Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

“Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.”—SM. 19:7.

1. Àwọn kókó ọ̀rọ̀ wo làwa èèyàn Ọlọ́run sábà máa ń jíròrò? Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe ń gbé wọn yẹ̀ wò látìgbàdégbà?

ǸJẸ́ ó ti ṣẹlẹ̀ rí pé nígbà tó ò ń múra sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, o wá ń rò ó lọ́kàn pé, ‘Ó dà bíi pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí rí’? Bóyá ó ti pẹ́ díẹ̀ tó o ti ń dara pọ̀ mọ́ ètò Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan wà tá a máa ń jíròrò látìgbàdégbà. Lára àwọn ohun tá a máa ń gbé yẹ̀ wò ni ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìràpadà, iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, títí kan àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́. Apá pàtàkì làwọn nǹkan yìí jẹ́ lára oúnjẹ tẹ̀mí wa. Bá a ṣe máa ń gbé àwọn kókó ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ó sì ń mú ká “di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.”—Ják. 1:22.

2. (a) Kí ni àwọn ìránnilétí Ọlọ́run sábà máa ń tọ́ka sí? (b) Báwo làwọn ìránnilétí Ọlọ́run ṣe yàtọ̀ sí tèèyàn?

2 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ìránnilétí” sábà máa ń dúró fún àwọn òfin, àṣẹ àtàwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn. Ìgbà gbogbo ni òfin àti ìlànà Jèhófà ṣeé gbára lé, àmọ́ àwọn èèyàn sábà máa ń yí òfin wọn pa dà tàbí kí wọ́n fi kún un. Lóòótọ́, àwọn òfin àti ìlànà kan wà fún àkókò kan pàtó ó sì lè jẹ́ torí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé, àmọ́ kò sígbà tí wọn ò wúlò. Onísáàmù náà sọ pé: “Òdodo àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sm. 119:144.

3, 4. (a) Nígbà míì, àwọn nǹkan wo ló máa ń wà lára àwọn ìránnilétí Jèhófà? (b) Àǹfààní wo ló máa ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá fi wọ́n sílò?

3 Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé, nígbà míì ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ máa ń wà lára àwọn ìránnilétí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn wòlíì Ọlọ́run máa ń kìlọ̀ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra yín, kí a má bàa ré ọkàn-àyà yín lọ, tí ẹ ó sì yà kúrò ní tòótọ́, tí ẹ ó sì jọ́sìn àwọn ọlọ́run mìíràn, tí ẹ ó sì tẹrí ba fún wọn, tí ìbínú Jèhófà a sì ru sí yín ní ti gidi.” (Diu. 11:16, 17) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run máa ń rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ kí wọ́n bàa lè ṣe ohun tó tọ́.

4 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n bẹ̀rù òun, kí wọ́n tẹ́tí sí òun, kí wọ́n sì ya orúkọ òun sí mímọ́. (Diu. 4:29-31; 5:28, 29) Ó dájú pé Ọlọ́run máa bù kún wọn gan-an tí wọ́n bá fi àwọn ìránnilétí rẹ̀ sílò.—Léf. 26:3-6; Diu. 28:1-4.

ỌWỌ́ TÍ ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ FI MÚ ÀWỌN ÌRÁNNILÉTÍ ỌLỌ́RUN

5. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbèjà Hesekáyà Ọba?

5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé jálẹ̀ ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nǹkan ò fara rọ fún wọn, síbẹ̀ Ọlọ́run kò gbàgbé ìlérí tó ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà gbógun ti ilẹ̀ Júdà tó sì ń halẹ̀ pé òun máa rọ Hesekáyà Ọba lóyè, Jèhófà rán ańgẹ́lì kan láti gbèjà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo, áńgẹ́lì Ọlọ́run pa “gbogbo akíkanjú, alágbára ńlá ọkùnrin,” ìyẹn àwọn ọmọ ogun Ásíríà. Àbùkù bá Senakéríbù, ló bá pa dà sílé. (2 Kíró. 32:21; 2 Ọba 19:35) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbèjà Hesekáyà Ọba? Ìdí ni pé Hesekáyà “ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà. Kò yà kúrò nínú títọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—2 Ọba 18:1, 5, 6.

