Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ẹ Ti Para Dà?

Ǹjẹ́ Ẹ Ti Para Dà?

“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà.”—RÓÒMÙ 12:2.

1, 2. Ipa wo ni bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà àti ibi tá a gbé dàgbà máa ń ní lórí wa?

KÒ SẸ́NÌ kan nínú wa tó lè sọ pé bí wọ́n ṣe tọ́ òun dàgbà àti ibi tí òun gbé dàgbà kò nípa lórí òun. Ó ní bá a ṣe ń múra, ó nírú oúnjẹ tá a fẹ́ràn, ó sì ní bá a ṣe ń hùwà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Àárín àwọn tá à ń gbé àtàwọn ipò tó yí wa ká wà lára ohun tó fà á.

2 Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì ju irú oúnjẹ tá a yàn láàyò àti irú aṣọ tá à ń wọ̀. Bí àpẹẹrẹ, láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ wa láwọn ohun tó dára tá a lè ṣe àtàwọn ohun tí kò dára tó yẹ ká sá fún. Ọ̀pọ̀ nínú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ ọ̀rọ̀ ara ẹni, ọwọ́ tí kálukú sì fi mú un yàtọ̀ síra. Àwọn ìpinnu tá à ń ṣe tiẹ̀ lè jẹ́ àbájáde ohun tí ẹ̀rí ọkàn wa sọ. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ‘àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin máa ń ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá.’ (Róòmù 2:14) Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé tí kò bá ti sí òfin kan pàtó nínú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ kan, a kàn lè ṣe nǹkan lọ́nà tí wọ́n gbà tọ́ wa dàgbà àti bí wọ́n ti ń ṣe nǹkan lágbègbè wa?

3. Bí àwọn tó wà lágbègbè wa bá tiẹ̀ gbà pé ọ̀nà kan ló dára jù láti gbà ṣe nǹkan, ìdí méjì wo ló fi yẹ kí àwa Kristẹni rò ó wò ká tó gbà pẹ̀lú wọn?

3 Ó kéré tán, ìdí méjì pàtàkì ni kò fi yẹ kí àwa Kristẹni ronú lọ́nà yẹn. Àkọ́kọ́ ni pé, Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 16:25) Torí pé a jẹ́ aláìpé, àwa èèyàn kò kúnjú ìwọ̀n láti pinnu ohun tó lè mú kí ìgbésí ayé wa yọrí sí rere láìsí àṣìṣe èyíkéyìí. (Òwe 28:26; Jer. 10:23) Ìdí kejì ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ló ń darí àwọn àṣà tó gbòde àtàwọn ìlànà tí ayé ń tẹ̀ lé. (2 Kọ́r. 4:4; 1 Jòh. 5:19) Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà, tá a sì fẹ́ kó bù kún wa, ó yẹ ká ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Róòmù 12:2.Kà á.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Àwọn kókó pàtàkì kan wà nínú Róòmù 12:2yẹ ká fún láfiyèsí. Àkọ́kọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká “para dà” tàbí yí pa dà? Èkejì, kí ló yẹ ká yí pa dà? Ìkẹta, báwo gan-an la ṣe lè para dà? Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ PARA DÀ?

5. Àwọn wo gan-an ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 12:2 kàn gbọ̀ngbọ̀n?

5 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn ará Róòmù, kì í ṣe àwọn aláìgbàgbọ́ tàbí gbogbo àwọn tó ń gbé nílùú Róòmù ló ń bá sọ̀rọ̀ bí kò ṣe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bíi tiẹ̀. (Róòmù 1:7) Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n para dà, kí wọ́n sì “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” Ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, ara nǹkan táwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù lákòókò yẹn mọ̀ sí “ètò àwọn nǹkan” ni àwọn ìlànà, àṣà, ìhùwàsí àti báwọn èèyàn ṣe ń ṣe nǹkan nílùú Róòmù. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà ‘ẹ jáwọ́’ fi hàn pé ètò àwọn nǹkan yẹn ṣì ń nípa lórí àwọn kan láàárín wọn. Ipa wo ló ní lórí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nígbà yẹn?

6, 7. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà láyé, báwo ni ohun tó ń lọ láwùjọ àti lágbo àwọn ẹlẹ́sìn ṣe jẹ́ ìpèníjà fún àwọn Kristẹni?

