisí. Iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ṣe ni pé, wọ́n pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyẹn mú káwọn èèyàn mọ bí ẹbọ ìràpadà Kristi ti ṣe pàtàkì tó, wọ́n tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé irọ́ pátápátá ni ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì, wọ́n sì kéde pé Àkókò Kèfèrí máa tó dópin. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwùjọ àwọn onísìn ló sọ pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi làwọn. Ìbéèrè pàtàkì tó nílò ìdáhùn ni pé: Èwo nínú àwùjọ àwọn onísìn yìí ni àlìkámà? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, Jésù ṣèbẹ̀wò sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí lọ́dún 1914. Ìbẹ̀wò àti ìṣẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ sì gba sáà àkókò kan, ìyẹn láti ọdún 1914 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919. *

ÀKÓKÒ TÍ JÉSÙ ṢE ÌBẸ̀WÒ ÀTI IṢẸ́ ÌWẸ̀NÙMỌ́

7. Kí ni Jésù rí nígbà tó bẹ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí wò lọ́dún 1914?

7 Kí ni Jésù rí nígbà tó bẹ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí wò? Ó rí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara tí wọ́n ń lo okun wọn àti ohun ìní wọn láti máa wàásù nílé lóko, ó sì ti lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún tí wọ́n ti wà lẹ́nu iṣẹ́ náà. * Ẹ wo bí inú Jésù àtàwọn ańgẹ́lì ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá àwọn kéréje yìí lẹ́nu iṣẹ́! Wọ́n dà bí ṣírí àlìkámà tó rọ́kú, tí àwọn èpò Sátánì kò sì tíì fún pa. Síbẹ̀, ó pọn dandan kí Jésù “fọ àwọn ọmọ Léfì [yìí] mọ́,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró. (Mál. 3:2, 3; 1 Pét. 4:17) Kí nìdí?

8. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún 1914?

8 Nígbà tó ku díẹ̀ kí ọdún 1914 parí, ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan torí pé wọn ò lọ sọ́run bí wọ́n ṣe rò tẹ́lẹ̀. Láàárín ọdún 1915 àti 1916, àwọn ará ìta gbógun ti ètò Ọlọ́run gan-an débi ti iṣẹ́ ìwàásù náà fi fẹ́rẹ̀ẹ́ dúró. Èyí tó wá burú jù ni pé lẹ́yìn ikú Arákùnrin Russell ní October 1916, ńṣe làwọn ará wa kan tún dá rúgúdù sílẹ̀, tí wọ́n ń ta ko ètò Jèhófà. Mẹ́rin lára àwọn méje tó ń mú ipò iwájú nínú àjọ Watch Tower Bible and Tract Society sọ pé àwọn ò ní gbà kí Arákùnrin Rutherford múpò iwájú. Wọ́n wá fẹ́ máa dá ìpínyà sílẹ̀ láàárín àwọn ará. Àmọ́, nígbà tó di oṣù August ọdún 1917, àwọn wọ̀nyí fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìwẹ̀nùmọ́ gan-an ló wáyé yẹn! Yàtọ̀ síyẹn, ìbẹ̀rù èèyàn mú kí àwọn kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ṣe ohun tí kò tọ́. Àmọ́ ṣá, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà kí Jésù wẹ àwọn mọ́, wọ́n sì ṣe àtúnṣe tó yẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù kà wọ́n sí Kristẹni tòótọ́, tá a fi wé àlìkámà, àmọ́ kò tẹ́wọ́ gba àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà tó wà nínú ìjọ, títí kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. (Mál. 3:5; 2 Tím. 2:19) Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Tá a bá fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká pa dà sínú ìjíròrò wa nípa àlìkámà àti èpò.

KÍ LÓ ṢẸLẸ̀ LẸ́YÌN TÍ ÀKÓKÒ ÌKÓRÈ BẸ̀RẸ̀?

9, 10. (a) Kí la máa jíròrò báyìí nípa àkókò ìkórè? (b) Kí ló kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ lákòókò ìkórè?