Àwọn ìránnilétí Jèhófà mú kí Jòsáyà gbèjà ìjọsìn tòótọ́ (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Báwo ni Jòsáyà Ọba ṣe fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

6 Ẹlòmíì tó tún ṣègbọràn sí Jèhófà ni Jòsáyà Ọba. Láti ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ló ti “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà . . . kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.” (2 Kíró. 34:1, 2) Jòsáyà fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ti pé ó mú kí ìbọ̀rìṣà kásẹ̀ nílẹ̀ ó sì mú kí ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò. Ohun tí Jòsáyà ṣe yìí mú kí Jèhófà bù kún òun àti gbogbo èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè náà.—Ka 2 Kíróníkà 34:31-33.

7. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n pa àwọn ìránnilétí Jèhófà tì?

7 Ó báni nínú jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn èèyàn Ọlọ́run ń fọkàn tán àwọn ìránnilétí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi dúró sójú kan, bí wọ́n bá gbọ́ràn díẹ̀, wọ́n á tún ṣàìgbọràn. Ní gbogbo ìgbà tí ìgbàgbọ́ wọn bá jó rẹ̀yìn, ńṣe lọ̀rọ̀ wọn máa ń dà bí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, wọ́n á dẹni tí ‘a ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́.’ (Éfé. 4:13, 14) Àbájáde kíkorò tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá tàpá sí àwọn ìránnilétí Ọlọ́run.—Léf. 26:23-25; Jer. 5:23-25.

8. Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

8 Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Bí Ọlọ́run ṣe ń gbà wọ́n níyànjú, tó sì ń bá wọn wí náà ló ń ṣe fún àwa náà lónìí. (2 Pét. 1:12) Nígbàkigbà tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, ńṣe là ń gba àwọn ìránnilétí rẹ̀. Torí pé a ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá, a lè yàn láti tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà tàbí ká ṣe ohun tá a gbà pé ó tọ́. (Òwe 14:12) Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí mélòó kan tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Jèhófà àti bí wọ́n ṣe lè ṣe wá láǹfààní tá a bá ń fi wọ́n sílò.

FI ARA RẸ SÁBẸ́ ỌLỌ́RUN KÓ O SÌ WÀ LÁÀYÈ

9. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù, kí ni Jèhófà ṣe láti mú kó dá wọn lójú pé òun wà pẹ̀lú wọn?

9 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò ológójì [40] ọdún, tí wọ́n ń gba inú ‘aginjù amúnikún-fún-ẹ̀rù,’ Jèhófà ò sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa bó ṣe máa darí wọn, bó ṣe máa dáàbò bò wọ́n àti bó ṣe máa tọ́jú wọn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ṣe àwọn ohun tó mú kí wọ́n rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, kí wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀. Bí Jèhófà ṣe ń ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ojú ọ̀nà tó nira yẹn, ó lo ọwọ̀n àwọsánmà lọ́sàn-án àti ọwọ̀n iná lálẹ́ láti máa rán wọn létí pé òun wà pẹ̀lú wọn. (Diu. 1:19; Ẹ́kís. 40:36-38) Ó tún pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò. “Ẹ̀wù wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú.” Ká sòótọ́, “wọn kò ṣaláìní nǹkan kan.”—Neh. 9:19-21.

10. Báwo ni Jèhófà ṣe ń darí àwa èèyàn rẹ̀ lónìí?

10 Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti wà ní bèbè ayé tuntun òdodo báyìí. Ṣé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa fún wa ní ohun tá a nílò láti la “ìpọ́njú ńlá” tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí já? (Mát. 24:21, 22; Sm. 119:40, 41) Òótọ́ ni pé Jèhófà kò lo ọwọ̀n àwọsánmà tàbí ọwọ̀n iná bó ṣe ń darí wa lọ sínú ayé tuntun. Àmọ́, ó ń lo ètò rẹ̀ láti mú ká wà lójúfò. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ètò Jèhófà ń tẹnu mọ́ ọn pé ká túbọ̀ mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run lágbára. Ètò náà ń rọ̀ wá pé ká máa ka Bíbélì déédéé, ká máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, ká máa pésẹ̀ sípàdé déédéé, ká sì máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé. Ǹjẹ́ a ti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ ká lè fi àwọn ìtọ́ni yìí sílò? Tá a bá ń fi àwọn ìtọ́ni náà sílò, a máa ní irú ìgbàgbọ́ tó máa pa wá mọ́ láàyè wọnú ayé tuntun.

Tá a bá ń fi àwọn ìránnilétí Jèhófà sílò, kò ní sí ewu ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, á sì rọrùn fáwọn èèyàn láti wọ ibẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa?

