Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Má Ṣe “Tètè Mì Kúrò Nínú Ìmọnúúrò Yín”!

Ẹ Má Ṣe “Tètè Mì Kúrò Nínú Ìmọnúúrò Yín”!

“Ẹ̀yin ará, . . . àwa béèrè lọ́wọ́ yín kí ẹ má ṣe tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò yín.”—2 TẸS. 2:1, 2.

1, 2. Kí nìdí tí ẹ̀tàn fi gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ lóde òní? Ọ̀nà wo ni ẹ̀tàn lè gbà wá? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ONÍRÚURÚ ẹ̀tàn ló wọ́pọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Àmọ́ kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu. Bíbélì mú kó ṣe kedere pé ògbólógbòó ẹlẹ̀tàn ni Sátánì Èṣù, òun sì ni olùṣàkóso ètò àwọn nǹkan yìí. (1 Tím. 2:14; 1 Jòh. 5:19) Bí a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí, bẹ́ẹ̀ ni inú túbọ̀ ń bí Sátánì torí pé “sáà àkókò kúkúrú” ló kù fún un. (Ìṣí. 12:12) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu bí àwọn tí Èṣù ń darí bá túbọ̀ ń tan irọ́ kálẹ̀ pàápàá jù lọ nípa àwọn tó ń gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ.

2 Ìgbà míì wà tí wọ́n máa ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń ṣini lọ́nà àti ògidì irọ́ sáfẹ́fẹ́ nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà àti àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Wọ́n máa ń tan àwọn ọ̀rọ̀ tí kò jóòótọ́ kálẹ̀ nínú àwọn àkòrí iwájú ìwé ìròyìn, nínú àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti nínú àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Èyí máa ń mú kí ọ̀rọ̀ dà rú mọ́ àwọn èèyàn kan lójú, wọ́n á sì gba àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́ láìwádìí.

3. Kí ló lè mú ká borí ẹ̀tàn?

3 A dúpẹ́ pé a ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó “ṣàǹfààní . . . fún mímú àwọn nǹkan tọ́,” èyí tó ń jẹ́ ká lè borí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí ọ̀tá wa ń lò láti kó ìrẹ̀wẹ̀sí bá wa. (2 Tím. 3:16) Ó ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Tẹsalóníkà ní ọ̀rúndún kìíní. Ó sọ pé wọ́n ti ṣi àwọn kan lára wọn lọ́nà, wọ́n sì gba ohun tí kì í ṣe òótọ́ gbọ́. Ó gbà wọ́n níyànjú pé “kí [wọ́n] má ṣe tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò [wọn].” (2 Tẹs. 2:1, 2) Àwọn nǹkan wo la lè rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n yìí, báwo la sì ṣe lè fi àwọn ìmọ̀ràn náà sílò?

ÀWỌN ÌKÌLỌ̀ TÓ BỌ́ SÁKÒÓKÒ

4. Kí ló mú kí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà wà lójúfò nípa “ọjọ́ Jèhófà” tó ń bọ̀? Kí ló ń mú kí àwa náà wà lójúfò?

4 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà, ó sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́ Jèhófà” tó ń bọ̀. Kò fẹ́ kí àwọn ará tó wà níbẹ̀ wà nínú òkùnkùn kí ọjọ́ náà má bàa dé bá wọn lójijì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rọ̀ wọ́n pé gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ìmọ́lẹ̀” kí wọ́n ‘wà lójúfò, kí wọ́n sì pa agbára ìmòye wọn mọ́.’ (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:1-6.) Lónìí, à ń retí ìgbà tí Ọlọ́run máa pa Bábílónì Ńlá, ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé run. Èyí ló máa jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ńlá Jèhófà. A dúpẹ́ pé a ti ní òye tó pọ̀ sí i nípa bí ète Jèhófà ṣe ń ní ìmúṣẹ. Bákan náà, a tún ń rí àwọn ìránnilétí tó bá àkókò mu gbà déédéé nínú ìjọ. Àwọn ìránnilétí yìí ló ń mú ká lè máa pa agbára ìmòye wa mọ́. Tá a bá ń fiyè sí àwọn ìkìlọ̀ tá à ń gbọ́ léraléra yìí, wọ́n máa mú ká túbọ̀ dúró lórí ìpinnu wa pé a ó máa ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” fún Ọlọ́run “pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò” wa.—Róòmù 12:1.

