Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Èyí Yóò Jẹ́ Ìrántí Fún Yín’

‘Èyí Yóò Jẹ́ Ìrántí Fún Yín’

“Ọjọ́ yìí yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín, ẹ ó sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọyọ̀ fún Jèhófà.”—Ẹ́KÍS. 12:14.

1, 2. Ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbàanì wo ló yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni kà sí pàtàkì? Kí nìdí?

TÓ O bá ń ronú nípa àwọn ayẹyẹ tó ti wáyé rí, èwo ló tètè máa ń wá sí ẹ lọ́kàn? Ẹnì kan tó ti ṣègbéyàwó lè sọ pé: “Ayẹyẹ ìgbéyàwó mi ni.” Ní ti àwọn míì, ó lè jẹ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan wáyé, táwọn èèyàn sì ṣe ayẹyẹ rẹ̀ nílé lóko. Irú bí ìgbà tí orílẹ̀-èdè wọn gba òmìnira. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ nípa ayẹyẹ kan tó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè, tí àwọn èèyàn ti ń ṣe ìrántí rẹ̀ fún ohun tó ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn báyìí?

2 Irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ wà. Bíbélì pè é ní Ìrékọjá. Òun ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì fi máa ń ṣe àyájọ́ ìgbà tí Ọlọ́run dá wọn nídè kúrò lóko ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ó yẹ kó o ka ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn sí pàtàkì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó kan àwọn apá pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé rẹ. O lè máa ronú pé, ‘Lóòótọ́, àwọn Júù ń ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá, àmọ́ èmi kì í ṣe Júù. Kí wá nìdí tó fi yẹ kí n ka ayẹyẹ àwọn Júù sí pàtàkì?’ O lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ tó gba àròjinlẹ̀ náà, pé: “A ti fi Kristi ìrékọjá wa rúbọ.” (1 Kọ́r. 5:7) Ká lè lóye bí gbólóhùn yẹn ti ṣe pàtàkì tó, ó yẹ ká mọ̀ nípa Ìrékọjá àwọn Júù, ká sì jíròrò bó ṣe tan mọ́ àṣẹ kan tí Jésù pa fún gbogbo àwa Kristẹni.

KÍ NÌDÍ TÍ WỌ́N FI ṢE ÌRÉKỌJÁ?

3, 4. Kí ló ṣẹlẹ̀ tí wọ́n fi ṣe Ìrékọjá àkọ́kọ́?

3 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé tí wọn kì í ṣe Júù mọ díẹ̀ lára ohun tó fà á tí wọ́n fi ṣe ohun tá a lè pè ní Ìrékọjá àkọ́kọ́. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti kà nípa rẹ̀ nínú ìwé Ẹ́kísódù tó wà nínú Bíbélì, wọ́n lè ti gbọ́ ìtàn náà lẹ́nu ẹnì kan, tàbí kí wọ́n ti wo fíìmù kan tó dá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

4 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà lóko ẹrú fún ọ̀pọ̀ ọdún nílẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà rán Mósè àti Áárónì arákùnrin rẹ̀ sí Fáráò, pé kí wọ́n lọ sọ fún un pé kó dá àwọn èèyàn Òun sílẹ̀. Ọba Íjíbítì tó jẹ́ agbéraga yìí kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ, torí náà Jèhófà fi onírúurú ìyọnu tó ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́, kọ lu ilẹ̀ náà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ọlọ́run mú kí àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì kú. Ìyẹn ni ìyọnu kẹwàá, òun ló sì mú kí Fáráò dá wọn sílẹ̀.—Ẹ́kís. 1:11; 3:9, 10; 5:1, 2; 11:1, 5.

5. Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe ní ìmúrasílẹ̀ fún bí Ọlọ́run ṣe máa dá wọn sílẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 Àmọ́, kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó dá wọn sílẹ̀? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé lásìkò tí ọ̀sán àti òru gùn dọ́gba nígbà ìrúwé ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nínú oṣù táwọn Hébérù ń pè ní Ábíbù, tá a wá mọ̀ sí oṣù Nísàn nígbà tó yá. * Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ láti Nísàn 10, kí wọ́n bàa lè tẹ̀ lé ìtọ́ni tí òun máa fún wọn ní Nísàn 14. Nísàn 14 máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn bá wọ̀, torí pé ìrọ̀lẹ́ sí ìrọ̀lẹ́ ni àwọn Hébérù máa ń ka ọjọ́ wọn. Ní Nísàn 14, agbo ilé kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ pa akọ àgùntàn kan (tàbí ewúrẹ́) kí wọ́n sì fi díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wọ́n ara òpó ilẹ̀kùn méjèèjì àti àtẹ́rígbà ilé wọn. (Ẹ́kís. 12:3-7, 22, 23) Ìdílé náà á wá jẹ ẹran náà ní sísun pa pọ̀ pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewébẹ̀ díẹ̀. Áńgẹ́lì Ọlọ́run máa ré kọjá lórí ilẹ̀ náà á sì pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ Ọlọ́run máa dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣègbọràn, lẹ́yìn náà ni wọ́n tó lè lọ kúrò lómìnira.—Ẹ́kís. 12:8-13, 29-32.

6. Ọwọ́ wo ló yẹ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run tó gbé láyé lẹ́yìn ìgbà yẹn fi mú Ìrékọjá?

6 Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti máa rántí bí Ọlọ́run ṣe dá wọn nídè. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ọjọ́ yìí yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín, ẹ ó sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọyọ̀ fún Jèhófà jálẹ̀ ìran-ìran yín. Kí ẹ sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ayẹyẹ yẹn ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n á tún wá ṣe àjọyọ̀ ọlọ́jọ́ méje míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nísàn kẹrìnlá gangan ni ọjọ́ Ìrékọjá, a tún lè pe àpapọ̀ ọjọ́ mẹ́jọ tí àjọyọ̀ fi wáyé náà ní Ìrékọjá. (Ẹ́kís. 12:14-17; Lúùkù 22:1; Jòh. 18:28; 19:14) Ìrékọjá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àjọyọ̀ (tàbí “àwọn àjọ̀dún”) * tí Ọlọ́run ní kí àwọn Hébérù máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀ lọ́dọọdún.—2 Kíró. 8:13.

7. Kí ni Jésù dá sílẹ̀ nígbà Ìrékọjá tí wọ́n jọ ṣe kẹ́yìn?

7 Torí pé Júù tó wà lábẹ́ Òfin Mósè ni Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, àwọn náà ṣe Ìrékọjá tó máa ń wáyé lọ́dọọdún. (Mát. 26:17-19) Nígbà tí wọ́n jọ ṣe é kẹ́yìn, Jésù dá ohun tuntun kan sílẹ̀ tó fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa ṣe lọ́dọọdún látìgbà yẹn lọ, ìyẹn ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Àmọ́, ọjọ́ wo ló yẹ kí wọ́n máa ṣe é?

ỌJỌ́ WO LÓ YẸ KÍ OÚNJẸ ALẸ́ OLÚWA MÁA WÁYÉ?

8. Bá a ṣe ń ṣe àgbéyẹ̀wò Ìrékọjá àti Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ìbéèrè wo ló jẹ yọ?

8 Gbàrà tí Jésù parí Ìrékọjá tó ṣe kẹ́yìn ló dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, látàrí ìyẹn, a jẹ́ pé ọjọ́ kan náà tí wọ́n ṣe Ìrékọjá ni ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun náà wáyé. Àmọ́, o lè ti kíyè sí i pé ọjọ́ tí Ìrékọjá àwọn Júù máa ń bọ́ sí lórí àwọn kàlẹ́ńdà kan lóde òní lè fi ọjọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ yàtọ̀ sí ọjọ́ tá a máa ń ṣe ìrántí ikú Kristi. Kí ló fà á tó fi yàtọ̀? Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lára ohun tó fà á. Lẹ́yìn tí Mósè ti sọ fún “gbogbo ìjọ àpéjọ Ísírẹ́lì” pé kí wọ́n “pa” ọ̀dọ́ àgùntàn náà, ó sọ àsìkò náà gan-an ní Nísàn 14 tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.—Ka Ẹ́kísódù 12:5, 6.