11 Yàtọ̀ sí pé àwọn ìtọ́ni tá a ti rí gbà ń mú ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí, wọ́n tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ohun tó kan ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń mú ká lè máa fi ojú tó tọ́ wo àwọn nǹkan tara, wọ́n sì ń mú kí ohun díẹ̀ tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, láìsí pé à ń ṣe àníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Àwọn ìtọ́ni míì tó tún ń ṣe wá láǹfààní ni èyí tí wọ́n fún wa nípa aṣọ àti ìmúra, bá a ṣe lè yan eré ìnàjú tó bójú mu àti bá a ṣe lè ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa bó ṣe yẹ ká kàwé tó. Ẹ tún wo àwọn ìránnilétí tá a rí gbà nípa bó ṣe yẹ ká máa bójú tó ilé wa, ọkọ̀ wa àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa lọ́nà tí ẹ̀mí wa ò fi ní wà nínú ewu àti bá a ṣe lè múra sílẹ̀ de àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì. Àwọn ìtọ́ni yìí fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún gan-an ni.

ÀWỌN ÌRÁNNILÉTÍ MÚ KÁWỌN KRISTẸNI ÌGBÀANÌ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

12. (a) Kí ni ohun kan tí Jésù máa ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn lọ́nà tí Pétérù ò jẹ́ gbàgbé láé? Kí ló yẹ kí ìyẹn mú kí àwa náà ṣe?

12 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn èèyàn Ọlọ́run ń rí ìránnilétí gbà déédéé. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Àmọ́, kò sọ ọ́ lọ́rọ̀ ẹnu nìkan, ó tún fi hàn wọ́n bí wọ́n ṣe lè ṣe é. Lọ́jọ́ tí Jésù máa kú, òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kóra jọ láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Nígbà táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣì ń jẹun lọ́wọ́, Jésù kúrò nídìí oúnjẹ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ tí ìránṣẹ́ sábà máa ń ṣe, ìyẹn ni pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ ẹsẹ̀ wọn. (Jòh. 13:1-17) Àwọn àpọ́sítélì kò jẹ́ gbàgbé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù fi hàn yìí. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pétérù tóun náà wà nídìí oúnjẹ lọ́jọ́ yẹn gba àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (1 Pét. 5:5) Ó yẹ kí àpẹẹrẹ Jésù mú kí gbogbo wa máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá ara wa lò.—Fílí. 2:5-8.

13. Ànímọ́ tó ṣe pàtàkì wo ni Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ létí pé kí wọ́n ní?

13 Ohun míì tí Jésù sábà máa ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ ni pé kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn náà kò lágbára láti lé ẹ̀mí èṣù tó ń dààmú ọmọkùnrin kan jáde, wọ́n bi Jésù pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwa kò lè lé e jáde?” Jésù dáhùn pé: ‘Nítorí ìgbàgbọ́ yín tí ó kéré ni. Nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, kò sí ohunkóhun tí kì yóò ṣeé ṣe fún yín.’ (Mát. 17:14-20) Ní gbogbo àkókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó tẹnu mọ́ ọn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́. (Ka Mátíù 21:18-22.) Láwọn àpéjọ àgbègbè, àyíká, àkànṣe àti láwọn ìpàdé ìjọ, a máa ń gba àwọn ìtọ́ni tó lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Àmọ́, ṣé à ń fi àwọn ìtọ́ni náà sílò? Kì í ṣe pé àwọn ìkórajọ yìí ń mú ká láyọ̀ nìkan ni, wọ́n tún ń jẹ́ ká lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

14. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa náà ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní?

14 Ọ̀pọ̀ ìránnilétí ló wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì pé ká máa fìfẹ́ hàn síra wa. Jésù sọ pé òfin kejì tó tóbi jù ni pé, “kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mát. 22:39) Bákan náà, Jákọ́bù tó jẹ́ iyèkan Jésù sọ pé ìfẹ́ jẹ́ “ọba òfin.” (Ják. 2:8) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo ń kọ̀wé sí yín, kì í ṣe àṣẹ tuntun, bí kò ṣe àṣẹ ti láéláé, èyí tí ẹ ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” (1 Jòh. 2:7, 8) Kí ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó sọ nípa “àṣẹ ti láéláé”? Àṣẹ Jésù tó ní ká ní ìfẹ́ ni Jòhánù ní lọ́kàn. Ó jẹ́ “ti láéláé” torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù fún wọn lófin yẹn, ìyẹn “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” Àmọ́, ó tún jẹ́ “tuntun” torí pé ó gba pé kéèyàn ṣe tán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ nítorí àwọn ẹlòmíì. Ó sì lè gba pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe bẹ́ẹ̀ bí àwọn nǹkan ṣe ń yí pa dà. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ṣé a mọrírì àwọn ìkìlọ̀ tí kì í jẹ́ ká fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó kúnnú ayé yìí? Tá ò bá ṣọ́ra, irú ẹ̀mí ayé bẹ́ẹ̀ lè mú ká gbàgbé ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni.

