Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Ronú Nípa Irú Èèyàn Tó Yẹ Kó O Jẹ́

Máa Ronú Nípa Irú Èèyàn Tó Yẹ Kó O Jẹ́

Ó ṣẹlẹ̀ pé ọba Síríà ń lépa Èlíṣà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run. Ló bá gbọ́ pé ó wà ní ìlú kan tí àwọn òkè ńláńlá yí ká tí wọ́n ń pè ní Dótánì. Nígbà tó fi máa di òru, ọba Síríà rán àwọn ẹlẹ́ṣin, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn ọmọ ogun lọ sí Dótánì. Nígbà tí ilẹ̀ máa fi mọ́, wọ́n ti yí ìlú náà ká.—2 Ọba 6:13, 14.

Nígbà tí ẹmẹ̀wà Èlíṣà jí, ó lọ síta, ló bá rí àwọn tó wá láti mú wòlíì náà. Ló bá kígbe pé, “Págà, ọ̀gá mi! Kí ni àwa yóò ṣe?” Èlíṣà wá sọ fún un pé: “Má fòyà, nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Ni wòlíì náà bá gbàdúrà pé: “Jèhófà, jọ̀wọ́, là á ní ojú, kí ó lè ríran.” Ẹsẹ yẹn tẹ̀ síwájú pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ẹmẹ̀wà náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ríran; sì wò ó! ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná yí Èlíṣà ká.” (2 Ọba 6:15-17) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí àti àwọn nǹkan míì tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíṣà?

Ohun tó mú kí ọkàn Èlíṣà balẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ogun Síríà wá gbógun tì í ni pé, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì dá a lójú pé Jèhófà máa fi agbára ńlá rẹ̀ gba òun. A ò lè retí pé kí Jèhófà máa fi iṣẹ́ ìyanu yanjú àwọn ìṣòrò wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lóde òní, àmọ́ ó dá wa lójú pé ó ń dáàbò bo gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀. Ńṣe ló dà bíi pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná yí àwa náà ká. Tá a bá ń fi ojú ìgbàgbọ́ “rí” àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná yìí tá a sì ń gbára lé Jèhófà nígbà gbogbo, a ó “máa gbé nínú ààbò” a ó sì máa rí ìbùkún Jèhófà gbà. (Sm. 4:8) Ẹ jẹ́ ká tún wo bá a ṣe lè jàǹfààní látinú àwọn nǹkan míì tó tún ṣẹlẹ̀ sí Èlíṣà.

ÈLÍṢÀ DI ÌRÁNṢẸ́ ÈLÍJÀ

Nígbà kan tí Èlíṣà ń túlẹ̀, wòlíì Èlíjà sún mọ́ ọn, ó sì sọ ẹ̀wù oyè rẹ̀ sí i lára. Èlíṣà mọ ìtúmọ̀ ohun tí Èlíjà ṣe yẹn. Ló bá ṣètò àpèjẹ kan láti fi dágbére fún bàbá àti ìyá rẹ̀ kó lè lọ máa ṣèránṣẹ́ fún Èlíjà. (1 Ọba 19:16, 19-21) Torí pé Èlíṣà ṣe tán láti fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà ní kíkún, ó di ohun èlò tó wúlò fún Jèhófà, ó sì di wòlíì tó rọ́pò Èlíjà.

Ó ṣeé ṣe kó tó ọdún mẹ́fà tí Èlíṣà fi ṣèránṣẹ́ fún Èlíjà. Láàárín àkókò yẹn Èlíṣà ni “ẹni tí ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà.” (2 Ọba 3:11) Nígbà ayé wọn, ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn láti máa fi ọwọ́ wọn jẹun, wọn kì í lo àmúga, ọ̀bẹ tàbí ohun èlò míì tó wọ́pọ̀ lónìí. Lẹ́yìn tí wọ́n bá jẹun tán, ìránṣẹ́ náà máa bu omi sí ọwọ́ ọ̀gá rẹ̀ kó lè fi fọ̀ ọ́. Èyí fi hàn pé díẹ̀ lára iṣẹ́ tí Èlíṣà ṣe jẹ́ iṣẹ́ tó rẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n láìka èyí sí, Èlíṣà ṣì kà á sí àǹfààní láti jẹ́ ìránṣẹ́ Èlíjà.

