Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ti Sọ Yín Di Mímọ́

A Ti Sọ Yín Di Mímọ́

“A ti wẹ̀ yín mọ́, . . . a ti sọ yín di mímọ́.” —1 KỌ́R. 6:11.

1. Nígbà tí Nehemáyà pa dà sí Jerúsálẹ́mù, àwọn nǹkan wo ló ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ tó bà á lọ́kàn jẹ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

LẸ́YÌN ọdún 443 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Nehemáyà pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, àwọn nǹkan tó rí bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an. Àwọn nǹkan yìí sì ń kọ àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù lóminú. Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nìyí: Olubi kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nínú ọ̀kan lára yàrá tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Àwọn ọmọ Léfì ò kọbi ara sí iṣẹ́ tí wọ́n gbé lé wọn lọ́wọ́ mọ́. Dípò tí àwọn alàgbà á fi máa mú ipò iwájú nínú ìjọsìn, ńṣe ni wọ́n ń ṣòwò lọ́jọ́ Sábáàtì. Àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ òkèèrè ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé níyàwó.—Neh. 13:6.

2. Báwo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe di èyí tá a yà sí mímọ́?

2 Orílẹ̀-èdè tí a yà sí mímọ́ fún Jèhófà ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fínnú fíndọ̀ gbà pé àwọn á ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Wọ́n sọ pé: “Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kís. 24:3) Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ̀ tàbí pé ó yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tirẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni wọ́n ní! Lẹ́yìn ogójì [40] ọdún tí Ọlọ́run ti yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ̀, Mósè rán wọn létí pé: “Ènìyàn mímọ́ ni ìwọ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti yàn láti di ènìyàn rẹ̀, àkànṣe dúkìá, nínú gbogbo ènìyàn tí wọ́n wà lórí ilẹ̀.”—Diu. 7:6.

3. Nígbà tí Nehemáyà pa dà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́ẹ̀kejì, báwo ni ipò nǹkan ṣe rí níbẹ̀?

3 Ó bani nínú jẹ́ pé gbogbo bí inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dùn pé àwọn jẹ́ orílẹ̀-èdè mímọ́ fún Ọlọ́run kò tọ́jọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wà tí wọ́n ń tiraka láti sin Ọlọ́run, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló jẹ́ pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sìn ín, ṣekárími ni wọn ń ṣe, wọ́n ò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run rárá. Nígbà tí Nehemáyà fi máa pa dà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́ẹ̀kejì, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí àwọn àṣẹ́kù tó jẹ́ olóòótọ́ dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì kí wọ́n lè tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Àmọ́, ibi pẹlẹbẹ náà ni ọ̀bẹ wọn ṣì ń fi lélẹ̀, torí pé iná ìtara wọn fún nǹkan tẹ̀mí tún ti ń kú lọ.

4. Àwọn kókó tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ mímọ́ wo la máa jíròrò?

4 Lọ́nà kan, Ọlọ́run ti ya àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ sí mímọ́ fún ara rẹ̀ bó ṣe yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì sí mímọ́. Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” ni Jèhófà yà sí mímọ̀ ní ti pé ó yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Ìṣí. 7:9, 14, 15; 1 Kọ́r. 6:11) Ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ pàdánù àjọṣe rere tó ní pẹ̀lú Jèhófà bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́, kí la lè ṣe tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò fi ní ṣẹlẹ̀ sí wa, ká lè máa wà ní mímọ́ ká sì wúlò fún Jèhófà? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò kókó mẹ́rin tá a fà yọ láti inú orí kẹtàlá [13] ìwé Nehemáyà: (1) Yẹra fún ẹgbẹ́ búburú; (2) máa kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà; (3) máa fi nǹkan tẹ̀mí ṣáájú àti (4) máa hùwà bíi Kristẹni nígbà gbogbo. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò níkọ̀ọ̀kan.

YẸRA FÚN ẸGBẸ́ BÚBURÚ

Báwo ni Nehemáyà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 5 àti 6)

5, 6. Ta ni Élíáṣíbù? Tani Tobáyà? Kí ló pa Élíáṣíbù àti Tobáyà pọ̀?

