Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Ronú Nípa Irú Èèyàn Tó Yẹ Kó O Jẹ́

Máa Ronú Nípa Irú Èèyàn Tó Yẹ Kó O Jẹ́

“Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run!”—2 PÉT. 3:11.

1, 2. Tá a bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, irú èèyàn wo ló yẹ ká jẹ́?

A SÁBÀ máa ń ronú nípa ohun táwọn èèyàn máa sọ nípa wa. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí Jèhófà máa rò nípa wa ló yẹ kó ká wa lára jù lọ? Ó ṣe tán, Jèhófà ni Ẹni gíga jù lọ láyé àti lọ́run, òun sì ni “orísun ìyè.”—Sm. 36:9.

2 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká kíyè sí “irú èèyàn” tá a fẹ́ kí Jèhófà mọ̀ wá sí, ó rọ̀ wá pé ká máa ṣe “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (Ka 2 Pétérù 3:11.) Tá a bá fẹ́ rí ojúure Ọlọ́run, “ìṣe” wa gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, yálà nínú ohun tá à ń rò, nínú ìwà wa àti nínú ìjọsìn wa. Bákàn náà, a ní láti máa ṣe “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,” ká máa bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run ká sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Torí náà, tá a bá fẹ́ rí ojúure Ọlọ́run, ó dáa ká máa kíyè sí ìwà wa, àmọ́ ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa kíyè sí ohun tó wà nínú ọkàn wa. Ká má gbàgbé pé Jèhófà jẹ́ “olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà.” Torí náà, ó mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni ìwà wa jẹ́ mímọ́ tàbí kò jẹ́ mímọ́, ó sì mọ̀ bóyá gbogbo ọkàn wa la fi ń sin òun tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.—1 Kíró. 29:17.

3. Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run?

3 Sátánì Èṣù kò fẹ́ ká rí ojúure Ọlọ́run. Àní sẹ́, ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú ká kẹ̀yìn sí Jèhófà. Sátánì kò kọ̀ láti lo irọ́ àti ẹ̀tàn láti mú wa jìnnà sí Ọlọ́run tá à ń sìn. (Jòh. 8:44; 2 Kọ́r. 11:13-15) Torí náà, á dára ká bi ara wa pé: ‘Báwo ni Sátánì ṣe ń tan àwọn èèyàn? Kí ni mo lè ṣe tí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà kò fi ní bà jẹ́?’

BÍ SÁTÁNÌ ṢE Ń TAN ÀWỌN ÈÈYÀN

4. Kí ni Sátánì máa ń ṣọ́ kí ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́? Kí sì nìdí?

4 Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn náà sọ pé, “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” (Ják. 1:14, 15) Sátánì máa ń sapá láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Torí náà, ó máa ń kíyè sí àwọn ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí, kí ó lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọkàn wa di ẹlẹ́gbin.

5, 6. (a) Kí ni Sátánì máa ń lò láti rí wa mú? (b) Àwọn ohun tó ń fani lọ́kàn mọ́ra wo ni Sátánì máa ń lò láti sọ ọkàn wa di ẹlẹ́gbin? Àtìgbà wo ló ti ń ṣe bẹ́ẹ̀?

5 Kí ni Sátánì máa ń lò láti sọ ọkàn wa di ẹlẹ́gbin? Bíbélì sọ pé, “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòh. 5:19) Lára irinṣẹ́ tí Sátánì ń lò ni “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” (Ka 1 Jòhánù 2:15, 16.) Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Sátánì ti ń fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n rẹ̀ darí ayé yìí. Bó sì ti jẹ́ pé inú ayé yìí náà là ń gbé, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má bàa fi ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀ mú wa.—Jòh. 17:15.

6 Àwọn nǹkan tí Sátánì ń lò lè sọ ọkàn èèyàn di ẹlẹ́gbin. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ àwọn nǹkan mẹ́ta tí Sátánì máa ń lò láti mú ká ṣe ohun tó fẹ́: (1) “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara,” (2) “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú,” àti (3) “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” Àwọn nǹkan yìí náà ni Sátánì lò láti dán Jésù wò ní aginjù. Torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Sátánì ti ń lo àwọn ìdẹ yìí, ó ti wá gbówọ́ gan-an báyìí, ó sì mọ bó ṣe lè yíwọ́ pa dà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ lò ó fún. Ká tó jíròrò ohun tá a lè ṣe kí Èṣù má bàa rí wa mú, ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe lo àwọn nǹkan kan láti fa ọkàn Éfà mọ́ra tó sì tàn án dẹ́ṣẹ̀ àti bí kò ṣe rí Ọmọ Ọlọ́run mú.

“ÌFẸ́KÚFẸ̀Ẹ́ ARA”

“Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” ló kó bá Éfà (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Báwo ni Sátánì ṣe lo “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” láti tan Éfà?