6 Lónìí, àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sí ìlú Róòmù máa ń rí àwókù tẹ́ńpìlì, sàréè, ohun ìránnilétí, gbọ̀ngàn ìṣeré, gbọ̀ngàn ìwòran àtàwọn nǹkan míì. Ọ̀rúndún kìíní ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn nǹkan yìí ti wà. Àwọn nǹkan yìí ló ń jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó ti wáyé láwùjọ àti lágbo àwọn ẹlẹ́sìn nílùú Róòmù láyé àtijọ́. A tún lè kà nípa àwọn eré ìdárayá oníjà àjàkú akátá, àwọn ìdíje fífi kẹ̀kẹ́ ogun sáré, àwọn eré orí ìtàgé àti orin tó dá lórí onírúurú ẹ̀kọ́, àwọn míì nínú wọn ò tiẹ̀ bójú mu. Ìlú Róòmù tún jẹ́ ibi tí ọrọ̀ ajé ti rọ̀ṣọ̀mù, nípa bẹ́ẹ̀ ó ṣeé ṣe láti dolówó rẹpẹtẹ.—Róòmù 6:21; 1 Pét. 4:3, 4.

7 Lóòótọ́, àwọn ará Róòmù ní tẹ́ńpìlì rẹpẹtẹ tí wọ́n kọ́ fún onírúurú òrìṣà, àmọ́ wọn ò ní àjọṣe gidi kan pẹ̀lú èyíkéyìí nínú àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ yẹn. Àwọn èèyàn náà gbà pé kò sóhun méjì tí ìsìn túmọ̀ sí ju pé káwọn ṣáà ti máa ṣe onírúurú ètùtù, bóyá nígbà tẹ́nì kan bá ń ṣègbéyàwó, tẹ́nì kan bá bímọ àti nígbà ìsìnkú. Wọ́n gbà pé ara ohun tó ṣe pàtàkì láwùjọ nìyẹn. Ṣé ẹ wá rí i pé ìpèníjà ńlá ló máa jẹ́ fún àwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Róòmù nígbà yẹn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló jẹ́ pé inú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà. Ó ṣe kedere nígbà náà pé wọ́n ní láti para dà tàbí yí pa dà kí wọ́n tó lè di Kristẹni tòótọ́. Ó sì dájú pé wọ́n á ṣì máa ṣe àwọn ìyípadà míì lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ìrìbọmi.

8. Báwo ni ayé tá à ń gbé yìí ṣe mú kó ṣòro fún àwa Kristẹni tòótọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

8 Bí àwọn ohun tó ń lọ nílùú Róòmù ṣe mú kó nira fún àwọn Kristẹni ìgbà yẹn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ni ayé tá à ń gbé lónìí ṣe mú kí nǹkan ṣòro fún àwa Kristẹni tá a ti ya ara wa sí mímọ̀ fún Jèhófà. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé onírúurú ọ̀nà ni ẹ̀mí ayé yìí gbà ń fara hàn. (Ka Éfésù 2:2, 3; 1 Jòhánù 2:16.) Torí pé inú ayé yìí là ń gbé, ojoojúmọ́ là ń kojú àwọn ohun tó lè kó èèràn ràn wá nínú ayé, yálà àwọn ohun tí ayé ń fẹ́, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú, àwọn nǹkan tí wọ́n kà sí bàbàrà àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń hùwà. Nípa bẹ́ẹ̀, a ní àwọn ìdí tó ṣe gúnmọ́ láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì pé ká “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí” àti pé ká “para dà.” Kí la ní láti ṣe?

KÍ LÓ YẸ KÁ YÍ PA DÀ?

9. Àwọn ìyípadà wo ni àwọn kan ṣe kó tó di pé wọ́n ṣèrìbọmi?

9 Béèyàn kan bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ń fi àwọn ohun tó ń kọ́ sílò, bẹ́ẹ̀ lá máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Bó ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ lá máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ. Kò tún ní lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìsìn èké mọ́, á jáwọ́ nínú ìwà èyíkéyìí tí kò yẹ tó ti ń hù tẹ́lẹ̀, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà lọ́nà tó yẹ Kristẹni. (Éfé. 4:22-24) Inú wá dùn pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń tẹ̀ síwájú lọ́nà yìí, tí wọ́n sì ń tóótun láti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Èyí sì ń múnú Jèhófà dùn gan-an ni. (Òwe 27:11) Àmọ́, ó yẹ ká bi ara wa pé: Ṣé gbogbo ìyípadà téèyàn ní láti ṣe kò jù yẹn lọ?