9 Jésù sọ pé “ìkórè ni ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 13:39) Ọdún 1914 sì ni àkókò ìkórè náà bẹ̀rẹ̀. Ní báyìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan márùn-ún tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wáyé lákòókò ìkórè.

10 Àkọ́kọ́, kíkó àwọn èpò jọ. Jésù sọ pé: “Ní àsìkò ìkórè, ṣe ni èmi yóò sì sọ fún àwọn akárúgbìn pé, Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀.” Lẹ́yìn ọdún 1914, àwọn ańgẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò jọ ní ti pé wọ́n ń yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára “àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró.”—Mát. 13:30, 38, 41.

11. Títí dòní olónìí, kí làwọn èèyàn fi mọ àwa Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sáwọn Kristẹni afàwọ̀rajà?

11 Bí iṣẹ́ kíkó àwọn èpò jọ ṣe ń bá a lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwùjọ méjèèjì yìí túbọ̀ ń ṣe kedere. (Ìṣí. 18:1, 4) Nígbà tó fi máa di ọdún 1919, ó ṣe kedere pé Bábílónì Ńlá ti ṣubú. Kí lohun pàtàkì tó mú kí àwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sí àwọn afàwọ̀rajà? Ohun náà ni iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn tó ń múpò iwájú lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ bó tí ṣe pàtàkì tó pé kí gbogbo Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 1919, tí wọ́n pè ní To Whom the Work Is Entrusted, rọ gbogbo Kristẹni ẹni àmì òróró pé kí wọ́n máa wàásù láti ilé dé ilé. Ìwé náà sọ pé: “Iṣẹ́ náà lè dà bí èyí tó ń kani láyà lóòótọ́, àmọ́ iṣẹ́ Olúwa ni, òun ló sì máa fún wa lókun láti ṣe é. Àǹfààní ńlá la ní bí a ti ń ní ìpín nínú iṣẹ́ yìí.” Kí làwọn Kristẹni yẹn ṣe nígbà tí wọ́n ka ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí? Ilé Ìṣọ́ 1922 (Gẹ̀ẹ́sì) ròyìn pé látìgbà yẹn lọ, ńṣe làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù yìí. Kò pẹ́ kò jìnnà, ìwàásù ilé-dé-ilé di ohun táwọn èèyàn mọ̀ mọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ yẹn, bó sì ṣe rí títí dòní náà nìyẹn.

12. Àtìgbà wo ni wọ́n ti ń kó àwọn Kristẹni tá a fi wé àlìkámà jọ?

12 Èkejì, kíkó àlìkámà jọ. Jésù pàṣẹ fáwọn ańgẹ́lì rẹ̀ pé: “Ẹ lọ kó àlìkámà jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi.” (Mát. 13:30) Àtọdún 1919 ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹni àmì òróró sínú ìjọ Kristẹni tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Ní ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó bá ṣì wà láàyè títí di òpin ètò àwọn nǹkan yìí, á máa kó wọn jọ nígbà tí wọ́n bá lọ sí ọ̀run.—Dán. 7:18, 22, 27.

13. Kí ni ìwé Ìṣípayá 18:7 fi hàn pé aṣẹ́wó náà tàbí Bábílónì Ńlá ń ṣe, títí kan ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

13 Ẹ̀kẹta, ẹkún àti ìpayínkeke. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ańgẹ́lì bá ti di àwọn èpò jọ? Nígbà tí Jésù ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò, ó sọ pé: “Níbẹ̀ ni ẹkún wọn àti ìpayínkeke wọn yóò wà.” (Mát. 13:42) Ṣé ìyẹn ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí? Rárá. Ní báyìí ná, ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ apá kan aṣẹ́wó náà tàbí Bábílónì Ńlá, ń sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í sì í ṣe opó, èmi kì yóò sì rí ọ̀fọ̀ láé.” (Ìṣí. 18:7) Òótọ́ ni pé ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gbà pé ọwọ́ òun ni àṣẹ wà, ó tiẹ̀ tún ń ṣe bí ọba lórí àwọn olóṣèlú. Ní báyìí ná, àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò kò sunkún, ṣe ni wọ́n ń yan fanda kiri. Àmọ́, nǹkan ò ní pẹ́ yí pa dà.

Àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn olóṣèlú máa tó wá sópin (Wo ìpínrọ̀ 13)

14. (a) Ìgbà wo làwọn Kristẹni afàwọ̀rajà máa payín keke, kí sì nìdí? (b) Báwo ni òye tuntun tá a ní nípa Mátíù 13:42 ṣe bá ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 112:10 mu? (Wo àfikún àlàyé.)

14 Nígbà ìpọ́njú ńlá, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pa gbogbo ìsìn èké run, àwọn tó ń ṣe ìsìn wọ̀nyẹn á máa wá ibi tí wọ́n á forí pa mọ́ sí, àmọ́ ẹ̀pa kò ní bóró mọ́. (Lúùkù 23:30; Ìṣí. 6:15-17) Nígbà tí wọ́n bá rí i pé kò sí ibi táwọn lè sá sí mọ́, wọ́n á wá máa sunkún kíkorò, wọ́n á sì máa payín keke bí inú ṣe ń bí wọn. Ìgbà yẹn ni wọ́n á máa “lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn,” bí Jésù ṣe sọ pé wọ́n máa ṣe lákòókò ìpọ́njú ńlá. *Mát. 24:30; Ìṣí. 1:7.

15. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èpò, ìgbà wo ló sì máa ṣẹlẹ̀?

15 Ẹ̀kẹrin, gbígbé wọn sọ sínú ìléru oníná. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èpò tí wọ́n dì jọ? Àwọn ańgẹ́lì máa “gbé wọn sọ sínú ìléru oníná.” (Mát. 13:42) Ìparun yán-án-yán-án nìyẹn túmọ̀ sí. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn tó ti ń ṣe ìsìn èké run nínú apá tó máa kẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, ìyẹn ogun Amágẹ́dọ́nì.—Mál. 4:1.

16, 17. (a) Kí lohun tó kẹ́yìn tí Jésù sọ nínú àkàwé rẹ̀? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó ṣì di ọjọ́ iwájú kó tó ṣẹ?

16 Ìkarùn-ún, títàn yòò. Níparí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.” (Mát. 13:43) Ìgbà wo nìyẹn máa wáyé, ibo ló sì ti máa ṣẹlẹ̀? Ó ṣì di ọjọ́ iwájú kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó ṣẹ. Kì í ṣe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Jésù ń sọ nípa rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ní ọ̀run ló ń sọ. * Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí méjì tá a fi gbà pé bẹ́ẹ̀ ló rí.

17 Àkọ́kọ́, ìgbà wo ló máa ṣẹlẹ̀? Jésù sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò.” Ó dájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ rẹ̀ tán ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, “ní àkókó yẹn.” Lédè míì, ìgbà tí wọ́n máa gbé àwọn èpò tí wọ́n dì jọ náà sọ sínú ìléru oníná ló ní lọ́kàn. Apá ìgbẹ̀yìn ìpọ́njú ńlá sì nìyẹn máa wáyé. Torí náà, ọjọ́ iwájú kan náà yìí ni àwọn ẹni àmì òróró máa “tàn yòò.” Èkejì, ibo ló ti máa wáyé? Jésù sọ pé àwọn olódodo máa ‘tàn yòò nínú ìjọba.’ Kí lèyí fi hàn? Ó fi hàn pé àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn tí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá bá ti kọjá yóò ti ní láti gba èdìdì wọn ìkẹyìn. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa kó wọn jọ sí ọ̀run bí Jésù ṣe sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá. (Mát. 24:31) Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa tàn yòò “nínú ìjọba Baba wọn.” Kété lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n á para pọ̀, wọ́n á sì dà bí ìyàwó fún Jésù nígbà “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”—Ìṣí. 19:6-9.

ÀǸFÀÀNÍ TÁ A RÍ

18, 19. Àǹfààní wo ló ṣe wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá a ṣe túbọ̀ lóye àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò?