5 Ka Nehemáyà 13:4-9. Torí pé àwọn tí kò fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló yí wa ká, kì í rọrùn rárá láti jẹ́ mímọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Élíáṣíbù àti Tobáyà yẹ̀ wò. Àlùfáà àgbà ni Élíáṣíbù. Àmọ́ ọmọ Ámónì ni Tobáyà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ aṣojú kan lábẹ́ ìjọba Páṣíà nígbà tí Páṣíà ń ṣàkóso ilẹ̀ Jùdíà. Tobáyà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ta ko Nehemáyà nígbà tó fẹ́ tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́. (Neh. 2:10) Jèhófà sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ Ámónì ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ dé itòsí tẹ́ńpìlì. (Diu. 23:3) Kí wá nìdí tí àlùfáà àgbà fi gbà pé kí Tobáyà máa gbé nínú ọ̀kan lára yàrá ìjẹun tó wà nínú tẹ́ńpìlì?

6 Àjọṣe tímọ́tímọ́ ló wà láàárín Tobáyà àti Élíáṣíbù. Nígbà tí Tobáyà máa fẹ́yàwó, Júù ló fẹ́, nígbà tọ́mọ rẹ̀ náà sì máa láyà, Júù lòun náà fẹ́. Ọ̀pọ̀ Júù ló sì máa ń sọ dáadáa nípa Tobáyà. (Neh. 6:17-19) Ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọ Élíáṣíbù fẹ́ ọmọbìnrin Sáńbálátì. Gómìnà Samáríà ni Sáńbálátì, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Tobáyà. (Neh. 13:28) Àjọṣe tó wà láàárín wọn yìí jẹ́ ká lóye ìdí tí Élíáṣíbù àlùfáà àgbà fi jẹ́ kí Tobáyà tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ àti alátakò mú òun ṣe ohun tí kò tọ́. Àmọ́, torí pé Nehemáyà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ńṣe ló kó àwọn ohun èlò ilé bí àga, tábìlì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́ tí Tobáyà ní jù síta.

7. Kí làwọn alàgbà àtàwọn míì lè ṣe kí wọ́n má bàa sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin níwájú Jèhófà?

7 Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun tó yẹ kó máa gbà wá lọ́kàn jù ni bá a ṣe máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ká tó lè jẹ́ mímọ́ ní ojú rẹ̀, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà tó fún wa. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú ìdílé wa mú ká máa tẹ àwọn ìlànà Jèhófà lójú. Èrò Jèhófà làwọn alàgbà máa ń jẹ́ kó darí wọn, kì í ṣe èrò tiwọn tàbí bí nǹkan ṣe rí lára wọn. (1 Tím. 5: 21) Wọ́n sì tún máa ń sapá láti yẹra fún ohunkóhun tó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.—1 Tím. 2:8.

8. Kí ló yẹ kí gbogbo àwọn tó bá ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà máa rántí tó bá dọ̀rọ̀ irú àwọn tó yẹ kí wọ́n mú lọ́rẹ̀ẹ́?

8 Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:33) Àwọn ìbátan wa kan lè mú kó ṣòro fún wa láti máa ṣe ohun tó tọ́. Ohun tó dáa ni Élíáṣíbù ṣe bó ṣe ti Nehemáyà lẹ́yìn nígbà tó ń tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, èyí sì mú káwọn Júù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Neh. 3:1) Àmọ́ nígbà tó yá, Tobáyà àtàwọn míì ní ipa búburú lórí rẹ̀, èyí ló sì sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin lójú Jèhófà. Tá a bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dára, wọ́n á fún wa níṣìírí láti máa ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí, bíi kíka Bíbélì lójoojúmọ́, lílọ sípàdé àti lílọ sí òde ẹ̀rí déédéé. Ó dájú pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ìbátan tó ń fún wa níṣìírí láti máa ṣe ohun tó tọ́, a sì mọrírì wọn gan-an.