7 Gbogbo èèyàn ló mọ bí oúnjẹ ti ṣe pàtàkì tó, ó ṣe tán, oúnjẹ lọ̀rẹ́ àwọ̀. Ẹlẹ́dàá wa náà sì dá ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ fún wa. Sátánì mọ̀ pé ó máa ń wù wá láti jẹun, torí náà ó lè fẹ́ lo ọ̀nà yìí láti mú wa jìnnà sí Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe lo ọ̀nà yìí láti tan Éfà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.) Sátánì sọ fún Éfà pé kò ní kú tó bá jẹ èso “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” àti pé lọ́jọ́ tó bá jẹ èso náà ló máa dà bí Ọlọ́run. (Jẹ́n. 2:9) Èṣù tipa bẹ́ẹ̀ dọ́gbọ́n sọ fún Éfà pé kò dìgbà tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run kó tó lè wà láàyè. Ẹ ò rí i pé irọ́ pátápátá nìyẹn! Níbi tí ọ̀rọ̀ dé yìí, ohun méjì ni Éfà lè ṣe: Ó lè kọ ohun tí Sátánì fi lọ̀ ọ́ tàbí kẹ̀, ó lè máa ronú lé ohun tí Sátánì sọ títí ọkàn rẹ̀ fi máa fà sí èso náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Éfà lè jẹ nínú àwọn èso igi míì nínú ọgbà náà, èyí tó wọ̀ ọ́ lójú gan-an ni igi tó wà láàárín ọgbà, tí Sátánì sọ fún un pé kó jẹ. Lọ́rọ̀ kan ṣá, Éfà “mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.” Bí Sátánì ṣe mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí ohun tí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ní kò gbọ́dọ̀ jẹ nìyẹn o.

Jésù kò jẹ́ kí ohunkóhun gbé ọkàn òun kúrò lórí ohun tó ṣe pàtàkì (Wo ìpínrọ̀ 8)

8. Báwo ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti lo “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” láti tan Jésù? Kí nìdí tí kò fi rí Jésù mú?

8 Ọgbọ́n kan náà yìí ni Sátánì lò nígbà tó ń dẹ Jésù wò ní aginjù. Lẹ́yìn tí Jésù ti gbààwẹ̀ fún ogójì [40] ọ̀sán àti ogójì òru, Sátánì mọ̀ pé ebi á ti máa pa á, torí náà ó fẹ́ fi oúnjẹ tàn án. Sátánì sọ pé, “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún òkúta yìí kí ó di ìṣù búrẹ́dì.” (Lúùkù 4:1-3) Ohun méjì ni Jésù lè ṣe: Ó lè pinnu pé òun kò ní torí àtijẹun kóun wá lo agbára tí òun ní láti ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó sì lè pinnu pé òun máa lo agbára náà. Jésù mọ̀ pé òun kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìyanu torí pé ó fẹ́ tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Lóòótọ́ ni ebi ń pa á, àmọ́ kò ní torí àtijẹun kó wá ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Jésù da Sátánì lóhùn pé, “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kò gbọ́dọ̀ tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè.’”—Lúùkù 4:4.

“ÌFẸ́KÚFẸ̀Ẹ́ OJÚ”

9. Kí ni gbólóhùn náà, “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” fi hàn? Báwo sì ni Sátánì ṣe lò ó láti tan Éfà jẹ?

9 Jòhánù tún sọ pé “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” wà lára ohun tó lè fani lọ́kàn mọ́ra. Gbólóhùn yìí fi hàn pé ọkàn èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ohun kan lẹ́yìn téèyàn ti wo nǹkan ọ̀hún. Sátánì lo ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú láti tan Éfà jẹ nígbà tó sọ fún un pé: “Ó dájú pé ojú yín yóò là.” Bí Éfà ṣe ń wo èso igi náà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ túbọ̀ ń fà sí i. Éfà wá rí i pé igi náà “dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni.”

10. Báwo ni Sátánì ṣe fi “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” dán Jésù wò? Kí ni Jésù sì ṣe?

10 Báwo ni Sátánì ṣe fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú dán Jésù wò? ‘Ó fi gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí à ń gbé han Jésù ní ìṣẹ́jú akàn.’ Èṣù sì wí fún un pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ yìí àti ògo wọn ni èmi yóò fi fún ọ.” (Lúùkù 4:5, 6) Kì í ṣe pé Jésù fi ojú rẹ̀ rí gbogbo ìjọba ayé yìí ní ìṣẹ́jú akàn o. Àmọ́, ńṣe ni Sátánì fi ògo ìjọba ayé yìí hàn án nínú ìran, èrò rẹ̀ sì ni pé àwọn nǹkan yẹn máa fa Jésù lọ́kàn mọ́ra. Ó wá sọ fún Jésù pé: “Bí o bá jọ́sìn níwájú mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.” (Lúùkù 4:7) Jésù kò gbà láé kí Sátánì sọ òun dìdàkudà. Kíá ló fún un lésì pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’”—Lúùkù 4:8.