18 Àǹfààní wo ló ṣe wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá a ṣe túbọ̀ fara balẹ̀ wo àkàwé Jésù yìí kínní-kínní? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àǹfààní mẹ́ta tó ṣe wá. Àkọ́kọ́, ó mú ká túbọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye. Àkàwé náà jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìdí pàtàkì tí Jèhófà fi fàyè gba ìwà ibi. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “fàyè gba àwọn ohun èlò ìrunú” kí ó lè ṣètò “àwọn ohun èlò àánú,” ìyẹn àwọn Kristẹni tá a fi wé àlìkámà. * (Róòmù 9:22-24) Ìkejì, ó túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Bí òpin ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, àwọn ọ̀tá wa máa túbọ̀ fúngun mọ́ wa gan-an, “ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí.” (Ka Jeremáyà 1:19.) Bí Jèhófà, Baba wa ọ̀run ti ń dáàbò bo ẹgbẹ́ àlìkámà látọjọ́ yìí wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣì máa lo Jésù àtàwọn ańgẹ́lì rẹ̀ láti máa wà pẹ̀lú wa “ní gbogbo àwọn ọjọ́” tó ṣẹ́ kù.—Mát. 28:20.

19 Ìkẹta, àkàwé náà mú ká dá ẹgbẹ́ àlìkámà náà mọ̀. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká dá ẹgbẹ́ àlìkámà náà mọ̀? Ìdí ni pé ìgbà tá a bá dá àwọn Kristẹni tá a fi wé àlìkámà mọ̀ la tó lè mọ ìdáhùn sí ìbéèrè tí Jésù béèrè nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn. Ó béèrè pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye?” (Mát. 24:45) Àwọn àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e máa jẹ́ ká rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn.

 

^ ìpínrọ̀ 2 Ìpínrọ̀ 2: Kó o lè rántí ohun tí àwọn apá yòókù nínú àkàwé náà túmọ̀ sí, a rọ̀ ọ́ pé kó o ka àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2010, tó ní àkòrí náà, “Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”.

^ ìpínrọ̀ 3 Ìpínrọ̀ 3: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì Jésù ti kú, tó sì jẹ́ pé àlìkámà ni Jésù fi àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù láyé wé kì í ṣe ẹrú, nígbà náà, àwọn ańgẹ́lì ni àwọn ẹrú náà dúró fún. Nínú àkàwé yìí, Jésù pa dà sọ pé àwọn ańgẹ́lì ni àwọn akárúgbìn náà.—Mát. 13:39.

^ ìpínrọ̀ 6 Ìpínrọ̀ 6: Òye tuntun lèyí. Tẹ́lẹ̀, a rò pé ọdún 1918 ni Jésù ṣèbẹ̀wò.

^ ìpínrọ̀ 7 Ìpínrọ̀ 7: Láti ọdún 1910 sí 1914, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pín ìwé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́rin [4,000,000] àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé ìléwọ́ tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì mílíọ̀nù [200,000,000].

^ ìpínrọ̀ 14 Ìpínrọ̀ 14: Òye tuntun lèyí jẹ́ nípa Mátíù 13:42. Tẹ́lẹ̀, a sọ nínú àwọn ìwé wa pé àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà yìí ti ń sunkún tí wọ́n sì ń payín keke fún ọ̀pọ̀ ọdún torí bí “àwọn ọmọ Ìjọba náà” ṣe ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà” ni wọ́n jẹ́. (Mát. 13:38) Àmọ́ o, ẹ kíyè sí i pé ìgbà tí Ọlọ́run bá máa pa wọ́n run ni wọ́n tó máa payín keke.—Sm. 112:10.

^ ìpínrọ̀ 16 Ìpínrọ̀ 16: Ìwé Dáníẹ́lì 12:3 sọ pé: “Àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye [ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró] yóò sì máa tàn bí ìtànyòò òfuurufú.” Nígbà tí wọ́n bá ṣì wà láyé, wọ́n á máa tàn yòò bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ìgbà tí wọ́n máa tàn yòò nínú Ìjọba ọ̀run ni Mátíù 13:43 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a rò pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.