Pọ́ọ̀lù kọ àwọn lẹ́tà tó fún àwọn Kristẹni ní ìkìlọ̀ tó bọ́ sákòókò (Wo ìpínrọ̀ 4 àti 5)

5, 6. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà kejì tó kọ sí àwọn ará ní Tẹsalóníkà? (b) Kí ni Ọlọ́run máa tó lo Jésù láti ṣe? Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

5 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà tó fi kọ lẹ́tà kejì sí wọn. Nínú lẹ́tà kejì yẹn ló ti sọ̀rọ̀ nípa ìpọ́njú tó ń bọ̀ nígbà tí Jésù Olúwa máa mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ “sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” (2 Tẹs. 1:6-8) Níbi tí a wá mọ̀ sí orí kejì nínú lẹ́tà náà báyìí ló ti jẹ́ ká rí i pé àwọn kan wà nínú ìjọ tí a ti ‘ru sókè’ nípa ọjọ́ Jèhófà débi tí wọ́n fi gbà gbọ́ pé dídé ọjọ́ náà ti kù sí dẹ̀dẹ̀ nígbà yẹn. (Ka 2 Tẹsalóníkà 2:1, 2.) Ìwọ̀nba ni òye tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní yẹn ní nípa bí Jèhófà ṣe ń mú ète rẹ̀ ṣẹ. Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí nínú lẹ́tà tó kọ lẹ́yìn ìgbà yẹn pé, ní ti àsọtẹ́lẹ̀: “Àwa ní ìmọ̀ lápá kan, a sì ń sọ tẹ́lẹ̀ lápá kan; ṣùgbọ́n nígbà tí èyíinì tí ó pé pérépéré bá dé, èyíinì tí ó jẹ́ ti apá kan ni a óò mú wá sí òpin.” (1 Kọ́r. 13:9, 10) Àmọ́, àwọn ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Pétérù àtàwọn arákùnrin adúróṣinṣin míì tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró nígbà yẹn láti kọ sílẹ̀ lè mú kí wọ́n gbára dì kí ìgbàgbọ́ wọ́n má sì yẹ̀.

6 Kí àwọn ará náà lè ní èrò tó tọ́, Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti ṣàlàyé pé ṣáájú ọjọ́ Jèhófà, ìpẹ̀yìndà ńlá máa wà àti pé “ọkùnrin oníwà àìlófin” yóò fara hàn. * Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà, Jésù Olúwa máa “sọ” gbogbo àwọn tí a ti tàn jẹ “di asán.” Àpọ́sítélì náà wá sọ ìdí náà gan-an tí ìdájọ́ yìí fi máa wá sórí wọn; ó jẹ́ nítorí pé “wọn kò tẹ́wọ́ gba ìfẹ́ òtítọ́.” (2 Tẹs. 2:3, 8-10) Torí náà, ó dára ká bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó? Ǹjẹ́ mò ń mọ òye tuntun tá a ní bí ètò Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ ẹ́ jáde fún ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé nínú ìwé ìròyìn yìí àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tó ń ṣàlàyé Bíbélì?’

FI ỌGBỌ́N YAN ÀWỌN TÓ Ò Ń BÁ KẸ́GBẸ́

7, 8. (a) Ewu wo ló dojú kọ àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Kí ló léwu gan-an fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní?

7 Ó dájú pé yàtọ̀ sí ewu látọ̀dọ̀ àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn ẹ̀kọ́ wọn, àwọn Kristẹni á máa dojú kọ àwọn ewu mìíràn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé “ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” Ó tún wá ṣàlàyé pé “nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tím. 6:10) “Àwọn iṣẹ́ ti ara” náà wà lára àwọn ewu tó dájú pé àwọn Kristẹni á máa dojú kọ.—Gál. 5:19-21.