“FÍFI ÀLÙMỌ́Ọ́NÌ ÌGBÉSÍ AYÉ ẸNI HÀN SÓDE LỌ́NÀ ṢEKÁRÍMI”

11. Báwo ni Sátánì ṣe tan Éfà?

11 Nígbà tí Jòhánù ń sọ nípa àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé, ó mẹ́nu kan “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” Lákòókò tí Ádámù àti Éfà nìkan wà láyé, kò sẹ́ni tí wọ́n máa fi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé wọn ṣe ṣekárími sí. Àmọ́, wọ́n hùwà ìgbéraga. Nígbà tí Sátánì ń tan Éfà, ó sọ fún un pé ohun àgbàyanu kan wà tí Ọlọ́run fi pa mọ́ fún un. Èṣù sọ fún un pé ọjọ́ náà gan-an tó bá jẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú” ni “yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́n. 2:17; 3:5) Sátánì tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé Éfà máa di òmìnira, kò ní sí lábẹ́ Jèhófà mọ́. Ó jọ pé ìgbéraga ló mú kí Éfà gba irọ́ yẹn gbọ́. Bí Éfà ṣe jẹ́ èso tí Ọlọ́run ní kí wọ́n má jẹ nìyẹn o, ó gbà pé òun ò ní kú lóòótọ́. Àbẹ́ ò rí i bó ṣe kó sọ́wọ́ Sátánì wẹ́rẹ́!

12. Ọ̀nà míì wo ni Sátánì tún gbà láti dẹ Jésù wò, àmọ́ kí ni Jésù sọ?

12 Jésù ní tiẹ̀ kò dà bí Éfà. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀! Sátánì lo ọgbọ́n míì láti tan Jésù, àmọ́ Jésù ò gbà kí Sátánì mú òun ṣe àṣehàn. Ó mọ̀ pé ńṣe nìyẹn máa túmọ̀ sí pé òun ń dán Ọlọ́run wò. Kò sí àní-àní pé ìwà ìgbéraga nìyẹn máa jẹ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù dá Sátánì lóhùn lọ́nà tó ṣe kedere tó sì ṣe tààràtà pé: “A sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’”—Ka Lúùkù 4:9-12.

KÍ LA LÈ ṢE TÍ ÀJỌṢE WA PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ KÒ FI NÍ BÀ JẸ́?

13, 14. Ṣàlàyé bí Sátánì ṣe ń lo àwọn nǹkan kan láti fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra lónìí.

13 Irú àwọn nǹkan tí Sátánì lò fún Éfà àti Jésù náà ló ń lò lónìí láti fà àwa èèyàn lọ́kàn mọ́ra. Kí ọkàn wa lè máa fà sí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara,” Èṣù ń lo ayé yìí láti máa gbé ìṣekúṣe, àjẹjù àti ìmutípara lárugẹ. Ó ń lo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, ní pàtàkì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, láti dẹkùn mú àwọn tí kò wà lójúfò. Á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú wọn nípasẹ̀ “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú.” Ẹ wo bí ìfẹ́ ọrọ̀, agbára àti òkìkí ṣe ń dẹkùn mú àwọn agbéraga àtàwọn tó nífẹ̀ẹ́ àtimáa fi ‘àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé wọn hàn sóde lọ́nà ṣekárími’!

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló yẹ kó wá sí ẹ lọ́kàn nígbà tó o bá dojú kọ àwọn nǹkan bí èyí? (Wo ìpínrọ̀ 13 àti 14)

14 Ńṣe ni “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé” dà bí ìjẹ táwọn apẹja máa ń fi tan ẹja. Ìjẹ yìí máa ń fa ẹja mọ́ra, àmọ́ ńṣe ni wọ́n máa ń fi ìjẹ náà kọ́ ẹnu ìwọ̀. Sátánì máa ń lo àwọn nǹkan táwọn èèyàn kà sí pàtàkì láti mú kí wọ́n rú òfin Ọlọ́run. Torí náà, tá ò bá ṣọ́ra, Sátánì lè lo àwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí láti sọ ọkàn wa di ẹlẹ́gbin. Ńṣe ló fẹ́ ká gbà pé ó yẹ ká kọ́kọ́ wá bá a ṣe máa fi ìgbádùn tẹ́ ara wa lọ́rùn ná, ká tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ronú àtiṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣé wàá gbà kí Sátánì fi ìjẹ rẹ̀ mú ọ?