KỌ́WỌ́ TI GBOGBO ÈTÒ TÓ JẸ MỌ́ ÌJỌSÌN JÈHÓFÀ

9. Kí ló fà á tí àwọn ọmọ Léfì fi pa iṣẹ́ wọn nínú tẹ́ńpìlì tì? Àwọn wo ni Nehemáyà sì dá lẹ́bi?

9 Ka Nehemáyà 13:10-13. Nígbà tí Nehemáyà máa fi pa dà sí Jerúsálẹ́mù, àwọn èèyàn ò ti iṣẹ́ tẹ́ńpìlì lẹ́yìn mọ́. Èyí ló mú kí àwọn ọmọ Léfì tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ ti wọ́n sì lọ́ ń ṣiṣẹ́ nínú oko wọn. Àwọn ajẹ́lẹ̀ ni Nehemáyà dá lẹ́bi fún èyí. Ó hàn pé àwọn ajẹ́lẹ̀ náà kò ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọn ò gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà tàbí pé wọ́n ń gbà á ti wọ́n ò sì kó o fáwọn tó wà ní tẹ́ńpìlì. (Neh. 12:44) Torí náà, Nehemáyà ṣètò bí wọ́n á ṣe máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà. Ó yan àwọn ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán láti máa bójú tó yàrá tí wọ́n ń kẹ́rù sí nínú tẹ́ńpìlì, àwọn ni yóò sì máa pín nǹkan fún àwọn ọmọ Léfì.

10, 11. Àǹfààní wo ni àwa èèyàn Jèhófà ní láti ti ìjọsìn Ọlọ́run lẹ́yìn?

10 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú èyí? Ó jẹ́ ká rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa fi àwọn ohun ìní wa tó níye lórí bọlá fún Jèhófà. (Òwe 3:9) Tá a bá ń fi ọrẹ ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn, a wulẹ̀ ń fún Jèhófà lára ohun tó jẹ́ tiẹ̀ ni. (1 Kíró. 29:14-16) A lè ronú pé a ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan tá a fẹ́ fún Jèhófà, àmọ́ tá a bá ní in lọ́kàn láti fún un ní nǹkan, kò sí ohun tó kéré jù.—2 Kọ́r. 8:12.

11 Lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, ìdílé kan ṣètò pé kí tọkọtaya kan máa wá jẹun nílè wọn. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe làwọn tọkọtaya yìí, wọ́n sì tún jẹ́ àgbàlagbà. Ìdílé náà sì tí ń gbà wọ́n lálejò fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ mẹ́jọ ló wà nínú ìdílé náà, ìyá wọn sọ pé: “Oúnjẹ ẹni mẹ́wàá là ń sè tẹ́lẹ̀, tá a bá wá fi tẹni méjì kún un kò tíì pọ̀ jù.” Òótọ́ ní pé oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ lè dà bí ohun tí kò tó nǹkan, àmọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe yẹn mọrírì rẹ̀ gan-an wọ́n sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Àǹfààní kékeré kọ́ ni wọ́n sì ṣe ìdílé náà. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí àti ìrírí tí wọ́n máa ń sọ fún ìdílé yẹn mú kí àwọn ọmọ wọn tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí gan-an. Gbogbo wọn pátá ló di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà tó yá.

12. Àpẹẹrẹ rere wo ni àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò nínú ìjọ máa ń fi lélẹ̀?

12 Ẹ̀kọ́ míì ta tún rí kọ́ ni pé, bíi ti Nehemáyà àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀, wọ́n ń kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Wọ́n ṣáà ní ẹṣin iwájú ni tẹ̀yìn ń wò sáré. Torí bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ wọn ń mú káwọn ará túbọ̀ gbárùkù ti ìjọsìn Ọlọ́run. Ohun táwọn alàgbà ń ṣe yìí tún mú kí wọ́n dà bíi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Lọ́nà wo? Pọ́ọ̀lù ti ìsìn tòótọ́ lẹ́yìn, ó sì tún fún àwọn ará láwọn àbá tó lè mú kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe táá jẹ́ kí wọ́n lè máa fi ọrẹ ṣètìlẹyìn.—1 Kọ́r. 16: 1-3; 2 Kọ́r. 9: 5-7.

MÁA FI NǸKAN TẸ̀MÍ ṢÁÁJÚ

13. Kí ni àwọn Júù kan ṣe tó fi hàn pé wọn ò pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́?

13 Ka Nehemáyà 13:15-21. Tá a bá lọ jẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ, àwọn nǹkan tẹ̀mí ò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sí wa mọ́. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Ẹ́kísódù 31:13, Ọlọ́run ṣètò Sábáàtì kó lè máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tá a ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ yà á sọ́tọ̀ fún ìjọsìn ìdílé, àdúrà àti láti máa ṣàṣàrò lórí Òfin Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn kan lára àwọn alájọgbáyé Nehemáyà kò tiẹ̀ fi ìyàtọ̀ sáàárín ọjọ́ Sábáàtì àtàwọn ọjọ́ tó kù, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn ni wọ́n kàn ń ṣe lọ ni tiwọn. Wọn ò fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run rárá. Kí wá ni Nehemáyà ṣe? Ṣe ló lé àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìbílẹ̀ tí wọ́n wá ṣòwò jáde, ó sì ní kí wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn àbáwọlé ìlú náà tó bá ti di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹfà, kí Sábáàtì tó bẹ̀rẹ̀.