Lónìí bákan náà, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kan tàbí òmíràn. Ohun tó sì ń mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì ń wù wọ́n láti lo gbogbo okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àwọn míì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míì wà lára àwọn tó ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn Jèhófà, àwọn míì sì tún ń sìn láwọn apá ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn míì, èyí sì máa ń gba pé kí wọ́n fi ilé àtàwọn èèyàn wọn sílẹ̀. Iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ gan-an ni ọ̀pọ̀ nínú wọn sì máa ń ṣe. Kò yẹ kí àwa Kristẹni ka irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sí èyí tó ń buni kù tàbí èyí tí kò ní láárí, torí Jèhófà mọyì rẹ̀ gan-an ni.—Héb. 6:10.

ÈLÍṢÀ FI ỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ IṢẸ́ RẸ̀

Kó tó di pé Ọlọ́run ‘fi ìjì ẹlẹ́fùúùfù gbé Èlíjà gòkè re ọ̀run’ ó rán an láti Gílígálì lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Èlíjà tiẹ̀ dá a lábàá pé kí Èlíṣà má ṣe tẹ̀ lé òun, àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Bí wọ́n ṣe tún ń rìn lọ, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èlíjà tún sọ fún Èlíṣà pé kó má ṣe tẹ̀ lé òun, àmọ́ Èlíṣà kò gbà láti dúró. (2 Ọba 2:1-6) Bí Rúùtù kò ṣe pa dà lẹ́yìn Náómì, bẹ́ẹ̀ náà ni Èlíṣà ṣe dúró ti Èlíjà gbágbáágbá. (Rúùtù 1:8, 16, 17) Kí nìdí? Ìdí ni pé Èlíṣà mọyì àǹfààní tí Ọlọ́run fún un yìí láti máa ṣèránṣẹ́ fún Èlíjà.

Àpẹẹrẹ àtàtà ni Èlíṣà fi lélẹ̀ fún wa yìí o! Tí wọ́n bá fún wa láǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ètò Ọlọ́run, a máa túbọ̀ mọyì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn tá a bá fi sọ́kàn pé Jèhófà gan-an là ń ṣiṣẹ́ sìn. Àǹfààní wo ló tún ga ju ìyẹn lọ?—Sm. 65:4; 84:10.

“BÉÈRÈ OHUN TÍ ÈMI YÓÒ ṢE FÚN Ọ”

Bí àwọn méjèèjì ṣe ń rìnrìn àjò, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí èmi yóò ṣe fún ọ kí a tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Ṣáájú àkókò yìí, nígbà tí Jèhófà bi Sólómọ́nì ní irú ìbéèrè yìí, ohun tó máa jẹ́ kí Sólómọ́nì sún mọ́ Jèhófà ló ní kó ṣe fún òun. Ohun tí Èlíṣà náà sì ṣe nìyẹn. Ó béèrè pé ‘kí ipa méjì nínú ẹ̀mí Èlíjà bà lé òun.’ (1 Ọba 3:5, 9; 2 Ọba 2:9) Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ìlọ́po méjì ogún ni àkọ́bí tó jẹ́ ọmọkùnrin máa ń gbà. (Diu. 21:15-17) Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Èlíṣà béèrè pé, kí òun dí ajogún Èlíjà nípa tẹ̀mí. Èyí fi hàn pé Èlíṣà náà fẹ́ ní irú ìgboyà tí Èlíjà ní, ẹni tó jẹ́ pé ó ń “jowú fún Jèhófà.”—1 Ọba 19:13, 14.

Kí wá ni Èlíjà sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí? Wòlíì Èlíjà sọ fún un pé: “Ìwọ béèrè ohun kan tí ó ṣòro. Bí o bá rí mi nígbà tí a bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rí mi, kì yóò ṣẹlẹ̀.” (2 Ọba 2:10) Ó jọ pé ohun méjì ni ìdáhùn Èlíjà yìí túmọ̀ sí. Àkọ́kọ́, Jèhófà nìkan ló máa pinnu bóyá Èlíṣà máa rí ohun tó béèrè yìí gbà. Èkejì, tí Èlíṣà bá fẹ́ rí ohun tó béèrè gbà, àfi kó rí i dájú pé òun wà pẹ̀lú Èlíjà nígbà gbogbo láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí.

OHUN TÍ ÈLÍṢÀ RÍ

Báwo ló ṣe rí lára Ọlọ́run nígbà tí Èlíṣà béèrè fún ipa méjì nínú ẹ̀mí Èlíjà? Àkọsílẹ̀ yẹn kà pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń rìn lọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn, họ́wù, wò ó! kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná kan àti àwọn ẹṣin oníná, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pààlà sáàárín àwọn méjèèjì; Èlíjà sì gòkè re ọ̀run nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù. Ní gbogbo àkókò náà, Èlíṣà rí i.” * Bí Jèhófà ṣe dá Èlíṣà lóhùn nìyẹn o! Ó rí i bí a ṣe gba Èlíjà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì tún gba ìlọ́po méjì ẹ̀mí Èlíjà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ajogún tẹ̀mí fún wòlíì náà.—2 Ọba 2:11-14.

