Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Wàá Yááfì Àwọn Nǹkan Torí Ìjọba Ọlọ́run?

Ṣé Wàá Yááfì Àwọn Nǹkan Torí Ìjọba Ọlọ́run?

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 KỌ́R. 9:7.

1. Onírúurú nǹkan wo ni àwọn èèyàn máa ń yááfì, kí sì nìdí?

ÀWỌN èèyàn máa ń fínnúfíndọ̀ yááfì àwọn nǹkan torí àwọn ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì. Àwọn òbí máa ń lo àkókò, owó àti okun wọn fún àǹfààní àwọn ọmọ wọn. Àwọn ọ̀dọ́ eléré ìdárayá tó ń lépa àtiṣojú orílẹ̀-èdè wọn níbi ìdíje Òlíńpíìkì máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lójoojúmọ́ láti ṣe ìdánrawò kíkankíkan kí wọ́n sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, nígbà táwọn ojúgbà wọn ń ṣeré tí wọ́n sì ń gbádùn ara wọn. Jésù pẹ̀lú yááfì àwọn nǹkan kan torí àwọn ohun tó kà sí pàtàkì. Kò lépa fàájì, bẹ́ẹ̀ ni kò sì bímọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ ẹ́ lógún ni bó ṣe máa mú kí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú. (Mát. 4:17; Lúùkù 9:58) Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè máa ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì jù lọ ni bí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run á ṣe máa tẹ̀ síwájú, wọ́n sì yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè sa gbogbo ipá wọn láti ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. (Mát. 4:18-22; 19:27) Torí náà, a lè bi ara wa pé, ‘Kí lohun tí mo kà sí pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi?’

2. (a) Kí ló ṣe pàtàkì jù lọ pé kí gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ yááfì? (b) Kí lohun míì tó tún ṣeé ṣe fún àwọn kan láti yááfì?

2 Ó pọn dandan pé kí gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ yááfì àwọn nǹkan kan. Wọ́n sì ṣe pàtàkì ká bàa lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, kí àjọṣe náà má sì bà jẹ́. Lára àwọn nǹkan tá a lè yááfì ni àkókò àti okun wa. A lè lo àkókò àti okun wa láti gbàdúrà, ká ka Bíbélì, ká ṣe ìjọsìn ìdílé, ká sì lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí. * (Jóṣ. 1:8; Mát. 28:19, 20; Héb. 10:24, 25) Nítorí bí a ṣe ń sapá àti bí Jèhófà ṣe ń bù kún wa, iṣẹ́ ìwàásù náà ń tẹ̀ síwájú lọ́nà tó yára kánkán, ọ̀pọ̀ èèyàn sì túbọ̀ ń rọ́ wọ “òkè ńlá ilé Jèhófà.” (Aísá. 2:2) Káwọn kan bàa lè máa kọ́wọ́ ti àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè sìn ní Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n lè máa ran àwọn tó ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ lọ́wọ́, kí wọ́n lè ṣètò àwọn àpéjọ, tàbí kí wọ́n kópa nínú ètò ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá. Ọlọ́run ò béèrè pé ká ṣe àwọn àfikún iṣẹ́ yìí ká tó lè jogún ìyè, àmọ́ wọ́n jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì tá a fi ń mú kí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú.

3. (a) Tá a bá yááfì àwọn nǹkan kan torí Ìjọba Ọlọ́run, àǹfààní wo la máa rí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?

3 Àkókò yìí ló ṣe pàtàkì gan-an pé ká kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run ju ti ìgbàkigbà rí lọ. A láyọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fínnúfíndọ̀ yááfì àwọn nǹkan nítorí Jèhófà! (Ka Sáàmù 54:6.) Irú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń mú ká láyọ̀ gan-an bá a ṣe ń dúró de Ìjọba Ọlọ́run. (Diu. 16:15; Ìṣe 20:35) Àmọ́, ó yẹ kí gbogbo wa yẹ ara wa wò dáadáa. Ṣé àwọn ọ̀nà míì wà tá a fi lè túbọ̀ yááfì àwọn nǹkan nítorí Ìjọba Ọlọ́run? Báwo la ṣe ń lo àkókò, owó, okun àtàwọn ẹ̀bùn àbínibí wa? Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò táá mú ká lè fínnúfíndọ̀ yááfì irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i.