9. Gẹ́gẹ́ bí Ẹ́kísódù 12:6 ṣe sọ, ìgbà wo ló yẹ kí wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá? (Tún wo àpótí náà,  “Ìgbà Wo Ni?”)

9 Ìwé kan tí wọ́n pè ní The Pentateuch and Haftorahs, ṣàlàyé pé ìwé Ẹ́kísódù 12:6 sọ pé kí wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn náà “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì náà.” Gbólóhùn yìí kan náà ni àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan lò. Ṣùgbọ́n àwọn ìtumọ̀ míì, títí kan Tanakh tó jẹ́ ìtumọ̀ àwọn Júù, túmọ̀ rẹ̀ sí “ní wíríwírí ọjọ́.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì sì sọ pé, “ní ọwọ́ alẹ́,” “ní wíríwírí ìrọ̀lẹ́,” tàbí “ní ọwọ́ ọjọ́rọ̀.” Torí náà, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀ àmọ́ tí ilẹ̀ kò tíì ṣú ni wọ́n gbọ́dọ̀ pa ọ̀dọ́ àgùntàn náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ Nísàn 14.

10. Ìgbà wo làwọn kan gbà pé wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn náà, àmọ́ ìbéèrè wo nìyẹn mú wá?

10 Nígbà tó yá, àwọn Júù kan rò pé ó ti ní láti gba ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó pa gbogbo ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n kó wá sí tẹ́ńpìlì. Torí náà, wọ́n gbà pé ìparí Nísàn 14 ni Ẹ́kísódù 12:6 ń tọ́ka sí, ìyẹn láàárín àkókò tí oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ (ní ọwọ́ ọjọ́rọ̀) àti ìgbà tí ọjọ́ yẹn parí lẹ́yìn tí oòrùn ti wọ̀. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ohun tó túmọ̀ sí nìyẹn, ìgbà wo wá ni wọ́n jẹ oúnjẹ Ìrékọjá? Ọ̀jọ̀gbọ́n Jonathan Klawans, tó jẹ́ ògbóǹtagí nínú ìtàn àwọn Júù ìgbàanì, sọ pé: “Ìgbà tí oòrùn bá wọ̀ ni ọjọ́ tuntun máa ń bẹ̀rẹ̀, torí náà ọjọ́ kẹrìnlá ni wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn náà, àmọ́ ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún gangan ni Ìrékọjá bẹ̀rẹ̀, tí wọ́n sì jẹ oúnjẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé Ẹ́kísódù kò ṣàlàyé rẹ̀ bẹ́ẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Ìwé àwọn Rábì . . . ò tilẹ̀ fìgbà kan sọ fún wa nípa bí wọ́n ṣe máa ń jẹ Seder [oúnjẹ Ìrékọjá] kí wọ́n tó pa Tẹ́ńpìlì run,” lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni.—Àwa la lo lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀.

11. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù ní ọjọ́ Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Kristẹni? (b) Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Sábáàtì Nísàn 15 ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ní “ọjọ́ ńlá”? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

11 Torí náà, ìdí wà fún wa láti béèrè pé, Ìrékọjá tó wáyé ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni wá ńkọ́? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ní Nísàn 13, bí ọjọ́ tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi “ẹran-ẹbọ ìrékọjá rúbọ” ti ń sún mọ́lé, Kristi sọ fún Pétérù àti Jòhánù pé: “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá sílẹ̀ fún wa láti jẹ.” (Lúùkù 22:7, 8) “Níkẹyìn . . . wákàtí náà dé” fún wọn láti jẹ oúnjẹ Ìrékọjá, lẹ́yìn tí oòrùn ti wọ̀ ní Nísàn 14, èyí tó bọ́ sí ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Thursday. Jésù jẹ oúnjẹ yẹn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, lẹ́yìn náà ló dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀. (Lúùkù 22:14, 15) Alẹ́ ọjọ́ yẹn ni wọ́n fàṣẹ ọba mú un tí wọ́n sì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Wọ́n kan Jésù mọ́gi nígbà tó ku díẹ̀ kí ọ̀sán pọ́n ní Nísàn 14, ó sì kú nígbà tí ọ̀sán ti pọ́n. (Jòh. 19:14) Torí náà, ọjọ́ kan náà tí wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá ni wọ́n fi “Kristi ìrékọjá wa rúbọ.” (1 Kọ́r. 5:7; 11:23; Mát. 26:2) Bí ọjọ́ àwọn Júù yẹn ti ń parí lọ, wọ́n sin Jésù, kí Nísàn 15 tó bẹ̀rẹ̀. *Léf. 23:5-7; Lúùkù 23:54.