8 O lè wá rí ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ní láti kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, tó pè ní “èké àpọ́sítélì” níbòmíì, léwu fún wọn gan-an. Àwọn èèyàn tó ń “sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn” náà wà lára wọn. (2 Kọ́r. 11:4, 13; Ìṣe 20:30) Nígbà tó yá, Jésù gbóríyìn fún ìjọ tó wà ní Éfésù torí pé wọn kò lè “gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra.” Àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù yẹn “dán” àwọn èèyàn yìí “wò,” wọ́n sì rí i pé wọ́n jẹ́ èké àpọ́sítélì, kódà, òpùrọ́ ni wọ́n. (Ìṣí. 2:2) Ó bá a mu nígbà náà pé nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará ní Tẹsalóníkà, ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Wàyí o, a ń pa àṣẹ ìtọ́ni fún yín, ẹ̀yin ará, ní orúkọ Jésù Kristi Olúwa, pé kí ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ olúkúlùkù arákùnrin tí ń rìn ségesège.” Lẹ́yìn náà ló dìídì mẹ́nu kan àwọn Kristẹni tí wọ́n “kò . . . fẹ́ ṣiṣẹ́.” (2 Tẹs. 3:6, 10) Bí Pọ́ọ̀lù bá sọ pé àwọn yìí ń rìn ségesège, mélòómélòó wá ni àwọn tí wọ́n yà bàrà kúrò nínú òtítọ́ tí wọ́n sì di apẹ̀yìndà! Láìsí àní-àní, ó léwu gan-an fáwọn Kristẹni ìgbà yẹn láti máa bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́, ó sì yẹ kí wọ́n yẹra fún wọn. Ohun tó yẹ kí àwa náà ṣe lóde òní nìyẹn.—Òwe 13:20.

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra bí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í méfò tàbí tó ń ṣe àríwísí?

9 A ti ń sún mọ́ ìgbà tí ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀, òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí sì ti sún mọ́lé. Torí náà, àwọn ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní wá túbọ̀ ṣe pàtàkì. Ó dájú pé a kò ní fẹ́ láti “tàsé ète” inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ká wá pàdánù ìwàláàyè títí láé tó ṣèlérí pé a máa gbádùn yálà lókè ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé. (2 Kọ́r. 6:1) A ní láti ṣọ́ra gidigidi tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan tó ń wá sí àwọn ìpàdé wa ń dọ́gbọ́n mú wa wọnú àwọn ìjíròrò táá jẹ́ ká máa méfò tàbí ká máa ṣe àríwísí.—2 Tẹs. 3:13-15.

‘Ẹ DI ÀWỌN ÀṢÀ ÀFILÉNILỌ́WỌ́ MÚ LÁÌJÁWỌ́’

10. Àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́ wo ni Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé kí wọ́n dì mú?

10 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà pé kí wọ́n “dúró gbọn-in gbọn-in” kí wọ́n sì rọ̀ mọ́ àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́. (Ka 2 Tẹsalóníkà 2:15.) Kí ni “àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́” tí wọ́n ti fi kọ́ wọn? Ó dájú pé kì í ṣe àwọn àṣà tó wà nínú ìsìn èké, èyí tí wọ́n fi ń kọ́ni bíi pé wọ́n níye lórí ju ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tí òun àtàwọn míì gbà lọ́wọ́ Jésù àti àwọn ohun tí Ọlọ́run mú kí òun alára sọ fún wọn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ yìí ló wá di apá kan Ìwé Mímọ́ tó ní ìmísí Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì. Kí nìdí? Ó sọ nípa wọn pé, “nínú ohun gbogbo ẹ ní mi lọ́kàn, ẹ sì ń di àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́ mú ṣinṣin gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” (1 Kọ́r. 11:2) Irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ wá láti orísun tó ṣeé gbára lé, wọ́n sì ṣeé fọkàn tán dáadáa.

11. Báwo ni àwọn kan ṣe lè di ẹni tí a tàn jẹ?

11 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Hébérù, ó pe àfiyèsí wọn sí ọ̀nà méjì tí Kristẹni kan lè gbà di ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ mọ́ tí kò sì dúró gbọn-in gbọn-in. (Ka Hébérù 2:1; 3:12.) Ó mẹ́nu ba ‘sísú lọ’ àti “lílọ kúrò.” Bí àpẹẹrẹ, bí omi bá ń gbé ọkọ̀ kan lọ kúrò ní etídò, èèyàn lè máà kọ́kọ́ mọ̀. Torí pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ láá máa jìnnà sí etídò. Àmọ́, bí ẹnì kan bá ti ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kúrò ní etídò, a jẹ́ pé ọwọ́ ara rẹ̀ ló fi mú kó bọ́ sí agbami. Bíi ti àwọn ọkọ̀ ojú omi méjèèjì yìí, àwọn kan lè má mọ̀ tí wọ́n á fi tàn wọ́n jẹ. Àwọn míì sì lè fàyè gba ẹ̀tàn, tí wọn kò sì ní ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú òtítọ́ mọ́.