ẸBỌ TÁWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ ÌGBÀANÌ RÚ

4. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jàǹfààní látinú ẹbọ rírú?

4 Ẹbọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ń rú ni Ọlọ́run máa ń wò tó fi ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. Ó pọn dandan kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rúbọ kí wọ́n bàa lè rí ojú rere Jèhófà. Àwọn ẹbọ kan wà tí Ọlọ́run pàṣẹ pé kí wọ́n rú nígbà tí àwọn míì jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe. (Léf. 23:37, 38) Wọ́n lè rú odidi ọrẹ ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tàbí kí wọ́n mú un wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Jèhófà. A rí àpẹẹrẹ kan tó ta yọ nípa àwọn ọrẹ ẹbọ nígbà tí wọ́n ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́ nígbà ayé Sólómọ́nì.—2 Kíró. 7:4-6.

5. Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó gba tàwọn aláìní rò?

5 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn èèyàn rẹ̀ mú kó mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè rí ohun kan náà fi rúbọ, torí náà ó sọ pé ohun tí agbára ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ká ni kó fi rúbọ. Òfin Jèhófà sọ pé kí wọ́n da ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n bá fi rúbọ sórí ilẹ̀, èyí tó máa jẹ́ “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀” nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù. (Héb. 10:1-4) Àmọ́ o, Jèhófà ò fi òfin yẹn ni àwọn èèyàn lára. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà á bí ẹnì kan bá mú oriri wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ torí pé kò lágbára láti mú ọrẹ ẹbọ wá látinú agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran. Látàrí èyí, àwọn aláìní pàápàá lè rúbọ sí Jèhófà tayọ̀tayọ̀. (Léf. 1:3, 10, 14; 5:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn fi rúbọ lè yàtọ̀ síra, ohun méjì kan wà tí Ọlọ́run retí látọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá mú ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe wá.

6. Kí ni Ọlọ́run retí pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá ń rúbọ ṣe? Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run béèrè yẹn?

6 Àkọ́kọ́, ohun tó dára jù lọ ni onítọ̀hún gbọ́dọ̀ fi rúbọ. Jèhófà sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé ọrẹ ẹbọ èyíkéyìí tí wọ́n bá máa mú wá gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá kó bàa lè “rí ìtẹ́wọ́gbà.” (Léf. 22:18-20) Bí àbùkù bá wà lára ẹran náà, Jèhófà ò ní wò ó gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà. Èkejì, ẹni tó bá mú ẹbọ wá fún Jèhófà gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́ àti láìní ẹ̀gbin. Bí ẹnì kan bá jẹ́ aláìmọ́, ó gbọ́dọ̀ mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi wá kó lè pa dà ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, ìgbà yẹn ló tó lè mú ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe wá fún Jèhófà. (Léf. 5:5, 6, 15) Ọ̀rọ̀ ńlá mà lèyí o! Jèhófà sọ pé bí ẹnì tó jẹ́ aláìmọ́ bá jẹ nínú ẹbọ ìdàpọ̀, tó ní nínú ọ̀rẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe, kí wọ́n ké e kúrò láàárín àwọn èèyàn òun. (Léf. 7:20, 21) Àmọ́, bí ẹni tó mú ẹbọ wá bá ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, tí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ kò sì ní àbùkù kankan, ó lè máa yọ̀ torí ọkàn rẹ̀ á bálẹ̀ pé ohun ti ṣe ohun tó tọ́.—Ka 1 Kíróníkà 29:9.

ÀWỌN ẸBỌ TÁ À Ń RÚ LÓNÌÍ

7, 8. (a) Báwo làwọn kan ṣe ń láyọ̀ torí pé wọ́n ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan torí Ìjọba Ọlọ́run? (b) Àwọn nǹkan wo ló wà ní ìkáwọ́ wa?