Ọ̀pọ̀ ní láti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé Sátánì yìí kí wọ́n sì para dà (Wo ìpínrọ̀ 9)

10. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín kéèyàn para dà àti kí ìwà èèyàn sunwọ̀n sí i?

10 Ká sóòótọ́, kéèyàn para dà kọjá pé kéèyàn kan máa tẹ̀ síwájú tàbí kí ìwà èèyàn sunwọ̀n sí i. Àwọn ọlọ́jà lè sọ pé àwọn ti mú ohun èèlò tàbí ọjà kan tí wọ́n ń polówó rẹ̀ sunwọ̀n sí i tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kọ ọ́ sára ohun èèlò tàbí ọjà náà. Àmọ́, ohun kan tó dájú ni pé ọjà yẹn kan náà ni, kì í ṣe òmíràn. Ó kàn lè jẹ́ pé èròjà kan péré ni wọ́n fi kún un, tí wọ́n tún wá jẹ́ kí ọ̀rá tàbí páálí rẹ̀ túbọ̀ lẹ́wà sí i. Nígbà tí ìwé atúmọ̀ èdè kan tí wọ́n pè ní Vine’s Expository Dictionary ń ṣàlàyé gbólóhùn náà “ẹ para dà,” ó sọ pé: “Nínú Róòmù 12:2, kéèyàn máa sapá láti ṣe ohun tí ayé yìí [tàbí ètò àwọn nǹkan yìí] ń ṣe yàtọ̀ pátápátá sí pé kí agbára ẹ̀mí mímọ́ mú kéèyàn para dà [tàbí yí pa dà] tàbí kí ìrònú èèyàn yí pa dà.” Nípa bẹ́ẹ̀, bí Kristẹni kan bá máa para dà, ó kọjá pé kó kàn kọ ìwà burúkú, ọ̀rọ̀ rírùn tàbí ìṣekúṣe sílẹ̀. Àwọn kan wà tí wọn ò tiẹ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì rárá tó sì jẹ́ pé wọ́n ń sapá láti sá fún àwọn nǹkan búburú wọ̀nyẹn. Nígbà náà, kí ló túmọ̀ sì fún Kristẹni kan láti para dà?

11. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, ọ̀nà wo lèèyàn lè gbà para dà?

11 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà.” “Èrò inú” ní í ṣe pẹ̀lú agbára ìrònú wa. Àmọ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì, ó tún ní í ṣe pẹ̀lú èrò ọkàn wa, ọ̀nà tá a gbà ń ronú àti ìwà wa. Kó tó di pé Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí sáwọn ará Róòmù, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n ń fi “ipò èrò-orí tí kò ní ìtẹ́wọ́gbà” hàn. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń lọ́wọ́ nínú “àìṣòdodo, ìwà burúkú, ojúkòkòrò, ìwà búburú, wọ́n kún fún ìlara, ìṣìkàpànìyàn, gbọ́nmi-si omi-ò-to, ẹ̀tàn” àtàwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́ mìíràn. (Róòmù 1:28-31) Èyí jẹ́ ká rí ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn tí wọ́n tọ́ dàgbà nírú àyíká bẹ́ẹ̀ àmọ́ tí wọ́n di ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé kí wọ́n “para dà” kí wọ́n sì ‘yí èrò inú wọn pa dà.’

‘Kí ẹ mú gbogbo ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.’—Éfé. 4:31

12. Kí lo kíyè sí nínú ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà ronú lóde òní? Báwo lèyí ṣe lè kó èèràn ran àwa Kristẹni?

12 Irú ìwà tí Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe rẹ̀ yìí gan-an làwọn èèyàn tó yí wa ká ń hù. Wọ́n máa ń ronú pé àwọn tí kò rọ́ọ̀ọ́kán tàbí àwọn tí kò rí ara gba nǹkan sí ló máa ń tẹ̀ lé ìlànà nínú ohun tí wọ́n ń ṣe. Ọ̀pọ̀ olùkọ́ àti òbí ló máa ń gbọ̀jẹ̀gẹ́, wọ́n máa ń fàyè gba àwọn ọmọ láti ṣe bó ṣe wù wọ́n. Lójú tiwọn, wọ́n gbà pé ohun tó bá wu kálukú ló lè ṣe, pé kò sí ẹni tó lè fi òté lé ohunkóhun pé ó tọ́ tàbí kò tọ́. Àwọn tó tiẹ̀ láwọn mọ Ọlọ́run pàápàá ronú pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe nǹkan lọ́nà tó wu àwọn, àti pé kì í ṣe dandan káwọn máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Sm. 14:1) Ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń ronú yìí lè kó èèràn ran àwa Kristẹni tòótọ́. Àwọn tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní irú èrò yẹn nípa ohun tí ètò Ọlọ́run ń ṣe. Wọ́n lè máa lọ́ tìkọ̀ láti kọ́wọ́ ti ètò tí ìjọ ṣe, wọ́n lè máa ṣàròyé nípa ohun tí kò bá èrò tiwọn mu. Wọ́n sì lè má fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa lórí eré ìnàjú, lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì àti lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga.