15. Báwo la ṣe lè borí ìdẹwò bíi ti Jésù?

15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Éfà jẹ́ kí Sátánì fi ìjẹ rẹ̀ mú òun, Jésù ní tiẹ̀ kò gbà fún Sátánì. Nígbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí Sátánì dẹ Jésù wo ni Jésù ń fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Ìwé Mímọ́ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé” tàbí, “A sọ ọ́ pé.” Táwa náà bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àá mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, àá sì lè máa rántí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa jẹ́ ká lè ronú lọ́nà tó tọ́ nígbà tá a bá dojú kọ ìdẹwò. (Sm. 1:1, 2) Tá a bá ń rántí àpẹẹrẹ àwọn tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin, èyí á mú káwa náà lè jẹ́ olóòótọ́ bíi tíwọn. (Róòmù 15:4) Tá a bá ń bẹ̀rù Jèhófà tọkàntọkàn, tá a nífẹ̀ẹ́ ohun tó nífẹ̀ẹ́, tá a sì kórìíra ohun tó kórìíra, Jèhófà á máa dáàbò bò wá.—Sm. 97:10.

16, 17. Báwo ni “agbára ìmọnúúrò” wa ṣe lè fi irú ẹni tá a jẹ́ gan-an hàn?

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká máa lo “agbára ìmọnúúrò” wa ká lè máa ronú bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, kì í ṣe bí ayé ṣe fẹ́. (Róòmù 12:1, 2) Pọ́ọ̀lù sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa sapá gidigidi ká bàa lè máa ronú lọ́nà tó tọ́. Ó sọ pé: “Àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ni àwa ń dojú wọn dé; a sì ń mú gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́r. 10:5) Ohun tá à ń rò máa ń nípa tó lágbára gan-an lórí wa, ó máa ń fi irú ẹni tá a jẹ́ gan-an hàn. Torí náà, á dára ká máa ‘bá a nìṣó ní ríronú’ lórí àwọn nǹkan tó ń gbéni ró.—Fílí. 4:8.

17 A ò lè jẹ́ mímọ́ tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí kò tọ́ ni ọkàn wa máa ń fà sí tá a sì ń ronú lé lórí. Ọkàn-àyà tí ó mọ́” la gbọ́dọ̀ fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (1 Tím. 1:5) Àmọ́ o, ọkàn máa ń ṣe àdàkàdekè. Torí náà, a lè má mọ̀ bí “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé” ti kó èèràn ràn wá tó. (Jer. 17:9) Nípa bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò ní dára ká máa ‘dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́, ká sì máa wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́? Ọ̀nà tá a sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa fòótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ara wa bóyá à ń tẹ̀ lé ohun tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì.—2 Kọ́r. 13:5.

18, 19. Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu pé irú ẹni tí Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ la máa jẹ́?

18 Ohun míì tí kò ní jẹ́ kí “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé” kó èèràn ràn wá ni pé ká máa rántí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Jòhánù láti kọ, pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòh. 2:17) Lóòótọ́, ayé tí Sátánì ń darí yìí dà bí èyí tí mìmì kan ò lè mì. Àmọ́, ọ̀sán kan òru kan ni Sátánì àtàwọn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ máa pa run. Kò sí ohun kankan nínú ayé Sátánì yìí tó láyọ̀lé. Tá a bá ń fi kókó yìí sọ́kàn, a ò ní jẹ́ kí àwọn nǹkan tí Èṣù ń lò láti fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra tàn wá jẹ.

19 Àpọ́sítélì Pétérù rọ̀ wá pé ká máa hùwà tó máa jẹ́ ká rí ojú rere Ọlọ́run bá a ṣe ń ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà tá a sì ń fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́!’ (2 Pét. 3:12) Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, ọjọ́ yẹn máa dé, Jèhófà á sì pa Sátánì àti gbogbo àwọn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ run. Àmọ́ ní báyìí ná, Sátánì á ṣì máa lo “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé” láti dẹ wá wò, bó ṣe dẹ Éfà àti Jésù wò. Ká má ṣe fìwà jọ Éfà tó jẹ́ pé bó ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ló jẹ ẹ́ lógún. Tó bá jẹ́ pé báwa náà á ṣe máa fi ìgbádùn tẹ́ ara wa lọ́rùn nìkan ló jẹ wá lógún, á jẹ́ pé Sátánì là ń sìn nìyẹn. Dípò ìyẹn, ẹ jẹ́ ká fìwà jọ Jésù, ká má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa máa fà sí àwọn nǹkan tí Sátánì ń lò, bó ti wù kí àwọn nǹkan náà fani lọ́kàn mọ́ra tó. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé irú ẹni tí Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ la máa jẹ́.