7 Bákan náà, lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ń fẹ́ láti máa lo ara wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ìyẹn sì dùn mọ́ Jèhófà. Èrè wà nínú pé ká máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ará wa. Arákùnrin kan tó máa ń bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sì tún wà lára àwọn tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìjábá ṣẹlẹ̀ sí sọ pé ìtẹ́lọ́rùn tí òun ń rí níbẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Ó sọ pé, “Nígbà tí àwọn ará bá dúró sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tuntun tàbí tí àwọn tí ìjábá ṣẹlẹ̀ sí bá rí ìrànwọ́ gbà, tí mo sì rí bí inú gbogbo wọn ṣe ń dùn tí wọ́n sì ń fi ìmọrírì hàn, ńṣe ló máa ń jẹ́ kí n rí i pé bí mo ṣe yọ̀ǹda ara mi tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe, bíi ti àwọn ẹbọ tá à ń rú lónìí (Wo ìpínrọ̀ 7 sí 13)

8 Ìgbà gbogbo ni ètò Jèhófà lóde òní máa ń wá bó ṣe máa ti iṣẹ́ Jèhófà lẹ́yìn. Ní ọdún 1904, Arákùnrin C. T. Russell sọ pé: “Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan kà á sí pé ńṣe ni Olúwa yan òun láti máa ṣe àbójútó àkókò, ipò, owó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí òun ní. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti lo àwọn tálẹ́ńtì yìí lọ́nà tó máa fi ògo fún Ọ̀gá náà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń ná wa ni ọ̀pọ̀ nǹkan ká tó lè yááfì àwọn nǹkan kan fún Jèhófà, ọ̀pọ̀ ìbùkún là ń rí gbà. (2 Sám. 24:21-24) Ṣé a lè túbọ̀ lo àwọn nǹkan tó wà ní ìkáwọ́ wa lọ́nà tó dára?

Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ Ọsirélíà

9. Tá a bá fẹ́ lo àkókò wa, ìlànà wo ló wà nínú àwọn ìtọ́ni Jésù nínú Lúùkù 10:2-4 tó yẹ ká fi sílò?

9 Àkókò wa. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá ká tó túmọ̀ àwọn ìwé wa sáwọn èdè míì ká sì tẹ̀ wọ́n, ká tó kọ́ àwọn ibi ìjọsìn, ká tó ṣètò àwọn àpéjọ, ká tó pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù, ká sì tó lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò míì tó pọn dandan. Síbẹ̀, a ò ní ju wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] lọ lóòjọ́. Jésù fún wa ní ìlànà kan tó lè ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí Jésù ń rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ wàásù, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n ‘má ṣe gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra nínú ìkíni ní ojú ọ̀nà.’ (Lúùkù 10:2-4) Kí nìdí tí Jésù fi fún wọn ní irú ìtọ́ni yẹn? Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé: “Ìkíni àwọn ará Ìlà Oòrùn kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé kéèyàn tẹrí ba díẹ̀ tàbí kó bọ ẹlòmíì lọ́wọ́ bíi tiwa. Ìdí ni pé bí àwọn ará Ìlà Oòrùn bá ń kíra, ńṣe ni wọ́n máa ń gbára wọn mọ́ra lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń tẹrí ba mọ́lẹ̀, wọ́n sì máa ń dọ̀bálẹ̀ gbalaja. Gbogbo èyí sì ń gba ọ̀pọ̀ àkókò.” Jésù ò sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa fojú pa àwọn èèyàn rẹ́ o! Ohun tó fi ń yé wọn ni pé àkókò tí wọ́n ní kò tó nǹkan, wọ́n sì gbọ́dọ̀ lo èyí tó pọ̀ jù lọ lára rẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. (Éfé. 5:16) Ǹjẹ́ àwa náà lè fi ìlànà yìí sílò ká bàa lè ní àkókò tó pọ̀ sí i láti fi kọ́wọ́ ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?

Àwọn akéde rèé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, nílẹ̀ Áfíríkà

10, 11. (a) Sọ díẹ̀ lára bá a ṣe ń lo àwọn ọrẹ tó wà fún iṣẹ́ kárí ayé. (b) Ìlànà wo ló wà nínú 1 Kọ́ríńtì 16:1, 2 tó lè ràn wá lọ́wọ́?