13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fi òótọ́ inú yẹ ara wa wò?

13 Torí náà, tá ò bá fẹ́ kí ayé yìí kó èèràn rẹ̀ ràn wá mọ́, ó yẹ ká fi òótọ́ inú yẹ ara wa wò. Ká wo irú ẹni tá a jẹ́ gan-an, ìwà wa, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, àwọn àfojúsùn wa àtàwọn ohun tá a kà sí pàtàkì. Àwọn nǹkan yìí lè má hàn sí àwọn míì. Wọ́n tiẹ̀ lè máa sọ fún wa pé à ń ṣe dáadáa. Ṣùgbọ́n, àwa gan-an la máa mọ̀ bóyá lóòótọ́ là ń jẹ́ kí àwọn ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì yí wa pa dà láwọn apá pàtàkì tá a mẹ́nu kàn yìí, tá a sì túbọ̀ ń jẹ́ kó mú ká yí pa dà.—Ka Jákọ́bù 1:23-25.

BÁWO GAN-AN LA ṢE LÈ PARA DÀ?

14. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ?

14 Ohun tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún la ní láti yí pa dà. Nípa bẹ́ẹ̀, a nílò ohun tó máa lè wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin, tí kì í ṣe oréfèé lásán. Kí lohun náà tó lè ràn wá lọ́wọ́? Nígbà tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe, irú ọwọ́ tá a bá fi mú ọ̀rọ̀ náà ló máa fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn, òun náà ló máa jẹ́ ká mọ àwọn ìyípadà tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè máa hùwà tó bá “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó pé” mu.—Róòmù 12:2; Héb. 4:12.

15. Irú ìyípadà wo lẹnì kan máa ṣe tí Jèhófà bá mọ ọ́n bí amọ̀kòkò ṣe ń mọ ìkòkò?

15 Ka Aísáyà 64:8. Àfiwé ọ̀rọ̀ tí wòlíì Aísáyà lò yìí jẹ́ ká rí àwọn kókó pàtàkì kan tó yẹ ká ronú lé. Báwo ni Jèhófà, tó jẹ́ Amọ̀kòkò náà ṣe ń mọ àwa èèyàn tó fi wé amọ̀? Ó dájú pé kì í ṣe ìrísí ojú wa tàbí bá a ṣe rí lóde ara ni Jèhófà fẹ́ tún ṣe ká lè túbọ̀ lẹ́wà sí i. Ńṣe ni Jèhófà ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn, kì í ṣe torí ká lè túbọ̀ lẹ́wà nípa tara. Tá a bá jẹ́ kó mọ wá, a máa yí irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún pa dà, tàbí lédè míì, ìyípadà nípa tẹ̀mí la máa ṣe. Ìyẹn sì ni ohun tá a nílò gan-an láti kojú ipa tí ayé búburú yìí lè ní lórí wa. Báwo gan-an ni Jèhófà ṣe ń mọ wá?

16, 17. (a) Sọ ohun tí amọ̀kòkò kan máa ń ṣe sí amọ̀ kó tó fi mọ nǹkan. (b) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń mú ká para dà di ẹni tó ṣeyebíye fún Jèhófà?

16 Kí amọ̀kòkò kan tó lè mọ ìkòkò tó dáa tó sì lágbára, ó ní láti lo amọ̀ tó lẹ̀ dáadáa. Àmọ́ o, ohun méjì kan wà tó ní láti ṣe. Àkọ́kọ́, ó máa fi omi po amọ̀ náà, á wá sẹ́ ẹ bí ìgbà téèyàn sẹ́ ògì, kó lè yọ àwọn ìdọ̀tí inú rẹ̀ kúrò. Lẹ́yìn náà, á jẹ́ kó silẹ̀, á sì yọ́ omi orí rẹ̀ kúrò. Tó bá ti fẹ́ lo amọ̀ náà, á fi ìwọ̀n omi tó yẹ po amọ̀ náà pọ̀, á tẹ̀ ẹ́, á wá ṣù ú láti fi mọ nǹkan tó fẹ́.

