ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ December 2013

Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe tí ìgbàgbọ́ wa ò fi ní di ahẹrẹpẹ. Ó tún sọ ìgbà tó yẹ ká máa ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa ṣe é.

Jèhófà Dáàbò Bò Wọ́n Lábẹ́ Òjìji Àwọn Òkè Ńlá | Ìkẹ́kọ̀ọ́

Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Jámánì ṣe ń rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbà lásìkò ìjọba Násì? Ewu wo làwọn ará náà kojú?

Ẹ Má Ṣe “Tètè Mì Kúrò Nínú Ìmọnúúrò Yín”!

Àwọn ìkìlọ̀ tó bọ́ sákòókò wo ló wà nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà? Kí ni kò ní jẹ́ kí wọ́n tàn wá jẹ?

Ṣé Wàá Yááfì Àwọn Nǹkan Torí Ìjọba Ọlọ́run?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè lo owó, okun àti ẹ̀bùn àbínibí wa láti ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ó dáa, wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí.

‘Èyí Yóò Jẹ́ Ìrántí Fún Yín’

Kí lohun táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa Ìrékọjá? Kí ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa túmọ̀ sí fún gbogbo wa?

“Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”

Báwo la ṣe máa ń mọ ọjọ́ tí Ìrántí Ikú Kristi bọ́ sí? Kí ni búrẹ́dì àti wáìnì tá a máa ń lò ṣàpẹẹrẹ?

Bí O Ṣe Lè Fara Da Ikú Ọkọ Tàbí Aya Rẹ

Ikú ọkọ tàbí aya ẹni máa ń fa ìrora ńlá tí kì í tán bọ̀rọ̀. Wo bí àjíǹde tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ká máa retí ṣe jẹ́ ohun ìtùnú.

Atọ́ka àwọn àkòrí inú Ilé Ìṣọ́ Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ọdún 2013

Wo àtọ́ká àwọn àkòrí inú Ilé Ìṣọ́ Ẹ̀dà Tó Wà Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ táa tẹ̀ lọ́dún 2013.