10 Owó wa. A nílò owó tó pọ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run. Owó tàbùàtabua là ń ná lọ́dọọdún láti bójú tó àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn míṣọ́nnárì. Látọdún 1999, a ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún àti ààbọ̀ [24,500] ní àwọn ilẹ̀ táwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Síbẹ̀, ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti irínwó [6,400] Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ṣì nílò. Lóṣooṣù, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! là ń tẹ̀ jáde. Ọrẹ àtinúwá yín la fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ náà.

11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìlànà kan tá a lè máa tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ fi owó ṣètọrẹ. (Ka 1 Kọ́ríńtì 16:1, 2.) Ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ̀ láti gba àwọn ará tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì níyànjú pé kí wọ́n má ṣe dúró di ìparí ọ̀sẹ̀ kí wọ́n tó wo iye tó ṣẹ́ kù sọ́wọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí wọ́n ya owó tí agbára wọn bá gbé sọ́tọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀. Bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lóde òní náà máa ń ṣètò sílẹ̀ káwọn náà lè fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn débi tí agbára wọ́n bá mọ. (Lúùkù 21:1-4; Ìṣe 4:32-35) Jèhófà máa ń mọrírì irú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀.

Ẹnì kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti sìn pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní Tuxedo, New York, nílẹ̀ Amẹ́ríkà

12, 13. Kí ló lè mú kí àwọn kan máa fà sẹ́yìn láti lo okun àti ẹ̀bùn àbínibí wọn, àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́?

12 Okun wa àti ẹ̀bùn àbínibí wa. Jèhófà máa ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń lo ẹ̀bùn àbínibí wa àti okun wa nítorí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba rẹ̀. Ó ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí àárẹ̀ bá mú wa. (Aísá. 40:29-31) Ṣé à ń ronú pé a kò ní òye tó pọ̀ tó tá a fi lè kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà? Ṣé à ń ronú pé àwọn míì wà tí wọ́n tóótun jù wá lọ láti ṣe iṣẹ́ náà? Rántí o, Jèhófà lè mú kí ẹ̀bùn àbínibí tí ẹnikẹ́ni ní sunwọ̀n sí i, bó ti ṣe fún Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù.—Ẹ́kís. 31:1-6; wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.

13 Jèhófà gbà wá níyànjú pé gbogbo ohun tí agbára wa bá gbé ni ká ṣe fún òun, a kò sì gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn. (Òwe 3:27) Nígbà táwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù ń tún tẹ́ńpìlì kọ́, Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ọwọ́ tí wọ́n fi mú iṣẹ́ ìkọ́lé náà. (Hág. 1:2-5) Ọkàn wọn ti pínyà wọn ò sì gbájú mọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́. Torí náà, ó máa dára kí àwa náà rò ó wò bóyá àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu la fi sípò àkọ́kọ́. Ǹjẹ́ àwa náà lè ‘fi ọkàn wa sí àwọn ọ̀nà wa,’ ká bàa lè túbọ̀ máa kó ipa ribiribi nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

BÁ A ṢE LÈ MÁA FI OHUN TÁ A NÍ RÚBỌ

14, 15. (a) Báwo ni àpẹẹrẹ àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ aláìní ṣe ń fún wa ní ìṣírí? (b) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

14 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbé láwọn ibi tí ìnira àti ipò òṣì ti wọ́pọ̀. Ètò Ọlọ́run máa ń sapá láti “dí” àìnító àwọn ará wa tó ń gbé ní irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀. (2 Kọ́r. 8:14) Síbẹ̀, àwọn ará wa tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti fi ọrẹ ṣètìlẹyìn. Inú Jèhófà máa ń dùn nígbà tí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ bá fi owó ti iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn tọ̀yàyàtọ̀yàyà.—2 Kọ́r. 9:7.