Èlíṣà wá mú ẹ̀wù oyè tó jábọ́ lára Èlíjà, ó sì wọ̀ ọ́. Èyí wá jẹ́ kó di mímọ̀ fún àwọn èèyàn pé Èlíṣà ti di wòlíì Ọlọ́run. Ohun tó tiẹ̀ wá mú kó túbọ̀ ṣe kedere pé ó ti di wòlíì Ọlọ́run ni bó ṣe di pé ó lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu, ìyẹn nígbà tó pín omi Odò Jọ́dánì.

Ó dájú pé ohun tí Èlíṣà rí nígbà tí Èlíjà gòkè re ọ̀run nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù nípa lórí rẹ̀ gan-an. Kì í ṣáà ṣe ojoojúmọ́ lèèyàn ń rí kẹ̀kẹ́ ogun oníná àti àwọn ẹṣin oníná! Torí náà, ńṣe ni èyí jẹ́ ẹ̀rí pé inú Jèhófà dùn sí ohun tí Èlíṣà béèrè. Òótọ́ ni pé tí Jèhófà bá dáhùn àdúrà wa, a kì í rí ìran kẹ̀kẹ́ ogun oníná àti àwọn ẹṣin oníná. Àmọ́, a máa ń fòye mọ̀ pé Jèhófà ń lo agbára ńlá rẹ̀ láti mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tá a bá sì rí i pé Jèhófà ń bù kún apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀, ńṣe ló dà bí ìgbà tí à ń fojú wa “rí” kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run Jèhófà tó wà lẹ́nu iṣẹ́.—Ìsík. 10:9-13.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Èlíṣà rí tó fi jẹ́ kó gbà pé lóòótọ́ ni agbára Jèhófà ga lọ́lá. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tún jẹ́ kí Èlíṣà ṣe iṣẹ́ ìyanu mẹ́rìndínlógún, ìyẹn sì jẹ́ ìlọ́po méjì iye iṣẹ́ ìyanu tí Èlíjà ṣe. * Ìgbà kejì tí Èlíṣà tún rí àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná ni ìgbà tí àwọn ọmọ ogun yí wọn ká ní Dótánì, èyí tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.

ÈLÍṢÀ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá yí Èlíṣà ká ní Dótánì, síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ balẹ̀. Kí nìdí tí ọkàn rẹ̀ fi balẹ̀? Ìdí ni pé, ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Àwa náà nílò irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, káwa náà bàa lè ní ìgbàgbọ́ àtàwọn apá tó kù nínú èso tẹ̀mí.—Lúùkù 11:13; Gál. 5:22, 23.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Dótánì yẹn tún jẹ́ kí Èlíṣà rí i pé ó bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ pé kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ tá ò lè fojú rí tí wọ́n ń dàábò bò wá. Wòlíì Èlíṣà rí i pé Jèhófà ti ṣètò ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì láti yí ìlú náà àti àwọn tó sàga tì í ká. Jèhófà wá bu ìfọ́jú lu àwọn ọ̀tá yẹn, ó sì gba Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀ là lọ́nà ìyanu. (2 Ọba 6:17-23) Nígbà tí nǹkan fi le koko yẹn àti láwọn ìgbà míì tí nǹkan kò rọrùn fún Èlíṣà, ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá.

Bíi ti Èlíṣà, ẹ jẹ́ káwa náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run. (Òwe 3:5, 6) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, “Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò fi ojú rere hàn sí wa, yóò sì bù kún wa.” (Sm. 67:1) Òótọ́ ni pé àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná ò yí wa ká lónìí. Àmọ́, nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀, Jèhófà máa dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀ tá a jẹ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé. (Mát. 24:21; Ìṣí. 7:9, 14) Títí dìgbà náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi fún wa.”—Sm. 62:8.

^ ìpínrọ̀ 16 Èlíjà kò gòkè re àwọn ọ̀run tó jẹ́ ibi ẹ̀mí tí Ọlọ́run àti àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ń gbé. Wo Ilé Ìṣọ́ September 15, 1997, ojú ìwé 15.

^ ìpínrọ̀ 19 Wo Ilé Ìṣọ́ August 1, 2005, ojú ìwé 10.