ÌRÁNTÍ TÓ NÍ ÌTUMỌ̀ PÀTÀKÌ FÚN Ọ

12, 13. Ọ̀nà wo ni ayẹyẹ Ìrékọjá táwọn Júù ń ṣe gbà kan àwọn ọmọ wọn?

12 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká pa dà sórí Ìrékọjá tí wọ́n ṣe ní Íjíbítì. Mósè sọ pé lọ́jọ́ iwájú, kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe Ìrékọjá; ó ní kí wọ́n máa pa á mọ́ bí ìlànà “fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Lára ohun tó máa ń wáyé nígbà ayẹyẹ ọdọọdún náà ni pé àwọn ọmọ máa ń bi àwọn òbí wọn nípa ohun tí ayẹyẹ náà túmọ̀ sí. (Ka Ẹ́kísódù 12:24-27; Diu. 6:20-23) Nípa bẹ́ẹ̀, Ìrékọjá á wá jẹ́ ohun “ìrántí” tó nítumọ̀ fáwọn ọmọdé pàápàá.—Ẹ́kís. 12:14.

13 Láti ìran dé ìran ni àwọn baba á máa ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú ayẹyẹ náà fún àwọn ọmọ wọn. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ ni pé Jèhófà lè dáàbò bo àwọn tó ń sìn ín. Àwọn ọmọ á wá mọ̀ pé ẹni gidi ni Ọlọ́run àti pé kì í ṣe ọlọ́run kan tí kò ṣeé lóye. Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún, ó sì máa ń gbèjà wọn. Ó fi ẹ̀rí èyí hàn nígbà tó “mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá àwọn ará Íjíbítì” tó sì dáàbò bo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó dá ẹ̀mí àwọn àkọ́bí wọn sí.

14. Kí ni àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè fi ìtàn Ìrékọjá kọ́ àwọn ọmọ wọn?

14 Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni kì í ṣàlàyé ohun tí Ìrékọjá yẹn túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ wọn lọ́dọọdún. Àmọ́, ṣé o máa ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan náà pé Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀? Ṣé o máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe dá ọ lójú tó pé Jèhófà ṣì ni Aláàbò àwọn èèyàn rẹ̀ lóòótọ́? (Sm. 27:11; Aísá. 12:2) Ṣé o kàn máa ń sọ ìtàn náà fún àwọn ọmọ rẹ lọ́nà tí kò ta wọ́n jí ni àbí ńṣe lẹ jọ máa ń jíròrò rẹ̀ lọ́nà tó gbádùn mọ́ wọn? Rí i pé ẹ̀kọ́ yìí wà lára àwọn nǹkan tẹ́ ẹ jọ ń jíròrò kí ìdílé rẹ bàa lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.

Kí lo máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ tẹ́ ẹ bá ń jíròrò nípa Ìrékọjá? (Wo ìpínrọ̀ 14)

15, 16. Kí lẹ lè fi ìtàn Ìrékọjá àtàwọn ohun tá a kà nínú ìwé Ẹ́kísódù kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà?