12. Àwọn ìgbòkègbodò òde òní wo ló lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́?

12 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni kan ní Tẹsalóníkà nìyẹn. Lóde òní ńkọ́? Àwọn nǹkan tó ń fi àkókò ṣòfò pọ̀ rẹpẹtẹ. Ronú nípa iye wákàtí táwọn èèyàn ń lò láti kàn sáwọn míì nídìí ìkànnì àjọlò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, láti ka lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ kí wọ́n sì tún fèsì, láti kópa nínú eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, tàbí kí wọ́n lè rí i pé àwọn mọ gbogbo ohun tó ń lọ lágbo eré ìdárayá. Èyíkéyìí nínú àwọn ìgbòkègbodò yìí lè fa ìpínyà ọkàn fún Kristẹni kan kó sì dín ìtara rẹ̀ kù. Kí ló máa wá jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ó lè dẹni tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbàdúrà látọkànwá mọ́, tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ìdákúrekú, tí kì í lọ sípàdé déédéé, tó sì ń lọ sóde ẹ̀rí lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n. Kí la lè ṣe tá ò fi ní jẹ́ káwọn nǹkan wọ̀nyí mú ká tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò wa?

OHUN TÍ KÒ NÍ JẸ́ KÁ TÈTÈ MÌ KÚRÒ NÍNÚ ÌMỌNÚÚRÒ WA

13. Ìwà wo ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn á máa hù? Kí ni kò ní jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa yingin?

13 Ohun kan tá ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. Ó sì yẹ ká mọ aburú tó wà nínú kéèyàn máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó kọ̀ láti gbà bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé nípa àkókò tá à ń gbé yìí pé: “Àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’” (2 Pét. 3:3, 4) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ibi tí ọ̀rọ̀ ayé yìí dé, ìyẹn á sì jẹ́ ká wà lójúfò pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. Ó pẹ́ tí ìpẹ̀yìndà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ ti fara hàn, ó sì wà títí dòní. “Ọkùnrin oníwà àìlófin” ṣì wà síbẹ̀, ó sì ń ta ko àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Látàrí èyí, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò, ká má ṣe gbàgbé pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé.—Sef. 1:7.

Tá a bá ń múra sílẹ̀ dáadáa fún iṣẹ́ ìwàásù tá a sì ń kópa nínú rẹ̀, a kò ní tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò wa (Wo ìpínrọ̀ 14 àti 15)

14. Tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, báwo ló ṣe lè jẹ́ ààbò fún wa?

14 Ìrírí ti fi hàn pé ọ̀nà pàtàkì kan téèyàn fi lè wà lójúfò tí kò sì ní tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò rẹ̀ ni pé kó máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. Torí náà, nígbà tí Kristi Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn láti pa gbogbo ohun tí òun ti kọ́ wọn mọ́, ńṣe ló ń fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìmọ̀ràn tó máa dáàbò bò wọ́n. (Mát. 28:19, 20) Tá a bá máa ṣiṣẹ́ lórí ìtọ́ni tí Jésù fún wa yìí, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé o rò pé ńṣe ni àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà á wulẹ̀ máa wàásù tí wọ́n á sì máa kọ́ni lọ́nà gbà-máà-póò-rọ́wọ́-mì, bíi pé iṣẹ́ kan tí kò gbádùn mọ́ni lásán ni? Rántí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn. Ó ní: “Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí. Ẹ má ṣe fojú tín-ín-rín àwọn ìsọtẹ́lẹ̀.” (1 Tẹs. 5:19, 20) Ẹ sì wo bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn tá a sì tún fi ń kọ́ àwọn ẹlòmíì ṣe ń gbádùn mọ́ni tó!