15. Kí ni iṣẹ́ pàtàkì tí Jésù wá ṣe láyé?

15 Jésù fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ òun lógún gan-an. Ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn hàn nínú bó ṣe wo àwọn aláìsàn àtàwọn aláìlera sàn àti bó ṣe jí òkú dìde. Àmọ́, kì í ṣe ìwòsàn tara ni iṣẹ́ pàtàkì tí Jésù wá ṣe láyé. Ohun tó wàásù àtèyí tó fi kọ́ni ló ṣe àwọn èèyàn láǹfààní jù lọ. Lọ́nà wo? A mọ̀ pé àwọn tí Jésù wò sàn àtàwọn tó jí dìde ní ọ̀rúndún kìíní pa dà darúgbó wọ́n sì kú, àmọ́ àwọn tó fara mọ́ ìwàásù rẹ̀ máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.—Jòh. 11:25, 26.

16. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ṣe gbilẹ̀ tó lónìí?

16 Iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní ọ̀rúndún kìíní ti dèyí tá à ń ṣe nílé lóko báyìí. Ó ṣe tán, Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19) Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe gudugudu méje lẹ́nu iṣẹ́ yìí, àwa náà sì ṣe yààyàà mẹ́fà! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ti lé ní mílíọ̀nù méje ń fìtara wàásù Ìjọba Ọlọ́run ní ilẹ̀ tó ju ọgbọ̀nlérúgba [230], a sì ń kọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Iṣẹ́ ìwàásù yìí jẹ́ ẹ̀rí pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí.

Ó YẸ KÁWA NÁÀ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

17. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù àti Pétérù gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni?

17 Ó ṣe kedere pé àwọn ìránnilétí mú kí ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni ìgbàanì túbọ̀ lágbára. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, ó kọ̀wé sí Tímótì pé: “Máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tí ìwọ gbọ́ lọ́dọ̀ mi mú.” (2 Tím. 1:13) Ẹ wò bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe máa fún Tímótì níṣìírí tó. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n ní àwọn ànímọ́ bí ìfaradà, ìfẹ́ni ará àti ìkóra-ẹni-níjàánu, ó sọ pé: “Èmi yóò múra tán nígbà gbogbo láti rán yín létí nǹkan wọ̀nyí, bí ẹ tilẹ̀ mọ̀ wọ́n, tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òtítọ́.”—2 Pét. 1:5-8, 12.

18. Ojú wo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi wo àwọn ìránnilétí?

18 Ó dájú pé “àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú” ni Pọ́ọ̀lù àti Pétérù kọ sínú lẹ́tà wọn. (2 Pét. 3:2) Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣàìka àwọn ìtọ́ni yẹn sí? Rárá o. Wọ́n gbà pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wọn ló mú kó fún wọn láwọn ìtọ́ni yẹn, àwọn ìtọ́ni yẹn sì ń mú kí wọ́n “máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.”—2 Pét. 3:18.

19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Jèhófà? Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?

19 Lónìí, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Jèhófà, tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí kì í kùnà. (Ka Jóṣúà 23:14.) Ìtàn bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn aláìpé lò fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wà nínú Bíbélì. Torí tiwa ni wọ́n ṣe ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìtàn wọ̀nyẹn. (Róòmù 15:4; 1 Kọ́r. 10:11) Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ló ti ṣẹ lójú wa. A lè fi àsọtẹ́lẹ̀ wé àwọn ìránnilétí tá a gbọ́ kó tó di pé wọ́n nímùúṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti dara pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wáyé ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” (Aísá. 2:2, 3) Bí àwọn nǹkan ṣe ń burú sí i láyè yìí tún jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń nímùúṣẹ. Bákan náà, bá a ṣe sọ lókè, iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé ń mú ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ.—Mát. 24:14.

20 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ẹlẹ́dàá wa ti ṣe tó lè mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e. Àmọ́ ṣé à ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Jèhófà. Ohun tí Arábìnrin Rosellen ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe túbọ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe túbọ̀ ń rí ọwọ́ ìfẹ́ rẹ̀ lára mi, ó ń bójú tó mi ó sì ń fún mi lókun.” Ǹjẹ́ kí àwa náà jàǹfààní bá a ṣe ń ṣègbọràn sí àwọn ìránnilétí Jèhófà.