15 Ní orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti tòṣì gan-an ní ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn ará kan ya ilẹ̀ kékeré kan sọ́tọ̀ nínú ọgbà wọn láti máa fi gbin irè oko. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ta irè oko náà, wọ́n á wá fi owó yẹn ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn. Ní orílẹ̀-èdè yẹn kan náà, ètò Ọlọ́run ṣètò láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí àwọn ará nílò gan-an. Àwọn ará tó wà ládùúgbò náà fẹ́ láti ṣèrànwọ́. Àmọ́, ìgbà tí wọ́n ń gbin irè oko wọn ni iṣẹ́ náà máa bọ́ sí. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n ti pinnu pé àwọn máa kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, wọ́n máa ń wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní ojú mọmọ, wọ́n á sì lọ sí oko tó bá di ìrọ̀lẹ́ kí wọ́n lè rí i dájú pé wọ́n gbin irè oko wọn. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ mà nìyẹn o! Èyí rán wa létí àwọn ará tó wà ní Makedóníà ní ọ̀rúndún kìíní. Wọ́n wà nínú “ipò òṣì paraku,” síbẹ̀ wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn lè ní àǹfààní láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ tó wà nílẹ̀. (2 Kọ́r. 8:1-4) Bíi tiwọn, ǹjẹ́ kí àwa náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ṣètìlẹyìn ní ìbámu pẹ̀lú ‘ìwọ̀n ìbùkún tí Jèhófà Ọlọ́run tí fi fún wa.’—Ka Diutarónómì 16:17.

16. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé àwọn ẹbọ wa ṣètẹ́wọ́gbà fún Jèhófà?

16 Àmọ́ ṣá, ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra kan rèé o! Bó ṣe rí nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe wa ṣètẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run. Ó lè má ṣètẹ́wọ́gbà tá a bá jẹ́ kí ọ̀kan pa èkejì lára nínú bá a ṣe ń bójú tó àwọn ojúṣe tó ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn Jèhófà àti nínú ìdílé. Bá a ṣe ń yọ̀ǹda àkókò wa tá a sì ń lo àwọn ohun ìní wa láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kò gbọ́dọ̀ dí wa lọ́wọ́ débi tá ò fi ní ráyè bójú tó ìdílé wa nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tá à ń fún Jèhófà ni ohun tí a kò ní. (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:12.) Ní àfikún sí ìyẹn, a gbọ́dọ̀ rí i pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà kò yingin ká má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣá. (1 Kọ́r. 9:26, 27) Àmọ́, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá ń jẹ́ kí àwọn ìlànà Bíbélì máa darí ìgbésí ayé wa, àwọn ẹbọ wa máa mú ká láyọ̀ ká sì ní ìtẹ́lọ́rùn, wọ́n á sì “ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì” fún Jèhófà.

ÀWỌN ẸBỌ WA ṢEYEBÍYE

17, 18. Kí lèrò wa nípa gbogbo àwọn tó ń yááfì àwọn nǹkan kan nítorí Ìjọba Ọlọ́run, kí ló sì yẹ kí gbogbo wa ronú lé lórí?

17 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń ‘tú ara wọn jáde bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu’ nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe láti kọ́wọ́ ti àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run. (Fílí. 2:17) A dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ ẹ̀yin tẹ́ ẹ yọ̀ǹda ara yín tinútinú bẹ́ẹ̀. A sì tún gbóríyìn fún ẹ̀yin aya àtẹ̀yin ọmọ àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú nínú ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àti ìfara-ẹni-rúbọ yín.

18 Ó gba pé ká ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára ká bàa lè máa ṣẹ̀tìlẹ́yìn fún àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa ronú tàdúràtàdúrà lórí bá a ṣe lè sa gbogbo ipá wa láti ṣe púpọ̀ sí i. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé èrè ńlá lo máa rí níbẹ̀ báyìí, wàá sì tún rí èrè tó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ “nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.”—Máàkù 10:28-30.

^ ìpínrọ̀ 2 Wo àpilẹ̀kọ náà, “Bá A Ṣe Lè Máa Rúbọ sí Jèhófà Tọkàntọkàn,” nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 2012, ojú ìwé 21 sí 25.