15. Àwọn nǹkan tó lè ṣeni láǹfààní wo la lè jíròrò nígbà ìjọsìn ìdílé?

15 Ó dájú pé gbogbo wa la fẹ́ ran ìdílé wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti rí i pé ọ̀nà kan táwọn lè gbà ṣe èyí ni pé kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kún ohun tí wọ́n á máa jíròrò nígbà ìjọsìn ìdílé wọn. Ẹ lè rí i pé ó máa ṣe ìdílé yín láǹfààní tẹ́ ẹ bá jíròrò nípa bẹ́ ẹ ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tó fìfẹ́ hàn. Kí ni ọ̀rọ̀ yín máa dá lé tẹ́ ẹ bá pa dà lọ? Àwọn kókó ọ̀rọ̀ wo ló lè mú káwọn tẹ́ ẹ lọ bẹ̀ wò fẹ́ láti túbọ̀ gbọ́rọ̀ yín? Ìgbà wo ló dára jù lọ kẹ́ ẹ pa dà bẹ̀ wọ́n wò? Àwọn míì tún máa ń fi díẹ̀ lára àkókò tí wọ́n fi ń ṣe ìjọsìn ìdílé múra àwọn ìpàdé sílẹ̀, kí wọ́n lè mọ àwọn nǹkan tá a máa jíròrò níbẹ̀. Ṣé ìwọ náà lè túbọ̀ máa múra sílẹ̀ kó o lè máa kópa? Tó o bá ń kópa nínú ìpàdé, ó máa fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, kò sì ní jẹ́ kó o tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò rẹ. (Sm. 35:18) Ó dájú pé tá a bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé, a ò ní máa méfò, a ò sì ní máa ṣiyè méjì.

16. Kí lohun tí kò ní jẹ́ kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fẹ́ láti mì kúrò nínú agbára ìmọnúúrò wọn?

16 Tá a bá ronú lórí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀ látọdún yìí wá ní ti bó ṣe ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó máa jẹ́ ká mọyì èrè àgbàyanu tó ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú. Àwọn ẹni àmì òróró ní ìrètí láti dara pọ̀ mọ́ Kristi lókè ọ̀run. Ẹ sì wo bí èyí ṣe jẹ́ ohun ìwúrí fún wọn láti má ṣe mì kúrò nínú agbára ìmọnúúrò wọn! Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà bá ipò wọn mu. Ó ní: “Ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ẹ̀yin ará tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́, nítorí pé Ọlọ́run yàn yín . . . nípa fífi ẹ̀mí sọ yín di mímọ́ àti nípa ìgbàgbọ́ yín nínú òtítọ́.”—2 Tẹs. 2:13.

17. Kí ló fún ẹ níṣìírí nínú ọ̀rọ̀ inú 2 Tẹsalóníkà 3:1-5?

17 Àwọn tó ń fojú sọ́nà láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé náà gbọ́dọ̀ máa sapá kí wọ́n má bàa tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò wọn. Tó o bá ní ìrètí láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé, fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù fìfẹ́ kọ sí àwọn ẹni àmì òróró bíi tiẹ̀ ní Tẹsalóníkà sọ́kàn. (Ka 2 Tẹsalóníkà 3:1-5.) Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ tó fìfẹ́ hàn yẹn. Láìsí àní-àní, lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà fún wa ní àwọn ìkìlọ̀ pàtàkì nípa ìméfò tàbí àwọn èrò tí ń kọni lóminú. Bí àwa Kristẹni ṣe ń gbé ní àkókò tí òpin ti sún mọ́lé yìí, a mọrírì àwọn ìkìlọ̀ náà gidigidi.

^ ìpínrọ̀ 6 Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìṣe 20:29, 30, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé láti àárín ìjọ Kristẹni ni “àwọn ènìyàn yóò . . . dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” Ìtàn jẹ́rìí sí i pé nígbà tó yá, ẹgbẹ́ àlùfáà àti ti ọmọ ìjọ bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni, “ọkùnrin oníwà àìlófin” ti fara hàn. Òun la wá mọ̀ sí gbogbo àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì lápapọ̀.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1990, ojú ìwé 10 sí 14.