Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣègbọràn sí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn tí Jèhófà Yàn

Ṣègbọràn sí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn tí Jèhófà Yàn

“Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín.”—HÉB. 13:17.

1, 2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé Jèhófà fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn?

JÈHÓFÀ fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn. (Ìsík. 34:11-14) Àfiwé yẹn ṣe pàtàkì nítorí pé ó jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ agbo ẹran máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀ tí wọ́n ò fi ní kú. Ó máa ń mú wọn lọ sí pápá oko àti ibi tí omi wà. (Sm. 23:1, 2) Ó máa ń ṣọ́ wọn tọ̀sán tòru. (Lúùkù 2:8) Ó ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ẹranko tó lè pa wọ́n jẹ. (1 Sám. 17:34, 35) Ó sì máa ń gbé èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sọ́wọ́. (Aísá. 40:11) Ó máa ń wá àwọn àgùntàn tó ṣáko lọ, ó sì ń tọ́jú àwọn tó fara pa.—Ìsík. 34:16.

2 Nítorí pé àwọn èèyàn Jèhófà láyé àtijọ́ ń gbé láàárín àwọn àgbẹ̀ àtàwọn darandaran, wọ́n tètè lóye ìdí pàtàkì tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́. Wọ́n mọ̀ pé àwọn àgùntàn ń fẹ́ àbójútó àti àkíyèsí tó dáa kí wọ́n lè dàgbà, kí wọ́n sì pọ̀ dáadáa. Ohun kan náà làwọn èèyàn nílò tó bá kan àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. (Máàkù 6:34) Tí kò bá sí àbójútó àti ìtọ́sọ́nà tó dáa, ìyà máa ń jẹ àwọn èèyàn. Ńṣe ni wọ́n tètè máa ń kó sínú ìdẹwò tí wọ́n á sì yà kúrò ní ọ̀nà títọ́, bí ìgbà tí “àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn” bá fọ́n ká. (1 Ọba 22:17) Àmọ́, Jèhófà máa ń fìfẹ́ pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Lóde òní, a lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú bí Bíbélì ṣe fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn. Jèhófà ṣì ń pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni bí àgùntàn nílò. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀ lóde òní àti bó ṣe ń pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn. A tún máa ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó yẹ káwọn àgùntàn náà máa ṣe bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn.

OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN ÀTÀTÀ FÚN WA NÍ ÀWỌN OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN NÍNÚ ÌJỌ

4. Ipa wo ni Jésù ń kó nínú pípèsè ohun táwọn àgùntàn Jèhófà nílò?

4 Jèhófà ti yan Jésù ṣe Orí ìjọ Kristẹni. (Éfé. 1:22, 23) Jésù tó jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà,” fi ohun tó wu Bàbá rẹ̀ hàn wá. Ó tún jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ àti ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ ṣe. Kódà, Jésù ‘fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.’ (Jòh. 10:11, 15) Ẹ wo ìbùkún tí ẹbọ ìràpadà Kristi jẹ́ fún aráyé! (Mát. 20:28) Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ Jèhófà ni pé, “kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú [Jésù]” má pa run, ṣùgbọ́n kí ó “ní ìyè àìnípẹ̀kun”!—Jòh. 3:16.

5, 6. (a) Àwọn wo ni Jésù ti yàn láti máa bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀? Kí ló ní káwọn àgùntàn ṣe kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ìṣètò yìí? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń fẹ́ láti máa ṣègbọràn sáwọn alàgbà ìjọ?

5 Báwo ni àwọn àgùntàn ṣe ń fetí sí Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà, Jésù Kristi? Jésù sọ pé: “Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.” (Jòh. 10:27) Ohun tó túmọ̀ sí láti máa fetí sí ohùn Olùṣọ́ àgùntàn Àtàtà ni pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nínú ohun gbogbo. Èyí kan ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó yàn sínú ìjọ Ọlọ́run. Jésù sọ pé àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á máa bá iṣẹ́ tí òun ti bẹ̀rẹ̀ náà nìṣó. Wọ́n á máa ‘kọ́ àwọn àgùntàn kéékèèké ti Jésù,’ wọ́n á sì ‘máa bọ́ wọn.’ (Mát. 28:20; ka Jòhánù 21:15-17.) Bí ìhìn rere ṣe ń tàn kálẹ̀ tí iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń pọ̀ sí i, Jésù ṣètò àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn láti máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ìjọ.—Éfé. 4:11, 12.