15 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe lágbára láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nìkan la lè rí kọ́ nínú ìtàn Ìrékọjá. Ó tún dá wọn nídè, ní ti pé ó ‘mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì.’ Ronú nípa ohun tí ìyẹn ní nínú. Ọlọ́run fi ọwọ̀n àwọsánmà àti ti iná ṣamọ̀nà wọn. Wọ́n la àárín Òkun Pupa kọjá bí omi òkun ṣe dúró bí ògiri ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì. Lẹ́yìn tí wọ́n bọ́ sí òdì kejì odò, wọ́n rí i ti omi náà ya bo àwọn ọmọ ogun Íjíbítì mọ́lẹ̀. Ìgbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run dá nídè wá gbe ohùn wọn sókè pé: “Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà . . . Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó gbé sọ sínú òkun. Okun mi àti agbára ńlá mi ni Jáà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ìgbàlà mi.”—Ẹ́kís. 13:14, 21, 22; 15:1, 2; Sm. 136:11-15.

16 Tó o bá ní àwọn ọmọ, ǹjẹ́ ò ń mú kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùdáǹdè? Ǹjẹ́ wọ́n lè rí i nínú ọ̀rọ̀ rẹ àtàwọn ìpinnu tó ò ń ṣe pé òótọ́ lo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùdáǹdè? Ó dájú pé o lè fi ohun tá a kà nínú Ẹ́kísódù orí 12 sí 15 kún ohun tẹ́ ẹ máa jíròrò nínú Ìjọsìn Ìdílé yín kó o sì tẹ́nu mọ́ bí Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Ní àwọn ìgbà míì, o lè lo ìwé Ìṣe 7:30-36 tàbí Dáníẹ́lì 3:16-18, 26-28 láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ Olùdáǹdè. Ká sòótọ́, ó gbọ́dọ̀ dá gbogbo wa lọ́mọdé àti lágbà lójú pé kì í ṣe ìgbà àtijọ́ nìkan ni Jèhófà jẹ́ Olùdáǹdè. Bó ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè nígbà ayé Mósè, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa dá àwa náà nídè lọ́jọ́ iwájú.—Ka 1 Tẹsalóníkà 1:9, 10.

OHUN TÓ YẸ KA MÁA RÁNTÍ

17, 18. Tá a bá ń ronú lórí ọ̀nà tí wọ́n gbà lo ẹ̀jẹ̀ nígbà Ìrékọjá àkọ́kọ́, kí ló yẹ kíyẹn máa rán wa létí?

17 Ó wà lára Òfin Mósè pé kí àwọn Júù máa ṣe ìrántí Ìrékọjá lọ́dọọdún. Ṣùgbọ́n àwa Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé a kò sí lábẹ́ Òfin Mósè. (Róòmù 10:4; Kól. 2:13-16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn wà tá a fọwọ́ pàtàkì mú, ìyẹn ni ikú Ọmọ Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn apá kan wà nínú ayẹyẹ Ìrékọjá tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì tó ní ìtumọ̀ pàtàkì fún wa.

18 Ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n fi wọ́n ara òpó ilẹ̀kùn méjèèjì àti àtẹ́rígbà ni Ọlọ́run fi dá ẹ̀mí àwọn àkọ́bí sí. Lóde òní, a kì í fi ẹran rúbọ sí Ọlọ́run, yálà ní ọjọ́ Ìrékọjá tàbí ní ìgbà èyíkéyìí mìíràn. Àmọ́ ẹbọ kan wà tó sàn jù, èyí tó lè gbà wá là títí láé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ìjọ àwọn àkọ́bí tí a ti kọrúkọ wọn sílẹ̀ ní ọ̀run.” “Ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n,” ìyẹn ẹ̀jẹ̀ Jésù, ni Ọlọ́run fi pa ìwàláàyè àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró yẹn mọ́. (Héb. 12:23, 24) Àwọn Kristẹni tí wọ́n nírètí láti máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé náà ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀jẹ̀ yẹn ni Ọlọ́run á fi dá ẹ̀mí àwọn sí. Ìgbà gbogbo ló yẹ kí wọ́n máa rán ara wọn létí bí Ọlọ́run ṣe mú kí èyí dá wọn lójú. Ó sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.”—Éfé. 1:7.