17 Ẹ kíyè sí i pé, amọ̀kòkò náà lo omi láti yọ àwọn ìdọ̀tí inú amọ̀ náà kúrò àti láti mú kí amọ̀ náà rọ̀ kí ó sì lẹ̀ tó bí ó ṣe fẹ́. Lẹ́yìn náà, á wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi mọ nǹkan tó fẹ́, títí kan ohun èlò tó gbẹgẹ́ pàápàá. A lè fi ipa tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń kó nínú ìgbésí ayé wa wé iṣẹ́ tí omi ń ṣe lára amọ̀ náà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò dára tá a ti ń hù kó tó di pé a mọ Ọlọ́run, ó sì ń mú ká yí pa dà ká lè wúlò fún Ọlọ́run. (Éfé. 5:26) Ẹ wo iye ìgbà tí ètò Ọlọ́run ti ń rọ̀ wá pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì máa lọ sí ìpàdé níbi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Kí nìdí tí wọ́n fi ń gbà wá níyànjú lemọ́lemọ́ pé ká máa ṣe àwọn nǹkan yìí? Ìdí ni pé tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń gbà kí Jèhófà mọ wá.—Sm. 1:2; Ìṣe 17:11; Héb. 10:24, 25.

Tí o bá ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, wàá lè yanjú àwọn ìṣòro tó o bá ní lọ́nà tó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. (a) Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká yí pa dà, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò? (b) Ìbéèrè wo ló ṣe pàtàkì pé ká bi ara wa?

18 Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká yí pa dà, ohun tá a máa ṣe kọjá ká kàn máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ka Bíbélì látìgbàdégbà, débi pé wọ́n ti wá dojúlùmọ̀ àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀. Bóyá o ti bá irú àwọn bẹ́ẹ̀ pàdé lóde ẹ̀rí. Àwọn kan tiẹ̀ wà tó lè sọ ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sọ lórí. * Àmọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ hàn nínú bí wọ́n ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan pé wọ́n tiẹ̀ mọ Bíbélì rárá. Kí ló fà á? Ohun kan ni pé kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè mú kẹ́nì kan yí pa dà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà wọ òun lọ́kàn ṣinṣin. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà nínú Bíbélì. Ó bọ́gbọ́n mú ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo gbà pé ohun tí mò ń kà yìí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀kọ́ ìsìn kan? Ṣé mo gbà pé òtítọ́ lohun tí mò ń kà yìí? Ṣé bí mo ṣe máa fi nǹkan tí mò ń kọ́ sílò ní ìgbésí ayé mi ló máa ń jẹ mí lógún ni àbí bí mo ṣe máa fi kọ́ àwọn ẹlòmíì ló máa ń gbà mí lọ́kàn? Ṣé ó máa ń ṣe mí bíi pé Jèhófà gan-an ló ń bá mi sọ̀rọ̀?’ Tá a bá ń ronú tá a sì ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìbéèrè yìí, á mú kó túbọ̀ máa wù wá láti sún mọ́ Jèhófà. Àá sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tá a bá wá nírú ìfẹ́ àtọkànwá bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ.—Òwe 4:23; Lúùkù 6:45.

19, 20. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló lè ṣe wá láǹfààní tá a bá fi í sílò?

19 Bá a ṣe ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà, ṣe ló máa mú ká túbọ̀ tẹra mọ́ ohun kan tó ṣeé ṣe ká ti ṣe tẹ́lẹ̀ déwọ̀n àyè kan. Ìyẹn ni pé, ó ṣeé ṣe ká ti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé: ‘Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀.’ (Kól. 3:9, 10) Ohun kan dájú, bá a ṣe túbọ̀ ń lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì ń ní ipa rere lórí ìgbésí ayé wa, bẹ́ẹ̀ ni a ṣe túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú. Àá tipa bẹ́ẹ̀ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tó máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì.

20 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: ‘Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fúnra yín di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.’ (1 Pét. 1:14, 15) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jáwọ́ nínú àwọn ìrònú àti ìwà wa àtijọ́, tá a sì para dà tàbí yí pa dà, a máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. A máa rí bí èyí ṣe jẹ́ òótọ́ nínú àpilẹ̀kọ́ tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 18 Wo àpẹẹrẹ tó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà February 1, 1994, ojú ìwé 10, ìpínrọ̀ 7.