6 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn alábòójútó ìjọ Éfésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sọ̀rọ̀, ó sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ti yàn wọ́n ṣe alábòójútó “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:28) Bí ọ̀ràn àwọn alábòójútó tòde òní náà ṣe rí nìyẹn, nítorí ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ mí sí la fi yàn wọ́n. Torí náà, tá a bá ń ṣègbọràn sí àwọn alábòójútó nínú ìjọ, à ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti Jésù, àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn ńlá náà. (Lúùkù 10:16) Ó dájú pé èyí ló yẹ kó jẹ́ ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń fẹ́ láti máa tẹrí bá fún àwọn alàgbà. Àmọ́, àwọn ohun míì tún wà tó mú kí irú ìtẹríba bẹ́ẹ̀ bọ́gbọ́n mu.

7. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?

7 Nígbà táwọn alàgbà bá ń tọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ sọ́nà, wọ́n máa ń fún wọn ní ìṣírí àti ìmọ̀ràn tó wá látinú Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn ìlànà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Ohun tí wọ́n ní lọ́kàn tí wọ́n fi ń fúnni nírú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ kì í ṣe láti máa pàṣẹ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa bí wọ́n ṣe máa lo ìgbésí ayé wọn. (2 Kọ́r. 1:24) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ láti fún àwọn Kristẹni bíi tiwọn ní ìlànà Ìwé Mímọ́ tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa àtèyí tó máa mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ kí nǹkan sì máa lọ létòlétò. (1 Kọ́r. 14:33, 40) Àwọn alàgbà “ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn” wa ní ti pé wọ́n fẹ́ láti ran ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Nítorí náà, wọ́n kì í jáfara láti ṣèrànwọ́ bí wọ́n bá rí i pé arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan fẹ́ “ṣi ẹsẹ̀ gbé” tàbí ó ti ṣì í gbé. (Gál. 6:1, 2; Júúdà 22) Ǹjẹ́ kò yẹ ká torí àwọn ìdí yìí “jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú”?—Ka Hébérù 13:17.

8. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe máa ń dáàbò bo agbo Ọlọ́run?

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tóun náà jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ Ọlọ́run sọ fún àwọn ará ní ìlú Kólósè pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kól. 2:8) Ìkìlọ̀ yìí jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì mìíràn tó fi yẹ ká máa fiyè sí ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ táwọn alàgbà ń fún wa. Àwọn alàgbà ń dáàbò bò agbo Ọlọ́run ní ti pé bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ba ìgbàgbọ́ àwọn ará jẹ́, àwọn alàgbà tètè máa ń sọ fún wọn. Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ nípa “àwọn wòlíì èké” àti “àwọn olùkọ́ èké” tí wọ́n á fẹ́ láti “ré àwọn ọkàn tí kò dúró sójú kan lọ” láti hùwà tí kò tọ́. (2 Pét. 2:1, 14) Àwọn alàgbà tòde òní gbọ́dọ̀ fúnni ní irú àwọn ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá yẹ. Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ ni wọ́n, wọ́n sì ní ìrírí nípa ìgbésí ayé. Yàtọ̀ síyẹn, ká tó yàn wọ́n, wọ́n ti fi hàn pé Ìwé Mímọ́ yé wọn dáadáa àti pé wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni ní ẹ̀kọ́ afúnni-nílera. (1 Tím. 3:2; Títù 1:9) Nítorí pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n ń ṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí wọ́n sì ń lo ọgbọ́n tó wá látinú Bíbélì, wọ́n ń darí agbo lọ́nà tó jáfáfá.

Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń dáàbò bo agbo ẹran rẹ̀ ni àwọn alàgbà ṣe ń dáàbò bo àwọn àgùntàn tó wà níkàáwọ́ wọn (Wo ìpínrọ̀ 8)

OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN ÀTÀTÀ Ń BỌ́ ÀWỌN ÀGÙNTÀN Ó SÌ Ń DÁÀBÒ BÒ WỌ́N

9. Báwo ni Jésù ṣe ń darí ìjọ Kristẹni lónìí tó sì ń bọ́ ọ?

9 Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí fún gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Ó ń tipasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa pèsè ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà míì ètò Ọlọ́run máa ń fún àwọn alàgbà ìjọ ní ìtọ́sọ́nà, bóyá nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí ìtọ́ni táwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń fúnni. Nírú àwọn ọ̀nà yẹn làwọn àgùntàn gbà ń rí ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere.