19. Báwo ni ọ̀nà tí wọ́n gbà bójú tó ẹran Ìrékọjá ṣe lè mú káwọn àsọtẹ́lẹ̀ túbọ̀ dá wa lójú?

19 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n lò fún oúnjẹ Ìrékọjá, Ọlọrun sọ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ fọ́ èyíkéyìí lára egungun rẹ̀. (Ẹ́kís. 12:46; Núm. 9:11, 12) “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run” tó wá láti fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà ńkọ́? (Jòh. 1:29) Àwọn ọ̀daràn méjì ni wọ́n kàn mọ́gi pẹ̀lú Jésù, ọ̀kan ní apá ọ̀tún rẹ̀ àti èkejì ní apá òsì rẹ̀. Àwọn Júù sọ fún Pílátù pé kó jẹ́ kí àwọn ṣẹ́ egungun àwọn ọkùnrin tí wọ́n kàn mọ́gi náà. Èyí á jẹ́ kí wọ́n tètè kú, kí wọ́n má bàa wà lórí igi títí di Nísàn 15, tó jẹ́ Sábáàtì ọjọ́ ńlá. Àwọn ọmọ ogun ṣẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ọ̀daràn méjì tí wọ́n kàn mọ́gi pẹ̀lú rẹ̀, “ṣùgbọ́n ní dídé ọ̀dọ̀ Jésù, bí wọ́n ti rí i pé ó ti kú nísinsìnyí, wọn kò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” (Jòh. 19:31-34) Ìyẹn bá ohun tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá mú, torí náà ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn jẹ́ “òjìji” ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Héb. 10:1) Bákan náà, ọ̀nà tí àwọn nǹkan yìí gbà wáyé ló jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:20 ní ìmúṣẹ, ó sì yẹ kí ìyẹn mú kí àsọtẹ́lẹ̀ túbọ̀ dá wa lójú.

20. Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ wo ló wà láàárín Ìrékọjá àti Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

20 Àmọ́ ṣá o, àwọn ìyàtọ̀ kan wà láàárín Ìrékọjá àti Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Àwọn ìyàtọ̀ náà fi hàn pé Ìrékọjá tí àwọn Júù ní láti máa ṣe ìrántí rẹ̀ kò ṣàpẹẹrẹ ohun tí Kristi sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe ní ìrántí ikú òun. Ní Íjíbítì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ nínú ẹran ọ̀dọ́ àgùntàn náà, àmọ́ wọn kò mu nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn yàtọ̀ sí ohun tí Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe. Ó sọ pé kí àwọn tí wọ́n máa bá òun ṣàkóso “nínú ìjọba Ọlọ́run” jẹ lára búrẹ́dì, kí wọ́n sì mu lára wáìnì tó ṣàpẹẹrẹ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ òun. A óò gbé èyí yẹ̀ wò lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.—Máàkù 14:22-25.

21. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé ká mọ̀ nípa Ìrékọjá?

21 Síbẹ̀, kò sí iyè méjì pé Ìrékọjá jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan nínú bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò, ó sì kọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lẹ́kọ̀ọ́ gan-an. Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ni Ìrékọjá jẹ́ ohun “ìrántí” fún, àwa Kristẹni náà gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ torí pé ó jẹ́ apá kan ‘gbogbo Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí, ká sì fi díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere tó kọ́ wa sọ́kàn.’—2 Tím. 3:16.

^ ìpínrọ̀ 5 Ábíbù ni àwọn Hébérù máa ń pe oṣù àkọ́kọ́ nínú kàlẹ́ńdà wọn. Àmọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Nísàn lẹ́yìn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé láti Bábílónì. Nísàn yẹn la máa lò nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 6 Bíbélì The Bible in Living English.

^ ìpínrọ̀ 11 Nígbà tí oòrùn wọ̀, Nísàn 15 bẹ̀rẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí pé lọ́dún yẹn, Sábáàtì (Sátidé) ti ọ̀sẹ̀ yẹn bọ́ sí ọjọ́ kan náà pẹ̀lú ọjọ́ àkọ́kọ́ Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú tó sábà máa ń jẹ́ sábáàtì. Torí pé Sábáàtì méjèèjì bọ́ sí ọjọ́ kan náà, Sábáàtì yẹn jẹ́ “ọjọ́ ńlá.”—Ka Jòhánù 19:31, 42.