14, 15. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa jẹ wá lógún ju bó ṣe yẹ lọ? (b) Báwo la ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run?

14 Kí la rí kọ́ lára Nehemáyà? Ẹ̀kọ́ kan ni pé ká má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa jẹ wá lógún ju bó ṣe yẹ lọ. Tá ò bá kíyè sára, a lè má pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, pàápàá jù lọ tá a bá ń gbádùn iṣẹ́ wa gan-an. Ká rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé èèyàn kan ò lè sìnrú fún ọ̀gá méjì. (Ka Mátíù 6:24.) Ó ṣe tán, ipò tí Nehemáyà wà mú kó láǹfààní láti di olówó rẹpẹtẹ, àmọ́ báwo ló ṣe lò àkókò rẹ̀? (Neh. 5:14-18) Dípò kó máa wá bó ṣe máa ṣòwò pẹ̀lú àwọn ará Tírè tàbí àwọn míì, ohun tó gbájú mọ́ ni bó ṣe máa ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ àti bó ṣe máa gbé orúkọ mímọ́ Jèhófà ga. Bákan náà ló ṣe rí lónìí, ohun tó máa ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní ló máa ń jẹ àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lógún, inú àwọn ará sì máa ń dùn sí ẹ̀mí rere tí wọ́n ń fi hàn yìí. Èyí sì máa ń mú kí ìfẹ́, àlàáfíà àti ààbò wà nínú ìjọ Ọlọ́run.—Ìsík. 34:25, 28.

15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò sọ pé kí àwa Kristẹni máa pa Sábáàtì mọ́, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run, òun pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe kúrò nínú tirẹ̀.” (Héb. 4:9, 10) Lónìí, àwa Kristẹni lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run, tá a bá jẹ́ onígbọràn, tá à ń ṣe gbogbo ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ tó ń ṣí pa yá mu. Ṣe ìwọ àti ìdílé rẹ máa ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn ìdílé, àwọn ìpàdé ìjọ àti iṣẹ́ ìwàásù? Ó lè gba pé ká ṣe àwọn ìpinnu tó lágbára lẹ́nu iṣẹ́ wa nígbà míì, pàápàá tí àwọn tó gbà wá síṣẹ́ tàbí àwọn tá a jọ ń ṣòwò kò bá ka àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni tó jẹ wá lógún sí. Tá a bá ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dà bíi pé ‘a ti ìlẹ̀kùn àbáwọlé sí ìlú ńlá ká lè lé àwọn oníṣòwò ará Tírè jáde.’ Èyí á jẹ́ ká lè gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí, àá sì lè fi wọ́n sí ipò tó yẹ. Torí pé a ti ya ara wa sí mímọ́, ó máa dáa ká bi ara wa pé, ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mo ti ya ara mi sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?’—Mát. 6:33.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI NÍGBÀ GBOGBO

16. Nígbà ayé Nehemáyà, kí ló fẹ́ ṣàkóbá fún àwọn èèyàn tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀?

16 Ka Nehemáyà 13:23-27. Nígbà ayé Nehemáyà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé àwọn àjèjì obìnrin níyàwó. Nígbà tí Nehemáyà kọ́kọ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, ṣe ló mú kí àwọn àgbà ọkùnrin jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí wọ́n sì buwọ́ lu ìwé pé àwọn ò ní fẹ́ àwọn kèfèrí. (Neh. 9:38; 10:30) Nígbà tí Nehemáyà máa pa dà lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, ó rí i pé àwọn ọkùnrin Júù ti gbé àwọn àjèjì obìnrin níyàwó. Kódà, ìwà wọn ò tiẹ̀ fẹ́ jọ tèèyàn Ọlọ́run mọ́ rárá. Àwọn ọmọ táwọn obìnrin yìí bí ò tiẹ̀ lè sọ èdè Hébérù débi tí wọ́n á lè kà á. Tí wọ́n bá wá dàgbà, ṣe wọ́n á lè sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì làwọn? Ṣe kì í ṣe pé ọmọ Áṣídódì, Ámónì tàbí Móábù ni wọ́n máa ka ara wọn sí? Bó ṣe jẹ́ pé wọn ò lóye èdè Hébérù, ṣé wọ́n á sì lè lóye Òfin Ọlọ́run? Báwo ni wọ́n ṣe fẹ́ mọ Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín dípò àwọn ọlọ́run èké táwọn ìyá wọn ń sìn? Ó yẹ kí wọ́n tètè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà, kò tó di pé ẹ̀pa ò ní bóró mọ́. Ohun tí Nehemáyà sì ṣe gan-an nìyẹn.—Neh. 13:28.

Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 17 àti 18)

17. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà?

17 Lónìí, ó yẹ ká gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara kí àwọn ọmọ wa lè máa fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù. Ẹ̀yin òbí, ẹ bi ara yín pé: ‘Ṣé àwọn ọmọ mi ń sọ “èdè mímọ́ gaara” dáadáa? Lédè míì, ṣé wọ́n lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa? (Sef. 3:9) Ṣé ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ mi ń sọ jọ tẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí, àbí tẹni tí ẹ̀mí ayé ń darí? Tó bá jẹ́ pé ó kù díẹ̀ káàtó, má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ wọn sú ẹ. Ó máa ń pẹ́ kéèyàn tó lè kọ́ èdè kan, pàápàá tọ́kàn èèyàn ò bá pa pọ̀. Kò sì rọrùn fún àwọn ọmọ rẹ náà, torí pé àwọn tó yí wọn ká ń fẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà, pé kẹ́ ẹ máa lo àkókò Ìjọsìn Ìdílé yín àtàwọn àkókò míì láti fi sùúrù kọ́ wọn kí wọ́n lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (Diu. 6:6-9) Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn àǹfààní téèyàn máa rí tí ìwà rẹ̀ bá yàtọ̀ sí ti ayé. (Jòh. 17:15-17) Kó o sì rí i pé ohun tí wọ́n ń kọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

18. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn òbí gan-an ló lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà?

18 Ohun kan ni pé, ọmọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu fúnra rẹ̀ bóyá òun máa sin Jèhófà tàbí òun kò ní sìn ín. Àmọ́, iṣẹ́ ń bẹ lọ́wọ́ ẹ̀yin òbí. Lára ohun tẹ́ ẹ ní láti ṣe ni pé kẹ́ ẹ fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀, kẹ́ ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó tọ́ láti ṣe àti èyí tí kò tọ́, kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Ẹ̀yin òbí, ẹ̀yin gan-an lẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Wọ́n nílò yín kí wọ́n lè máa hùwà tó yẹ Kristẹni nígbà gbogbo. Àmọ́ o, gbogbo wa ló yẹ ká wà lójúfò ká má bàa pàdánù “ẹ̀wù àwọ̀lékè” ìṣàpẹẹrẹ wa, ìyẹn àwọn ìwà àti ìṣe tó ń fi wá hàn gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Kristi.—Ìṣí. 3: 4, 5; 16:15.

ỌLỌ́RUN MÁA RÁNTÍ RẸ “FÚN RERE”

19, 20. Kí ló máa mú kí Jèhófà rántí wa sí rere?

19 Ọ̀kan lára àwọn alájọgbáyé Nehemáyà ni wòlíì Málákì, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ‘ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.’ (Mál. 3:16, 17) Jèhófà ò jẹ́ gbàgbé àwọn tó ń bẹ̀rù rẹ̀ látọkànwá tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀.—Héb. 6:10.

20 Nehemáyà gbàdúrà pe: “Jọ̀wọ́, Ọlọ́run mi, rántí mi fún rere.” (Neh. 13:31) Orúkọ tiwa náà máa wà nínú ìwé ìrántí Ọlọ́run bíi ti Nehemáyà, tá a bá ń yẹra fún ẹgbẹ́ búburú, tá à ń kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà, tá à ń fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú, tá a sì ń hùwà tó yẹ Kristẹni nígbà gbogbo. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ‘máa dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́.’ (2 Kọ́r. 13:5) Tá ò bá jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó dájú pé ó máa rántí wa sí rere.