10. Kí ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ gbọ́dọ̀ ṣe nípa àwọn tó ṣáko lọ kúrò nínú agbo?

10 Iṣẹ́ àwọn alábòójútó ni láti dáàbò bo ìlera tẹ̀mí àwọn ará ìjọ, kí wọ́n máa tọ́jú rẹ̀, kí wọ́n sì máa bójú tó o, pàápàá ìlera àwọn tó ti ṣera wọn léṣe nípa tẹ̀mí tàbí àwọn tí wọ́n ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. (Ka Jákọ́bù 5:14,  15.) Àwọn kan lára wọn lè ti ṣáko lọ kúrò nínú agbo kí wọ́n sì ti ṣíwọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Kristẹni. Tí irú èyí bá ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ kò yẹ kí alàgbà kan tó nífẹ̀ẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti wá àwọn àgùntàn tó ti sọ nù rí kó sì rọ̀ wọ́n láti pa dà sínú agbo, ìyẹn sínú ìjọ? Ó dájú pé á ṣe bẹ́ẹ̀! Jésù ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.”—Mát. 18:12-14.

IRÚ OJÚ WO LÓ YẸ KÁ MÁA FI WO ÀṢÌṢE ÀWỌN OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN NÍNÚ ÌJỌ?

11. Kí nìdí tó fi ṣòro fún àwọn kan láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn alàgbà?

11 Olùṣọ́ Àgùntàn pípé ni Jèhófà àti Jésù. Àmọ́ èèyàn aláìpé ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n gbéṣẹ́ lé lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa bójú tó ìjọ. Òtítọ́ pọ́ńbélé yìí lè mú kó ṣòro fún àwọn kan láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn alàgbà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń sọ pé: ‘Èèyàn aláìpé bíi tiwa ni wọ́n. Kí ló dé tá a ó fi máa fetí sí ìmọ̀ràn wọn?’ Òótọ́ ni pé aláìpé ni àwọn alàgbà. Àmọ́, ó yẹ ká máa fojú tó tọ́ wo àṣìṣe àti kùdìẹ̀-kudiẹ wọn.

12, 13. (a) Kí la lè sọ nípa àṣìṣe àwọn kan tí Jèhófà ti lò ní ipò àbójútó? (b) Kí nìdí tí àṣìṣe àwọn ọkùnrin tó wà nípò abójútó fi wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì?

12 Ìwé Mímọ́ sọ kedere pé àwọn èèyàn tí Jèhófà lò nígbà àtijọ́ láti darí àwọn èèyàn rẹ̀ ní àṣìṣe tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fòróró yan Dáfídì láti jẹ́ ọba àti aṣáájú Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, ó jẹ́ kí ìdẹwò borí òun, ó sì jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà àti ìpànìyàn. (2 Sám. 12:7-9) Àpẹẹrẹ míì ni ti àpọ́sítélì Pétérù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbé iṣẹ́ ńlá lé e lọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ó ṣe àwọn àṣìṣe ńlá. (Mát. 16:18, 19; Jòh. 13:38; 18:27; Gál. 2:11-14) Kò sí èèyàn kankan láti ìgbà Ádámù àti Éfà tó jẹ́ ẹni pípé, àyàfi Jésù.

13 Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ káwọn tó kọ Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ àṣìṣe àwọn ọkùnrin tó yanṣẹ́ fún? Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí Ọlọ́run fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ fi hàn wá pé òun lè lo àwọn ọkùnrin aláìpé láti darí àwọn èèyàn òun. Ká sòótọ́, ìgbà gbogbo ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, kò yẹ ká máa fi àìpé àwọn tó ń múpò iwájú láàárín wa lónìí kẹ́wọ́ láti máa kùn sí wọ́n tàbí ká máa ṣàìgbọràn sí àṣẹ wọn. Jèhófà fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn arákùnrin yìí ká sì máa ṣègbọràn sí wọn.—Ka Ẹ́kísódù 16:2, 8.

14, 15. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ láyé àtijọ́?

14 Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń múpò iwájú láàárín wa. Ronú nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ láwọn ìgbà tí nǹkan le láyé àtijọ́. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, ipasẹ̀ Mósè àti Áárónì ni Ọlọ́run gbà ń pàṣẹ fún wọn. Kí wọ́n tó lè yè bọ́ nínú ìyọnu kẹwàá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn pé kí wọ́n se àkànṣe oúnjẹ, kí wọ́n sì fi lára ẹ̀jẹ̀ àgùntàn tí wọ́n pa wọ́n àwọn òpó ilẹ̀kùn àti òkè ẹnu ọ̀nà ilé wọn. Ṣé wọ́n gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tó sọ ìtọ́ni náà fún wọn ni? Rárá o, ńṣe ni wọ́n fetí sí àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì, tí àwọn náà gba àwọn ìtọ́ni pàtó látọ̀dọ̀ Mósè. (Ẹ́kís. 12:1-7, 21-23, 29) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Mósè àtàwọn àgbà ọkùnrin ló gba àwọn ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Jèhófà, tí wọ́n sì sọ wọ́n fún àwọn èèyàn rẹ̀. Lóde òní, àwọn alàgbà nínú ìjọ ń kó ipa pàtàkì tó jọ èyí.

15 Ó ṣeé ṣe kó o rántí àwọn ìgbà kan nínú ìtàn Bíbélì tí Jèhófà pèsè ìtọ́ni agbẹ̀mílà nípasẹ̀ àwọn èèyàn tàbí àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ aṣojú rẹ̀. Ní gbogbo ìgbà yẹn, Ọlọ́run rí i pé ó dára kí ẹnì kan ṣojú fún òun. Àwọn ońṣẹ́ náà sọ̀rọ̀ ní orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì sọ ohun táwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣe kí wọ́n lè yè bọ́ nínú àjálù. Ṣé a ò rò pé Jèhófà lè ṣe ohun tó jọ èyí nígbà Amágẹ́dọ́nì? Ohun tá a retí lóde òní ni pé kí àwọn alàgbà tá a fún ní iṣẹ́ aṣojú Jèhófà tàbí ti ètò rẹ̀ máa ṣọ́ra gan-an kí wọ́n má ṣe lo àṣẹ tá a gbé lé wọn lọ́wọ́ nílòkulò.

“AGBO KAN, OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN KAN”

16. “Ọ̀rọ̀” wo ló yẹ ká máa fetí sí?

16 Àwọn èèyàn Jèhófà para pọ̀ jẹ́ “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan,” ìyẹn Jésù Kristi. (Jòh. 10:16) Jésù sọ pé òun máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Nítorí pé Ọba ni Jésù lọ́run, ìkáwọ́ rẹ̀ ni gbogbo nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ wà títí tá á fi mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ayé Sátánì yìí. Ká lè wà ní ìṣọ̀kan láìséwu nínú agbo Ọlọ́run, a ní láti fetí sí ‘ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn wa,’ tó ń sọ ọ̀nà tó yẹ ká tọ̀ fún wa. Ara “ọ̀rọ̀” náà ni ohun tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń sọ nípasẹ̀ Bíbélì àti ohun tí Jèhófà àti Jésù ń sọ nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n ti yàn sípò olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ.—Ka Aísáyà 30:21; Ìṣípayá 3:22.

Àwọn alàgbà máa ń dáàbò àwọn ìdílé olóbìí kan lọ́wọ́ ẹgbẹ́ búburú (Wo ìpínrọ̀ 17, 18)

17, 18. (a) Ewu wo ni àwọn àgùntàn Ọlọ́run dojú kọ, àmọ́ kí ló fi wá lọ́kàn balẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Bíbélì sọ pé Sátánì ń rìn káàkiri “bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8) Bí ẹranko ẹhànnà tí ebi ń pa ni Sátánì ṣe ń dọdẹ àwọn àgùntàn Ọlọ́run, ó ń wá àǹfààní láti mú àwọn tí kò kíyè sára tàbí àwọn tó ṣáko lọ. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn tá a jọ wà nínú agbo Ọlọ́run àti “olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó ọkàn [wa].” (1 Pét. 2:25) Ìṣípayá 7:17 sọ nípa àwọn tó máa la ìpọ́njú ńlá já pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn . . . náà [Jésù], yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” Ǹjẹ́ ìlérí kan wà tó dára ju èyí lọ?

18 Nígbà tá a ti jíròrò ipa pàtàkì tí àwọn alàgbà ń kó ní ipò olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, a ní láti bi ara wa pé, Báwo ni àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò yìí ṣe máa rí i dájú pé àwọn ń hùwà sáwọn àgùntàn Jésù lọ́nà tó dáa? A óò jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.